Wò Ó! Gbọ̀ngàn Ìjọba Ní Niue
NIUE jẹ́ erékùṣù kékeré oníyùn ní South Pacific, ó jìnnà tó 2,160 kìlómítà ní ìlà oòrùn àríwá New Zealand. Gẹ́gẹ́ bí ìwé pẹlẹbẹ tí ń sọ̀rọ̀ nípa ìrìn àjò ti sọ, orúkọ náà, Niue, jẹ yọ láti inú ọ̀rọ̀ méjì, Niu, tí ó túmọ̀ sí “igi àgbọn,” àti e, tí ó túmọ̀ sí “kíyè sí i,” tàbí “wò ó.” Ìwé pẹlẹbẹ náà wí pé: “Gẹ́gẹ́ bí ìtàn àdáyébá ti sọ, àkọ́kọ́ lára àwọn àtìpó ará Polynesia sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, nígbà tí wọ́n dé, tí wọ́n sì rí àwọn igi àgbọn, tí ń so ní ilẹ̀ náà.”
Lónìí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní Niue láyọ̀ láti sọ fún àwọn àlejò pé, “E! Fale he Kautu ha mautolu!” tí ó túmọ̀ sí, “Wò ó! Gbọ̀ngàn Ìjọba Wa!” Èé ṣe tí wọ́n fi ní irú ìmọ̀lára jíjinlẹ̀ báyìí nípa gbọ̀ngàn yìí? Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa níbi gbogbo máa ń fi Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn yangàn, pàápàá bí ó bá jẹ́ pé àwọn fúnra wọn ni wọ́n kọ́ ọ. Ṣùgbọ́n láti kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba sí erékùṣù tí ó jìnnà réré láàárín South Pacific tí ó lọ salalu, jẹ́ ohun tí ó ṣòro gidigidi. Ó ṣe tán, Niue tó kìkì 260 kìlómítà níbùú lóòró, kìkì 2,300 ènìyàn ni ó sì wà ní gbogbo erékùṣù náà.
Ìbéèrè náà dìde pé, ta ni yóò kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba náà. Ìjọ kan ṣoṣo tí ó wà ní Niue ní kìkì Ẹlẹ́rìí 32. Gbogbo ohun èèlò ìṣiṣẹ́ tí ó ṣe pàtàkì tí a nílò, bí i kẹ̀kẹ́ ẹrù, katakata, àti ọkọ̀ agbẹ́rùsókè, jẹ́ ti ìjọba. Síwájú sí i, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo ohun èèlò ìkọ́lé ṣíṣe kókó jù lọ—irin, búlọ́ọ̀kù oníkọnkéré, ohun ìbolé, àwọn ohun èèlò iná mànàmáná àti ti omi, ohun èèlò orin, àti àga—ni a óò fi ọkọ̀ ojú omi tí ń ṣiṣẹ́ lẹ́ẹ̀kan láàárín ọ̀sẹ̀ márùn-ún kó wọlé láti New Zealand. Lákòótán, ilẹ̀ olókùúta tí erékùṣù náà jẹ́ yóò mú kí iṣẹ́ ìkọ́lé náà ṣòro, a sì ní láti kọ́ gbọ̀ngàn náà lọ́nà tí yóò fi lè dúró kojú ìjì líle ti ilẹ̀ olóoru. Ní tòótọ́, ìdáwọ́lé apániláyà ni fún ẹnikẹ́ni!
Ṣùgbọ́n, ìyàtọ̀ pàtàkì kan wà níhìn-ín. Ní ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, Gbọ̀ngàn Ìjọba jẹ́ ojúkò ìjọsìn tòótọ́ ní àdúgbò, wọ́n sì ń wo Jehofa Ọlọrun fún ìtọ́sọ́nà àti ìrànlọ́wọ́. (Orin Dafidi 56:11; 127:1) Àwọn Kristian arákùnrin ní New Zealand, títí kan àwọn mẹ́ḿbà ìjọ Niue ní Auckland, dìde láti ṣèrànwọ́ fún àwùjọ àwọn Ẹlẹ́rìí kékeré ní Niue, nípa ṣíṣètìlẹyìn tọkàntọkàn fún iṣẹ́ ìkọ́lé náà.
Ìpinnu Láti Dáwọ́ Lé E
Ní June 1994, níbi ìkọ́lé Gbọ̀ngàn Ìjọba ní Rotorua, New Zealand, ìpè wáyé fún àwọn tí wọ́n bá nífẹ̀ẹ́ sí lílọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìdáwọ́lé ní Niue. Ó yani lẹ́nu pé, 200 àwọn Kristian arákùnrin àti arábìnrin ni wọ́n yọ̀ọ̀da ara wọn. Lára àwọn wọ̀nyí, a yan 80 ènìyàn, títí kan àwọn káfíńtà, òṣìṣẹ́ onírin, òṣìṣẹ́ omi ẹ̀rọ, kanlékanlé, rẹ́lérẹ́lé, akunlé, oníṣẹ́ mànàmáná, oníṣẹ́ ohun èèlò ìkọrin, apokọnkéré, bíríkìlà, àti lébìrà.
Àwọn ará ya àwòrán ilé, wọ́n sì tẹ̀ síwájú, ní gbígbẹ́kẹ̀lé Jehofa. Ọ̀kan lára àwọn alàgbà méjì, nínú ìjọ tí ó wà ní Niue, tí ó jẹ́ oníṣòwò ládùúgbò, bẹ̀rẹ̀ ṣíṣètò fífi ọkọ̀ ojú omi kó àwọn ohun èèlò wọlé. A ṣe àkànṣe ètò ìrìn àjò ọkọ̀ òfuurufú àti ilé gbígbé fún àwọn alábòójútó àwọn òṣìṣẹ́ náà, àwọn ẹni tí wọ́n yọ̀ọ̀da láti san owó tí yóò ná wọn, wọ́n sì dájọ́ tí kíkọ́ ilé náà yóò bẹ̀rẹ̀. A ṣètò pé kí iṣẹ́ náà parí ní 20 ọjọ́, láti March 4 sí March 23, 1995, nígbà tí a óò ya Gbọ̀ngàn Ìjọba náà sí mímọ́.
Olùdarí iṣẹ́ náà tí ó wá láti New Zealand, ní ọ̀sẹ̀ kan ṣáájú láti ṣètò àwọn nǹkan sọ pé: “Ẹ̀rú bà mí fún ìgbà àkọ́kọ́ nígbà tí mo rí ilẹ̀ náà. Kìkìdá àpáta ni ilẹ̀ náà. Kìkì gbígbẹ́ ìpìlẹ̀ ilé náà yóò gba ọ̀sẹ̀ méjì.” Ṣùgbọ́n ó jẹ́wọ́ lẹ́yìn náà pé, òún ti fojú kéré àwọn Ẹlẹ́rìí ládùúgbò. Ó sọ pé: “Àwọn arákùnrin ní Niue mọ̀ nípa òkúta. Wọ́n mọ ibi tí a ti lè fọ́ àpáta tí àwọn ńláńlá yóò fọ́ yángá.” A parí gbígbẹ́ ìpìlẹ̀ ilé náà ní ọjọ́ méjì!
Ní March 4, ọkọ̀ òfuurufú àkọ́kọ́ tí ó kún fún àwọn Ẹlẹ́rìí láti New Zealand dé, wọ́n sì ṣe iṣẹ́ kọnkéré. Bí àwùjọ àwọn tí iṣẹ́ kàn ti ń wá, onírúurú ẹ̀ka iṣẹ́ náà ni a ń parí. Iṣẹ́ ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ń bẹ̀rẹ̀ ní agogo 7:00 òwúrọ̀, pẹ̀lú ìjíròrò ẹsẹ Bibeli ojoojúmọ́ ní ṣókí. Àwọn arákùnrin kan ń ṣiṣẹ́ fún wákàtí 12 lójúmọ́, nínú òòrùn tí ó gbóná tó ìwọ̀n 36 lórí òṣùwọ̀n Celsius. Níkẹyìn, ní March 23, wọ́n ti tẹ́ ojú ilẹ̀ náà. Àkọlé kan tí ó fani mọ́ra tí a fi igi máńgòrò ṣe fi ilé náà hàn gẹ́gẹ́ bíi “Gbọ̀ngàn Ìjọba Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa.”
Ẹ̀mí Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àti Ẹ̀mí Aájò Àlejò
Kókó pàtàkì tí ó dá kún àṣeyọrí ìdáwọ́lé náà ni ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àwọn ènìyàn Niue. Àwọn ará abúlé, tí ẹ̀mí tí àwọn arákùnrin fi hàn wú lórí, fi oúnjẹ àti owó ṣètọrẹ. Ọ̀pọ̀ wo kíkọ́ gbọ̀ngàn náà gẹ́gẹ́ bí ìdáwọ́lé tiwọn. Àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba àti àwọn oníṣòwò ṣe ju ohun tí a retí lọ. A pèsè àwọn irin iṣẹ́ tí a nílò, àti ilé iṣẹ́ pákó pẹ̀lú. Ilé iṣẹ́ tí ń mójú tó fífi ọkọ̀ ojú omi kó ẹrù pàápàá yí ìtòlẹ́sẹẹsẹ wọn padà láti lè rí i dájú pé, a kó àwọn ohun èèlò tí a nílò dé ní àkókò.
Ní tòótọ́, àwọn àlejò mọrírì iṣẹ́ àṣekára àti ẹ̀mí aájò àlejò àwọn Ẹlẹ́rìí ní Niue, tí wọ́n yọ̀ọ̀da ilé wọn àti àwọn ohun ìní wọn. Òṣìṣẹ́ kan sọ pé: “Àwọn arábìnrin ní àdúgbò yani lẹ́nu púpọ̀.” Ní àfikún sí oúnjẹ ọ̀sán tí ń gbóná fẹlifẹli lójoojúmọ́, àwọn arábìnrin tún ń pèsè oúnjẹ lóròòwúrọ̀ ní 6:30. Àwọn kan ń jí ní 4:30 ìdájí láti se oúnjẹ. Ọ̀kan lára àwọn tí ń ṣiṣẹ́ ìkọ́lé náà sọ pé: “Mo lérò pé a gbé ní ọ̀nà tí ó dára ní Niue ju bí a ti ń gbé ní ilé wa lọ.”
Ní March 10, ìwé agbéròyìnjáde Niue Star ròyìn ìṣẹ̀lẹ̀ náà nínú ìtàn ojú ìwé rẹ̀ àkọ́kọ́, pẹ̀lú àkọlé náà “Gbọ̀ngàn Ìjọba Àkọ́kọ́ ní Niue,” ó sì fi àwòrán àwọn ará New Zealand àti Niue tí ń ṣiṣẹ́ ní ibi ìkọ́lé náà hàn. Ó ròyìn pé títóbi gbọ̀ngàn náà jẹ́ 280 mítà níbùú lóòró àti pé ó lè gba 70 sí 100 ènìyàn. Àpilẹ̀kọ náà fi kún un pé: “Òpò náà ni a lè parí ní [ọ̀sẹ̀] méjì nítòótọ́, ṣùgbọ́n ní ti èyí, a óò sún un síwájú. Níbi tí iṣẹ́ dé yìí, ní kìkì ọjọ́ méjì lẹ́yìn tí iṣẹ́ bẹ̀rẹ̀, ìpìlẹ̀, àwọn férémù, igi ìrólé àti òrùlé, ni a ti gbé ró, ṣáájú àkókò.”
Oníṣòwò kan ládùúgbò sọ pé, ó wu òun kí gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní Erékùṣù Niue lọ wo iṣẹ́ ìdáwọ́lé náà, kí wọ́n sì kọ́ ẹ̀kọ́ lára rẹ̀. Ó sọ pé òún retí pé yóò fi ohun tí ìfẹ́ àti ìfọwọ́sowọ́pọ̀ lè ṣe han gbogbo ènìyàn.
Àwùjọ 204 ni ó wá síbi ìyàsímímọ́ náà. Ìrírí tí ó ru gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní ìjókòó lọ́kàn sókè ni ìgbékalẹ̀ àkànṣe kan nínú èyí tí àwọn arákùnrin àti arábìnrin àti àwọn ọmọdé ará Niue, ti fi orin àti ijó ṣàpẹẹrẹ bí wọ́n ṣe kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba náà. A dúpẹ́ lọ́wọ́ àwùjọ àwọn akọ́lé náà àti Jehofa, ẹni tí ó fi ẹ̀mí rẹ̀ sún èrò inú, ọkàn àti ọwọ́ láti ṣàṣeparí iṣẹ́ náà.—Isaiah 40:28-31.