ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w96 2/15 ojú ìwé 30-31
  • Ipò Wo Ni Ìbínú Ní Nínú Ìgbésí Ayé Ìránṣẹ́ Ọlọrun?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ipò Wo Ni Ìbínú Ní Nínú Ìgbésí Ayé Ìránṣẹ́ Ọlọrun?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àìní Pàtàkì fún Ṣíṣàkóso Rẹ̀
  • Yíyẹra fún Àbájáde Tí Ń Pani Lara
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
w96 2/15 ojú ìwé 30-31

Ipò Wo Ni Ìbínú Ní Nínú Ìgbésí Ayé Ìránṣẹ́ Ọlọrun?

ÌFÌBÍNÚHÀN lè tọ̀nà bí a bá gbé e karí ìlànà. Ẹnì kan lè fi ìkannú òdodo hàn lọ́nà tí ó tọ́. A pàṣẹ fún wa láti “fi tẹ̀gàntẹ̀gàn kórìíra ohun burúkú.” (Romu 12:9) Bibeli pèsè ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àpẹẹrẹ ìkannu òdodo.—Eksodu 11:8; 32:19; Numeri 16:12-15; 1 Samueli 20:34; Nehemiah 5:6; Esra 7:7; tún wo 2 Samueli 12:1-6.

Ṣùgbọ́n, ìbínú ti ènìyàn sábà máa ń jẹ́ èyí tí kò tọ́, ní ọ̀pọ̀ ìgbà, a kì í ṣàkóso rẹ̀. A sábà máa ń gbé e karí ìdí tí kò tó nǹkan, a sì máa ń fi í hàn láìbìkítà fún ohun tí yóò jẹ́ àbájáde rẹ̀. Lẹ́yìn tí Jehofa ti dá Ninefe sí, inú Jona bàjẹ́, “ó sì bínú púpọ̀.” Jona kò láàánú, Jehofa sì ní láti tún ojú ìwòye rẹ̀ ṣe. (Jona 4:1-11) Ọba Ussiah ti Juda bínú nígbà tí àwọn àlùfáà Jehofa tún ojú ìwòye rẹ̀ ṣe, ó sì tẹ̀ síwájú nínú ipa ọ̀nà ọ̀yájú rẹ̀, èyí tí ó jìyà sí. (2 Kronika 26:16-21) Ìgbéraga Naamani tí ó fi àìtẹ́tí sí ìmọ̀ràn hàn, ṣokùnfà ìkannú àti ìrunú níhà ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ yọrí sí pípàdánù ìbùkún láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun.—2 Awọn Ọba 5:10-14.

Àìní Pàtàkì fún Ṣíṣàkóso Rẹ̀

Ìbínú tí kò tọ́, tí a kò sì ṣàkóso rẹ̀ ti sún ọ̀pọ̀ ènìyàn sínú ẹ̀ṣẹ̀ tí ó burú sí i, àní ìwà ipá pàápàá. “Kaini sì bínú gidigidi,” ó sì pa Abeli. (Genesisi 4:5, 8) Esau fẹ́ pa Jekọbu, ẹni tí ó gba ìbùkún bàbá wọn. (Genesisi 27:41-45) Nínú ìbínú rẹ̀, Saulu ju ọ̀kọ̀ fún Dafidi àti Jonatani. (1 Samueli 18:11; 19:10; 20:30-34) Ìwàásù Jesu bí àwọn tí wọ́n pésẹ̀ sí sínágọ́gù ní Nasareti nínú, wọ́n sì sakun láti taari rẹ̀ lulẹ̀ láti orí òkè. (Luku 4:28, 29) Àwọn aṣáájú ìsìn tí inú ń bí “rọ́lu [Stefanu] pẹlu ìfìmọ̀ṣọ̀kan,” wọ́n sì sọ ọ́ ní òkúta pa.—Ìṣe 7:54-60.

Ìbínú, àní nígbà tí ó bá tọ̀nà pàápàá, tí a kò bá ṣàkóso rẹ̀, léwu, yóò sì mú ìyọrísí búburú wá. Simeoni àti Lefi ní ìdí láti fi ìkannú hàn sí Ṣekemu fún bíba Dina àbúrò wọn jẹ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọbìnrin náà jẹ̀bi díẹ̀. Ṣùgbọ́n pípa ilé Ṣekemu nípakúpa jẹ́ ìfìyàjẹni tí ó ré kọjá ààlà. Nítorí náà, Jekọbu bàbá wọn dá ìbínú wọn tí wọn kò ṣàkóso lẹ́bi, ó fi bú. (Genesisi 34:1-31; 49:5-7) Nígbà tí a bá mú ẹnì kan bínú gidigidi, ó ní láti ṣàkóso ìbínú rẹ̀. Ìráhùn àti ọ̀tẹ̀ àwọn ọmọ Israeli bí Mose nínú, ẹni ọlọ́kàn tútù jù lọ lórí ilẹ̀ ayé, dé orí ìwà ìbínú tí kò lè ṣàkóso nínú èyí tí ó ti kùnà láti ya Jehofa sí mímọ́, èyí tí a sì fi ìyà jẹ ẹ́ fún.—Numeri 12:3; 20:10-12; Orin Dafidi 106:32, 33.

A ka ìbínú mọ́ àwọn iṣẹ́ tí ara mìíràn tí ń múni ṣe họ́ọ̀, irú bí ìwà àìníjàánu, ìbọ̀rìṣà, bíbá ẹ̀mí lò, àti mímu àmuyíràá. Irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ yóò mú kí ẹnì kan má lè jogún Ìjọba Ọlọrun. (Galatia 5:19-21) A kò gbọ́dọ̀ gbọ́ ọ̀rọ̀ ìbínú nínú ìjọ. Àwọn ọkùnrin tí ń ṣojú ìjọ nínú àdúrà ní láti yẹra fún ìmọ̀lára ìbínú àti inú burúkú. (1 Timoteu 2:8) A pàṣẹ fún àwọn Kristian láti lọ́ra nípa ìrunú, a sọ fún wọn pé, ìrunú ènìyàn kì í ṣiṣẹ́ yọrí sí òdodo Ọlọrun. (Jakọbu 1:19, 20) A gbà wọ́n nímọ̀ràn láti “yàgò fún ìrunú,” kí wọ́n sì fi ẹ̀san sílẹ̀ fún Jehofa. (Romu 12:19) A kò lè lo ọkùnrin kan gẹ́gẹ́ bí alábòójútó nínú ìjọ Ọlọrun, bí ó bá sábà ń bínú.—Titu 1:7.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan ẹnì kan lè bínú, nígbà míràn kí ó sì tọ̀nà, kò ní láti jẹ́ kí ó di ẹ̀ṣẹ̀ nípa gbígbìn ín sínú tàbí wíwà ní ipò ìbínú fún ìgbà pípẹ́. Kò ní láti jẹ́ kí oòrùn wọ̀ bá òun ní irú ipò bẹ́ẹ̀, nítorí pé, nípa bẹ́ẹ̀ yóò fún Èṣù ní àyè láti rí oun mú. (Efesu 4:26, 27) Ní pàtàkì, bí ó bá jẹ́ ọ̀ràn ìbínú láàárín àwọn Kristian arákùnrin wọn, ó ní láti gbé àwọn ìgbésẹ̀ tí ó yẹ láti wá àlàáfíà tàbí láti yanjú ọ̀ràn náà ní ọ̀nà tí Ọlọrun pèsè. (Lefitiku 19:17, 18; Matteu 5:23, 24; 18:15; Luku 17:3, 4) Ìwé Mímọ́ fún wa nímọ̀ràn pé, nínú ọ̀ràn yìí, a ní láti kíyè sí ẹgbẹ́ tí a ń kó, kí a má ṣe bá ẹnikẹ́ni tí ó bá ń bínú tàbí tí ó ń ní ìrunú kẹ́gbẹ́ pọ̀, nípa bẹ́ẹ̀ kí a yẹra fún ìdẹkùn fún ọkàn wa.—Owe 22:24, 25.

Jesu Kristi, nígbà tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé, fún wa ní àpẹẹrẹ pípé. Àwọn àkọsílẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀ kò sọ àkókò kan nígbà tí kò lè ṣàkóso ìbínú rẹ̀, tàbí nígbà tí ó yọ̀ọ̀da fún ìwà àìlófin, ọ̀tẹ̀, àti ìhalẹ̀ àwọn ọ̀tá Ọlọrun láti mú kí ó bínú, kí ó sì mú kí ó fi irú nǹkan bẹ́ẹ̀ hàn sí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tàbí àwọn ẹlòmíràn. Ní àkókò kan, yíyigbì ọkàn-àyà àwọn Farisi mú kí “ó ní ẹ̀dùn-ọkàn gidigidi” sí wọn, ó sì wò wọ́n pẹ̀lú ìkannú. Ìwòsàn ni ó ṣe tẹ̀ lé e. (Marku 3:5) Ní àkókò míràn, nígbà tí ó lé àwọn tí ń ba tẹ́ḿpìlì Ọlọrun jẹ́, tí wọ́n sì ń tẹ Òfin Mose lójú nípa sísọ ilé Jehofa di ilé ọjà títà jáde, kì í ṣe nípasẹ̀ ìbínú tí kò ṣeé ṣàkóso, tí kò tọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, Ìwé Mímọ́ fi hàn pé, ó jẹ́ ìtara tí ó yẹ fún ilé Jehofa.—Johannu 2:13-17.

Yíyẹra fún Àbájáde Tí Ń Pani Lara

Kì í ṣe kìkì pé ìbínú ń ní àbájáde búburú lórí ìlera wa nípa tẹ̀mí nìkan ni, ṣùgbọ́n ó ń ní ìyọrísí tí ó lágbára lórí àwọn ẹ̀yà ara ìyára. Ó lè mú kí ẹ̀jẹ̀ ru, ó lè fa ìyípadà nínú òpó ẹ̀jẹ̀, ìṣòro èémí, ó lè ba ẹ̀dọ̀ jẹ́, ó lè mú ìyípadà wá nínú ìsunjáde òróòro, ó lè ní ìyọrísí lórí ẹ̀yà ara tí ń mú oúnjẹ dà. Ìbínú àti ìrunú, bí èrò ìmọ̀lára lílágbára, ni àwọn dókítà ti sọ pé wọ́n ń dá kún àwọn òkùnrùn bí ikọ́ àwúgbẹ, àrùn ojú, àrùn awọ ara, àyúnbó, ọgbẹ́ inú, àti ìṣòro eyín àti tí oúnjẹ dídà, wọ́n ń mú kí àwọn àrùn wọ̀nyí le sí i, tàbí kí wọ́n tilẹ̀ ṣokùnfà wọn pàápàá. Ìrunú àti ìbínú lè ṣàkóbá fún ọ̀nà ìgbàronú dé bi tí ẹnì kan kò ní lè dé ìparí èrò tí ó bọ́gbọ́n mu tàbí kí ó ṣe ìdájọ́ tí ó yè kooro. Àbájáde ìrunú sábà máa ń jẹ́ sáà ìsoríkọ́ gan-an ní ti èrò orí. Nítorí náà, ó bọ́gbọ́n mu, kì í ṣe lọ́nà ti ìsìn nìkan, ṣùgbọ́n ní ti ara ìyára pẹ̀lú, láti ṣàkóso ìbínú, kí a sì lépa àlàáfíà àti ìfẹ́.—Owe 14:29, 30; Romu 14:19; Jakọbu 3:17; 1 Peteru 3:11.

Gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti wí, àkókò òpin jẹ́ àkókò ìrunú àti ìbínú, nígbà tí àwọn orílẹ̀-èdè bínú sí bí Jehofa ṣe gba agbára láti ṣàkóso, tí a sì lé Èṣù jù sí orí ilẹ̀ ayé, “ó ní ìbínú ńlá, ní mímọ̀ pé sáà àkókò kúkúrú ni oun ní.” (Ìṣípayá 11:17, 18; 12:10-12) Pẹ̀lú irú ipò amunilómi bẹ́ẹ̀, yóò dára kí àwọn Kristian ṣàkóso ẹ̀mí wọn, ní yíyẹra fún èrò ìmọ̀lára apanirun ti ìbínú.—Owe 14:29; Oniwasu 7:9.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́