“Iṣẹ́ Jehofa ni”
Ẹṣin ọ̀rọ̀ àpilẹ̀kọ kan nìyẹn nínú ìwé agbéròyìnjáde El Norte, ti Monterrey City, Mexico. Àpilẹ̀kọ náà dá lórí Gbọ̀ngàn Àpéjọ tuntun ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa.
Monterrey jẹ́ ìlú ńlá tí ó ní àwọn olùgbé 2,300,000 (títí fi mọ́ àwọn agbègbè ẹ̀yìn odi) ní apá ìhà àríwá Mexico, ó sì ní 19,200 akéde Ìjọba. Fún nǹkan bí ọdún kan àti ààbọ̀, àwọn Ẹlẹ́rìí pawọ́ pọ̀ láti kọ́ Gbọ̀ngàn Àpéjọ kan tí ó jojú ní gbèsè, tí ó sì ṣeé lò, tí ó ní 3,000 ìjókòó aláfẹ̀yìntì àti ẹ̀rọ amúlétutù. Àwọn Ẹlẹ́rìí àdúgbò kún fún ayọ̀, nígbà tí ọ̀kan nínú mẹ́ḿbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa gbé ọ̀rọ̀ ìyàsímímọ́ náà kalẹ̀. Ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà ní ìtàn ṣókí nípa iṣẹ́ ní Monterrey nínú, a sì fọ̀rọ̀ wá àwọn tí wọ́n lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìkọ́lé náà lẹ́nu wò. Lẹ́yìn náà ni 4,500 ènìyàn tí wọ́n pésẹ̀ sí ìpàdé náà gbádùn ọ̀rọ̀ ìyàsímímọ́ náà.
Ìkẹta nínú àwọn Gbọ̀ngàn Àpéjọ tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́ ní Mexico nìyí, nínú ohun tí a ṣàpèjúwe gẹ́gẹ́ bí ìgbétásì fún “Kíkọ́ Àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba àti Gbọ̀ngàn Àpéjọ Púpọ̀, Tí Wọ́n Tóbi, Tí Wọ́n Sì Dára Sí I.”
Pẹ̀lú àwọn akéde tí ó lé ní 443,000 ní Mexico, àti pẹ̀lú 1,492,500 tí wọ́n pésẹ̀ sí Ìṣe Ìrántí ní 1995, àwọn Gbọ̀ngàn Àpéjọ tuntun, irú èyí tí ó wà ní Monterrey, dájúdájú yóò ṣiṣẹ́ fún ète àtọ̀runwá.