A Dá Ẹjọ́ Tí A Pe Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa
LẸ́YÌN sísún un síwájú léraléra, nígbẹ̀yìn gbẹ́yín, Ilé Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn ní Tessalonika, Gíríìkì, pàdé ní June 8, 1995, láti gbọ́ ẹjọ́ tí a gbé dìde lòdì sí àwọn obìnrin mẹ́rin tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jehofa. Kí ni ẹ̀sùn tí a fi kàn wọ́n? Ìsọnidaláwọ̀ṣe, tí òfin Gíríìkì ti gbẹ́sẹ̀ lé fún èyí tí ó ju ẹ̀wádún márùn-ún lọ.
Ṣùgbọ́n, nígbà tí ìgbẹ́jọ́ yóò fi bẹ̀rẹ̀, olórí ẹlẹ́rìí fún àwọn olùpẹ̀jọ́—àlùfáà tí ó rúná sí ẹjọ́ náà lòdì sí àwọn obìnrin mẹ́rin náà—ti dolóògbé. Àlùfáà míràn gbìyànjú láti jẹ́rìí dípò rẹ̀, ṣùgbọ́n ilé ẹjọ́ kò tẹ́wọ́ gba ìjírẹ̀ẹ́bẹ̀ rẹ̀. Nítorí náà, kò yani lẹ́nu pé ìgbẹ́jọ́ náà wáyé fún ìṣẹ́jú 15 péré! Adájọ́ náà gbé àwọn ẹ̀rí àwọn olùpẹ̀jọ́ yòókù yẹ̀ wò, ó sì rí i pé àwọn tí a fẹ̀sùn kàn náà kò jẹ̀bi sísọni di aláwọ̀ṣe lọ́nà tí kò bófin mu. Ìpinnu yìí fi hàn pé ilé ẹjọ́ Gíríìkì ṣe tán láti bọ̀wọ̀ fún ìpinnu tí Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Europe ṣe ní 1993, kí wọ́n sì tẹ̀ lé e.
Ó yani lẹ́nu jù lọ láti rí àwọn obìnrin mẹ́ta tí wọ́n jẹ́rìí gbe olùpẹ̀jọ́ bí wọ́n ti tọ àwọn Ẹlẹ́rìí tí a fẹ̀sùn kan lọ, tí wọ́n sì ń bá wọn yọ̀ tọkàntọkàn. Ọ̀kan nínú wọn sọ pé: “A tọrọ àforíjì fún gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀.” Ó fi kún un pé: “Kì í ṣẹjọ́ọ wa. Àlùfáà ni ó fi dandan mú wa láti pè yín lẹ́jọ́. Nísinsìnyí tí ó sì ti kú, a fẹ́ kí ẹ wá sí abúlé wa àti sí ilé wa.”
Nípa báyìí, Jehofa tún ti fún àwọn ènìyàn rẹ̀ ní Gíríìkì ní ìṣẹ́gun àgbàyanu lẹ́ẹ̀kan sí i. Òfin Ìsọnidaláwọ̀ṣe ni a fi lélẹ̀ ní Gíríìkì ní 1938 àti 1939. Ní 1993, Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn tí Ilẹ̀ Europe pàṣẹ pé, lílo òfin yìí láti ṣe inúnibíni sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa lòdì.—Wo Ilé-Ìṣọ́nà, September 1, 1993, ojú ìwé 27 sí 31.