“Ẹ̀wù Mímọ́ Trier”
TRIER, pẹ̀lú ìtàn tí ó ti ní fún 2,000 ọdún sẹ́yìn, ni ìlú ọlọ́jọ́ pípẹ́ jù lọ ní Germany.a Fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún, Trier ti ní àjọṣe lílágbára pẹ̀lú Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì. Ní 1996, kàtídírà tí ó wà ní Trier ṣàfihàn ohun ìṣẹ̀ǹbáyé kan, tí a rò pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìlú ńlá náà fúnra rẹ̀ lọ́jọ́ orí. A pè é ní Ẹ̀wù Mímọ́ Trier.
Ẹ̀wù náà gùn tó mítà 1.57, ó sì fẹ̀ tó 1.09 mítà, ó sì jẹ́ alápá péńpé. Òwú ni a fi ṣe é, gẹ́gẹ́ bí Hans-Joachim Kann sì ti sọ nínú ìwé rẹ̀, Wallfahrtsführer Trier und Umgebung (Atọ́nà Àwọn Arìnrìn-Àjò Ìsìn sí Trier àti Àgbègbè Rẹ̀), a sábà máa ń wọ̀ ọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀wù àwọ̀lékè. Àwọn ìfojúdíwọ̀n kan tí a ṣe fi hàn pé ojúlówó ẹ̀wù náà—tí a ti tún rán lọ́pọ̀ ìgbà, tí a sì ti fi aṣọ mìíràn lẹ̀ la àwọn ọ̀rúndún já—ti wà láti ọ̀rúndún kejì tàbí ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa pàápàá. Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ìyẹn yóò mú kí ó jẹ́ ẹ̀wù tí ó ṣọ̀wọ́n, ohun ìṣẹ̀ǹbáyé kan tí ó fani lọ́kàn mọ́ra.
Ṣùgbọ́n, àwọn kan tẹnu mọ́ ọn pé, kì í ṣe pé ẹ̀wù náà ṣọ̀wọ́n nìkan ni, ṣùgbọ́n ó tún jẹ́ mímọ́—ìdí abájọ rèé tí a fi fún un ní orúkọ náà, Ẹ̀wù Mímọ́. Èyí jẹ́ nítorí pé kò ní ojú rírán, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ tí Jésù Kristi wọ̀ kò ti ní. (Jòhánù 19:23, 24) Àwọn kan sọ pé, “Ẹ̀wù Mímọ́” náà ní ti gidi jẹ́ ti Mèsáyà náà.
Bí ẹ̀wù náà ṣe dé Trier kò dáni lójú. Iṣẹ́ ìtọ́ka kan sọ pé “olú ọbabìnrin Helena, ìyá Constantine Ńlá, ni ó gbé e fún ìlú náà.” Kann tọ́ka sí i pé, ìròyìn àkọ́kọ́ tí ó ṣeé gbára lé sọ pé láti 1196 ni ẹ̀wù náà ti wọ Trier.
Ẹ̀wù náà, tí a fi pa mọ́ sínú kàtídírà, ni a ti ṣàfihàn rẹ̀ látìgbàdégbà láti ọ̀rúndún kẹrìndínlógún. Fún àpẹẹrẹ, a ṣe èyí ní 1655, kété lẹ́yìn Ogun Ọgbọ̀n Ọdún, tí ó ná Trier lówó púpọ̀. Lọ́pọ̀ ìgbà, títa àwọn ohun ìránnilétí ìrìn àjò ìsìn látìgbàdégbà ti mú owó jaburata wọlé.
Ìrìn àjò ìsìn mẹ́ta ti “Ẹ̀wù Mímọ́” ni a ṣe ní ọ̀rúndún yìí—ní 1933, 1959, àti 1996. Ní 1933, a kéde ìrìn àjò ìsìn ní ọjọ́ kan náà tí a yan Hitler sípò gẹ́gẹ́ bíi káńsẹ́lọ̀ ẹgbẹ́ Reich ti Germany. Kann tọ́ka sí i pé, ìṣekòńgẹ́ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ méjèèjì yí lọ́jọ́ kan náà tẹnu mọ́ àwọn ipò tí ó yí ìrìn àjò ìsìn náà ká. Ẹgbẹ́ ọmọ ogun Nazi tí wọ́n wà nínú aṣọ ọmọ ogun, dúró wáwááwá láti ṣàyẹ́sí àwọn arìnrìn-àjò ìsìn níta kàtídírà. Mílíọ̀nù méjì àbọ̀ ènìyàn ni ó wo ẹ̀wù náà lọ́dún yẹn.
Herbert, olùgbé Trier fún ọ̀pọ̀ ọdún, fi ìrìn àjò ìsìn ti 1959 wé ti 1996. “Ní 1959, èrò kún ojú pópó fọ́fọ́, tí àwọn ìsọ̀ tí a ti ń ta ohun ìránnilétí ìrìn àjò ìsìn sì fẹ́rẹ̀ẹ́ wà ní gbogbo igun ọ̀nà. Lọ́dún yìí, gbogbo rẹ̀ pa lọ́lọ́ ju ti ìṣáájú.” Ní tòótọ́, kìkì 700,000 ènìyàn ni ó wá wo ẹ̀wù náà ní 1996, ó fi mílíọ̀nù kan dín sí iye ti 1959.
Èé Ṣe Tí Wọ́n Fi Ń Lọ Wo Ẹ̀wù Náà?
Ṣọ́ọ̀ṣì tẹnu mọ́ ọn pé a kò ní láti wo ẹ̀wù náà gẹ́gẹ́ bí ohun ìbọláfún. A ń wo ẹ̀wù tí kò ní ojú rírán náà gẹ́gẹ́ bí ohun ìṣàpẹẹrẹ ìṣọ̀kan ṣọ́ọ̀ṣì. Ìwé agbéròyìnjáde náà, Frankfurter Allgemeine Zeitung, ròyìn pé, nígbà tí ó ń kéde ìrìn àjò ìsìn náà, Bíṣọ́ọ̀bù Spital wí pé: “Ipò tí ó ṣàjèjì nínú ayé wa ń pe àwa Kristẹni níjà láti ní ìdáhùn tí ó ṣàjèjì. A ní láti ta ko ìkórìíra, ìwà òǹrorò, àti ìwà ipá tí ń peléke sí i.” Bíṣọ́ọ̀bù náà ṣàlàyé pé, wíwo ẹ̀wù náà yóò ránni létí ìṣọ̀kan.
Àmọ́, èé ṣe tí ẹnì kan fi nílò “Ẹ̀wù Mímọ́” láti lè rántí ìṣọ̀kan ṣọ́ọ̀ṣì? Bí ẹ̀wù náà bá bà jẹ́, tàbí bí ó bá ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, tàbí bí a bá fi hàn pè ayédèrú ni ńkọ́? Ìṣọ̀kan ṣọ́ọ̀ṣì yóò ha wà nínú ewu nígbà náà bí? Àwọn ènìyàn tí kò lè rìnrìn àjò ìsìn lọ sí Trier ńkọ́? Ó ha lè jẹ́ pé ìṣọ̀kan láàárín ṣọ́ọ̀ṣì kò jẹ wọ́n lọ́kàn bí?
Ìwé Mímọ́ kò mẹ́nu kàn án pé, àwọn Kristẹni ìjímìjí nílò ohunkóhun tí ó ṣeé fojú rí láti rán wọn létí àìní fún ìṣọ̀kan Kristẹni. Ní tòótọ́, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún àwọn Kristẹni níṣìírí pé: “Nípa ìgbàgbọ́ ni àwa ń rìn, kì í ṣe nípa ohun tí a rí.” (Kọ́ríńtì Kejì 5:7) Nípa báyìí, a ṣàpèjúwe ìṣọ̀kan tí àwọn Kristẹni tòótọ́ ń gbádùn gẹ́gẹ́ bí “ìṣọ̀kan ṣoṣo nínú ìgbàgbọ́.”—Éfésù 4:11-13.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo Jí! April 22, 1980, (Gẹ̀ẹ́sì) ojú ìwé 21 sí 23.