ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w96 3/15 ojú ìwé 7
  • Ọ̀rẹ́ Wọn Pàtàkì Jù Lọ Mú Wọn Dúró

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọ̀rẹ́ Wọn Pàtàkì Jù Lọ Mú Wọn Dúró
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Èmi Ògbóǹkangí Olóṣèlú Tẹ́lẹ̀ Di Kristẹni Tí Kò Dá Sí Ìṣèlú Mọ́
    Jí!—2002
  • A Fi Orúkọ Ọlọ́run Ṣe Àwọn Ilé Lọ́ṣọ̀ọ́ ní Czech
    Jí!—1998
  • Mo Kọ́ Láti Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Inúnibíni Nítorí Ẹ̀sìn—Kí Ló Fà Á?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
w96 3/15 ojú ìwé 7

Ọ̀rẹ́ Wọn Pàtàkì Jù Lọ Mú Wọn Dúró

ÌBÁDỌ́RẸ̀Ẹ́ kan tí ń mú àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa dúró ní pàtàkì. Ó jẹ́ ipò ìbátan ṣíṣeyebíye wọn pẹ̀lú Ọ̀rẹ́ wọn pàtàkì jù lọ, Jehofa Ọlọrun. (Fi wé Jakọbu 2:23.) Ó ń tì wọ́n lẹ́yìn nígbà ìdánwò ìgbàgbọ́ ńláǹlà.

Ọ̀pọ̀ àwọn olùṣàkíyèsí ti gbóríyìn fún àkọsílẹ̀ ìwà títọ́ tí àwọn Ẹlẹ́rìí ní lábẹ́ àwọn ìṣàkóso bóofẹ́-bóokọ̀. Ọ̀kan nínú wọn ni Jiří Krupička, ọ̀mọ̀wé nínú ọgbọ́n èrò orí àti ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì ìṣẹ̀dá, tí ó wá láti Czechoslovakia ní 1968 lẹ́yìn tí ó ti lo ọ̀pọ̀ ọdún ní àwọn ibùdó ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ ti Kọ́múníìsì. Nínú ìwé rẹ̀, Renesance rozumu (Rírántí Àwọn Olóye), ó sọ̀rọ̀ nípa ìjìyà àti ìdúróṣinṣin àwọn Ẹlẹ́rìí tí a fi sẹ́wọ̀n nítorí àìdásítọ̀túntòsì wọn.

Lábẹ́ ìṣàkóso Kọ́múníìsì, ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí ni a fi sẹ́wọ̀n nítorí ìgbàgbọ́ wọn. Bí a tilẹ̀ fi wọ́n sẹ́wọ̀n, wọ́n kọ̀ láti wa uranium fún ète ogun. (Isaiah 2:4) Krupička ṣàpèjúwe ìran tí ó rí ní ọ̀kan nínú àwọn ibi ìwakùsà wọ̀nyí ní 1952. Ó rí àwọn ènìyàn méjì tí wọ́n dúró bí ère yìnyín nínú ojú ọjọ́ tí otútù ti mú gan-an. Àgbá onímẹ́tàlì bo orí àti òkè ara wọn.

Krupička kọ̀wé pé: “Wọ́n ti dúró síbẹ̀ pẹ̀lú àkísà aṣọ ọgbà ẹ̀wọ̀n lára wọn láti òwúrọ̀ kùtù. Báwo ni wọ́n ṣe lè fara da dídúró fún àkókò pípẹ́ tó bẹ́ẹ̀ lórí ẹsẹ̀ tí ó ti dì? Nípasẹ̀ agbára ìgbàgbọ́ ni. Àgbá náà ti gbó, ó sì ti dógùn-ún. Ẹnì kan fi tagbáratagbára tẹ àgbá náà mọ́ orí àti èjìká wọn, tó bẹ́ẹ̀ tí àjákù àgbà náà fi fa ẹ̀wù àti ara ọ̀kan nínú àwọn ọkùnrin náà ya, tí ẹ̀jẹ̀ sì ń kán láti apá rẹ̀.

“Ẹ̀ṣọ́ náà ní kí àwa tí a tò dúró sí iwájú àwọn, ọ̀gágun náà sì bá wa sọ̀rọ̀ díẹ̀. Ó wí pé, kíkọ̀ láti ṣiṣẹ́ jẹ́ ọ̀tẹ̀, a óò sì fi ìyà tí ó tọ́ jẹ ẹni tí ó bá ṣe bẹ́ẹ̀. Kò sí àyè fún ṣíṣe ìranù elérò ìmọ̀lára nípa ogun, pípa àwọn alátakò ogun wọ̀nyí yóò sì kọ́ wọn lọ́gbọ́n, àwọn ọ̀tá ìjọba àjùmọ̀ní wọ̀nyí.”

Ọ̀gágun náà gbé irin ńlá kan, ó sì jàn án mọ́ àgbá náà. Ọkùnrin tí ó wà nínú rẹ̀ ṣubú lulẹ̀, àgbá náà ṣì bo orí rẹ̀ síbẹ̀. Krupička kò lè gbà gbé ohun tí ó ṣẹlẹ̀ tẹ̀ lé e láé.

Ó wí pé: “Ohùn orin ń jáde wá láti inú àgbá náà. Ohùn tí ó tuni lára, sísọ̀rọ̀ wúyẹ́wúyẹ́ sí Ọlọrun nínú àdúrà, ẹni tí ó lè gbọ́ ohunkóhun láti ibikíbi—àní wọ́n tilẹ̀ gbìyànjú kíkọrin láti inú àwọn àgbá uranium tí ó ti gbó, tí ó sì ti dógùn-ún. Ó gbọ́ ọ ketekete ju orin tí ẹgbẹ́ akọrin ń kọ nínú kàtídírà ńlá lọ.”

Ní September 1, 1993, òfin yọ̀ọ̀da fún iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Czech. Inú àwọn Ẹlẹ́rìí ní Czech ń dùn nísinsìnyí láti máa bá iṣẹ́ ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Kristian wọn lọ pẹ̀lú òmìnira. Bẹ́ẹ̀ ni, inú wọ́n dùn láti sọ fún àwọn ẹlòmíràn nípa Jehofa, Ọ̀rẹ́ wọn pàtàkì jù lọ.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Àwọn tí wọ́n wá sí àpéjọpọ̀ ní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Czech

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́