Kí Ní Ṣẹlẹ̀ sí Ìwà Títọ́?
NÍ ÈYÍ tí ó fi díẹ̀ lé ní ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn, Barney Barnato, olókòwò dáyámọ́ńdì, darí dé láti Gúúsù Áfíríkà sí England. Nígbà tí ó dé, inú rẹ̀ kò dùn sí ìtàn tí ìwé agbéròyìnjáde kan kọ nípa rẹ̀. Nítorí náà, ó fún olóòtú ìwé ìròyìn náà ní àkọsílẹ̀ kékeré kan, láti fi kọ àpilẹ̀kọ kejì, “láti ṣàtúnṣe àwọn nǹkan kan,” pẹ̀lú ìwé sọ̀wédowó fún owó gọbọi.
Olóòtú náà, J. K. Jerome, ju ìwé kékeré náà sínú apẹ̀rẹ̀ ìdabébàsí, ó sì dá ìwé sọ̀wédowó náà pa dà. Ó ya Barnato lẹ́nu, ó sì lọ́po owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ náà. A kọ èyí bákan náà. Ó béèrè pé: “Eélòó lo ń fẹ́?” Ní rírántí ìṣẹ̀lẹ̀ náà, Jerome sọ pé: “Mo ṣàlàyé fún un pé, a kì í ṣe bẹ́ẹ̀—ní London.” Dájúdájú, a kò lè fi owó ra ìwà títọ́ olóòtú rẹ̀.
A tú “ìwà títọ́” sí “ìdúróṣánṣán ní ti ìwà rere; àìlábòsí.” A lè gbẹ́kẹ̀ lé oníwàtítọ́ ènìyàn. Ṣùgbọ́n lónìí, ìwà àyídáyidà—àìníwàtítọ́—ń jin onírúurú ipò ìgbésí ayé lẹ́sẹ̀.
Ní Britain, àwọn ilé iṣẹ́ agbéròyìnjáde ti sọ ọ̀rọ̀ náà, “àìníwàtítọ́” di ọ̀rọ̀ tí ó wọ́pọ̀ láti túmọ̀ ìpàdánù ìwà títọ́ ní ti ìwà híhù. Gẹ́gẹ́ bí ìwé agbéròyìnjáde náà, The Independent, ti sọ ọ́, àìníwàtítọ́ ń nípa lórí “gbogbo nǹkan láti orí àjọṣepọ̀ ìfẹ́ àti wíwá ojú rere lábẹ́ ìjọba ìbílẹ̀, títí dórí gbígbàbẹ̀tẹ́lẹ̀ lórí àwọn ohun tí a ń kó ránṣẹ́ sí ilẹ̀ òkèèrè.” Kò yẹ àgbègbè èyíkéyìí nínú ìgbésí ayé sílẹ̀.
Àwọn Ìlànà Ìwà Títọ́ Tí Ń Lọ Sókè Sódò
Dájúdájú, ìwà títọ́ kò túmọ̀ sí ìjẹ́pípé, ṣùgbọ́n, ó fi ànímọ́ pàtàkì hàn nínú ẹnì kan. Nínú ayé dolówó-ọ̀sán-gangan tí a wà yí, a lè rí ìwà títọ́ gẹ́gẹ́ bí ohun ìdènà, kì í ṣe ìwà funfun. Fún àpẹẹrẹ, àwọn ọmọ ilé ìwé tí ń lo àwọn ẹ̀rọ tí ó díjú láti fi ṣe awúrúju nínú ìdánwò túbọ̀ ń pọ̀ sí i, àwọn ìhùmọ̀ tuntun wọ̀nyí sì ṣòro gan-an láti rí. Ọ̀jọ̀gbọ́n yunifásítì kan tí ó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Britain, sọ pé, èyí tí ó lé ní ìdajì àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ tí ó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Britain ni ó ti ṣe awúrúju rí, kì í sì í ṣe Britain nìkan ni a ti ń ṣe é.
Ohun tí kò yẹ kí a gbójú fò dá ni ohun tí ń ná àwọn ènìyàn tí kò mọwọ́ mẹsẹ̀ nígbà tí àwọn aláìṣeé-gbẹ́kẹ̀lé bá purọ́, tí wọ́n sì tanni jẹ. Fún àpẹẹrẹ, gbé ọ̀ràn ìlú kan ní India, tí a ń pè ní Bhopal, yẹ̀ wò, níbi tí gáàsì onímájèlé ti pa iye tí ó lé ní 2,500 ọkùnrin, obìnrin, àti ọmọdé, tí ó sì ṣe ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rún léṣe, ní 1984. Ìwé agbéròyìnjáde náà, The Sunday Times, ròyìn pé: “Ètò ìrànwọ́ tí a ṣe láti ran àwọn tí ọ̀ràn kàn lọ́wọ́ ni ìwà ìbàjẹ́ ti tàbùkù sí. . . . Ẹgbẹẹgbẹ̀rún owó èrú tí a ń béèrè fún, ìwé tí a yí àti ẹ̀rí èké, ti mú kí ṣíṣàyẹ̀wò àwọn ọ̀ràn tí ó tọ́ ṣòro gan-an.” Nítorí èyí, ní ọdún mẹ́wàá lẹ́yìn náà, nǹkan bíi 3,500,000 dọ́là péré nínú 470,000,000 dọ́là tí a yà sọ́tọ̀ láti ná lórí àwọn tí ìjábá náà kàn, ni a tí ì pín fún àwọn tí ó wà nínú àìní.
Ìsìn ńkọ́? Báwo ni ó ṣe ṣe sí nínú ọ̀ràn ìwà títọ́ yìí? Ó bani nínú jẹ́ pé, àwọn ọ̀pá ìdiwọ̀n rẹ̀ kò yàtọ̀ sí tayé. Fún àpẹẹrẹ, gbé ọ̀ràn bíṣọ́ọ̀bù Roman Kátólíìkì náà, Eamon Casey, yẹ̀ wò, ẹni tí ó jẹ́wọ́ pé òun ni bàbá ọmọ àlè kan, tí ó ti di ọ̀dọ́langba báyìí. Gẹ́gẹ́ bí ìwé agbéròyìnjáde ilẹ̀ Britain náà, Guardian, ti sọ, ọ̀ràn Casey “kì í ṣe ohun àjèjì rárá.” Ní ọ̀nà kan náà, ìwé agbéròyìnjáde náà, The Times, ròyìn pé: “Òtítọ́ nípa ojútì Bíṣọ́ọ̀bù Casey kì í ṣe pé, ìwàkiwà rẹ̀ jẹ́ àrà ọ̀tọ̀, bí kò ṣe pé, àìṣòótọ́ sí ẹ̀jẹ́ ànìkàngbé kì í ṣe ohun tuntun, bẹ́ẹ̀ sì ni kì í ṣe èyí tí kò wọ́pọ̀.” Ní títi ìjiyàn yí lẹ́yìn, ìwé agbéròyìnjáde náà, The Glasgow Herald, tí ilẹ̀ Scotland, sọ pé, ìpín 2 péré nínú ọgọ́rùn-ún àwọn àlùfáà Roman Kátólíìkì, ní United States, ni ó ti yẹra fún bíbá obìnrin ṣe àti bíbá ọkùnrin ẹlẹgbẹ́ wọn ṣe. Yálà iye yìí pé pérépéré tàbí kò pé pérépéré, ó ń fi orúkọ burúkú tí àwọn àlùfáà Kátólíìkì ti ṣe fún ara wọn ní ti ọ̀ràn ìwá híhù hàn.
Ní dídojúkọ irú àwọn àpẹẹrẹ bẹ́ẹ̀, ó ha ṣeé ṣe fún ẹnì kan láti pa ìwà títọ́ ní ti ìwà híhù mọ́ bí? Ó ha jẹ́ ohun yíyẹ bí? Kí ni yóò béèrè fún, kí sì ni àwọn èrè ṣíṣe bẹ́ẹ̀?