Èé Ṣe Tí Àwọn Àkókò Wọ̀nyí Fi Burú Tó Bẹ́ẹ̀?
NÍGBÀ tí o bá jókòó láti ka ìwé ìròyìn tàbí láti gbọ́ ìròyìn orí tẹlifíṣọ̀n tàbí tẹ́tí sí ìròyìn tí a ń kà lórí rédíò, ìwọ máa ń retí àtigbọ́ ìròyìn burúkú kan, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Ó tilẹ̀ lè má yà ọ lẹ́nu láti gbọ́ pé ogun kan ṣì ń lọ lọ́wọ́, pé ìwà ọ̀daràn oníwà ipá ṣì pọ̀ rẹpẹtẹ, tàbí pé ìyàn kan ṣì ń jà rànyìn ní orílẹ̀-èdè kan tí ń gòkè àgbà.
Tí ibi tí o ń gbé bá jìnnà díẹ̀ sí ibi tí àwọn nǹkan wọ̀nyí ti ń ṣẹlẹ̀, ó ṣeé ṣe kí irú àwọn ìròyìn bẹ́ẹ̀ má fi bẹ́ẹ̀ kó ìdààmú bá ọ lemọ́lemọ́. Ó ṣe tán, ta ní lè fọ̀ràn ogunlọ́gọ̀ tí ń jìyà wọ̀nyẹn ro ara rẹ̀ wò, tí kò ní nípa lórí rẹ̀? Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ó ṣòro gan-an láti ṣàìkáàánú nígbà tí a bá dojú kọ ọ̀nà tí ìyà gbà ń nípa lórí àwọn ènìyàn. Ní ọ̀rọ̀ míràn, ọ̀tọ̀ ni pé kí a kà nípa ogun, kí a sì ronú lórí iye àwọn ènìyàn tí ó bá a lọ, ọ̀tọ̀ sì tún ni pé kí a kà nípa Adnan kékeré, ọmọ Bosnia ọlọ́dún mẹ́sàn-án kan, tí bọ́ǹbù tí ó run ilé wọn pa ìyá rẹ̀. A yìnbọn pa bàbá Adnan ní oṣù díẹ̀ lẹ́yìn náà, bí wọ́n ti ń rìn ní òpópónà kan. Ẹ̀jẹ̀ dà lára arábìnrin rẹ̀ níṣojú rẹ̀ títí ó fi kú, ní ọ̀sẹ̀ bíi mélòó kan lẹ́yìn náà, bọ́ǹbù tí ó balẹ̀ sínú ọgbà ilé ẹ̀kọ́ wọn ni ó ṣekù pa á. Àwọn dókítà tí ó tọ́jú Adnan fún hílàhílo rí i pé a ti pa ìmọ̀lára ọmọdékùnrin náà kú pátápátá, kò nímọ̀lára kankan mọ́—títí kan ẹ̀mí ìtọpinpin pàápàá. Ìbẹ̀rù àti ìrántí ìṣẹ̀lẹ̀ àtẹ̀yìnwá ń pọ́n ọn lójú ní àwọn wákàtí tí ojú rẹ̀ dá; àlákálàá kì í jẹ́ kí ó sun oorun àsùnwọra. Adnan kì í ṣe ọ̀kan nínú iye kan. Ọmọdé kan tí ìyà ń pọ́n lójú ni; a kò lè ṣàìmá káàánú rẹ̀.
Bí ọ̀rọ̀ ti rí nìyẹn pẹ̀lú àwọn ìṣòro mìíràn nínú ayé. Ọ̀tọ̀ ni láti kà nípa ìyàn; ọ̀tọ̀ sì tún ni láti rí àwòrán ọmọdébìnrin ọlọ́dún márùn-ún abikùn rogodo kan, tí ẹsẹ̀ rẹ̀ gbẹ, tí ó sì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kú nítorí àìróńjẹjẹ. Ọ̀tọ̀ ni kí a kà nípa iye ìwà ọ̀daràn; ọ̀tọ̀ sì tún ni kí a gbọ́ nípa opó àgbàlagbà kan, tí a lù bí ẹní máa kú, tí a jà lólè, tí a sì fipá bá lòpọ̀. Ọ̀tọ̀ ni kí a kà nípa ìdílé tí ń forí ṣánpọ́n; ọ̀tọ̀ sì tún ni kí a gbọ́ pé, ìyá kan dìídì febi pa ọmọ inú rẹ̀, ó sì hùwà òǹrorò sí i.
Ó ń kó ìrora ọkàn báni láti kà nípa àwọn nǹkan báwọ̀nyí. Ṣùgbọ́n, ẹ wo bí ó ti burú tó, nígbà tí ọ̀kan nínú àwọn àjálù tí ó kárí ayé yìí bá pọ́n wa lójú ní tààràtà! Nígbà tí ibi bá ṣẹlẹ̀ sí ọ, ipò àgbáyé, tí ìròyìn àgbáyé máa ń gbé jáde, lè di èyí tí ó bò ọ́ mọ́lẹ̀. Ó ń kó ìpayà báni láti kojú òkodoro òtítọ́ náà pé, jíjìyà lọ́wọ́ ìwà ipá, ogun, ìyàn, àti àrùn túbọ̀ ń peléke sí i dé ìwọ̀n tí a kò tí ì rí irú rẹ̀ rí nínú ìtàn ẹ̀dá ènìyàn. Ipa kíkojú ohun tí ń ṣẹlẹ̀ gan-an nínú ọ̀rúndún ogún yìí lè pani kú ní tòótọ́—ìdàrúdàpọ̀ ọkàn, ìbẹ̀rù, àti ìsoríkọ́ wọ́pọ̀.
Àwọn ènìyàn inú ọ̀pọ̀ ìsìn ń wá ìdáhùn sí irú àwọn ìbéèrè tí ń yọni lẹ́nu bíi, Èé ṣe tí àwọn nǹkan fi burú tó bẹ́ẹ̀? Ibo ni aráyé ń forí lé?
Lọ́nà tí ó bani nínú jẹ́, àwọn ìsìn òde òní kò pèsè ìdáhùn tí ń tẹ́ni lọ́rùn. Nígbà tí o kọ́kọ́ rí ìbéèrè tí ó wà níwájú ìwé ìròyìn yí, o lè ti ṣiyè méjì—ìhùwàpadà rẹ sì yéni. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn ìsìn tí ń rin kinkin mọ́lànà máa ń gbìyànjú láti sọ pé Bíbélì sọ ohun tí kò sọ—ọjọ́ àti wákàtí náà gan-an tí ayé yìí yóò wá sí òpin. (Wo Mátíù 24:36.) Àwọn tí ó ṣe ìwé ìròyìn yí jáde ń yàn láti jẹ́ kí Bíbélì ṣàlàyé ara rẹ̀. Ó lè yà ọ́ lẹ́nu láti gbọ́ pé, àlàyé tí Bíbélì ṣe nípa àwọn ọjọ́ ìkẹyìn jẹ́ òtítọ́, ó sì bọ́gbọ́n mu. Bíbélì sì ṣe ju ṣíṣàlàyé ìdí tí àwọn nǹkan fi burú tó bẹ́ẹ̀. Ó tún pèsè ìrètí fún ọjọ́ ọ̀la, èyí tí ń tuni nínú ní tòótọ́. A rọ̀ ọ́ láti gbé àwọn àpilẹ̀kọ tí ó tẹ̀ lé e yẹ̀ wò láti rí i bí èyí ṣe rí bẹ́ẹ̀.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 2]
Iwájú ìwé àti ojú ìwé 32: AFP/Corbis-Bettmann
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]
Jobard/Sipa Press