‘Ì Bá Ṣe Pé Gbogbo Ènìyàn Dà Bí Wọn Ni!’
Ìwọ̀nyí ni àwọn ọ̀rọ̀ akọ̀ròyìn kan nínú ìwé àtìgbàdégbà ti Luxembourg Letzebuerger Journal. Àwọn wo ni ó ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ?
Ó lọ sí Poland láti pésẹ̀ síbi ayẹyẹ àjọ̀dún àádọ́ta ọdún ti ìdáǹdè Auschwitz ó sì ṣàkíyèsí pé ẹgbẹ́ àwùjọ kan tí ó jìyà gan-an níbẹ̀ ni a kò mẹ́nu kàn rárá. Nínú ìròyìn rẹ̀ ti February 2, 1995, ó fi hàn pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni ẹgbẹ́ àwùjọ náà, ó sì kọ̀wé pé: “Kì í ṣe ìhánimọ́lé tàbí ibùdó ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ tí ó rorò jù lọ, tàbí fífi ìpanirẹ́ lọ́nà tí ó bani nínú jẹ́ nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n tí a ti ń febi pani halẹ̀ mọ́ni, tàbí fífi àáké tàbí ayùn pani ni ó lè mú wọn kọ ìgbàgbọ́ wọn sílẹ̀.” Ó ń bá a lọ pé: “Ìgboyà tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa fi ń dojú kọ ikú tilẹ̀ ya àwọn ẹ̀ṣọ́ SS tí wọ́n jẹ́ òkú-òǹrorò lẹ́nu.”
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa kò wá ikú. Ṣùgbọ́n, bíi ti àwọn Kristian ní ọ̀rúndún kìíní, ẹgbẹẹgbẹ̀rún wọn yàn láti kú ju kí wọ́n fi àwọn ìlànà Kristian báni dọ́rẹ̀ẹ́ lọ. Irú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀ fi wọ́n hàn yàtọ̀ gédégbé ní àwọn ọjọ́ ṣíṣú dùdù ti Ìṣàkóso Nazi.
Akọ̀ròyìn náà parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Ì bá ṣe pé gbogbo àwọn ènìyàn dà bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni!” Bí wọ́n bá rí bẹ́ẹ̀ ni, ogun àgbáyé kejì kì bá tí wáyé.