ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w95 10/1 ojú ìwé 29-31
  • Singapore Tẹ Òmìnira Ìjọsìn Mọ́lẹ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Singapore Tẹ Òmìnira Ìjọsìn Mọ́lẹ̀
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Ìsọ̀rí
  • Wọn Kì í Ṣe Ewú fún Ìdáwà àti Ìṣọ̀kan Orílẹ̀-Èdè
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
w95 10/1 ojú ìwé 29-31

Singapore Tẹ Òmìnira Ìjọsìn Mọ́lẹ̀

NÍ ÌRỌ̀LẸ́ February 24, 1995, àwọn ọlọ́pàá gbé sùnmọ̀mí wọ inú ilé mẹ́rin ní ìlú ńlá Singapore. Lápapọ̀, ènìyàn 69 ni a fàṣẹ ọba mú.a Obìnrin kan, ẹni ọdún 71, àti àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin ọlọ́dún 15 méjì wà lára wọn. Èé ṣe? Ó ha jẹ́ nítorí ìwà ọ̀daràn tàbí ìgbòkègbodò láti dojú ìjọba bolẹ̀ bí? Bẹ́ẹ̀ kọ́. Kò sí ọ̀kan lára wọn tí ó lọ́wọ́ nínú ohunkóhun tí a tilẹ̀ lè kà sí eléwu, ìwà pálapàla, tàbí tí ó lòdì sí ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà, bí ó ṣe wù kí ó mọ. Wọn kò wu àwọn ìlànà ọ̀nà ìwà híhù, ààbò, àti ire àwọn ará Singapore ẹlẹgbẹ́ wọn léwu. Síbẹ̀, lẹ́yìn gbígbọn ilé mẹ́rẹ̀ẹ̀rin náà yẹ́bẹ́yẹ́bẹ́, àwọn ọlọ́pàá mú àwọn ènìyàn 69 náà, tí wọ́n ti péjọ pọ̀ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli, kí wọ́n sì gbádùn àpéjọpọ̀ ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà, lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá. Níbẹ̀ ni a fi wọ́n sí di ilẹ̀ mọ́, a fi ìbéèrè wádìí ọ̀rọ̀ lẹ́nu wọn, a gba ìtẹ̀ka wọn, a sì yà wọ́n ní fọ́tò—àní, a pá wọn láyà gẹ́gẹ́ bí àwọn ọ̀daràn lásán! Ní àkókò yìí—tí ó gùn tó wákàtí 18 nínú ipò tí kò bára dé—a kò gbà wọ́n láyè láti rí agbẹjọ́rò, bẹ́ẹ̀ sì ni a kò yọ̀ọ̀da fún wọn láti tẹ àwọn mẹ́ḿbà ìdílé wọn láago láti sọ ibi tí wọ́n wà fún wọn. Ẹnì kan lè finú mòye irú ipa tí ìgbésẹ̀ páápààpá bẹ́ẹ̀ ti lè ní lórí àwọn aráàlú tí wọ́n jẹ́ alálàáfíà, tí wọ́n sì jẹ́ apòfinmọ́ wọ̀nyí!

Ìran náà ránni létí bí nǹkan ti rí ní àwọn ọjọ́ amúnisoríkọ́ ti Nazi ní Germany àti ti sànmánì oníwà òǹrorò ti Kọmunisti ní Soviet Union àti Ìlà Oòrùn Europe. Kì í ṣe ohun tí olùṣèbẹ̀wò ṣákálá kan sí Singapore yóò retí láti rí ní ìlú ńlá àti ìpínlẹ̀ òde òní, tí ó mọ́ tónítóní, tí ó sì lọ́rọ̀. Singapore ti ṣe orúkọ rere fún ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí onítẹ̀síwájú lọ́nà àràmàǹdà ní ti ọrọ̀ ajé àti ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà ní ọ̀rúndún ogún yìí. Ó jẹ́ ìjọba dẹmọ tí a polongo pé ó ní òfin tí ó fi àwọn ìpìlẹ̀ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn dá àwọn aráàlú rẹ̀ lójú, títí kan òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ, ìsìn, àti ìpéjọ.

Síbẹ̀, àwọn tí a fàṣẹ ọba mú ní February, ni a dajú sọ kìkì nítorí pé wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jehofa tí ń pàdé pọ̀ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli, kí wọ́n sì ṣàjọpín ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ Kristian. Ẹ̀sùn tí a fi kàn wọ́n ni “lílọ sí ìpàdé àwùjọ tí kò bófin mu.”

Ní tòótọ́, a ti fi ìdámọ̀ lábẹ́ òfin du àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní Singapore láti 1972, nígbà tí a yọ orúkọ Ìjọ Singapore kúrò nínú ìwé ìforúkọsílẹ̀, tí a sì fòfin de àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́, títí kan Bibeli, tí a tẹ̀ jáde láti ọwọ́ Watch Tower Bible and Tract Society. Kò sí àǹfààní kankan láti pe àwọn ìméfò tí a torí rẹ̀ gbé ìgbésẹ̀ yìí níjà. Láìpẹ́ yìí, a pé ìbófinmu kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà ọlọ́lá-àṣẹ yìí níjà ní àwọn ilé ẹjọ́ Singapore nínú ẹjọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí mẹ́rin tí a ti dá lẹ́bi ní February 1994 pé, a ká àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli tí a ti gbẹ́sẹ̀ lé mọ́ wọn lọ́wọ́. A gbọ́ ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tí a pè ní ìlòdì sí ìdálẹ́bi wọn ní August 1994, a sì tú u ká lójú ẹsẹ̀. Àdájọ́ Àgbà Yong Pung How ti Ilé Ẹjọ́ Gíga gbé èrò rẹ̀ jáde ní oṣù tí ó tẹ̀ lé e. Ìdájọ́ rẹ̀ ni pé, a kò tẹ òmìnira ìsìn kankan lójú àti pé ìdálẹ́bi náà tọ́ lórí ìpìlẹ̀ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa jẹ́ ewu fún ààbò orílẹ̀-èdè nítorí pé wọn kì í lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ológun. Ní February 17, 1995, àwọn Ẹlẹ́rìí mẹ́rin náà béèrè fún ìyọ̀ọ̀da láti pẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn lórí ìpinnu tí kò bára dé yìí sí Ilé Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn ti Singapore. A kò fọwọ́ sí ìwé ìpẹ̀jọ́ náà.

Ìpinnu ìkẹyìn yìí ni àwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn tí ìjọba ń ṣàkóso ní Singapore gbé lékè. Kò sí iyè méjì pé ìpinnu ilé ẹjọ́ yìí àti ohun tí ìpolongo náà yọrí sí ń tọ́ka sí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó tẹ̀ lé e. Láàárín ọ̀sẹ̀ kan ìfàṣẹ ọba mú àwọn Ẹlẹ́rìí 69 náà wáyé. Ẹ̀sùn tí a fi kan mẹ́rin lára àwọn wọ̀nyí—tí wọ́n jẹ́ ọmọ Britain, France, àti Luxembourg—ni a fagi lé lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn. Bí ó ti wù kí ó rí, ìrírí bíbanilẹ́rù ni èyí jẹ́ fún wọn. Ọkùnrin kan ti gbé ní Singapore fún ọ̀pọ̀ ọdún, ó sì ti ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀ pẹ̀lú aya rẹ̀. Wọ́n pàdánù iṣẹ́ wọn àti ilé tí wọ́n háyà, a sì fipá mú wọn láti sọ pé, ó dìgbòó ṣe, sí ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ kòrí-kòsùn.

Àwọn àgbàlagbà 63 tí wọ́n ṣẹ́kù ni a fẹ̀sùn kàn pé wọ́n jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ àwùjọ kan tí a ti fòfin dè, a sì tún fi ẹ̀sùn níní àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a ti kà léèwọ̀ kan àwọn kan. Wọ́n dojú kọ ẹwọn ọdún mẹ́ta ó pẹ́ tán ní ọgbà ẹ̀wọ̀n tàbí $3,000 owó Singapore ($2,100, owó U.S.) gẹ́gẹ́ bí owó ìtanràn tàbí méjèèjì. Àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin ọlọ́dún 15 méjèèjì fara hàn lọ́tọ̀ọ̀tọ̀ ní ilé ẹjọ́ àwọn ọ̀jẹ̀wẹ́wẹ́.

Wọn Kì í Ṣe Ewú fún Ìdáwà àti Ìṣọ̀kan Orílẹ̀-Èdè

Káàkiri àgbáyé, ní èyí tí ó lé ní 200 ilẹ̀ níbi tí wọ́n ń gbé, a mọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn tí ó mẹ̀yẹ, aláìlábòsí, àti olùpòfinmọ́. A mọ̀ wọ́n fún ìkọ̀jálẹ̀ wọn láti lọ́wọ́ nínú irú ìgbòkègbodò èyíkéyìí láti dojú ìjọba bolẹ̀, tàbí láti lòdì sí ìjọba—ìgbésẹ̀ tí kò bá ìlànà Kristian mú tí ó lè yọrí sí dídi ẹni tí a yọ lẹ́gbẹ́, tàbí tí a fi ẹ̀tọ́ jíjẹ́ mẹ́ḿbà dù. Ní ti gàsíkíá, ìjọba Singapore kò ní ohunkóhun láti bẹ̀rù nípa wọn. Wọn kì í ṣe ewu fún ààbò orílẹ̀-èdè Singapore tàbí èrò ìdáwà àti ìṣọ̀kan orílẹ̀-èdè. (Romu 13:1-7) A ṣàlàyé èyí ní kedere, nínú lẹ́tà kan tí a kọ ní March 21, 1995, láti ọwọ́ Milton G. Henschel, ààrẹ Watch Tower Bible and Tract Society, sí Olórí Ìjọba Goh Chok Tong, ti Singapore. A tún lẹ́tà yìí tẹ̀ jáde níhìn-ín fún àǹfààní àwọn òǹkàwé wa.

Àwọn olùfẹ́ òmìnira tí ń bẹ lẹ́nu iṣẹ́ ajé, nínú ìjọba, àti lẹnu iṣẹ́ àdáni yóò máa kíyèsí i pẹ̀lú ọkàn ìfẹ́, láti rí bí ipò yìí ní Singapore ṣe ń lọ sí. Ìjọba Singapore yóò ha hùwà ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìpìlẹ̀ ẹ̀tọ́ àti òmìnira ọmọnìyàn tí òfin òun fúnra rẹ̀ àti ti àpapọ̀ àwùjọ àwọn orílẹ̀-èdè káàkiri ń lò bí? Dájúdájú, àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa káàkiri ayé ní ìdàníyàn jíjinlẹ̀ nípa àwọn olùjọsìn ẹlẹgbẹ́ wọn, ní Singapore. Wọ́n ń rańtí wọn nínú àdúrà, wọ́n sì ń fi ìdálójú tí a rí nínú Bibeli sọ́kàn pé: “Jehofa jẹ́ olùfẹ́ ìdájọ́ òdodo, òun kì yóò sì fi àwọn tí ó dúró ṣinṣin síhà ọ̀dọ̀ rẹ̀ sílẹ̀.”—Orin Dafidi 37:28, NW.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Láti ọ̀pọ̀ oṣù tí a ti fàṣẹ ọba mú àwọn 69 wọ̀nyí, àwọn Ẹlẹ́rìí 11 mìíràn ni a ti fàṣẹ ọba mú, tí a sì fẹ̀sùn kàn wọ́n pé, wọ́n ní àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí kò bófin mu.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 30]

March 21, 1995

Goh Chok Tong

Olórí Ìjọba

Istana Annexe

Singapore 0923

Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Singapore

Lee Kuan Yew

Mínísítà Àgbà

Ọ́fíìsì Olórí Ìjọba

460 Alexandra Road

37-00 PSA Bldg

Singapore 0511

Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Singapore

Ẹ̀yin Ọlọ́lá Ọ̀wọ́n:

Ìròyìn kan tí a fi ṣọwọ́ láìpẹ́ yìí láti Singapore lórí ẹ̀rọ ìròyìn Reuters, tí a kọ ní February 25, 1995, kó ìdààmú báni gidigidi. Ó fi tóni létí pé àwọn ìpàdé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni àwọn ọlọ́pàá ti túká, tí wọ́n sì ti fàṣẹ ọba mú àwọn 69. Ìròyìn yìí ti darí àfiyèsí ayé sí ipò tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa wà ní Singapore, níbi tí a ti fòfin de ìgbòkègbodò wọn àti àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wọn fún ohun tí ó lé ní 20 ọdún.

Ó ṣòro láti lóye ìdí tí ètò àjọ ìsìn kan, tí ń ṣiṣẹ́ ní gbangba pẹ̀lú ààbò òfin pátápátá ní àwọn orílẹ̀-èdè tí ó lé ní 200 fi níláti di èyí tí a fòfin dè ní Singapore, orílẹ̀-èdè kan tí ń lo àwọn ìlànà dẹmọ. Èyí tí ó kó ìdààmú báni jù lọ ni ríronú nípa ìmúdanilójú òfin ilẹ̀ Singapore ní ti òmìnira ìjọsìn fún àwọn aráàlú rẹ̀.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa kò tí ì fìgbà kan rí jẹ́ ewu fún ààbò orílẹ̀-èdè níbikíbi. Ní tòótọ́, jákèjádò ayé, wọ́n ní orúkọ rere ti jíjẹ́ ẹni àlàáfíà, òṣìṣẹ́kára, adúróṣánṣán ní ti ìwà rere, àti olùpofinmọ́—àwọn ànímọ́ tí ó dá mi lójú pé ẹ ń gbé lárugẹ ní orílẹ̀-èdè yín.

Òtítọ́ ni pé, ní rírọ̀ tímọ́tímọ́ wọn mọ́ àwọn ọ̀pá ìdiwọ̀n Bibeli fún àwọn Kristian láìgba gbẹ̀rẹ́, ipò àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni a ti ṣì lóye tàbí tí a ti fi hàn lọ́nà òdì lọ́pọ̀ ìgbà. Ṣùgbọ́n, ìyẹn kò ha jẹ́ òtítọ́ nípa olùdásílẹ̀ ìsìn Kristian, ẹni tí a fi hàn lọ́nà òdì gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó lòdì sí “Kesari,” ìjọba ọjọ́ rẹ̀? Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa wulẹ̀ ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jesu àti ti àwọn Kristian ìjímìjí ni. Wọ́n ń bọ̀wọ̀ fún ìjọba ibi tí wọ́n ń gbé, wọ́n ń san owó orí, wọ́n sì ń gbé ìwà rere lárugẹ. Wọ́n jẹ́ àwọn aráàlú tí ń fi ẹ̀rí ọkàn bìkítà, adúróṣánṣán sì ni wọ́n. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa kò tí ì fìgbà kan rí kópa nínú ìgbòkègbodò kankan láti dojú ìjọba bolẹ̀ ní orílẹ̀-èdè èyíkéyìí, mo sì lè mú un dáa yín lójú pé, wíwà wọn ní Singapore kò wu ire orílẹ̀-èdè yín léwu.

Látàrí àwọn ìròyìn àwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn láìpẹ́ yìí, ìgbésẹ̀ ìpalẹ́numọ́ tí ìjọba yín gbé lòdì sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní Singapore ti di ohun tí gbogbo ayé ti mọ̀. Ní pàtàkì, ó ti di ọ̀ràn ìdàníyàn fún àwọn mílíọ̀nù 12 alábàákẹ́gbẹ́pọ̀ wọn, tí wọ́n wà kàákiri ayé. Mo rọ̀ yín láti lo àǹfààní ipò yín láti yanjú ọ̀ràn náà kí ẹ sì fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa tí ń bẹ ní orílẹ̀-èdè yín ní òmìnira ìjọsìn àti ti ẹ̀rí ọkàn, tí Òfin mú dá wọn lójú.

Mo lérò pé ìjíròrò olótìítọ́ inú pẹ̀lú àwọn aṣojú àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa yóò ṣèrànwọ́ láti mú èdè àìyedè èyíkéyìí nípa ètò àjọ àti ìgbòkègbodò wa kúrò, yóò sì fi yín lọ́kàn balẹ̀ pé ìjọba Singapore kò ní ohunkóhun láti bẹ̀rù láti ọ̀dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Inú mi yóò dùn láti ṣètò fún irú ìpàdé bẹ́ẹ̀.

Mo ń retí èsì yín.

Tiyín pẹ̀lú ọ̀wọ̀ tí ó jinlẹ̀,

Milton G. Henschel

Ààrẹ

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 31]

Nik Wheeler/H. Armstrong Roberts

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́