ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w96 10/15 ojú ìwé 25-29
  • Àyíká Ipò Fún Ìdàgbàsókè ní Equatorial Guinea

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àyíká Ipò Fún Ìdàgbàsókè ní Equatorial Guinea
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Fífúnrúngbìn ní Kùtùkùtù Àwọn Ọjọ́
  • “Àìní Wọn Nípa Tẹ̀mí Jẹ Wọ́n Lọ́kàn”
  • Mímú Kí Ìdàgbàsókè Tẹ̀ Síwájú Nípa Pípéjọpọ̀
  • Fífi Sùúrù Bomi Rin Irúgbìn Náà
  • Ríran Àwọn Ènìyàn Lọ́wọ́ Láti Mú Ìgbésí Ayé Wọn Sunwọ̀n Sí i
  • Dídi Ẹrú Ọlọ́run
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
w96 10/15 ojú ìwé 25-29

Àyíká Ipò Fún Ìdàgbàsókè ní Equatorial Guinea

IGBÓ kìjikìji ni èrò tí yóò kọ́kọ́ wá sọ́kàn arìnrìn àjò kan bí ọkọ̀ òfuurufú rẹ̀ ṣe ń balẹ̀ gẹẹ ní pápákọ̀ òfuurufú ti orílẹ̀-èdè, ní Equatorial Guinea. Àwọn igi ńláńlá yí ọ̀nà ọkọ̀ òfuurufú ká, wọ́n sì mú kí àwọn ilé pápákọ̀ òfuurufú dà bíi pé wọ́n kéré. Igbó títutù yọ̀yọ̀ gbalẹ̀ kan láti etíkun títí dé ṣóńṣó orí òkè, eji wọwọ òjò àti ìdiwọ̀n ìgbóná-òun-ìtutù tí ń wà ní àárín 80 sí 90 yípo ọdún ń mú kí wọ́n gbọ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀.

Oríṣi ìdàgbàsókè ńláǹlà míràn tún ń ṣẹlẹ̀ ní Equatorial Guinea, “ìdàgbà tí Ọlọ́run ń fi fúnni.” (Kólósè 2:19) Gẹ́gẹ́ bí òṣìṣẹ́ olóyè ará Etiópíà tí ó béèrè fún ìrànlọ́wọ́ Fílípì, ọ̀pọ̀ níhìn-ín ń dàníyàn láti lóye Ìwé Mímọ́. (Ìṣe 8:26-39) Kì í ṣe ohun àjèjì kí ẹnì kan tọ ọ̀kan nínú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ lójú pópó, kí ó sì béèrè fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àwọn Ẹlẹ́rìí tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 325 ní Equatorial Guinea ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí ó lé ní ẹgbẹ̀rún.

Fífúnrúngbìn ní Kùtùkùtù Àwọn Ọjọ́

Equatorial Guinea, orílẹ̀-èdè tí ó kéré jù lọ ní Áfíríkà, wà ní gúúsù Nàìjíríà àti Cameroon. (Wo àwòrán ilẹ̀.) Àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n jẹ́ ará Nàìjíríà tí wọ́n wáṣẹ́ wá sí oko kòkó ni wọ́n kọ́kọ́ mú ìhìn rere náà wá síhìn-ín. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a dá ọ̀pọ̀ ìjọ tí ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì sílẹ̀, a pa wọ́n rẹ́ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn nígbà tí àwọn arákùnrin wọ̀nyí padà sí Nàìjíríà. Ṣùgbọ́n, kété lẹ́yìn tí orílẹ̀-èdè náà gbòmìnira ní ọdún 1968, a rán tọkọtaya míṣọ́nnárì mẹ́ta ti Watchtower wá síhìn-ín. Ìṣòro ìṣèlú kò jẹ́ kí wọ́n lè dúró pẹ́, ṣùgbọ́n ìjẹ́rìí wọn mú èso rere jáde.

Santiago, ọ̀kan nínú àwọn míṣọ́nnárì náà, pàdé Buenaventura, ọkùnrin gíga kan, tí ó taagun, tí àwọn ará àdúgbò mọ̀ gẹ́gẹ́ bí erìkìnà. Ó jẹ́ olùfọkànsìn tí ó bọ̀wọ̀ fún Bíbélì, síbẹ̀ inú rẹ̀ kì í pẹ́ ru. Ìwọ̀sí bíńtín ti tó láti mú kí ó lu ẹnì kan lálùbolẹ̀. Nígbà tí inú bí i ní ilé ọtí kan, gbogbo àwọn tí ó wà níbẹ̀ fọ́n ká, wọn tilẹ̀ gba ojú fèrèsé bẹ́ síta, kí wọn baà lè bọ́ lọ́wọ́ ìkúùkù rẹ̀. Ní ti gidi, bí ó ṣe ń tẹ́tí sí Santiago, ó pète láti lù ú lálùbolẹ̀ bí kò bá lè pèsè ẹ̀rí ìdánilójú nínú Ìwé Mímọ́ fún ohun tí ó sọ. Ó sọ fún ara rẹ̀ pé: ‘Kò sí ẹni tí ó lè fi ọ̀bọ lọ erìkìnà.’ Ohun tí ó gbọ́ fà á lọ́kàn mọ́ra, ní pàtàkì nípa ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun lórí párádísè ilẹ̀ ayé, nítorí náà ó gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Bí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà ṣe ń tẹ̀ síwájú, ìfẹ́ ọkàn Buenaventura láti wà láàyè títí láé nínú Párádísè túbọ̀ lágbára sí i, ó sì kẹ́kọ̀ọ́ pé òun yóò ní láti mú ìgbésí ayé òun bá ìlànà Ọlọ́run mu láti baà lè jèrè irú ẹ̀bùn bẹ́ẹ̀. Ní mímọ̀ pé àwọn Kristẹni tòótọ́ kò gbọdọ̀ “fi ibi san ibi fún ẹnì kankan,” ó bẹ̀rẹ̀ sí sapá gidigidi láti ṣàkóso ìbínú rẹ̀.—Róòmù 12:17.

Ìdánwò gan-an dé ní ọjọ́ kan, nígbà tí ó ṣèèṣì fọ́ ife oníbàárà kan ní ilé ọtí kan. Inú bí ọkùnrin náà, ó sì di ìgbájú rù ú. Àwọn tí ó kù nínú ilé ọtí náà fọ́n ká, ní ríretí pé kí ìjà àjàkúakátá bẹ́ sílẹ̀. Àmọ́, Buenaventura rọra san owó ife tí ó fọ́, ó ra ọtí mìíràn fún ọkùnrin náà, ó sì tọrọ àforíjì fún ìwà òmùgọ̀ rẹ̀. Nígbà tí àwọn aládùúgbò rí i pé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ti ṣe irú ìyípadà bẹ́ẹ̀ nínú rẹ̀, ọ̀pọ̀ ṣe tán láti jẹ́ kí ó máa bá wọn kẹ́kọ̀ọ́. Nígbà tí Buenaventura yóò fi ṣèrìbọmi, ó ti ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì márùn-ún. Ó ti ṣiṣẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà fún ọdún márùn-ún tí ó kọjá, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ènìyàn ṣì ń pè é ní erìkìnà, nísinsìnyí, wọ́n wulẹ̀ fi ń bá a ṣàwàdà ni.

“Àìní Wọn Nípa Tẹ̀mí Jẹ Wọ́n Lọ́kàn”

Ní àwọn ọdún 1970, àwọn Ẹlẹ́rìí díẹ̀ tí ó wà ládùúgbò ń bá wíwàásù àti pípàdé pọ̀ nìṣó dé ibi tí agbára wọ́n mọ. Lẹ́yìn náà, ọ̀pọ̀ míṣọ́nnárì tọkọtaya ará Sípéènì wá láti ṣèrànlọ́wọ́. Andrés Botella, tí ó ti ṣiṣẹ́ sìn ní Equatorial Guinea fún ọdún 12, rántí pé kété lẹ́yìn tí òún dé, bí ‘àìní nípa tẹ̀mí ti àwọn ènìyàn náà ṣe ń jẹ wọ́n lọ́kàn’ wú òun lórí. (Mátíù 5:3) Ó sọ pé: “Ìdùnnú gidi ni ó jẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú irú àwọn ènìyàn onímọrírì bẹ́ẹ̀.”

Mary, arábìnrin ará Sípéènì, ń bá ọ̀ṣọ́ọ́rọ́ obìnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ María kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ẹni tí ó sọ pé àwọn òbí òun, Francisco àti Fausta, pẹ̀lú nífẹ̀ẹ́ sí kíkẹ́kọ̀ọ́. Níwọ̀n bí Mary ti ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ 15, tí ibi tí àwọn òbí María sì ń gbé nasẹ̀ díẹ̀, ọ̀sẹ̀ púpọ̀ kọjá kí ó tó lè bẹ̀ wọ́n wò.

Nígbà tí Mary àti ọkọ rẹ̀, Serafín, bá àwọn òbí náà pàdé nígbẹ̀yìngbẹ́yín, wọ́n ti ní ìwé náà Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Ayea àti Bíbélì kan, wọ́n sì ti ń hára gàgà láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́. Nítorí náà, ojú ẹsẹ̀ ni wọ́n bẹ̀rẹ̀. Serafín ṣàkíyèsí pé àwọn òbí María ti dojúlùmọ̀ pẹ̀lú àkójọpọ̀ ẹ̀kọ́ náà dáradára. Ohun kan náà ni ó ṣẹlẹ̀ nígbà ìkésíni ẹlẹ́ẹ̀kejì, nígbà tí wọ́n kárí orí kejì. Serafín rántí pé: “Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ dà bíi bíbá Ẹlẹ́rìí méjì tí wọ́n ti ṣèrìbọmi ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́.” Nígbà ìbẹ̀wò kẹta, níwọ̀n bí ó ti dà bíi pé wọ́n mọ àkójọpọ̀ ẹ̀kọ́ náà dáradára, Serafín dábàá pé kí òun wulẹ̀ máa béèrè ìbéèrè, kí wọ́n sì máa dáhùn, láti lè mọ bí wọ́n ṣe lóye rẹ̀ níti gidi tó. Ó rí i pé Francisco àti Fausta ti fúnra wọn kẹ́kọ̀ọ́ ìwé náà látòkè délẹ̀!

Báwo ni ìmọ̀ wọn tuntun ṣe nípa lórí wọn? Ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí wọ́n ti kọ́, wọ́n ti dẹ́kun lílọ sí àwọn ìpàdé ìbẹ́mìílò, wọ́n sì ti já okùn àjọṣe wọn pẹ̀lú Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì. Síwájú sí i, Francisco kò mu sìgá mọ́, wọn kò sì jẹ́ ẹran tí a kò dú mọ́. Níwọ̀n bí ó ti hàn gbangba pé wọ́n fi ohun gbogbo tí wọ́n kọ́ sílò, a fún wọn níṣìírí láti bẹ̀rẹ̀ sí ṣàjọpín ìmọ̀ wọn pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Kíá ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí wàásù fún àwọn aládùúgbò wọn. Láàárín oṣù mẹ́ta péré, wọ́n ti tóótun fún ìrìbọmi. Nísinsìnyí, ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ni Francisco, ọpẹ́ sì ni fún àpẹẹrẹ rere àti ìtara wọn nínú wíwàásù, mẹ́ta nínú àwọn ọmọbìnrin wọn ti di Ẹlẹ́rìí nísinsìnyí, àwọn ọmọkùnrin wọn méjèèjì ń wá sí ìpàdé, àwọn ìbátan mẹ́fà mìíràn sì ń kẹ́kọ̀ọ́.

Kò pẹ́ lẹ́yìn tí ó ṣe ìrìbọmi, Francisco bá Pablo pàdé, Kátólíìkì olùfọkànsìn tí ń ṣiṣẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bí agbọ́pàá àlùfáà ní ṣọ́ọ̀ṣì rẹ̀. Pablo máa ń darí ìsìn nígbà tí àlùfáà kò bá sí nílé. Bí mẹ́ḿbà ṣọ́ọ̀ṣì kan bá ń ṣàìsàn, yóò ṣẹ̀bẹ̀wò; bí ẹní kan kò bá wá sí ṣọ́ọ̀ṣì, Pablo yóò lọ fún un ní ìṣírí; bí ẹnì kan bá sì kú, yóò ṣe gbogbo ohun tí ó bá lè ṣe láti tu ìdílé náà nínú. Lọ́nà tí ó yéni, gbogbo àwọn tí ó wà ní ẹkùn náà fẹ́ràn Pablo.

Níwọ̀n bí Pablo ti ní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún Bíbélì, ó tètè tẹ́wọ́ gba ohun tí Francisco fi lọ̀ ọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú rẹ̀. Kíá ni Pablo mọ bí ìhìn iṣẹ́ Bíbélì ti lọ́gbọ́n nínú tó, lẹ́yìn tí ó sì ti kẹ́kọ̀ọ́ díẹ̀, ó pinnu láti lo díẹ̀ lára àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí ó ti kọ́ nígbà ọ̀kan nínú “ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn” tí ó ṣe sọ́dọ̀ mẹ́ḿbà ṣọ́ọ̀ṣì kan tí ń ṣàìsàn. Kété lẹ́yìn náà, nínú ọ̀kan nínú àwọn ìwàásù rẹ̀ ọjọ́ Sunday, Pablo ṣàlàyé ìjẹ́pàtàkì lílo orúkọ Ọlọ́run, Jèhófà, àti ìdí tí kò fi yẹ kí a lo ère.

Níwọ̀n bí ó ti tẹ́wọ́ gba òtítọ́ náà dáradára, ó retí pé àwọn mẹ́ḿbà yòó kù nínú ṣọ́ọ̀sì rẹ̀ yóò hùwà padà bákan náà. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìwàásù mẹ́ta tàbí mẹ́rin ti àwọn ìwàásù tí a gbéka orí Bíbélì wọ̀nyí, Pablo kíyè sí i pé inú àwọn ènìyàn náà kò dùn sí ìsọfúnni tí òún ń gbé kalẹ̀. Nítorí náà, ó pinnu láti fi ṣọ́ọ̀ṣì náà sílẹ̀, kí ó sì máa dara pọ̀ mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà déédéé. Láàárín oṣù díẹ̀, ó tóótun fún ìrìbọmi, ó sì jẹ́ olùfìtara wàásù ìhìn rere náà báyìí. Bí kò tilẹ̀ lè wàásù ní àkókò kíkún, ó ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mẹ́wàá lọ́wọ́.

Mímú Kí Ìdàgbàsókè Tẹ̀ Síwájú Nípa Pípéjọpọ̀

Àwọn Ẹlẹ́rìí ní Equatorial Guinea mú àṣẹ Bíbélì náà láti má ṣe kọ ìpéjọpọ̀ sílẹ̀ ní ọ̀kúnkúndùn. (Hébérù 10:25) Láti ọdún 1994, nígbà tí ìjọba ti fàṣẹ sí iṣẹ́ náà lẹ́ẹ̀kan sí i, àwọn ará ti ń hára gàgà láti ní àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tí ó bójú mu. Ní tòótọ́, ọ̀pọ̀ jù lọ ìjọ ti kọ́ gbọ̀ngàn tiwọn fúnra wọn tàbí kí wọ́n wà lẹ́nu àtikọ́ ọ́.

Ní Mongomo, níbi tí àwọn tí ń wà sì ìpàdé ní ọjọ́ Sunday tí ń lọ sókè dé ìlọ́po méjì ààbọ̀ iye àwọn akéde Ìjọba, ìjọ náà ti ń ṣiṣẹ́ kára láti kọ́ ibi ìpàdé ńlá. Àwọn ìsìn míràn ní Mongomo sábà máa ń gba àwọn òṣìṣẹ́ láti kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì wọn, nítorí náà, a kò ṣàìkíyè sí ìgbòkègbodò àwọn Ẹlẹ́rìí. Ní ọjọ́ kan, pásítọ̀ Iglesia Nueva Apostólica, (New Apostolic Church) dúró láti béèrè lọ́wọ́ ọ̀kan nínú àwọn alàgbà, iye tí ó ń san fún àwọn òṣìṣẹ́ kára wọ̀nyí. Pásítọ̀ náà wí pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òún ti gba àwọn ọ̀mọ̀lé kan tí wọ́n jẹ́ mẹ́ḿbà ṣọ́ọ̀ṣì òun, iṣẹ́ náà ń falẹ̀ gidigidi. Ó ṣe kàyéfì bóyá òún lè gba àwọn òṣìṣẹ́ tí ń kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba. Nígbà tí a sọ fún un pé gbogbo àwọn Ẹlẹ́rìí náà ń ṣiṣẹ́ lọ́fẹ̀ẹ́, pẹ̀lú ìyàlẹ́nu ni ó fi bá tirẹ̀ lọ.

Wíwà sí ìpàdé lè béèrè fún ìrúbọ níwọ̀nba níhà ọ̀dọ̀ àwọn tí wọ́n ń gbé ibi tí ó jìnnà sí Gbọ̀ngàn Ìjọba. Juan, ọ̀dọ́mọkùnrin kan tí ó ṣe batisí ní ọdún 1994, dojú kọ ipò yìí. Ó gbọ́ nípa òtítọ́ ní Gabon, níbi tí ó ti kọ́ ìwé Walaaye Titilae dé ìlàjì. Lẹ́yìn náà ó padà sí Equatorial Guinea, sí abúlé rẹ̀ tí ó wà ní nǹkan bíi 100 kìlómítà sí Mongomo. Èyí gbé ìpèníjà kan dìde fún un láti máa bá ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ lọ. Ṣùgbọ́n kò mikàn. Lóṣooṣù, ó máa ń fi kẹ̀kẹ́ ológeere rìrìn àjò wákàtí mẹ́jọ lọ sí Mongomo, níbi tí Santiago, ọ̀kan nínú àwọn alàgbà àdúgbò, ti ń bá a ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́. Ó máa ń wà ní Mongomo fún ọjọ́ díẹ̀, ó sì máa ń kẹ́kọ̀ọ́ fún ìgbà mẹ́ta tàbí mẹ́rin nígbà tí ó bá wà níbẹ̀. Lọ́nà yìí, ó ṣeé ṣe fún un láti parí ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, kí ó sì tóótun fún ìrìbọmi.

Báwo ni Juan ṣe ń bá a nìṣó láti jẹ́ alágbára nípa tẹ̀mí pẹ̀lú ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ díẹ̀ bẹ́ẹ̀ tí ó ń ní pẹ̀lú àwọn Kristẹni? Ju gbogbo rẹ̀ lọ, nípa jíjẹ́ olùfìtara wàásù ìhìn rere náà ni. Ó ti wàásù fún gbogbo ènìyàn tí ó wà ní abúlé rẹ̀, nígbà tí yóò sì fi ṣe ìrìbọmi, ó ti ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì 13. Mẹ́fà nínú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ bá a lọ sí àpéjọ àkànṣe ní Mongomo láti fojú rí ìrìbọmi rẹ̀. Ó ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ déédéé pẹ̀lú àwọn olùfìfẹ́hàn tí ó wà ní agbègbè náà, lọ́pọ̀ ìgbà nǹkan bí 20 máa ń wá síbẹ̀.

Fífi Sùúrù Bomi Rin Irúgbìn Náà

Kì í ṣe gbogbo ìdàgbàsókè nípa tẹ̀mí ni ó ń yára kánkán. Nígbà míràn ó ń béèrè ọ̀pọ̀ sùúrù kí irúgbìn náà tó lè méso jáde. Èyí jẹ́ òtítọ́ nínú ọ̀ràn Paca, ẹni tí ó kọ́kọ́ gbọ́ ìhìn rere náà ní ọdún 1984, nígbà tí Edita, arábìnrin aṣáájú ọ̀nà kan, jẹ́rìí fún un ní ọjà. Nígbà tí Edita bẹ Paca wò nínú ilé rẹ̀ ní ọ̀sẹ̀ tí ó tẹ̀ lé e, Paca gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò tẹ̀ síwájú tó bẹ́ẹ̀, Edita tẹra mọ́ ọn nítorí pé ó fòye mọ àwọn ànímọ́ dáradára nínú Paca. Edita ṣàlàyé pé: “Ó dà bí ẹni bí àgùntàn, mo sì gbàdúrà sí Jèhófà pé kí ó ṣí ọkàn-àyà rẹ̀.”

Paca ń bá ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ nìṣó ní ìdákúrekú fún ọdún mẹ́rin àti ààbọ̀ ṣùgbọ́n, síbẹ̀, ìtẹ̀síwájú rẹ̀ kò tó nǹkan. Nítorí náà, nígbà tí wọ́n parí ìwé Walaaye Titilae, Edita bá Paca sọ òòtọ́ ọ̀rọ̀ nípa ìjẹ́pàtàkì mímú òtítọ́ ní ọ̀kúnkúndùn. Nínú ìsapá rẹ̀ láti dé ọkàn-àyà Paca, Edita tilẹ̀ bú sẹ́kún.

Paca rántí pé: “Ìmọ̀ràn àtọkànwá náà gún mi ní kẹ́ṣẹ́. Láti ìgbà náà wá, mo bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìyípadà nínú ìgbésí ayé mi. Mo forúkọ sílẹ̀ nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run, mo sì di akéde tí kò tí ì ṣe ìrìbọmi ní ọdún kan náà yẹn. Ọjọ́ tí mo ṣe ìrìbọmi nígbẹ̀yìngbẹ́yín ní ọjọ́ aláyọ̀ jù lọ nínú ìgbésí ayé mi!” Ìtara ọkàn tí Paca ní nísinsìnyí jẹ́ òdìkejì pátápátá sí ẹ̀mí ìdágunlá tí ó ní tẹ́lẹ̀. Ní báyìí, ó ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì 13, ó sì dájú pé, ó ń mú sùúrù pẹ̀lú àwọn tí kò bá yára tẹ̀ síwájú.

Ríran Àwọn Ènìyàn Lọ́wọ́ Láti Mú Ìgbésí Ayé Wọn Sunwọ̀n Sí i

Nípa gbígbé ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà Bíbélì, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Equatorial Guinea ti ní orúkọ rere fún àìlábòsí àti jíjẹ́ ọmọlúwàbí. Ọkùnrin kan, tí ó hàn gbangba pé ìwà wọn ti wú u lórí, tọ alàgbà kan ní Ìjọ Bata lọ, ó sì béèrè pé: “Ìwọ ha ni ìwé Reasoning bí?b Jíjẹ́ ẹni ayé ti sú mi. N óò fẹ́ láti di ọ̀kan nínú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà!”

Antonio, ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan ní Ìjọ Malabo, jẹ́ àpẹẹrẹ rere kan ní ti ẹni ayé tí ó di Ẹlẹ́rìí. Kí ó tó kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó gbé ìgbésí ayé aláìlèkóra-ẹni-níjàánu. Ọtí ni ó ń fi ọ̀pọ̀ jù lọ owó tí ó ń rí nínú títún aago ṣe mu, ó sì ń gbé ìgbésí ayé oníwà pálapàla. Kí ni ó ràn án lọ́wọ́ láti yí ìgbésí ayé rẹ̀ padà? Ohun tí a sọ lọ́nà lílágbára nínú Kọ́ríńtì Kìíní 6:9, 10 pé: “Kí a má ṣe ṣì yín lọ́nà. Kì í ṣe àwọn àgbèrè, . . . tàbí àwọn ọ̀mùtípara, . . . ni yóò jogún ìjọba Ọlọ́run,” wú u lórí gidigidi. Ó mọ̀ pé láti lè rí ojú rere Ọlọ́run, òún gbọ́dọ̀ yí ìgbésí ayé òun padà. Nítorí èyí, ó bẹ̀rẹ̀ sí í kíyè sí ẹgbẹ́ tí ó ń kó. (Òwe 13:20) Nígbà tí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ àtijọ́ bá pè é láti lọ mu ọtí, yóò kọ ìkésíni wọn, yóò sì jẹ́rìí fún wọn dípò títẹ̀ lé wọn lọ. Kò pẹ́ kò jìnnà, wọ́n dẹ́kun yíyọ ọ́ lẹ́nu.

Gbogbo ìsapá wọ̀nyí ha já mọ́ nǹkan kan bí? Antonio ṣàlàyé pé: “Inú mi dùn púpọ̀ pé mo ti yí ìgbésí ayé mi padà. Ìlera mi gbé pẹ́ẹ́lí sí i nísinsìnyí bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti lé ní ẹni 60 ọdún, nígbà tí ó sì jẹ́ pé àwọn ọ̀rẹ́ mi àtijọ́ ti kú tàbí wọ́n ń ṣòjòjò. Wàyí o, mo ní àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́ dípò àwọn tí ń wulẹ̀ ń fẹ́ ọ̀rẹ́ kan tí yóò múra tán láti bá wọn san owó ọtí mìíràn tí wọ́n bá rà. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, mo ní ipò ìbátan rere pẹ̀lú Ọlọ́run. Mo ń ṣiṣẹ́ sìn nísinsìnyí gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà déédéé, mo sì ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú ọkùnrin kan tí òun pẹ̀lú ní ìṣòro ọtí mímu, nítorí náà mo lè lo ìrírí mi láti ràn án lọ́wọ́.”

Dídi Ẹrú Ọlọ́run

Ní nǹkan bí 200 ọdún sẹ́yìn, a kó àwọn ènìyàn tí wọ́n ń gbé ní erékùṣù Equatorial Guinea jọ, a sì fọkọ̀ òkun kó wọn lọ sí America gẹ́gẹ́ bí ẹrú. Lónìí, ọ̀pọ̀ ń fínnúfíndọ̀ di ẹrú—ẹrú Ọlọ́run. Irú ipò ẹrú yìí ti mú òmìnira tòótọ́ wá fún wọn, ó ti dá wọn sílẹ̀ kúrò nínú ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ Bábílónì àti àṣà ìbẹ́mìílò. Ó tún ti kọ́ wọn láti gbé ìgbésí ayé tí ń tẹ́ni lọ́rùn, tí ó sì ń méso jáde. Wọ́n ti wá nírìírí ìlérí Jésù pé: “Ẹ óò sì mọ òtítọ́, òtítọ́ yóò sì dá yín sílẹ̀ lómìnira.”—Jòhánù 8:32.

Pẹ̀lú 1,937 tí ó wá síbi ayẹyẹ Ìṣe Ìrántí ti 1995—nǹkan bí ìlọ́po mẹ́ta akéde tí ó wà ní orílẹ̀-èdè náà—àwọn ìfojúsọ́nà gíga lọ́lá ń bẹ fún ìdàgbàsókè tẹ̀mí. Bí àwọn Ẹlẹ́rìí ní Equatorial Guinea ṣe ń fi tìtaratìtara gbin irúngbìn, tí wọ́n sì ń bomi rìn ín, wọ́n ní ìdánilójú pé ‘Ọlọ́run yóò mú kí ó máa dàgbà.’ (Kọ́ríńtì Kìíní 3:6) Láìsí iyè méjì, àyíká ipò fún ìdàgbàsókè tẹ̀mí wà ní Equatorial Guinea!

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A tẹ̀ ẹ́ jáde láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.

b A tẹ̀ ẹ́ jáde láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́