Nígbà Tí ‘Ẹ̀fúùfù Lè Gbéni Lọ Sí Ibikíbi’
“NÍGBÀ tí ẹnì kan kò bá mọ èbúté tí òun ń rè, ibikíbi ni ẹ̀fúùfù lè gbé e lọ.” Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, tí a mọ̀ sí ti ọlọ́gbọ́n èrò orí ọ̀rúndún kìíní ti Romu, Lucius Annaeus Seneca, jẹ́rìí sí òtítọ́ tí a ti mọ̀ tipẹ́tipẹ́ náà pé: Kí ìgbèsí ayé tó lè ní ìdarísọ́nà, góńgó ṣe pàtàkì.
Bí ó ti wù kí ó rí, ní ọ̀pọ̀ ìgbà, ìgbésí ayé máa ń fì síhìn-ín sọ́hùn-ún láìní ìfojúsùn kankan. Kìkì yíyẹra fún gegele àti àjàyíká ìjì tí ó wà nínú ìgbésí ayé ojoojúmọ́ ti tẹ́ ọ̀pọ̀ lọ́rùn. Láìsí ohun gúnmọ́ kan pàtó lọ́kàn, wọ́n dà bí ìgbì òkun tí “ẹ̀fúùfù ń gbé síwá ní àkókò kan tí ó tún ń gbé sẹ́yìn ní àkókò mìíràn.” (Jakọbu 1:6, “Phillips”) Fún irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀, ‘ẹ̀fúùfù lè gbéni lọ sí ibikíbi.’
Bibeli pèsè àpẹẹrẹ àwọn tí wọ́n ní góńgó, tí wọ́n sì tipa báyìí ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ẹni àwòfiṣàpẹẹrẹ fún àwọn Kristian lónìí. Mose “fi tọkàntara wo sísan èrè-ẹ̀san naa.” (Heberu 11:26) Paulu kọ̀wé pé: “Mo ń sáré tààràtà sí góńgó náà kí n baà lè jèrè ẹ̀bùn náà.” Ó gba àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ níyànjú láti “ní irú ìṣarasíhùwà kan náà.”—Filippi 3:14, 15, “Today’s English Version.”
Pẹ̀lú ojú wa tí a fi tọkàntara tẹ̀ mọ́ àwọn ìlérí Bibeli, ǹjẹ́ kí a máa fara wé ìgbàgbọ́ irú àwọn ọkùnrin tí wọ́n ní góńgó bẹ́ẹ̀.—Fi wé Heberu 13:7.