Kí Ni Ọlọ́run Ń béèrè Lọ́wọ́ Wa?
“Èyí ni ohun tí ìfẹ́ fún Ọlọ́run túmọ̀ sí, pé kí a pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́; síbẹ̀ àwọn àṣẹ rẹ̀ kì í sì í ṣe ẹrù ìnira.”—JÒHÁNÙ KÍNÍ 5:3.
1, 2. Èé ṣe tí kò fi yani lẹ́nu pé Ọlọ́run ń béèrè àwọn ohun kan lọ́wọ́ àwọn tí ó bá fẹ́ jọ́sìn rẹ̀ lọ́nà tí ó tẹ́wọ́ gbà?
“ÌSÌN mi tẹ́ mi lọ́rùn!” Kì í ha í ṣe ohun tí àwọn ènìyàn sábà máa ń sọ nìyẹn bí? Ṣùgbọ́n, ní ti gidi, ohun tí ó yẹ kí ìbéèrè náà jẹ́ ni pé, “Ìsìn mí ha tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn bí?” Bẹ́ẹ̀ ni, Ọlọ́run ní àwọn ohun tí ó ń béèrè lọ́wọ́ àwọn tí wọ́n fẹ́ láti jọ́sìn rẹ̀ lọ́nà tí ó tẹ́wọ́ gbà. Ó ha yẹ kí ìyẹn yà wá lẹ́nu bí? Ní ti gidi kò yẹ kí ó rí bẹ́ẹ̀. Ká sọ pé o ní ilé mèremère kan, ọ̀kan tí o ṣẹ̀ṣẹ̀ fi owó gọbọi tún ṣe. Ìwọ yóò ha gba ẹnikẹ́ni ṣáá láyè láti gbé ibẹ̀ bí? Dájúdájú, ìwọ kì yóò ṣe bẹ́ẹ̀! Ẹnikẹ́ni yòó wù tí yóò bá jẹ́ ayálégbé ní láti lè kún ojú ìwọ̀n àwọn ohun tí o ń béèrè fún.
2 Lọ́nà kan náà, Jèhófà Ọlọ́run pèsè ilé ayé yìí fún ìdílé ẹ̀dá ènìyàn. Láìpẹ́, lábẹ́ ìṣàkóso Ìjọba rẹ̀, a óò “tún” ilẹ̀ ayé “ṣe”—a óò sọ ọ́ di párádísè ẹlẹ́wà. Jèhófà yóò ṣàṣeparí èyí. Ó ná an ní ohun púpọ̀, ó jọ̀wọ́ Ọmọkùnrin bíbí kan ṣoṣo rẹ̀, kí ó baà lè ṣeé ṣe. Dájúdájú, Ọlọ́run gbọ́dọ̀ ní àwọn ohun tí ó ń béèrè lọ́wọ́ àwọn tí wọ́n fẹ́ gbé ibẹ̀!—Orin Dáfídì 115:16; Mátíù 6:9, 10; Jòhánù 3:16.
3. Báwo ni Sólómọ́nì ṣe ṣàkópọ̀ ohun tí Ọlọ́run ń retí lọ́dọ̀ wa?
3 Báwo ni a ṣe lè mọ ohun tí Ọlọ́run ń béèrè? Jèhófà mí sí Ọba Sólómọ́nì láti ṣàkópọ̀ ohun tí Òun ń retí lọ́dọ̀ wa. Lẹ́yìn ríronú lórí gbogbo ohun tí ó ti lépa—títí kan ọrọ̀, iṣẹ́ ìkọ́lé, ọkàn-ìfẹ́ nínú orin, àti ìfẹ́ eré ìfẹ́—Sólómọ́nì wá mọ èyí pé: “Òpin gbogbo ọ̀rọ̀ náà tí a gbọ́ ni pé: Bẹ̀rù Ọlọ́run kí o sì pa [àwọn àṣẹ, NW] rẹ̀ mọ́: nítorí èyí ni fún gbogbo ènìyàn.” (Ìkọ̀wé wínníwínní jẹ́ tiwa.)—Oníwàásù 12:13.
‘Àwọn Àṣẹ Rẹ̀ Kì í Ṣe Ẹrù Ìnira’
4-6. (a) Kí ni ìtúmọ̀ olówuuru tí ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí a túmọ̀ sí “ẹrù ìnira” ní? (b) Èé ṣe tí a fi lè sọ pé àwọn àṣẹ Ọlọ́run kì í ṣe ẹrù ìnira?
4 “Pa [àwọn àṣẹ, NW] rẹ̀ mọ́.” Ní pàtàkì, ohun tí Ọlọ́run ń retí lọ́wọ́ wa nìyẹn. Ìyẹn ha ti pọ̀ ju ohun tí ó lè béèrè lọ bí? Bẹ́ẹ̀ kọ́ rárá. Àpọ́sítélì Jòhánù sọ ohun kan fún wa tí ó fini lọ́kàn balẹ̀ nípa àwọn àṣẹ Ọlọ́run, tàbí àwọn ohun tí ó ń béèrè fún. Ó kọ̀wé pé: “Èyí ni ohun tí ìfẹ́ fún Ọlọ́run túmọ̀ sí, pé kí a pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́; síbẹ̀ àwọn àṣẹ rẹ̀ kì í sì í ṣe ẹrù ìnira.”—Jòhánù Kíní 5:3.
5 Ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà tí a túmọ̀ sí “ẹrù ìnira” ní òwuuru túmọ̀ sí “wúwo.” Ó lè tọ́ka sí ohun kan tí ó nira láti kún ojú ìwọ̀n rẹ̀ tàbí tí ó ṣòro láti ṣe. Ní Mátíù 23:4, a lò ó láti ṣàpèjúwe “ẹrù wíwúwo,” àwọn òfin àti àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ tí ènìyàn gbé kalẹ̀, tí àwọn akọ̀wé àti Farisí gbé ka àwọn ènìyàn lórí. O ha lóye ohun tí àpọ́sítélì Jòhánù tí ó jẹ́ arúgbó ń sọ bí? Àwọn àṣẹ Ọlọ́run kì í ṣe ẹrù wíwúwo, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn kò ṣòro jù fún wa láti pa mọ́. (Fi wé Diutarónómì 30:11.) Ní ìyàtọ̀ gédégédé, nígbà tí a bá nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, kíkún ojú ìwọ̀n àwọn ohun tí ó ń béèrè fún máa ń mú wa láyọ̀. Ó ń fún wa ní àǹfààní ṣíṣeyebíye láti fi ìfẹ́ wa fún Jèhófà hàn.
6 Láti fi ìfẹ́ wa fún Ọlọ́run hàn, ó yẹ kí a mọ ohun tí òun ń retí lọ́dọ̀ wa ní pàtó. Nísinsìnyí, jẹ́ kí a gbé márùn-ún nínú àwọn ohun tí Ọlọ́run ń béèrè yẹ̀ wò. Bí a ti ń gbé wọn yẹ̀ wò, fi ohun tí Jòhánù sọ sọ́kàn pé: ‘Àwọn àṣẹ Ọlọ́run kì í ṣe ẹrù ìnira.’
Gba Ìmọ̀ Ọlọ́run Sínú
7. Orí kí ni ìgbàlà wa sinmi lé?
7 Ohun àkọ́kọ́ tí a béèrè fún jẹ́ gbígba ìmọ̀ Ọlọ́run sínú. Gbé ọ̀rọ̀ Jésù tí a kọ sílẹ̀ nínú Jòhánù orí 17 yẹ̀ wò. Ọ̀rọ̀ yìí wáyé ní alẹ́ tí ó kẹ́yìn ìwàláàyè Jésù gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ènìyàn. Jésù ti lo apá tí ó pọ̀ jù lọ ní ìrọ̀lẹ́ náà fún mímúra àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ sílẹ̀ fún àtilọ rẹ̀. Ọjọ́ ọ̀la wọn jẹ ẹ́ lógún, ọjọ́ ọ̀la wọn àìnípẹ̀kun. Ní gbígbé ojú rẹ̀ sókè ọ̀run, ó gbàdúrà fún wọn. Ní ẹsẹ 3, a kà pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni náà tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.” Bẹ́ẹ̀ ni, ìgbàlà wọn sinmi lórí “gbígbà tí” wọ́n “bá ń gba ìmọ̀” Ọlọ́run àti ti Kristi “sínú.” Ìyẹn kan àwa náà pẹ̀lú. Láti lè rí ìgbàlà, a gbọ́dọ̀ gba irú ìmọ̀ bẹ́ẹ̀ sínú.
8. Kí ni ó túmọ̀ sí láti “gba ìmọ̀” Ọlọ́run “sínú”?
8 Ṣùgbọ́n kí ni ó túmọ̀ sí láti “gba ìmọ̀” Ọlọ́run “sínú”? Ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà tí a túmọ̀ níhìn-ín sí ‘gbígba ìmọ̀ sínú’ dúró fún “láti wá mọ̀, láti gbà” tàbí “láti lóye lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́.” Ṣàkíyèsí pẹ̀lú pé, ìtúmọ̀ náà ‘gbígbà ìmọ̀ sínú’ dọ́gbọ́n túmọ̀ sí pé, èyí jẹ́ ọ̀nà kan tí ń bá a nìṣó. Nípa báyìí, láti gba ìmọ̀ Ọlọ́run sínú túmọ̀ sí láti wá mọ̀ ọ́n, kì í ṣe lóréfèé, ṣùgbọ́n láti mọ̀ ọ́n dunjú, ní mímú ìbádọ́rẹ̀ẹ́ olóye dàgbà pẹ̀lú rẹ̀. Ipò ìbátan tí ń bá a nìṣó pẹ̀lú Ọlọ́run ń mú ìmọ̀ tí ń pọ̀ sí i nípa rẹ̀ wá. Ọ̀nà yìí lè máa bá a nìṣó títí láé, nítorí a kò lè kọ́ gbogbo ohun tí ó yẹ kí a mọ̀ nípa Jèhófà tán láé.—Róòmù 11:33.
9. Kí ni a lè kọ́ nípa Jèhófà láti inú ìwé ìṣẹ̀dá?
9 Báwo ni a ṣe ń gba ìmọ̀ Ọlọ́run sínú? Ìwé méjì ń bẹ tí ó lè ràn wá lọ́wọ́. Àkọ́kọ́ ni ìwé ìṣẹ̀dá. Àwọn ohun tí Jèhófà dá—ohun ẹlẹ́mìí àti ohun aláìlẹ́mìí—ń fún wa ní òye inú nípa irú ẹni tí ó jẹ́. (Róòmù 1:20) Gbé àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ yẹ̀ wò. Ìró gììrì àrágbáyamúyamù ìtàkìtì omi, híhó ibú òkun nígbà ìjì, ìrísí ojú ọ̀run oníràwọ̀ ní alẹ́ kan tí ojú ọjọ́ mọ́ kedere—irú àwọn ohun bẹ́ẹ̀ kò ha kọ́ wa pé Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run tí ó “le ní ipá”? (Aísáyà 40:26) Ọmọdé kan tí ń rẹ́rìn-ín bí ó ṣe ń wo ọmọ ajá tí ń ju ìrù rẹ̀ tàbí ọmọ ológbò kan tí ń fi bọ́ọ̀lù tí a fi òwú ṣe ṣeré—ìyẹn kò ha fi hàn pé Jèhófà, “Ọlọ́run aláyọ̀,” jẹ́ ẹni tí ó lè dẹ́rìn-ín pani bí? (Tímótì Kíní 1:11) Adùn oúnjẹ kan tí ó mìnrìngìndìn, òórùn dídùn òdòdó ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ eléwéko tútù, àwọn àwọ̀ fífanimọ́ra tí labalábá ẹlẹgẹ́ kan ní, ìró àwọn ẹyẹ tí ń kọrin nígbà ìrúwé, ìfọwọ́gbánimọ́ra onífẹ̀ẹ́ láti ọ̀dọ̀ olólùfẹ́ kan—a kò ha fòye mọ̀ láti inú irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ pé Ẹlẹ́dàá wa jẹ́ Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́, tí ó fẹ́ kí a gbádùn ìgbésí ayé bí?—Jòhánù Kíní 4:8.
10, 11. (a) Kí ni a kò lè rí kọ́ nípa Jèhófà àti àwọn ète rẹ̀ láti inú ìwé ìṣẹ̀dá? (b) Àwọn ìbéèrè wo ni ó jẹ́ pé kìkì inú Bíbélì ni a ti lè rí ìdáhùn wọn?
10 Ṣùgbọ́n, ààlà wà nínú ohun tí a lè kọ́ nípa Jèhófà láti inú ìwé ìṣẹ̀dá. Fún àpẹẹrẹ: Kí ni orúkọ Ọlọ́run? Èé ṣe tí ó fi dá ilẹ̀ ayé, tí ó sì fi aráyé sínú rẹ̀? Èé ṣe tí Ọlọ́run fi fi àyè gba ìwà ibi? Kí ni ọjọ́ ọ̀la ní ní ìpamọ́ fún wa? Láti lè rí ìdáhùn sí irú àwọn ìbéèrè bẹ́ẹ̀, a gbọ́dọ̀ lọ sínú ìwé kejì tí ń fi ìmọ̀ Ọlọ́run fúnni—Bíbélì. Nínú ojú ewé rẹ̀, Jèhófà ṣí àwọn nǹkan payá nípa ara rẹ̀, títí kan orúkọ rẹ̀, àkópọ̀ ìwà rẹ̀, àti àwọn ète rẹ̀—ìsọfúnni tí a kò lè rí gbà láti orísun mìíràn.—Ẹ́kísódù 34:6, 7; Orin Dáfídì 83:18; Ámósì 3:7.
11 Nínú Ìwé Mímọ́, Jèhófà tún ń fúnni ní ìmọ̀ ṣíṣe kókó nípa àwọn ẹlòmíràn tí ó yẹ kí a mọ̀. Fún àpẹẹrẹ, Ta ni Jésù Kristi, ipa wo sì ni ó ń kó nínú ṣíṣàṣeparí àwọn ète Jèhófà? (Ìṣe 4:12) Ta ni Sátánì Èṣù? Àwọn ọ̀nà wo ni ó ń gbà ṣi àwọn ènìyàn lọ́nà? Báwo ni a ṣe lè yẹra fún jíjẹ́ kí ó ṣì wá lọ́nà? (Pétérù Kíní 5:8) Inú Bíbélì nìkan ni àwọn ìdáhùn agbẹ̀mílà sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí wà.
12. Báwo ni ìwọ yóò ṣe ṣàlàyé ìdí tí kò fi jẹ́ ẹrù ìnira láti gba ìmọ̀ nípa Ọlọ́run àti àwọn ète rẹ̀ sínú?
12 Ó ha jẹ́ ẹrù ìnira láti gba irú ìmọ̀ bẹ́ẹ̀ nípa Ọlọ́run àti àwọn ète rẹ̀ sínú bí? Rárá o! Ìwọ ha lè rántí ìmọ̀lára tí o ní nígbà tí o kọ́kọ́ kẹ́kọ̀ọ́ pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run, pé Ìjọba rẹ̀ yóò mú Párádísè pa dà wá sí ilẹ̀ ayé yìí, pé ó fi Ọmọkùnrin rẹ̀ olùfẹ́ lélẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìràpadà fún ẹ̀ṣẹ̀ wa, àti àwọn òtítọ́ ṣíṣeyebíye mìíràn? Kò ha dà bíi ṣíṣí ìbòjú àìmọ̀kan kúrò, tí o sì lè rí nǹkan kedere fún ìgbà àkọ́kọ́? Gbígba ìmọ̀ Ọlọ́run sínú kì í ṣe ẹrù ìnira. Ó jẹ́ ohun tí ń mú inú ẹni dùn!—Orin Dáfídì 1:1-3; 119:97.
Kíkúnjú Ìwọ̀n Ọ̀pá Ìdiwọ̀n Ọlọ́run
13, 14. (a) Bí a ti ń gba ìmọ̀ Ọlọ́run sínú, àwọn ìyípadà wo ni a gbọ́dọ̀ ṣe nínú ìgbésí ayé wa? (b) Àwọn àṣà búburú wo ni Ọlọ́run ń béèrè pé kí a yẹra fún?
13 Bí a ṣe ń gba ìmọ̀ Ọlọ́run sínú, a wá rí i pé ó yẹ kí a ṣe ìyípadà nínú ìgbésí ayé wa. Èyí mú wa dé orí ohun kejì tí a ń béèrè. A gbọ́dọ̀ kún ojú ìwọ̀n ọ̀pá ìdiwọ̀n Ọlọ́run fún ìwà tí ó tọ̀nà, kí a sì tẹ́wọ́ gba òtítọ́ rẹ̀. Kí ni òtítọ́? Ohun tí a gbà gbọ́ tí a sì ṣe ha ṣe pàtàkì lójú Ọlọ́run bí? Dájúdájú, ọ̀pọ̀ ènìyàn lónìí kò rò bẹ́ẹ̀. Ìròyìn kan tí Ṣọ́ọ̀ṣì England tẹ̀ jáde ní ọdún 1995 sọ pé, a kò gbọ́dọ̀ ka gbígbé pa pọ̀ láìṣègbéyàwó sí ẹ̀ṣẹ̀. Bíṣọ́ọ̀bù ṣọ́ọ̀ṣì kan sọ pé: “Àpólà ọ̀rọ̀ náà, ‘gbígbé nínú ẹ̀ṣẹ̀’ jẹ́ pípeni lórúkọ tí kò tọ́, kò sì ranni lọ́wọ́.”
14 Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, nígbà náà, “gbígbé nínú ẹ̀ṣẹ̀” kì í ha í ṣe ẹ̀ṣẹ̀ mọ́ bí? Lọ́nà tí ó yéni yékéyéké, Jèhófà sọ ìmọ̀lára rẹ̀ nípa irú ìwà bẹ́ẹ̀ fún wa. Ọ̀rọ̀ rẹ̀, Bíbélì, wí pé: “Kí ìgbéyàwó ní ọlá láàárín gbogbo ènìyàn, kí ibùsùn ìgbéyàwó sì wà láìní ẹ̀gbin, nítorí Ọlọ́run yóò dá àwọn àgbèrè àti àwọn panṣágà lẹ́jọ́.” (Hébérù 13:4) Ìbálòpọ̀ takọtabo ṣáájú ìgbéyàwó lè má jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ lójú ìwòye onígbọ̀jẹ̀gẹ́ tí àwùjọ àlùfáà àti àwọn olùreṣọ́ọ̀ṣì ní, ṣùgbọ́n ẹ̀ṣẹ̀ ńlá ni lójú Ọlọ́run! Bẹ́ẹ̀ náà sì ni panṣágà, bíbá ìbátan ẹni lò pọ̀, àti bíbá ẹ̀yà kan náà lò pọ̀. (Léfítíkù 18:6; Kọ́ríńtì Kíní 6:9, 10) Ọlọ́run ń béèrè pé kí a yàgò fún irú àwọn àṣà bẹ́ẹ̀, èyí tí òun kà sí àìmọ́.
15. Báwo ni àwọn ohun tí Ọlọ́run ń béèrè fún ṣe kan ọ̀nà tí a ń gbà bá àwọn ẹlòmíràn lò àti ohun tí a gbà gbọ́?
15 Ṣùgbọ́n, yíyàgò fún àwọn àṣà tí Ọlọ́run kà sí ẹ̀ṣẹ̀ kò tó. Àwọn ohun tí Ọlọ́run ń béèrè fún tún ní bí a ṣe ń bá àwọn ẹlòmíràn lò nínú. Nínú ìdílé, ó ń retí pé kí ọkọ àti aya nífẹ̀ẹ́ ara wọn, kí wọ́n sì bọ̀wọ̀ fún ara wọn. Ọlọ́run ń béèrè pé kí àwọn òbí bójú tó àìní àwọn ọmọ wọn nípa ti ara, nípa ti ẹ̀mí, àti nípa ti èrò ìmọ̀lára. Ó sọ fún àwọn ọmọ pé kí wọ́n gbọ́ràn sí àwọn òbí wọn. (Òwe 22:6; Kólósè 3:18-21) Àwọn ohun tí a sì gbà gbọ́ ńkọ́? Jèhófà Ọlọ́run fẹ́ kí a yẹra fún àwọn ìgbàgbọ́ àti àṣà tí ó wá láti inú ìjọsìn èké tàbí tí ó lòdì sí àwọn ẹ̀kọ́ ṣíṣe kedere tí Bíbélì fi kọ́ni.—Diutarónómì 18:9-13; Kọ́ríńtì Kejì 6:14-17.
16. Ṣàlàyé ìdí tí kì í fi ṣe ẹrù ìnira láti kúnjú ìwọ̀n àwọn ọ̀pá ìdíwọ̀n Ọlọ́run fún ìwà tí ó tọ̀nà, kí a sì tẹ́wọ́ gba òtítọ́ rẹ̀.
16 Ó ha jẹ́ ẹrù ìnira fún wa láti kún ojú ìwọ̀n àwọn ọ̀pá ìdiwọ̀n Ọlọ́run fún ìwà tí ó tọ̀nà, kí a sì tẹ́wọ́ gba òtítọ́ rẹ̀ bí? Kò rí bẹ́ẹ̀, bí a bá gbé àwọn àǹfààní rẹ̀ yẹ̀ wò—ìgbéyàwó nínú èyí tí ọkọ àti aya ti nífẹ̀ẹ́ ara wọn, tí wọ́n sì ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ara wọn, dípò ìgbéyàwó tí ó forí ṣánpọ́n nítorí àìṣòótọ́; ilé tí àwọn ọmọ ti nímọ̀lára pé àwọn òbí àwọn nífẹ̀ẹ́ àwọn tí wọ́n sì nílò àwọn, dípò ìdílé nínú èyí tí àwọn ọmọ ti nímọ̀lára pé a kò nífẹ̀ẹ́ àwọn, pé a ṣá àwọn tì, pé a kò sì nílò àwọn; ẹ̀rí ọkàn mímọ́ àti ìlera tí ó jíire, dípò ìmọ̀lára ẹ̀bi àti ara tí àrùn AIDS tàbí àwọn àrùn míràn tí ìbálòpọ̀ ń tàtaré rẹ̀ ti sọ di hẹ́gẹhẹ̀gẹ. Dájúdájú, àwọn ohun tí Jèhófà ń béèrè kò fi ohunkóhun tí a fẹ́ láti lè gbádùn ìgbésí ayé dù wá!—Diutarónómì 10:12, 13.
Fi Ọ̀wọ̀ Hàn fún Ìwàláàyè àti Ẹ̀jẹ̀
17. Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo ìwàláàyè àti ẹ̀jẹ̀?
17 Bí o ti ń mú ara rẹ bá àwọn ọ̀pá ìdiwọ̀n Ọlọ́run mu, ìwọ wá ń mọrírì bí ìwàláàyè ti ṣeyebíye tó ní tòótọ́. Wàyí o, ẹ jẹ́ kí a jíròrò ohun kẹta tí Ọlọ́run ń béèrè. A gbọ́dọ̀ fi ọ̀wọ̀ hàn fún ìwàláàyè àti ẹ̀jẹ̀. Ìwàláàyè jẹ́ ohun mímọ́ ọlọ́wọ̀ lójú Jèhófà. Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe yẹ kí ó rí, nítorí pé òun ni Orísun ìwàláàyè. (Orin Dáfídì 36:9) Họ́wù, àní ìwàláàyè ọmọ tí a kò tí ì bí pàápàá nínú ìyá rẹ̀ ṣeyebíye lójú Jèhófà! (Ẹ́kísódù 21:22, 23) Ẹ̀jẹ̀ dúró fún ìwàláàyè. Nítorí náà, ẹ̀jẹ̀ pẹ̀lú jẹ́ ohun mímọ́ ọlọ́wọ̀ lójú Ọlọ́run. (Léfítíkù 17:14) Nítorí náà, kò yẹ kí ó yà wá lẹ́nu pé, Ọlọ́run ń retí pé kí a fi ojú tí òun fi ń wo ìwàláàyè àti ẹ̀jẹ̀ wò ó.
18. Kí ni ojú ìwòye Jèhófà nípa ìwàláàyè àti ẹ̀jẹ̀ ń béèrè lọ́wọ́ wa?
18 Kí ni bíbọ̀wọ̀ fún ìwàláàyè àti ẹ̀jẹ̀ ń béèrè lọ́wọ́ wa? Gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, a kò ní máa fi ìwàláàyè wa sínú ewu tí kò pọn dandan kìkì nítorí ìgbádùn. A mọ ìjẹ́pàtàkì ààbò, nítorí náà a gbọ́dọ̀ rí i dájú pé ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ wa àti ilé wa fọkàn ẹni balẹ̀. (Diutarónómì 22:8) A kì í lo tábà, a kì í jẹ ẹ̀pà betel, tàbí kí a lo oògùn líle tàbí oògùn tí ń pani lọ́bọlọ̀ fún fàájì. (Kọ́ríńtì Kejì 7:1) Nítorí pé a fetí sí Ọlọ́run nígbà tí ó sọ pé ‘ta kété sí ẹ̀jẹ̀,’ a kì í gba ẹ̀jẹ̀ sí ara wa. (Ìṣe 15:28, 29) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a nífẹ̀ẹ́ ìwàláàyè, a kì yóò gbìyànjú láti du ìwàláàyè wa ti ìsinsìnyí nípa rírú òfin Ọlọ́run, kí a sì tipa bẹ́ẹ̀ wu ìfojúsọ́nà wa fún ìyè àìnípẹ̀kun léwu!—Mátíù 16:25.
19. Ṣàlàyé bí a ṣe ń jàǹfààní nínú fífi ọ̀wọ̀ hàn fún ìwàláàyè àti ẹ̀jẹ̀.
19 Ó ha jẹ́ ẹrù ìnira fún wa láti wo ìwàláàyè àti ẹ̀jẹ̀ bí ohun mímọ́ ọlọ́wọ̀ bí? Kò rí bẹ́ẹ̀ rárá! Ronú nípa rẹ̀. Ó ha jẹ́ ẹrù ìnira láti má ṣe ní àrùn jẹjẹrẹ ẹ̀dọ̀ fóró tí tábà mímu ń fà bí? Ó ha jẹ́ ẹrù ìnira láti yè bọ́ lọ́wọ́ sísọ àwọn oògùn tí ó lè pani lára di bárakú nípa ti ara àti èrò orí bí? Ó ha jẹ́ ẹrù ìnira láti yẹra fún kíkó àrùn AIDS, àrùn mẹ́dọ̀wú, tàbí àwọn àrùn míràn láti inú ìfàjẹ̀sínilára bí? Ó ṣe kedere pé, yíyẹra tí a bá yẹra fún àwọn ìwà àti àṣà tí ó lè pani lára jẹ́ fún ire wa dídára jù lọ.—Aísáyà 48:17.
20. Báwo ni ìdílé kan ṣe jàǹfààní nínú níní ojú ìwòye Ọlọ́run nípa ìwàláàyè?
20 Gbé ìrírí yìí yẹ̀ wò. Ní ọdún mélòó kan sẹ́yìn, obìnrin Ẹlẹ́rìí kan tí ó lóyún oṣù mẹ́ta ààbọ̀ ni ẹ̀jẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í ya lára rẹ̀ ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kan, wọ́n sì tètè gbé e lọ sí ilé ìwòsàn. Lẹ́yìn tí dókítà yẹ̀ ẹ́ wò, obìnrin náà gbọ́ bí dókítà náà ṣe ń sọ fún ọ̀kan lára àwọn nọ́ọ̀sì pé, yíyọ ni wọn yóò yọ oyún náà kúrò. Ní mímọ ojú ìwòye Jèhófà nípa ìwàláàyè ọmọ tí a kò tí ì bí, ó kọ̀ jálẹ̀ láti ṣẹ́ oyún náà, ní sísọ fún dókítà pé: “Bí ó bá ṣì wà láàyè, ẹ fi í sílẹ̀ síbẹ̀!” Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ẹ̀jẹ̀ ṣì máa ń dà lára rẹ̀, ṣùgbọ́n oṣù díẹ̀ lẹ́yìn náà, ó bí ọmọkùnrin làǹtì-lanti kan tí oṣù rẹ̀ kò tí ì pé, ẹni tí ó ti di ọmọ ọdún 17 báyìí. Ó ṣàlàyé pé: “Gbogbo èyí ni a sọ fún ọmọ wa, ó sì sọ pé inú òun dùn pé a kò yọ òun dà nù. Ó mọ̀ pé ṣíṣiṣẹ́sìn tí a ń ṣiṣẹ́ sin Jèhófà ni ìdí kan ṣoṣo tí ó mú kí òun wà láàyè lónìí.” Ó dájú pé, níní ojú ìwòye Ọlọ́run nípa ìwàláàyè kì í ṣe ẹrù ìnira fún ìdílé yìí!
Ṣíṣiṣẹ́sìn Pa Pọ̀ Pẹ̀lú Àwọn Ènìyàn Jèhófà Tí A Ṣètò Jọ
21, 22. (a) Pẹ̀lú àwọn wo ni Jèhófà retí pé kí a ṣiṣẹ́ sin òun? (b) Báwo ni a ṣe lè mọ àwọn ènìyàn Ọlọ́run tí a ṣètò jọ?
21 Àwa nìkan kọ́ ni ó ń ṣe àwọn ìyípadà tí a nílò láti mú ìgbésí ayé wa bá ọ̀pá ìdiwọ̀n Ọlọ́run mu. Jèhófà ní àwọn ènìyàn lórí ilẹ̀ ayé yìí, ó sì ń retí pé kí a bá wọn kẹ́gbẹ́ pọ̀ ní ṣíṣiṣẹ́sin òun. Èyí mú wa dé orí ohun kẹrin tí a ń béèrè. A gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ sin Jèhófà nínú ètò àjọ rẹ̀ tí ẹ̀mí ń darí.
22 Ṣùgbọ́n, báwo ni a ṣe lè dá àwọn ènìyàn Ọlọ́run, tí a ṣètò jọ mọ̀? Ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀pá ìdiwọ̀n tí a fi lélẹ̀ nínú Ìwé Mímọ́, wọ́n ní ojúlówó ìfẹ́ láàárín ara wọn, wọ́n ní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún Bíbélì, wọ́n ń bọlá fún orúkọ Ọlọ́run, wọ́n ń wàásù nípa Ìjọba rẹ̀, wọn kì í sì í ṣe apá kan ayé burúkú yìí. (Mátíù 6:9; 24:14; Jòhánù 13:34, 35; 17:16, 17) Ètò àjọ ìsìn kan ṣoṣo ní ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé yìí tí ó ní gbogbo àmì ìsìn Kristẹni tòótọ́ wọ̀nyí—Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà!
23, 24. Báwo ni a ṣe lè ṣàkàwé pé kì í ṣe ẹrù ìnira láti ṣiṣẹ́ sin Jèhófà pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀ tí a ṣètò jọ?
23 Ó ha jẹ́ ẹrù ìnira láti ṣiṣẹ́ sin Jèhófà pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀ tí ó ṣètò jọ bí? Kò rí bẹ́ẹ̀ rárá! Ní òdì kejì pátápátá, àǹfààní ṣíṣeyebíye ni ó jẹ́ láti ní ìfẹ́ àti ìtìlẹyìn ìdílé kárí ayé ti àwọn Kristẹni arákùnrin àti arábìnrin. (Pétérù Kíní 2:17) Fojú inú wo yíyèbọ́ nínú ọkọ̀ kan tí ó rì, tí o sì rí ara rẹ nínú omi, tí o ń gbìyànjú láti léfòó. Nígbà tí o rí i pé o kò lè tiraka mọ́, ẹnì kan gbá ọ mú láti inú ọkọ̀ kan tí a fi ń gba ẹ̀mí là. Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn mìíràn wà tí wọ́n yè bọ́! Nínú ọkọ̀ náà tí a fi ń gba ẹ̀mí là, ìwọ àti àwọn yòó kù ń gba títu ọkọ̀ náà lọ sí èbúté lọ́wọ́ ara yín, tí ẹ ń gbé àwọn olùyèbọ́ mìíràn ní ojú ọ̀nà.
24 A kò ha wà ní irú ipò kan náà bí? A ti fà wá jáde láti inú “omi” tí ó léwu, ti ayé burúkú yìí, sínú “ọkọ̀ tí a fi ń gba ẹ̀mí là,” ètò àjọ Jèhófà ti orí ilẹ̀ ayé. Nínú rẹ̀, a ń ṣiṣẹ́ sìn ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ bí a ṣe ń forí lé “èbúté” ayé tuntun òdodo. Bí pákáǹleke ìgbésí ayé yóò bá mú kí a káàárẹ̀ lójú ọ̀nà, ẹ wo bí ó ṣe yẹ kí a ṣọpẹ́ tó fún ìtìlẹyìn àti ìtùnú tí àwọn Kristẹni alábàákẹ́gbẹ́pọ̀ ń fúnni!—Òwe 17:17.
25. (a) Kí ni ojúṣe wa sí àwọn tí wọ́n ṣì wà nínú “omi” ayé burúkú yìí? (b) Kí ni ohun tí Ọlọ́run ń béèrè fún tí a óò jíròrò nínú ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó tẹ̀ lé e?
25 Àwọn yòó kù ńkọ́—àwọn aláìlábòsí ọkàn tí wọ́n ṣì wà nínú “omi”? Ojúṣe wa ni láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti wá sínú ètò àjọ Jèhófà, àbí kì í ṣe ojúṣe wa? (Tímótì Kíní 2:3, 4) Wọ́n nílò ìrànlọ́wọ́ láti mọ ohun tí Ọlọ́run ń béèrè. Èyí mú wa dé orí ohun karùn-ún tí Ọlọ́run ń béèrè. A gbọ́dọ̀ jẹ́ adúróṣinṣin olùpòkìkí Ìjọba Ọlọ́run. A óò jíròrò ohun tí èyí ní nínú nínú ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó tẹ̀ lé e.
Ìwọ Ha Rántí Bí?
◻ Èé ṣe tí àwọn àṣẹ Ọlọ́run kì í fi í ṣe ẹrù ìnira?
◻ Báwo ni a ṣe ń gba ìmọ̀ Ọlọ́run sínú?
◻ Èé ṣe tí kì í fi í ṣe ẹrù ìnira láti kúnjú ìwọ̀n àwọn ọ̀pá ìdiwọ̀n Ọlọ́run fún ìwà tí ó tọ̀nà, kí a sì tẹ́wọ́ gba òtítọ́ rẹ̀?
◻ Kí ni ojú ìwòye Ọlọ́run nípa ìwàláàyè àti ẹ̀jẹ̀ ń béèrè lọ́wọ́ wa?
◻ Pẹ̀lú àwọn wo ni Ọlọ́run retí pé kí a ṣiṣẹ́ sin òun, báwo sì ni a ṣe lè mọ̀ wọ́n?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
A ń kọ́ nípa Jèhófà láti inú ìwé ìṣẹ̀dá àti láti inú Bíbélì
[Àwọn Credit Line]
Ọ̀nì: Nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda onínúure ti Australian International Public Relations; béárì: Safari-Zoo ti Ramat-Gan, Tel Aviv