Ìwàláàyè Ha Wà Lẹ́yìn Ikú Bí?
FÚN ọ̀pọ̀ ẹgbẹ̀rúndún, ìbéèrè méjì ni ó ti ń pin aráyé lẹ́mìí: Èé ṣe tí a fi ní láti darúgbó, kí a sì kú lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn? Ìwàláàyè èyíkéyìí tí a ń nímọ̀lára rẹ̀ ha wà lẹ́yìn ikú bí?
Ọ̀pọ̀ ènìyàn ni ìbéèrè àkọ́kọ́ ti pin lẹ́mìí nítorí pé ìmọ̀ ìṣègùn sáyẹ́ǹsì pàápàá, pẹ̀lú gbogbo arabaríbí àwárí rẹ̀, kò tí ì lè pèsè ìdáhùn gúnmọ́ tàbí ìdáhùn tí ń tẹ́ni lọ́rùn.
Ọ̀pọ̀ yanturu ìdáhùn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ti wà sí ìbéèrè kejì. Bí ó ti wù kí ó rí, ní gbogbogbòò, a wádìí ìdáhùn lórí bóyá ìwàláàyè tí a ń nímọ̀lára rẹ̀ ń bẹ lẹ́yìn ikú, lẹ́nu àwọn tí wọ́n sọ pé kì í ṣe ìwàláàyè yìí ni gbogbo ohun tí ó wà àti àwọn tí wọ́n rinkinkin mọ́ ọn bákan náà pé ìwàláàyè ń dópin nígbà ikú. Ọ̀pọ̀ nínú ẹgbẹ́ tí a mẹnu kàn kẹ́yìn yìí sọ fún wa pé ó dá àwọn lójú hán-ún-hán-ún pé ìwàláàyè kúkúrú tí ènìyàn ń ní ni gbogbo ohun tí ó lè fojú sọ́nà fún. Lọ́pọ̀ ìgbà, bí a bá jiyàn èyí, ìdáhùn àfigbera-ẹni-lẹ́sẹ̀ tí a máa ń rí gbà ni pé: “Ó dára, kò sí ẹni tí ó tí ì tibẹ̀ wá láti sọ fún wa, àbí ó wà?”
Bí ó ti máa ń ṣẹlẹ̀ nínú àwọn ìbéèrè míràn tí ń fa àríyànjiyàn, ọ̀pọ̀ ń bẹ tí wọn kò tí ì pinnu síbẹ̀—ní sísọ pé àwọ́n máa ń gbọ́ tìhín tọ̀hún lọ́nà kan tàbí òmíràn. Ṣùgbọ́n àwọn mìíràn yóò dáhùn, bóyá pẹ̀lú àìbìkítà pé: “A ní láti dúró di ìgbà tí àkókò yẹn bá dé!”
Ìbéèrè Ọlọ́jọ́ Pípẹ́
Ará Ìlà Oòrùn náà, Jóòbù, tí a mọ̀ bí ẹní mowó, tí ó gbajúmọ̀ nítorí sùúrù rẹ̀ lójú ìjìyà, ni ó gbé ìbéèrè àkọ́kọ́ dìde nípa ìwàláàyè lẹ́yìn ikú, ní nǹkan bí 3,500 ọdún sẹ́yìn. Jóòbù gbé ìbéèrè rẹ̀ kalẹ̀ lọ́nà yìí pé: “Ènìyàn kú, a sì sin ín; ó mí èémí rẹ̀ ìkẹyìn kò sì sí mọ́. Bí omí ti í pòórá nínú òkun tàbí bí ìsàlẹ̀ odò ti í yán tí í sì í gbẹ, bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn dùbúlẹ̀ tí kò sì dìde . . . Bí ènìyàn bá kú, yóò ha tún wà láàyè bí?”—Jóòbù 14:10-14, New International Version.
Ṣùgbọ́n kì í ṣe Jóòbù nìkan ni ó béèrè ìbéèrè nípa ìwàláàyè lẹ́yìn ikú. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, Encyclopædia of Religion and Ethics, fúnni ní ìsọfúnni tí ń lani lóye yìí lábẹ́ àkòrí náà, “Ipò Tí Àwọn Òkú Wà,” pé: “Kò sí kókó ẹ̀kọ́ kan ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ìwàláàyè ẹ̀dá tí ó ré kọjá ìmọ̀ rẹ̀, tí ó tí ì gba èrò inú ènìyàn pátápátá bíi ti ipò rẹ̀ lẹ́yìn ikú. [Àwọn ọmọ ìbílẹ̀] ní gbogbo ẹkùn ayé ní gbogbogbòò ní èrò ṣíṣe kedere, tí ó sì dájú hán-ún, nípa ayé ẹ̀mí—ìgbésí ayé tí ó wà níbẹ̀, àwọn ohun tí a fi lè dá a mọ̀ yàtọ̀, ìrísí ojú ilẹ̀ rẹ̀—èyí sì fi hàn bí kókó ẹ̀kọ́ náà ṣe jẹni lógún lọ́nà gíga tó. Ìbẹ̀rù tí ó tàn kálẹ̀ nípa àwọn òkú tọ́ka sí èrò àtijọ́ náà pé ìwàláàyè kò dópin sí ipò tí àwọn òkú wà. Ikú ti ké agbára kúrò; ìyẹ́n dájú ṣáká; ṣùgbọ́n àwọn agbára mìíràn kò ha wà lẹ́nu iṣẹ́, àbí àwọn agbára wọ̀nyẹn kò ha dáńgájíá láti fara hàn lọ́nà jíjáfáfá, tí ó sì lè yani lẹ́nu bí? Yálà àwọn ènìyàn kọ́kọ́ gbà gbọ́ pé ẹ̀mí, ọkàn, tàbí ẹ̀mí òkú, máa ń fi ara sílẹ̀, tàbí wọn kì í ṣe bẹ́ẹ̀, ó dà bíi pé a ní ọ̀pọ̀ ìdí láti gbà gbọ́ pé wọ́n gbà pé àwọn òkú ṣì ń wà láàyè ní irú àwọn ọ̀nà kan.”
O lè jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ìsọ̀rí mẹ́ta tí a mẹ́nu kàn lókè, ìyẹn ni pé: àwọn tí kò ní ìdánilójú nípa ohun tí ń ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ikú; àwọn tí wọ́n ní ìdánilójú pé irú ìwàláàyè kan ń bẹ lẹ́yìn ikú; tàbí àwọn tí wọ́n ní ìdánilójú pé ìwàláàyè yìí ni gbogbo ohun tí ó wà. Ohun yòó wù kí ọ̀ràn náà jẹ́, a ké sí ọ láti fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó tẹ̀ lé e. Wò ó bóyá ìwọ yóò rí ẹ̀rí dídánilójú tí ó bá Bíbélì mu nínú rẹ̀ pé ìfojúsọ́nà àgbàyanu fún ìgbésí ayé aláyọ̀ ń bẹ lẹ́yìn ikú, bí yóò ṣe wáyé, ibi tí yóò ti wáyé, àti ìgbà tí yóò wáyé.