Ìdí Tí Ó Fi Lo Orúkọ Títóbi Lọ́lá Jù Lọ náà
“MO TI ṣẹ̀, ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí ọ̀kan lára àwọn olùṣelámèyítọ́ mi sọ, nínú fífi ọ̀rọ̀ náà ‘Jehofa’ dípò ‘Oluwa,’ èyí tí ó ti fi ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún jẹ́ alábàádọ́gba rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àṣà.”
Èyí ni ọ̀rọ̀ J. J. Stewart Perowne nínú ọ̀rọ̀ àkọ́sọ ìtẹ̀jáde kejì rẹ̀ ti ìtumọ̀ ìwé Orin Dafidi, tí a tẹ̀ jáde lákọ̀ọ́kọ́ ní 1864. Olùṣelámèyítọ́ náà, nígbà tí ó ń kọ̀wé nínú ìwé ìròyìn Saturday Review ti July 2, 1864, ta ko lílo orúkọ Ọlọrun nínú ìtumọ̀ náà, níwọ̀n bí a kò ti lò ó mọ́ yálà nínú ṣọ́ọ̀ṣì àwọn Júù tàbí ti Kristian. Ó sọ pé a mọ orúkọ náà Jehofa mọ àwọn Júù púpọ̀púpọ̀, àti pé kí a lo ọ̀rọ̀ míràn, irú bí “Oluwa” tàbí “Ọlọrun,” “tí kò sí ohun tí ó jẹ́ ti àdúgbò tàbí ti orílẹ̀ èdè nípa rẹ̀.”
Perowne kò fara mọ́ àríyànjiyàn wọ̀nyí, níwọ̀n bí kò ti “fẹ́ yọ lẹ́tà kan ṣoṣo kúrò” nínú ìṣípayá Ọlọrun sí ènìyàn. Ó jẹ́wọ́ ní tòótọ́ pé àwọn atúmọ̀ èdè tí wọ́n túmọ̀ orúkọ àtọ̀runwá náà ní èdè Heberu sí “Oluwa” kùnà láti fi ìyàtọ̀ hàn láàárín àwọn ọ̀rọ̀ Heberu méjì náà.
Síwájú sí i, Perowne tẹnu mọ́ ọn pé àwọn aláṣẹ tí wọ́n tóótun, tí wọ́n fara mọ́ ìmúpadàbọ̀sípò orúkọ àtọ̀runwá náà wà. Ó fa ọ̀rọ̀ olókìkí akéwì ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì kan, Samuel Taylor Coleridge, yọ pé:
“Èé ṣe tí ẹ fi ń bá ìtumọ̀ Heberu sí èdè Gẹ̀ẹ́sì nìṣó nípasẹ̀ alárinà, nípasẹ̀ Septuagint? A kò ha ti gba ọ̀rọ̀ Heberu náà Jehofa lò bí? Κύριος, tàbí Oluwa, ti inú Septuagint, kò ha ti jẹ́ arọ́pò ní èdè Gíríìkì ní àìmọye ìgbà fún ọ̀rọ̀ Heberu náà, Jehofa bí? Èé ṣe, nígbà náà, tí ẹ kò fi dá ọ̀rọ̀ ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà padà; kí ẹ sì lo Jehofa fún Jehofa délẹ̀délẹ̀ nínú Májẹ̀mú Láéláé; àti nínú gbogbo ẹsẹ ìwé nínú Májẹ̀mú Tuntun tí ó bá ń tọ́ka sí ti Láéláé, nípa ọ̀rọ̀ Heberu náà nínú ẹsẹ ìwé tí a bá tọ́ka sí náà?”
Perowne jẹ́wọ́ pé a kò mọ pípè orúkọ náà gan-an fún àmì ọ̀rọ̀ Heberu mẹ́rin fún orúkọ Ọlọrun, ṣùgbọ́n ó wí pé: “Bí ó bá jẹ́ tìtorí kìkì ìgbàgbọ́ nínú ohun asán ni a kò fi lo orúkọ náà mọ́ nínú Ṣọ́ọ̀ṣì àwọn Júù, bí ó bá sì jẹ́ tìtorí ṣíṣe àdàkọ àwọn Ìtẹ̀jáde ti Gíríìkì àti ti Latin ni Ìtẹ̀jáde èdè [Gẹ̀ẹ́sì] tiwa fi sọ ọ̀rọ̀ náà nù, kò sí ìdí kankan tí ó fẹsẹ̀ múlẹ̀ tí ó lè lòdì sí pípadà sí bí a ṣe ń lò ó ní ìpilẹ̀ṣẹ̀.” Perowne fara mọ́ “Jehofa” nítorí a mọ̀ ọ́n dáradára. Láti ìgbà náà wá, àwọn ìtumọ̀ òde òní mélòó kan ti lo orúkọ àtọ̀runwá náà pẹ̀lú. Bibeli New World Translation of the Holy Scriptures lo orúkọ náà Jehofa ní èyí tí ó ju 7,200 ìgbà lọ nínú Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Heberu àti ti Gíríìkì.
Nínú ìtumọ̀ rẹ ti ìwé Orin Dafidi, Perowne gbìyànjú láti dìrọ̀ “tímọ́tímọ́ mọ́ àkójọpọ̀ Heberu náà, nínú àkànlò èdè rẹ̀ àti nínú ọ̀nà ìgbàkọ gbólóhùn ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan.” Nígbà tí ó ń túmọ̀ Orin Dafidi 69, ẹsẹ 5 àti 6, o rí i pé òún ní láti fi ìyàtọ̀ hàn láàárín àwọn ọ̀rọ̀ Heberu náà fún “Ọlọrun” (ʼElo·himʹ), “Oluwa” (ʼAdho·naiʹ), àti “Jehofa”: “Ọlọrun [ʼElo·himʹ], Ìwọ́ mọ ìwà òmùgọ̀ mi, ẹ̀bi mi kò sì lùmọ́ kúrò lójú Rẹ. Oluwa [ʼAdho·naiʹ], Jehofa (Ọlọrun) àwọn ọmọ ogun, má ṣe jẹ́ kí ojú kí ó ti àwọn tí ó dúró dè Ọ́ nítorí mi. Má ṣe jẹ́ kí àwọn tí ń wá Ọ nítorí mi, kí ó dààmú nítorí mi, Ọlọrun Israeli.”