ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w96 2/15 ojú ìwé 32
  • Òtítọ́ Ìròyìn Rere

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Òtítọ́ Ìròyìn Rere
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
w96 2/15 ojú ìwé 32

Òtítọ́ Ìròyìn Rere

ÀJÁKÙ ìwé àfọwọ́kọ kéékèèké mẹ́ta ti Ìròyìn Rere ti Matteu, tí a mọ̀ sí P64, ti wà ní ìkáwọ́ Kọ́lẹ́ẹ̀jì Magdalen ní Oxford, England, láti 1901. Ní àwọn àkókò kan, àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ gbà gbọ́ pé ọjọ́ wọn ti pẹ́ tó apá ìparí ọ̀rúndún kejì, Sànmánì Tiwa.

Láìpẹ́ yìí, Carsten P. Thiede, tí ó jẹ́ ògbóǹtagí nínú ìmọ̀ ẹ̀kọ́ pápírọ́ọ̀sì ní Paderborn, Germany, ṣe ìwádìí fínnífínní lórí P64, tí ó ní àwọn apá ẹsẹ 10 láti Matteu orí 26 nínú. Kí ni àbáyọrí rẹ̀? Nígbà tí ó ń kọ̀wé nínú Zeitschrift für Papyrologie und Epigraphik (Ìwé Ìròyìn Àtìgbàdégbà Lórí Ìmọ̀ Ẹ̀kọ́ Pápírọ́ọ̀sì àti Àkọlé), Thiede ṣàpèjúwe àwọn àjákù ti Oxford gẹ́gẹ́ bí “àjákù ìwé àfọwọ́kọ alábala ti Kristian ní ọ̀rúndún kìíní, bóyá tí ọjọ́ rẹ̀ ṣáájú ọdún 70 Lẹ́yìn Ikú Oluwa Wa (bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè máà rí bẹ́ẹ̀).”

Àkíyèsí Thiede dá ìjíròrò tí ó gbalégbòde sílẹ̀ nínú ìròyìn àti láàárín àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀. Èé ṣe? Nítorí pé, ohun tí a tẹ́wọ́ gbà lọ́wọ́lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí apá tí ó ṣẹ́ kù tí ó pẹ́ jù lọ lára ẹsẹ ìwé láti inú Ìròyìn Rere ni P52, tí ó jẹ́ àjákù Ìròyìn Rere ti Johannu láti nǹkan bí ọdún 125 Sànmánì Tiwa, tàbí tí kò ṣáájú ọ̀rúndún kejì.

A kò tí ì mọ̀ bóyá ọjọ́ tuntun tí a fún àjákù pápírọ́ọ̀sì P64 ni àwọn ènìyàn yóò tẹ́wọ́ gbà níbi gbogbo. Èyí ó wù kí ó jẹ́, ọjọ́ tí ó ṣáájú kì yóò mú kí P64 jẹ́ àwọn àjákù Ìròyìn Rere tí ó tí ì pẹ́ jù lọ nìkan ni; yóò tún fúnni ní ẹ̀rí síwájú sí i tí ń tọ́ka sí i pé, Ìròyìn Rere ti Matteu ni a kọ ní tòótọ́ ní ọ̀rúndún kìíní, ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ ṣáájú ọdún 70 Sànmánì Tiwa, nígbà tí ògìdìgbó àwọn ẹlẹ́rìí ìṣẹ̀lẹ̀ ìgbésí ayé Jesu ṣì wà láàyè láti gbe òtítọ́ Ìròyìn Rere náà lẹ́sẹ̀.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 32]

Nípasẹ̀ ìyọ̀ọ̀da President and Fellows of Magdalen College, Oxford.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́