Àràádọ́ta Ọ̀kẹ́ Yóò Lọ Síbẹ̀ Ìwọ Ńkọ́?
Yóò lọ síbo? Síbi ayẹyẹ ọdọọdún ti ìrántí ikú Jésù Kristi. Ní 1996, àròpọ̀ 12,921,933 ni ó pésẹ̀ jákèjádò ayé.
Èé ṣe tí àwọn ènìyàn fi lọ? Nítorí ohun tí ikú Jésù túmọ̀ sí fún aráyé. Ó túmọ̀ sí ìtura kúrò lọ́wọ́ àìsàn, ìyà, àti ikú. A óò jí àwọn olólùfẹ́ wa tí ó ti kú pàápàá dìde sí ìyè lórí ilẹ̀ ayé tí a ti sọ di párádísè kan.
Báwo ni ikú Jésù Kristi ṣe lè mú irú ìbùkún bẹ́ẹ̀ wá? A ké sí ọ láti wádìí. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà ọ́ tọwọ́tẹsẹ̀ láti wá pé jọ pẹ̀lú wọn fún ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì yí.
Lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba tí ó sún mọ́ ilé rẹ jù lọ. Ọjọ́ tí ó bọ́ sí ní ọdún yìí ni Sunday, March 23, lẹ́yìn tí oòrùn bá ti wọ̀. Wádìí àkókò náà gan-an tí a óò bẹ̀rẹ̀ lọ́wọ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ládùúgbò.