ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w96 11/1 ojú ìwé 19-21
  • A Gbé Òmìnira Ìsìn Lárugẹ Ní Japan

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • A Gbé Òmìnira Ìsìn Lárugẹ Ní Japan
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Ọ̀ràn Àríyànjiyàn Wo Ni Ó Wà Nílẹ̀?
  • Ìpinnu Ilé Ẹjọ́ Àgbègbè Ru Ìmọ̀lára Àwọn Tí Wọ́n Gbọ́ Nípa Rẹ̀ Sókè
  • Ìṣarasíhùwà Àìmọtara-Ẹni-Nìkan Tí Àwọn Olùpẹ̀jọ́ Náà Ní
  • Ó Di Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ
  • Ìyọrísí Rẹ̀ Rìn Jìnnà
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
w96 11/1 ojú ìwé 19-21

A Gbé Òmìnira Ìsìn Lárugẹ Ní Japan

FÚN ọ̀pọ̀ ọdún ní Japan, àwọn ọ̀dọ́ akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti dojú kọ ẹtì kan: Ṣe kí wọ́n tẹ̀ lé ẹ̀rí ọkàn wọn tí a fi Bíbélì kọ́ ni, tàbí kí wọ́n tẹ̀ lé ìlànà ẹ̀kọ́ ilé ẹ̀kọ́ tí ó ta ko ẹ̀rí ọkàn wọn. Kí ni ó fa ẹtì náà? Nítorí pé eré ìgbèjà ara ẹni jẹ́ apá kan ètò ẹ̀kọ́ eré ìmárale ní ilé ẹ̀kọ́ wọn. Àwọn ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí nímọ̀lára pé irú eré bẹ́ẹ̀ kò bá àwọn ìlànà Bíbélì mu, irú èyí tí a rí nínú Aísáyà orí 2, ẹsẹ 4. Èyí kà pé: “Wọn óò fi idà wọn rọ ọ̀bẹ píláù, wọn óò sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ dòjé; orílẹ̀-èdè kì yóò gbé idà sókè sí orílẹ̀-èdè; bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò kọ́ ogun jíjà mọ́.”

Nítorí àìfẹ́ kọ́ iṣẹ́ tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ogun jíjà, èyí tí ó ní ṣíṣe ìpalára fún ẹlòmíràn nínú, àwọn ọ̀dọ́ Kristẹni Ẹlẹ́rìí ṣàlàyé fún àwọn olùkọ́ wọn pé, ẹ̀rí ọkàn àwọn kò lè yọ̀ọ̀da fún wọn láti lọ́wọ́ nínú eré ìgbèjà ara ẹni. Lẹ́yìn gbígbìyànjú láti yí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wọ̀nyí lọ́kàn padà, láti tẹ́wọ́ gba ìlànà ẹ̀kọ́ ilé ẹ̀kọ́, ọ̀pọ̀ àwọn olùkọ́ tí ó lóye gbà lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn láti bọ̀wọ̀ fún ẹ̀rí ọkàn àwọn akẹ́kọ̀ọ́, kí wọ́n sì pèsè àwọn ìgbòkègbodò àfidípò.

Àmọ́, inú bí àwọn olùkọ́ kan, àwọn ilé ẹ̀kọ́ kan sì mú kí àwọn ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí fìdí rẹmi nínú ẹ̀kọ́ eré ìmárale. Ní ọdún 1993, ó kéré tán Ẹlẹ́rìí mẹ́sàn-án ni a kò gbà kí wọ́n lọ sí ipele ẹ̀kọ́ míràn, tí a sì fipá mú láti fi ilé ẹ̀kọ́ sílẹ̀ tàbí tí a lé jáde fún ṣíṣàì lọ́wọ́ nínú eré ìgbèjà ara ẹni.

Ó ṣe kedere pé, ó tó àkókò láti gbèjà ẹ̀tọ́ àwọn ọ̀dọ́ Kristẹni láti lè rí ìmọ̀ ẹ̀kọ́ gbà láìjẹ́ pé wọ́n fi ẹ̀rí ọkàn wọn báni dọ́rẹ̀ẹ́. Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ márùn-ún tí a kò jẹ́ kí wọ́n lọ sí ipele ẹ̀kọ́ kejì ní ilé ẹ̀kọ́ Kobe Municipal Industrial Technical College (tí a ń pè ní Kobe Tech fún ìkékúrú) pinnu láti fi ẹsẹ̀ òfin tọ̀ ọ́.

Ọ̀ràn Àríyànjiyàn Wo Ni Ó Wà Nílẹ̀?

Ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn 1990, nígbà tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ márùn-ún náà wọ ilé ẹ̀kọ́ Kobe Tech, wọ́n ṣàlàyé fún àwọn olùkọ́ náà pé, àwọn kò ní lè lọ́wọ́ nínú eré kendo (eré àfidàjà ti àwọn ará Japan), nítorí ojú ìwòye wọn tí a gbé karí Bíbélì. Ẹ̀ka tí ń rí sí ẹ̀kọ́ eré ìmárale gbé àtakò gbígbóná janjan dìde, kò sì yọ̀ọ̀da ọ̀nà àfidípò fún wọn láti lè rí máàkì gbà fún ẹ̀kọ́ eré ìmárale. Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà fìdí rẹmi nínú ẹ̀kọ́ eré ìmárale, ìyọrísí èyí sì ni pé, wọ́n ní láti tún ìpele kíní kà (ọdún àkọ́kọ́ nínú ẹ̀kọ́ kọ́lẹ́ẹ̀jì). Ní April ọdún 1991, wọ́n pẹjọ́ sí Ilé Ẹjọ́ Àgbègbè Kobe, ní sísọ pé ìgbésẹ̀ ilé ẹ̀kọ́ náà lòdì sí ìmúdánilójú òfin ní ti òmìnira ìsìn.a

Ilé ẹ̀kọ́ náà sọ pé pípèsè àwọn ìgbòkègbodò àfidípò yóò wulẹ̀ jẹ́ fífi ojú rere hàn sí ìsìn kan pàtó, tí yóò sì tipa bẹ́ẹ̀ nípa lórí àìṣègbè ní ti ètò ẹ̀kọ́ gbogbogbòò. Ìyẹn nìkan kọ́, wọ́n sọ pé àwọn kò ní ohun èèlò, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn kò ní òṣìṣẹ́ tí ó lè pèsè ètò ẹ̀kọ́ eré ìmárale àfidípò.

Ìpinnu Ilé Ẹjọ́ Àgbègbè Ru Ìmọ̀lára Àwọn Tí Wọ́n Gbọ́ Nípa Rẹ̀ Sókè

Nígbà tí a ń gbọ́ ẹjọ́ náà lọ́wọ́, méjì nínú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ márùn-ún náà tún fìdí rẹmi nínú ẹ̀kọ́ eré ìmárale, nígbà tí ó jẹ́ pé ekukáká ni àwọn mẹ́ta mìíràn fi páàsì, tí wọ́n sì bọ̀ sí ipele tí ó tẹ̀ lé e. Òfin ilé ẹ̀kọ́ náà ni pé, a óò lé akẹ́kọ̀ọ́ tí kò bá ṣe dáradára tó, tí ó sì tún ipele kan kà fún ọdún méjì léraléra lọ. Nítorí èyí, ọ̀kan nínú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ méjì náà pinnu láti kúrò ní ilé ẹ̀kọ́ náà kí a tó lé e lọ, ṣùgbọ́n èyí èkejì, Kunihito Kobayashi, kọ̀ láti kúrò. Nítorí náà, a lé e lọ. Lọ́nà tí ó dùn mọ́ni, ìpíndọ́gba máàkì Kunihito nínú gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ títí kan ẹ̀kọ́ eré ìmárale, tí ó ti fìdí rẹmi pẹ̀lú máàkì 48, jẹ́ 90.2 nínú 100. Òun ni ó ṣe ipò kíní nínú kíláàsì tirẹ̀ tí ó ní akẹ́kọ̀ọ́ 42 nínú.

Ní February 22, 1993, Ilé Ẹjọ́ Àgbègbè Kobe dá ilé ẹ̀kọ́ Kobe Tech láre, ó sì wí pe: “Ìgbésẹ̀ tí ilé ẹ̀kọ́ náà gbé kò tẹ òfin lójú,” bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ilé ẹjọ́ náà gbà pé “a kò lè sẹ́ pé a ka òmìnira ìjọsìn tí olùpẹ̀jọ́ náà ní lọ́wọ́ kò lọ́nà kan ṣáá, nípa ohun tí ilé ẹ̀kọ́ náà ń béèrè fún láti lọ́wọ́ nínú eré kendo.”

Gẹ́gẹ́ bíi ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní ọ̀rúndún kìíní, olùpẹ̀jọ́ náà pinnu láti pẹjọ́ kò-tẹ́-mi-lọ́rùn sí ọ̀dọ̀ àwọn aláṣẹ gíga jù ní ti òfin. (Ìṣe 25:11, 12) Ẹjọ́ náà lọ sí Ilé Ẹjọ́ Gíga ti Osaka.

Ìṣarasíhùwà Àìmọtara-Ẹni-Nìkan Tí Àwọn Olùpẹ̀jọ́ Náà Ní

Gbajúmọ̀ ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan, Ọ̀jọ̀gbọ́n Tetsuo Shimomura ti Yunifásítì Tsukuba, gbà láti jẹ́rìí gẹ́gẹ́ bí ògbógi ẹlẹ́rìí, ní Ilé Ẹjọ́ Gíga ti Osaka. Gẹ́gẹ́ bí ògbóǹtagí nínú ìmọ̀ ẹ̀kọ́ àti òfin, ó tẹnu mọ́ bí ìgbésẹ̀ ilé ẹ̀kọ́ náà nínú ìbálò rẹ̀ pẹ̀lú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ṣe kún fún àìgbatẹnirò tó. Kunihito Kobayashi sọ ìmọ̀lára rẹ̀ jáde ní ilé ẹjọ́ náà, ìṣarasíhùwà olóòótọ́ ọkàn rẹ̀ sì gbún ọkàn àwọn tí ó wà nínú ilé ẹjọ́ náà ní kẹ́ṣẹ́. Síwájú sí i, ní February 22, 1994, Ẹgbẹ́ Àwọn Amòfin Kobe, ní pípolongo pé ìgbésẹ̀ ilé ẹ̀kọ́ náà tẹ òmìnira ìjọsìn Kunihito àti ẹ̀tọ́ rẹ̀ láti rí ìmọ̀ ẹ̀kọ́ gbà lójú, dábàá pé kí ilé ẹ̀kọ́ náà gbà á padà.

Bí àkókò tí a óò gbé ìpinnu Ilé Ẹjọ́ Gíga ti Osaka kalẹ̀ ti ń sún mọ́ etílé, gbogbo àwọn ọ̀dọ́ Kristẹni tí ọ̀ràn náà kàn ń hára gàgà láti bá ìjàkadì náà dópin. Wọ́n nímọ̀lára pé àwọn ń ja ìjà òfin nítorí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí tí ń dojú kọ irú ọ̀ràn kan náà ní ilé ẹ̀kọ́ jákèjádò Japan. Ṣùgbọ́n níwọ̀n bí a kò ti lé wọn kúrò ní ilé ẹ̀kọ́, ó ṣeé ṣe dáradára kí ilé ẹjọ́ náà tú ẹjọ́ wọn ká. Wọ́n sì mọ̀ pé, bí àwọn bá fawọ́ ẹ̀bẹ̀ wọn sẹ́yìn, ìwà àìbọ́gbọ́nmu tí ilé ẹ̀kọ́ náà hù ní lílé Kunihito jáde, yóò wá sójú táyé. Nípa báyìí, gbogbo akẹ́kọ̀ọ́ náà yọwọ́ nínú ẹjọ́ náà, ó ku Kunihito nìkan.

Ní December 22, 1994, Adájọ́ Àgbà Reisuke Shimada ti Ilé Ẹjọ́ Gíga ti Osaka gbé ìpinnu kan kalẹ̀ tí ó ta ko ìdájọ́ Ilé Ẹjọ́ Àgbègbè Kobe. Ilé ẹjọ́ náà rí i pé, ìdí tí Kunihito ní fún títa ko eré kendo jẹ́ látọkànwá àti pé, ìpalára tí ó mú wá fún un nítorí ìgbésẹ̀ tí ó gbé karí èrò ìgbàgbọ́ ìsìn rẹ̀ ga lọ́lá. Adájọ́ Àgbà Shimada sọ pé, ó yẹ kí ilé ẹ̀kọ́ náà ti pèsè àwọn ìgbòkègbodò àfidípò. Ìpinnu àtàtà yìí gún ọkàn àwọn tí wọ́n bìkítà nípa ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn ní kẹ́ṣẹ́. Ṣùgbọ́n, ilé ẹ̀kọ́ náà pẹjọ́ kò-tẹ́-mi-lọ́rùn sí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti Japan, ní fífi ìmọ̀ ẹ̀kọ́ du Kunihito fún ohun tí ó lé ní ọdún kan mìíràn.

Ó Di Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ

Ọ̀rọ̀ olóòtú kan nínú ìwé ìròyìn Kobe Shimbun sọ lẹ́yìn náà pé: “Ìgbìmọ̀ Ilé Ẹkọ́ ti Ìlú Kobe àti ilé ẹkọ́ náà ì bá ti gba Ọ̀gbẹ́ni Kobayashi padà sí ilé ẹ̀kọ́ ní àkókò yẹn [lẹ́yìn ìpinnu Ilé Ẹjọ́ Gíga Osaka]. . . . Ìwà àtakò láìnídìí tí wọ́n hù ti fi sáà pàtàkì nínú ìgbà ọ̀dọ́ du ọmọkùnrin náà.” Síbẹ̀, ilé ẹ̀kọ́ Kobe Tech mú ìdúró gbọn-in nínú ẹjọ́ yìí. Ìyọrísí rẹ̀ ni pé, ó di kókó ọ̀rọ̀ nínú ìròyìn káàkiri orílẹ̀-èdè náà. Àwọn olùkọ́ àti aláṣẹ ilé ẹ̀kọ́ ní orílẹ̀-èdè náà kíyè sí i, ìpinnu kan láti ọ̀dọ̀ ilé ẹjọ́ gíga jù lọ ní orílẹ̀-èdè náà ni yóò sì dúró gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ àtẹ̀lé lílágbára ní ti òfin fún irú ẹjọ́ bẹ́ẹ̀ ní ọjọ́ ọ̀la.

Ní January 17, 1995, nǹkan bí ọ̀sẹ̀ kan lẹ́yìn tí ilé ẹ̀kọ́ náà ti pẹjọ́ kò-tẹ́-mi-lọ́rùn sí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ, ìmìtìtì ilẹ̀ Kobe kọ lù Ashiya City níbi tí Kunihito àti ìdílé rẹ̀ ń gbé. Ní nǹkan bí aago márùn-ún àbọ̀ ìdájí ọjọ́ yẹn, ìṣẹ́jú díẹ̀ kí ìmìtìtì ilẹ̀ náà tó kọ lu agbègbè náà, Kunihito fi ilé rẹ̀ sílẹ̀ láti lọ ṣe iṣẹ́ àbọ̀ṣẹ́ rẹ̀. Ó ń gun kẹ̀kẹ́ lọ lójú ọ̀nà tí ó gba abẹ́ Ọ̀nà Márosẹ̀ Hanshin kọjá, nígbà tí ìmìtìtì náà sì ṣẹlẹ̀, díẹ̀ ni ó kù kí ó dé apá tí ó wó lulẹ̀. Lọ́gán, ó padà sílé, ó sì rí i pé àjà àkọ́kọ́ ilé òun ti wó pátápátá. Kunihito rí i pé òun ì bá ti pàdánù ẹ̀mí òun nínú ìmìtìtì ilẹ̀ náà, ó sì dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún yíyọ̀ọ̀da fún òun láti là á já. Ká ní ó ti kú ni, ó ṣeé ṣe kí ẹjọ́ eré kendo ti parí síbẹ̀ láìsí ìpinnu Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ.

Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Japan sábà máa ń ṣàyẹ̀wò ẹjọ́ kò-tẹ́-mi-lọ́rùn lórí ìwé nìkan, tí yóò sì dájọ́ bóyá ìpinnu ilé ẹjọ́ kékeré náà tọ̀nà tàbí kò tọ̀nà. Àyàfi bí ìdí pàtàkì bá wà láti yí ìpinnu ilé ẹjọ́ kékeré náà padà, kì í sí ìgbẹ́jọ́ mọ́. Ilé ẹjọ́ náà kì í fi ìgbà tí wọn yóò sọ ìpinnu wọn tó àwọn tí ọ̀ràn kàn létí. Nítorí náà, ó ya Kunihito lẹ́nu lówùúrọ̀ March 8, 1996, nígbà tí a sọ fún un pé, a óò ṣe ìpinnu náà lówùúrọ̀ ọjọ́ yẹn. Sí ìdùnnú àti ayọ̀ rẹ̀, ó gbọ́ pé Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti kín ìpinnu Ilé Ẹjọ́ Gíga ti Osaka lẹ́yìn.

Adájọ́ mẹ́rin, pẹ̀lú Adájọ́ Shinichi Kawai tí ó jẹ́ olùdarí, dájọ́ pẹ̀lú ìfẹnukò pé “ó yẹ́ kí a ka ìgbésẹ̀ tí a ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ yìí sí ìwà àìtọ́ gbáà tí a bá fojú ìlànà ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà wò ó, ó ti yà kúrò lójú ọ̀nà ẹ̀tọ́ tí ó bá ọgbọ́n ìrònú mu, nítorí náà kò bófin mu.” Ilé ẹjọ́ náà kan sáárá sí òótọ́ ọkàn Kunihito láti kọ̀ láti ṣe eré kendo, ò sí wí pé: “Ìdí tí olùpẹjọ́ kò-tẹ́-mi-lọ́rùn fi kọ̀ láti lọ́wọ́ nínú eré kendo jẹ́ èyí tí ó ṣe pàtàkì, ó sì ní ìsopọ̀ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú ìpìlẹ̀ ìgbàgbọ́ rẹ̀ gan-an.” Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ náà dájọ́ pé, ilé ẹ̀kọ́ náà lè pèsè, ó sì ti yẹ kí ó pèsè ọ̀nà àfidípò kí ó baà lè bọ̀wọ̀ fún ìgbàgbọ́ olùpẹjọ́ kò-tẹ́-mi-lọ́rùn náà.

Ìyọrísí Rẹ̀ Rìn Jìnnà

Kò sí iyè méjì pé ìpinnu yìí yóò fi àpẹẹrẹ àtẹ̀lé tí ó dára lélẹ̀, èyí tí ó dá òmìnira ìjọsìn ní ilé ẹ̀kọ́ láre. Ìwé agbéròyìnjáde náà, The Japan Times, wí pé: “Ìdájọ́ náà ni àkọ́kọ́ irú rẹ̀ tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ yóò ṣe lórí ọ̀ràn ìmọ̀ ẹ̀kọ́ àti òmìnira ìsìn.” Bí ó ti wù kí ó rí, ìpinnu náà kò mú ẹrù iṣẹ́ tí akẹ́kọ̀ọ́ kọ̀ọ̀kan ní láti di ìdúró tí ó bá ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ mu mú nígbà tí ó bá dojú kọ àdánwò ìgbàgbọ́ kúrò.

Ọ̀jọ̀gbọ́n Masayuki Uchino ti Yunifásítì Tsukuba sọ pé ọ̀kan nínú àwọn kókó abájọ tí ó sún àwọn adájọ́ náà láti dá Kunihito láre ni pé, ó jẹ́ “akẹ́kọ̀ọ́ olóòótọ́ ọkàn, ẹni tí àṣeyọrí rẹ̀ nínú ìmọ̀ ẹ̀kọ́ ta yọ lọ́lá.” Bíbélì fún àwọn Kristẹni tí ń dojú kọ ìdánwò ìgbàgbọ́ wọn ní ìmọ̀ràn yìí pé: “Ẹ tọ́jú ìwà yín kí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè, pé, nínú ohun náà tí wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ lòdì sí yín gẹ́gẹ́ bí aṣebi, kí wọ́n lè tipa àwọn iṣẹ́ yín àtàtà èyí tí wọ́n jẹ́ ẹlẹ́rìí olùfojúrí rẹ̀ yin Ọlọ́run lógo ní ọjọ́ náà fún àbẹ̀wò rẹ̀.” (Pétérù Kìíní 2:12) Àwọn Kristẹni ọ̀dọ́ olùṣòtítọ́ lè fihàn pé ìdúró wọn tí ó bá Bíbélì mu jẹ́ ohun tí ó yẹ kí àwọn ènìyàn bọ̀wọ̀ fún nípa gbígbé gbogbo ìgbésí ayé wọn ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà Bíbélì.

Lẹ́yìn ìpinnu Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ náà, a gba Kunihito Kobayashi padà sí ilé ẹ̀kọ́ Kobe Tech. Ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí àwọn pẹ̀lú Kunihito jọ wọ ilé ẹ̀kọ́ nígbà kan náà, ti kẹ́kọ̀ọ́ yege. Kunihito ń kẹ́kọ̀ọ́ nísinsìnyí pẹ̀lú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí ó fi ọdún márùn-ún jù lọ. Lójú ọ̀pọ̀ ènìyàn ayé, ó dà bí ẹni pé ò ti fi ọdún márùn-ún tí ó ṣeyebíye nínú ìgbà ọ̀dọ́ rẹ̀ ṣòfò. Bí ó ti wù kí ó rí, ìwà títọ́ Kunihito ṣeyebíye lójú Jèhófà Ọlọ́run, dájúdájú ìrúbọ rẹ̀ kì í sì í ṣe lórí asán.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Fún kúlẹ̀kúlẹ̀ ìsọfúnni, jọ̀wọ́ wo ojú ìwé 10 sí 14 ti October 8, 1995, ìtẹ̀jáde Jí!, tí a tẹ̀ jáde láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]

Ọwọ́ òsì: Ilé Kunihito lẹ́yìn ìmìtìtì ilẹ̀ náà

Nísàlẹ̀: Kunihito lónìí

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́