Àwọn Ẹlẹ́rìí Títí Dé Apá Ibi Jíjìnnà Jù Lọ ní Ilẹ̀ Ayé
ETAH
THULE
GODHAVN
GODTHÅB
JULIANEHÅB
ANGMAGSSALIK
THULE jẹ́ apá kan orúkọ tí a ń lò ní ìgbàanì láti ṣàpèjúwe góńgó pàtàkì, agbègbè ilẹ̀ kan pàtó tàbí ohun mìíràn. Lónìí, Thule jẹ́ orúkọ ìletò kan ní àríwá jíjìnnà jù lọ ti Greenland, erékùṣù tí ó tóbi jù lọ lágbàáyé. A sọ ìletò náà ní orúkọ yẹn ní ọdún 1910, nígbà tí olùyẹ̀wòkiri náà, Knud Rasmussen, ará Denmark lò ó gẹ́gẹ́ bí ibi ìkóríjọ fún ìrìn àjò ìpẹ̀kun ayé. Àní nísinsìnyí, ìrìn àjò akọni ni lílọ sí Thule jẹ́, kì í ṣe ìrìn àjò afẹ́.
Síbẹ̀síbẹ̀, àìní kánjúkánjú kan ń bẹ fún rírin ìrìn àjò akọni lọ sí Thule. Ní dídáhùn padà sí àṣẹ Jésù pé: “Ẹ . . . jẹ́ ẹlẹ́rìí mi . . . títí dé apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé,” àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń hára gàgà láti mú ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run lọ sí ibi yìí, ọ̀kan nínú àwọn ìletò wíwà pẹ́ títí jù lọ, ti ẹ̀dá ènìyàn lórí ilẹ̀ ayé, ní ìpẹ̀kun ìhà àríwá.—Ìṣe 1:8; Mátíù 24:14.
‘Nígbà Wo Ni A lè Lọ Sí Thule?’
Ní 1955, àwọn Ẹlẹ́rìí ará Denmark méjì tí wọ́n fẹ́ nípìn-ín nínú wíwàásù “títí dé apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé” gúnlẹ̀ sí Greenland. Àwọn mìíràn dé lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, iṣẹ́ ìwàásù wọn kárí ìhà gúúsù àti ìwọ̀ oòrùn etíkun títí dé ibi Ìyawọlẹ̀ Òkun Melville títí dé apá kan etíkun ìhà ìlà oòrùn. Ṣùgbọ́n a dé àwọn apá tí ó tún jìnnà ju ìyẹn lọ, bíi Thule, nípasẹ̀ lẹ́tà tàbí tẹlifóònù.
Ní ọjọ́ kan ní 1991, Bo àti aya rẹ̀, Helen, àwọn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún méjì, dúró lórí àpáta kan, wọ́n sì ń wo Ìyawọlẹ̀ Òkun Melville nísàlẹ̀. Ní bíbojú wo ìhà àríwá wọ́n ronú pé, ‘Nígbà wo ni a óò tó lè gòkè lọ sí Thule láti mú ìhìn rere Ìjọba náà tọ àwọn ènìyàn ibẹ̀ lọ?’
Ní 1993, Werner, òjíṣẹ́ alákòókò kíkún mìíràn, gbìdánwò láti kọjá ibi Ìyawọlẹ̀ Òkun Melville pẹ̀lú ọkọ̀ ojú omi ayára-bí-àṣá, onímítà 5.5 rẹ̀ Qaamaneq (Ìmọ́lẹ̀). Ó ti tukọ̀ ní 1,200 kìlómítà láti Godthåb títí dé agbègbè Upernavik. Síbẹ̀, ríré ibi Ìyawọlẹ̀ Òkun Melville kọjá—400 kìlómítà omi Arctic gbalasa—kì í ṣe ohun tí ó rọrùn. Fún èyí tí ó pọ̀ jù lọ nínú ọdún, yìnyín máa ń dí ìyawọlẹ̀ òkun náà. Werner kẹ́sẹ járí nínú ríré ibi ìyawọlẹ̀ òkun náà kọjá, àní bí ó tilẹ̀ pàdánù ẹ́ńjìnnì kan nítorí yìnyín. Ó ṣì gbìyànjú láti ṣe iṣẹ́ ìwàásù díẹ̀ kí ó tó padà.
Lílọ sí Thule
Lẹ́yìn ìrìn àjò yẹn, Werner bẹ̀rẹ̀ sí í ṣètò míràn. Ó bá Arne àti Karin sọ̀rọ̀—tí àwọn náà ní ọkọ̀ ojú omi, onímítà méje pẹ̀lú ìjókòó mẹ́rin, jù gbogbo rẹ̀ lọ, ó tún ní ohun èèlò ìrìnnà òde òní—nípa jíjùmọ̀ rin ìrìn àjò lọ sí Thule. Àwọn ọkọ̀ ojú omi náà yóò pèsè ibùgbé, tí ọkọ̀ ojú omi méjì bá sì ń rin ìrìn àjò pọ̀, ríré Ìyawọlẹ̀ Òkun Melville kọjá kì yóò léwu púpọ̀. Láti lè kárí ìlú náà gan-an pẹ̀lú 600 olùgbé rẹ̀ àti àwọn ìletò mẹ́fà tí ó wà ní agbègbè náà, wọ́n nílò ìrànlọ́wọ́ sí i. Nítorí náà, wọ́n ké sí Bo àti Helen pẹ̀lú Jørgen àti Inge—tí gbogbo wọn jẹ́ òjíṣẹ́ onírìírí tí ó ti dojúlùmọ̀ pẹ̀lú rírin ìrìn àjò ní orílẹ̀-èdè yìí—láti dara pọ̀ mọ́ wọn. Márùn-ún nínú àwùjọ yìí tún lè sọ èdè Greenland.
Wọ́n fi àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ránṣẹ́ síwájú. Wọ́n di ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ kún ọkọ̀ ojú omi, bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ni àwọn ohun kòṣeémánìí bí oúnjẹ àti omi, epo ọkọ̀, títí kan ẹ́ńjìnnì míràn, àti ọkọ̀ òbèlè onírọ́bà. Lẹ́yìn náà, ní August 5, 1994, lẹ́yìn ìmúrasílẹ̀ ọ̀pọ̀ oṣù, ẹgbẹ́ náà pàdé pọ̀, ọkọ̀ ojú omi méjèèjì sì wà ní sẹpẹ́, a sì di ẹrù sínú wọn ní èbútékọ̀ Ilulissat. Ìrìn àjò sí ìhà àríwá ti yá. Werner, Bo, àti Helen wà nínú ọkọ̀ ojú omi tí ó kéré jù lọ. Bo kọ̀wé pé: “Kìkì ohun tí o lè ṣe ni kí o jókòó tàbí kí o sùn sórí ìjókòó rẹ, kí o sì di nǹkan mú.” Ẹ jẹ́ kí a máa bá àkọsílẹ̀ ìrìn àjò ọkọ̀ òkun náà lọ.
“Òkun pípa rọ́rọ́ lọ salalu. Ìran àrímáleèlọ ṣí payá níwájú wa—òkun tí ń kọ mànà, àwọn ègé kùrukùru gbígbópọn, oòrùn yẹ́ríyẹ́rí àti àwọ sánmà ṣíṣú bí aró, yìnyín líléfòó tí ó jẹ́ onírúurú ìrísí fífani mọ́ra àti oríṣiríṣi àwọ̀, òbúkọ òkun aláwọ̀ ilẹ̀ ń yáàrùn lórí yìnyín líléfòó, etíkun tí ó ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè ṣíṣú dùdù àti pẹ̀tẹ́lẹ̀ díẹ̀—ìyípadà ìran náà kò lópin.
“Àmọ́ ṣáá o, apá tí ó fani lọ́kàn mọ́ra jù lọ ni ṣíṣèbẹ̀wò sí àwọn ìletò tí ó wà lẹ́bàá ọ̀nà. Àwọn ènìyàn, lọ́pọ̀ ìgbà àwọn ọmọdé, sábà máa ń jókòó sórí afárá etíkun láti rí àwọn àlejò náà kí wọ́n sì kí wọn káàbọ̀. A pín ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, a sì yá àwọn ènìyàn náà ní fídíò nípa ètò àjọ wa. Ó ṣeé ṣe fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ láti wò ó kí a tó lọ. Ní Gúúsù Upernavik, ọ̀pọ̀ ènìyàn tukọ̀ wá sí ibi tí ọkọ̀ ojú omi wá wà kí a tó sọ̀kalẹ̀ rárá. Nítorí náà, gbogbo ìrọ̀lẹ́ náà ni àlejò fi ń wọlé wá, tí a sì ń dáhùn àwọn ìbéèrè wọn lórí Bíbélì.”
Wàyí o, lẹ́yìn ìrìn àjò oníkìlómítà 700 àkọ́kọ́, ọkọ̀ ojú omi méjì náà ti wà ní sẹpẹ́ láti ré Ìyawọlẹ̀ Òkun Melville kọjá.
Ìpènijà Líle Koko
“Èyí ni a gbà níbi gbogbo pé ó jẹ́ apá tí ó le jù lọ nínú ìrìn àjò náà. A sì ní láti kọjá láìdúró nítorí pé, ìletò Savissivik (níbi tí agbègbè ìpínlẹ̀ náà ti bẹ̀rẹ̀, tí a sì ti lè rí ibùgbé) ni yìnyín ṣì dí.
“Nítorí náà a gbéra. Níwọ̀n bí yìnyín ti pọ̀ púpọ̀, a tukọ̀ gba ojú òkun gbalasa lọ. Ọpẹ́ ni pé, omi pa rọ́rọ́. Fún ọ̀pọ̀ wákàtí àkọ́kọ́ kò sí ìṣòro—a ń tukọ̀ la ọ̀pọ̀ ibùsọ̀ òkun kọjá. Ní ìrọ̀lẹ́, a ń wo Cape York lọ́ọ̀ọ́kán, a sì rọra yíwọ́ sí ìhà àríwá, níbi tí ó sún mọ́ ilẹ̀. Nísinsìnyí a tún ti kan yìnyín—tí ó ti wà tipẹ́, tí ó gbópọn, yìnyín líléfòó tí ń yòrò bí ojú tí ṣe lè rí i tó. A ń gba etí yìnyín náà lọ fún ìgbà pípẹ́, nígbà míràn a óò dọ́gbọ́n gba ọ̀nà tóóró. Kùrukùru tún wà níbẹ̀, tí ó ní àwọ̀ eérú, tí ó sì gbópọn, tí ó sábà máa ń rẹwà bí oòrùn yẹ́ríyẹ́rí bá ta sí i. Ìgbì pẹ̀lú kò gbẹ́yìn! Kùrukùru, ìgbì, àti yìnyín, gbogbo rẹ̀ ní ọwọ́ kan náà—èyíkéyìí nínú ìwọ̀nyí jẹ́ ìpènijà gidi.”
Kíkí Wa Káàbọ̀
“Bí a ti ń sún mọ́ Pituffik ni a ń wọnú omi pípa rọ́rọ́. Ìṣẹ̀dá kí wa káàbọ̀ lọ́nà kíkàmàmà: oòrùn ta sórí àwọ sánmà dúdú bí aró; itọ́ odò ńlá, tí ń kọ mànà, tí àwọn yìnyín ńláńlá léfòó sórí rẹ̀ wà níwájú wa; òjìji àpáta Dundas tún wà níwájú lọ́hùn-ún—Thule àtijọ́!” Nǹkan bí 100 kìlómítà sí ìhà àríwá, àwọn arìnrìn àjò náà dé ibi tí wọ́n ń lọ gan-an.
Wọ́n ń hára gàgà nísinsìnyí láti bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù láti ilé dé ilé. A dá méjì lára wọn lóhùn lọ́nà tí kò bára dé ní ẹnu ọ̀nà tí wọ́n kọ́kọ́ dé. Wọ́n wí pé: “A kò tẹ́wọ́ gbà wa gan-an bí wọ́n ti máa ń ṣe ní Denmark. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ jù lọ gbà wá tọwọ́tẹsẹ̀. Àwọn ènìyàn náà jẹ́ onírònú àti olórí pípé. Àwọn kan sọ pé, àwọn ti gbọ́ nípa wa, wọ́n sì láyọ̀ pé a wá nígbẹ̀yìngbẹ́yín. A bá àwọn ọmọlúwàbí ènìyàn pàdé, irú bí àwọn aṣọdẹ séálì tí wọ́n wà lẹ́nu ìrìn àjò akọni sí Ìhà Ìpẹ̀kun Àríwá, àti àwọn ọmọ onílẹ̀, tí wọ́n ní ìtẹ́lọ́rùn, tí wọ́n sì ń ṣọ́wó ná, tí wọ́n tún ní ẹ̀mí tàbítàbí nípa ọ̀làjú òde òní.”
Àwọn ọjọ́ díẹ̀ tí ó tẹ̀ lé e, mú ìrírí àtàtà wá fún gbogbo wa. Wọ́n fi ìmọrírì tẹ́wọ́ gba ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì níbi gbogbo. Ní ọ̀pọ̀ ilé, àwọn Ẹlẹ́rìí bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lójú ẹsẹ̀. Inge sọ̀rọ̀ nípa ilé kan níbi tí ó ti rí ẹni tí ó fi ìfẹ́ hàn: “Ilé oníyàrá kan náà mọ́ tónítóní, ó sì tura. Fún ọjọ́ mẹ́ta léraléra, a bẹ ọkùnrin oníwà tútù náà tí ń gbé níbẹ̀ wò, a sì fẹ́ràn rẹ̀ púpọ̀. Ojúlówó aṣọdẹ séálì ni, ọkọ̀ ojú omi rẹ̀ sì wà ní ìta ilé rẹ̀. Ó ti pa ọ̀pọ̀ béárì ìpẹ̀kun ayé, àwọn òbúkọ òkun, àti séálì pẹ̀lú. Nígbà tí a ṣèbẹ̀wò kẹ́yìn, a gbàdúrà pẹ̀lú rẹ̀, ojú rẹ̀ sì lé roro fún omijé. Wàyí o, a gbọ́dọ̀ fi ohun gbogbo lé Jèhófà lọ́wọ́, kí a sì fojú sọ́nà fún àkókò àti àǹfààní láti padà wá.”
Àwọn Eskimo ará Kánádà ṣèbẹ̀wò léraléra sí Thule. Inge ròyìn pé: “Èmi àti Helen bá ọ̀pọ̀ àwọn Eskimo láti Kánádà pàdé. Ó dùn mọ́ni pé wọ́n lè jùmọ̀ sọ̀rọ̀ pọ̀ pẹ̀lú àwọn ará Greenland; ó dà bí pé èdè tí ó jọra ni àwọn ará agbègbè Arctic ń sọ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Eskimo ará Kánádà ní èdè tiwọn ti wọ́n ń kọ sílẹ̀, wọ́n lè ka ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa ní èdè Greenlandic. Èyí lè ṣí àwọn àǹfààní arùmọ̀lára sókè sílẹ̀ fún wọn.”
A tún lo ọkọ̀ ojú omi láti ṣèbẹ̀wò sí àwọn ìletò tí ó jìnnà tó 50 sí 60 kìlómítà. “Bí a ṣe ń lọ sí ìletò Qeqertat, a ń gba ọ̀nà etíkun lọ, pẹ̀lú ìrètí pé a óò rí àwọn tí ń ṣọdẹ ẹran omi narwhal. Gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti retí, lórí òkè àpáta kan, a rí àgọ́ kan níbẹ̀, tí ó ní ìdílé mẹ́ta tàbí mẹ́rin nínú, tí wọ́n wọ ẹ̀wù onírun, pẹ̀lú àgọ́ wọn àti ọkọ̀ ojú omi wọn. Pẹ̀lú ọ̀kọ̀ ní ọwọ́ wọn, àwọn ọkùnrin náà jókòó lórí àpáta láti máa ṣọ́ ẹran omi narwhal tí àwọn ènìyàn fẹ́ràn púpọ̀. Níwọ̀n bí wọ́n ti dúró fún ọ̀pọ̀ ọjọ́ láìrí ohunkóhun pa, inú wọn kò dùn láti rí wa nítorí pé a lè lé àwọn ẹja àbùùbùtán padà! Ó dà bí ẹni pé ìgbòkègbodò tiwọn ni ó gbà wọ́n lọ́kàn. Àwọn obìnrin tẹ́wọ́ gba ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ díẹ̀, ṣùgbọ́n àkókò kò tí ì sí fún ìjíròrò síwájú sí i. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín a gúnlẹ̀ sí Qeqertat ní agogo 11 alẹ́, a sì parí ìkésíni wa tí ó kẹ́yìn ní ìletò náà ní agogo méjì òru!”
“Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, a gúnlẹ̀ sí Siorapaluk, ìletò ìpẹ̀kun àríwá ní Greenland. Ó wà lórí yanrìn etíkun ní ìsàlẹ̀ àwọn àpáta tí ewéko tútù bò lórí ní àyíká aṣálẹ̀ kan.” Ní ti gidi, àwọn Ẹlẹ́rìí ti dé apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé, ó kéré tán, ní apá àríwá, nínú iṣẹ́ ìwàásù wọn.
Ìrìn Àjò Parí
Àwọn Ẹlẹ́rìí ti parí iṣẹ́ wọn. Wọ́n ti wàásù láti ilé dé ilé àti láti àgọ́ dé àgọ́, wọ́n fúnni ní ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́, wọ́n gba àsansílẹ̀ owó, wọ́n fi fídíò hàn wọ́n, wọ́n bá ọ̀pọ̀ àwọn ará Greenland sọ̀rọ̀, wọ́n sì darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Wàyí o, ilé tóó lọ. “Nígbà tí a wọ inú ọkọ̀ òbèlè wa lálẹ́ ọjọ́ yẹn láti tukọ̀ lọ sí ìletò Moriusaq, àwọn ènìyàn díẹ̀ wà nísàlẹ̀ ní etíkun láti kí wa pé ó dìgbòóṣe, ní fífi àwọn ìwé ńlá àti ìwé pẹlẹbẹ tí wọ́n ti gbà juwọ́ sí wa.”
Nígbà tí ó ṣe, ní àdádó kan ní etíkun náà, ó ya àwọn Ẹlẹ́rìí náà lẹ́nu láti rí ọkùnrin kan tí ń juwọ́ láti orí àpáta—níbẹ̀ ní ibi tí ó jẹ́ àdádó pátápátá! “Àmọ́ ṣáá o, a sọ̀kalẹ̀ láti lọ bá a. Ó jẹ́ ọ̀dọ́kùnrin kan láti Berlin, Germany, tí ó ń rin ìrìn àjò etíkun nínú ọkọ̀ ojú omi rẹ̀, tí ó sì ti wà lẹ́nu rẹ̀ fún oṣù kan. Ní Germany, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń bẹ̀ ẹ́ wò déédéé, ó sì ní ọ̀pọ̀ ìwé wọn lọ́wọ́. A lo ọ̀pọ̀ wákàtí lọ́dọ̀ rẹ̀, orí rẹ̀ sì wú gan-an fún pípàdé àwọn Ẹlẹ́rìí ní irú ibi bẹ́ẹ̀.”
A kí àwọn òjíṣẹ́ arìnrìn àjò náà káàbọ̀ lọ́nà tí ó ga lọ́lá nígbà tí a padà sí ìletò Savissivik, tí a yẹ sílẹ̀ nígbà tí a ń lọ. Àwọn kan ti gba ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wa ní ọdún tí ó kọjá, wọ́n sì ti kà á, ebi oúnjẹ tẹ̀mí sì ń pa wọ́n.
Pípadà ré ibi Ìyawọlẹ̀ Òkun Melville kọjá gba wákàtí 14. “A rí wíwọ̀ oòrùn, èyí tí ń gba ọ̀pọ̀ wákàtí níhìn-ín, pẹ̀lú ìyípadà léraléra sí onírúurú àwọ̀ fífani mọ́ra. Yíyọ oòrùn, èyí tí ó tẹ̀ lé e, ń gba ọ̀pọ̀ wákàtí pẹ̀lú. Bí wíwọ̀ oòrùn tí ó dà bí abẹ̀bẹ̀ pupa rírẹ̀ dòdò ṣe bo àwọ sánmà ìhà ìlà oòrùn àríwá, oòrùn tún yọ ní itòsí gúúsù. Ìran kan tí ó ṣòro láti ṣàpèjúwe—kódà láti ya fọ́tò rẹ̀—bí ó ṣe rí gan-an.” Agbo òṣìṣẹ́ náà kò sùn tí ilẹ̀ fi mọ́.
“Nígbà ti a óò fi dé Kullorsuaq, ó ti rẹ̀ wá tẹnutẹnu. Ṣùgbọ́n inú wá dùn, ọkàn wa sì balẹ̀. A ti parí ìrìn àjò wa pẹ̀lú ìkẹ́sẹjárí! Nínú ìrìn àjò yòókù, a rí ọ̀pọ̀ àwọn tí ó fi ìfẹ́ hàn ní àwọn ìlú àti ìletò tí ó wà ní etíkun. Ìbéèrè tí wọ́n sábà máa ń béèrè ni pé, ‘Èé ṣe tí díẹ̀ nínú yín kò fi lè dúró sọ́dọ̀ wa? Kò wù wá kí ẹ tètè fi wá sílẹ̀!’”
Ní Qaarsut, ìdílé oníwà-bí-ọ̀rẹ́ kan ké sí márùn-ún nínú àwọn àlejò náà láti wá jẹun pẹ̀lú wọn. “Ìdílé náà fẹ́ kí a sùn di ilẹ̀ẹ́mọ́. Ṣùgbọ́n níwọ̀n bí àwọn èbútékọ̀ míràn tí ó sàn jù ti wà ní 40 kìlómítà níwájú, a kò sùn, a sì ń tukọ̀ wa lọ. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn a gbọ́ pé, ìṣùpọ̀ yìnyín líléfòó kan fọ́ ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ìgbì sì sojú ọkọ̀ ojú omi kékeré 14 dé níbi tí a wà lánàá!”
Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, àwùjọ náà padà sí Ilulissat, lẹ́yìn tí wọ́n parí ìrìn àjò akọni wọn sí Thule. Ní nǹkan bí àkókò yẹn gan-an, àwọn akéde méjì ti rin ìrìn àjò lọ sí àwọn apá jíjìnnà jù lọ ní ìlà oòrùn etíkun Greenland. Nínú ìrìn àjò méjèèjì yìí, àwọn akéde náà fi àpapọ̀ 1,200 ìwé ńlá, 2,199 ìwé pẹlẹbẹ, àti 4,224 ìwé ìròyìn sóde, wọ́n sì gba 152 àsansílẹ̀ owó. Tẹlifóònù àti lẹ́tà ni a fi ń kàn sí ọ̀pọ̀ àwọn olùfìfẹ́hàn nísinsìnyí.
Láìka àkókò, okun, àti owó tí ó ní nínú sí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń rí ìdùnnú ńláǹlà nínú títẹ̀ lé àṣẹ Ọ̀gá wọn láti “jẹ́ ẹlẹ́rìí . . . títí dé apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé.’—Ìṣe 1:8.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 28]
Ní Ìlà Oòrùn Etíkun Greenland
Ó FẸ́RẸ̀Ẹ́ jẹ́ àkókò kan náà tí àwùjọ akéde náà dé Thule, ni tọkọtaya Ẹlẹ́rìí kan, Viggo àti Sonja, rin ìrìn àjò lọ sí agbègbè ìpínlẹ̀ míràn tí a kò ṣe rí—Ittoqqortoormiit (Scoresbysund) ní ìlà oòrùn etíkun Greenland. Láti lè débẹ̀, wọ́n ní láti rin ìrìn àjò lọ sí Iceland, kí wọ́n wọ ọkọ̀ òfuurufú padà sí Constable Point lórí etíkun Greenland, wọ́n sì tibẹ̀ wọ hẹlikọ́pítà.
Àwọn aṣáájú ọ̀nà méjì wọ̀nyí, tí èdè àbínibí wọn jẹ́ ti àwọn ará Greenlandic sọ pé: ‘Ìgbà àkọ́kọ́ tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò wà síhìn-ín nìyí. Láìka pé wọ́n wà ní àdádó sí, orí àwọn ènìyàn náà pé lọ́nà tí ó yani lẹ́nu. Síbẹ̀, inú wọn tún dùn láti kọ́ ohun tuntun. Gẹ́gẹ́ bí àwọn tí ó lẹ́bùn ìtàn sísọ, wọ́n fi ìháragàgà sọ fún wa nípa bí wọ́n ṣe ń ṣọdẹ séálì àti àwọn ìrírí mìíràn nípa ìṣẹ̀dá.” Báwo ni wọ́n ṣe dáhùn padà sí iṣẹ́ ìwàásù náà?
“Nígbà tí a ń wàásù láti ilé dé ilé, a pàdé J——, ẹni tí í ṣe katikíìsì. Ó wí pé: “Mo dúpẹ́ púpọ̀ pé ẹ fi mi kún àwọn ti ẹ óò bẹ̀ wò.’ A fi ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wa hàn án àti bí a ṣe lè lò ó. Ní ọjọ́ kejì, ó wá sọ́dọ̀ wa, ó sì fẹ́ láti kọ́ nípa orúkọ Jèhófà. A fi àlàyé kan nínú àkíyèsí ẹsẹ̀ ìwé hàn án nínú Bíbélì èdè àwọn ará Greenland tirẹ̀. Nígbà tí a kúrò, ó tẹ àwọn ọ̀rẹ́ wa láago ní Nuuk láti bá òun dúpẹ́ fún ìbẹ̀wò wa. A gbọ́dọ̀ máa bá a nìṣó ní ríran ọkùnrin yìí lọ́wọ́.
“A tún pàdé O——, olùkọ́ kan tí ó mọ̀ nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó fún wa ní wákàtí méjì láti bá kíláàsì rẹ̀ sọ̀rọ̀ tí ó ní àwọn ọmọ ọdún 14 sí 16. Nítorí náà, a fi fídíò wa hàn wọ́n, a sì dáhùn àwọn ìbéèrè wọn. Kíá ni wọ́n gba Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́a àti àwọn ìwé mìíràn. A pàdé mẹ́ta nínú àwọn ọmọbìnrin náà lẹ́yìn náà. Wọ́n ní ọ̀pọ̀ ìbéèrè, ọ̀kan nínú wọn sì ní ọkàn ìfẹ́ gan-an. Ó béèrè pé, ‘Báwo ni ẹnì kan ṣe lè di Ẹlẹ́rìí? Yóò jẹ́ ohun tí ó dára púpọ̀ láti dà bíi tiyín. Dádì mi pẹ̀lú fẹ́ràn ohun tí ẹ ń ṣe.’ A ṣèlérí láti kọ̀wé.
“Nínú ọ̀kan nínú àwọn ìletò náà, a pàdé katikíìsì míràn, M——, a sì ní ìjíròrò fífani mọ́ra pẹ̀lú rẹ̀. Ó sọ pé òun yóò rí i dájú pé àwọn ọkùnrin tí wọ́n ṣọdẹ lọ yóò rí ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wa gbà láìpẹ́ bí wọ́n bá ti ń padà dé. Nítorí náà, òun ni ‘akéde’ wa ní àdádó yẹn.”
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ ìrìn àjò aláyìípoyípo, tí ó sì ń tánni lókun, àwọn aṣáájú ọ̀nà méjì náà nímọ̀lára pé a bù kún ìsapá wọn ní jìngbìnnì.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A tẹ̀ ẹ́ jáde láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.