“Ìdájọ́ Tí A Gbé Ka Ìwádìí”—Ẹ̀kọ́ Tí A Gbé Ka Bíbélì Ha Ni Bí?
OCTOBER 22, 1844, jẹ́ ọjọ́ ìfojúsọ́nà ńláǹlà fún nǹkan bí 50,000 ènìyàn ní ìhà Ìlà Oòrùn Etíkun United States. Olórí ẹ̀sìn wọn, William Miller, ti wí pé Jésù Kristi yóò pa dà dé ní ọjọ́ yẹn gan-an. Àwọn Ọmọlẹ́yìn Miller, bí a ṣe ń pè wọ́n, dúró ní àwọn ilé ìpàdé wọn títí ilẹ̀ fi ṣú. Bẹ́ẹ̀ ni ilẹ̀ ọjọ́ kejì ṣe mọ́ bá wọn, Olúwa kò mà dé o. Ọkàn wọn pòrúurùu, wọ́n pa dà sílé, lẹ́yìn náà wọ́n rántí ọjọ́ yẹn gẹ́gẹ́ bí “Ọjọ́ Ìjákulẹ̀ Ńláǹlà.”
Síbẹ̀, láìpẹ́ ìjákulẹ̀ ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún ìrètí. Ọ̀ṣọ́ọ́rọ́ obìnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ellen Harmon, mú kí àwùjọ kékeré Àwọn Ọmọlẹ́yìn Miller kan gbà gbọ́ dájú pé Ọlọ́run ti fi han òun nínú ìran pé ìṣirò àkókò tí àwọn ṣe tọ̀nà. Ó gbà gbọ́ pé ìṣẹ̀lẹ̀ mánigbàgbé kan ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ yẹn—Kristi wọnú “ibi mímọ́ jù lọ nínú àwọn ibi mímọ́ tí ń bẹ ní ọ̀run.”
Ní ohun tí ó lé ní ẹ̀wádún kan lẹ́yìn náà, oníwàásù, ẹlẹ́sìn Adventist James White (tí ó ti gbé Ellen Harmon níyàwó) ṣẹ̀dá àpólà ọ̀rọ̀ kan láti ṣàpèjúwe irú iṣẹ́ tí Kristi ń ṣe láti October 1844. Nínú ìwé ìròyìn Review and Herald ti January 29, 1857, White sọ pé Jésù ti bẹ̀rẹ̀ “ìdájọ́ tí a gbé ka ìwádìí.” Èyí sì ti di ìgbàgbọ́ pàtàkì láàárín nǹkan bíi mílíọ̀nù méje àwọn tí wọ́n pe ara wọn ní ẹlẹ́sìn Seventh-Day Adventist.
Ṣùgbọ́n, àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan tí a bọ̀wọ̀ fún nínú Ṣọ́ọ̀ṣì Seventh-Day Adventist (SDA) ti ń ṣe kàyéfì bí “ìdájọ́ tí a gbé ka ìwádìí” bá jẹ́ ẹ̀kọ́ tí a gbé ka Bíbélì. Èé ṣe tí wọ́n fi ń pa dà ronú lórí ọ̀ràn yí? Bí o bá jẹ́ ẹlẹ́sìn Seventh-Day Adventist, ìbéèrè yí yóò kàn ọ́. Ṣùgbọ́n, lákọ̀ọ́kọ́ ná, kí ni “ìdájọ́ tí a gbé ka ìwádìí”?
Kí Ni A Ń Pè Bẹ́ẹ̀?
Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí a so ẹ̀kọ́ yìí mọ́ ni Dáníẹ́lì 8:14. Ó kà pé: “Ó sì wí fún mi pé, títí fi di ọgbọ̀nkànlá lé ọgọ́rùn-ún ti alẹ́ ti òwúrọ̀: nígbà náà ni a óò sì ya ibi mímọ́ sí mímọ́.” (King James Version) Nítorí àpólà ọ̀rọ̀ náà “nígbà náà ni a óò sì ya ibi mímọ́ sí mímọ́,” ọ̀pọ̀ ẹlẹ́sìn Adventist so ẹsẹ yìí pọ̀ mọ́ Léfítíkù orí 16. Ó ṣàpèjúwe bí àlùfáà àgbà àwọn Júù ṣe ń ya ibi mímọ́ sí mímọ́ ní Ọjọ́ Ètùtù. Wọ́n tún so àwọn ọ̀rọ̀ Dáníẹ́lì mọ́ Hébérù orí 9, tí ó ṣàpèjúwe Jésù gẹ́gẹ́ bí Àlùfáà Àgbà Títóbi Jù ní ọ̀run. Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan tí ó jẹ́ ẹlẹ́sìn SDA sọ pé a gbé ìrònú yìí ka ọgbọ́n “fífi ọ̀rọ̀ túmọ̀ ọ̀rọ̀.” Ẹnì kan rí “ọ̀rọ̀ kan bí ibi mímọ́ nínú Dán. 8:14, ó rí ọ̀rọ̀ kan náà nínú Léf. 16, ó tún rí ọ̀rọ̀ kan náà nínú Héb. 7, 8, 9,” ó sì parí èrò sí pé “ohun kan náà ní gbogbo wọn ń sọ.”
Bí àwọn ẹlẹ́sìn Adventist ṣe ronú nìyí: Àwọn àlùfáà Ísírẹ́lì ìgbàanì ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn ojoojúmọ́ ní apá ibi kan nínú tẹ́ńpìlì tí a ń pè ní Ibi Mímọ́, tí ń yọrí sí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀. Ní Ọjọ́ Ètùtù, àlùfáà àgbà yóò ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ ọdọọdún nínú Ibi Mímọ́ Jù Lọ (yàrá inú pátápátá nínú tẹ́ńpìlì) tí ń yọrí sí pípa ẹ̀ṣẹ̀ rẹ́. Wọ́n parí èrò sí pé iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristi gẹ́gẹ́ bí àlùfáà ní ọ̀run pín sí apá méjì. Apá àkọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ nígbà ìgòkè re ọ̀run rẹ̀ ní ọ̀rúndún kìíní, ó sì parí ní 1844, ó sì yọrí sí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀. Apá kejì, tàbí “ipele ìṣèdájọ́,” bẹ̀rẹ̀ ní October 22, 1844, ó ṣì ń bá a lọ, yóò sì yọrí sí pípa ẹ̀sẹ̀ rẹ́. Báwo ni a ṣe ṣàṣeparí èyí?
Láti 1844, wọ́n sọ pé Jésù ti ń ṣèwádìí nípa àkọsílẹ̀ ìgbésí ayé gbogbo àwọn tí wọ́n sọ pé àwọn jẹ́ onígbàgbọ́ (lákọ̀ọ́kọ́ àwọn òkú, lẹ́yìn náà àwọn alààyè) láti pinnu bí wọ́n bá yẹ fún ìyè ayérayé. Àyẹ̀wò yìí ni “ìdájọ́ tí a gbé ka ìwádìí.” Lẹ́yìn tí a bá ti dá àwọn ènìyàn lẹ́jọ́ tán, a óò pa ẹ̀ṣẹ̀ àwọn tí ó bá yege ìdánwò yí rẹ́ kúrò nínú àkọsílẹ̀. Ṣùgbọ́n, Ellen White ṣàlàyé pé, ‘a óò pa orúkọ’ àwọn tí kò yege ‘rẹ́ kúrò nínú ìwé ìyè.’ Nípa báyìí, “a óò ti pinnu kádàrá gbogbo ènìyàn fún ìyè tàbí fún ikú.” Ní àkókò yẹn, a óò ti sọ ibi mímọ́ ti ọ̀run di mímọ́, Dáníẹ́lì 8:14 yóò sì ti ní ìmúṣẹ. Ohun tí àwọn ẹlẹ́sìn Seventh-Day Adventist fi kọ́ni nìyẹn. Ṣùgbọ́n ìtẹ̀jáde SDA kan Adventist Review jẹ́wọ́ pé: “Ọ̀rọ̀ náà ìdájọ́ tí a gbé ka ìwádìí kò sí nínú Bíbélì.”
Kò Sí Ìsopọ̀ Kankan Nínú Èdè Tí A Lò
Ẹ̀kọ́ yìí ti kó ìdààmú ọkàn bá àwọn ẹlẹ́sìn Adventist kan. Olùṣàkíyèsí kan sọ pé: “Ìtàn fi hàn pé ìdààmú ọkàn dé bá àwọn adúróṣinṣin aṣáájú ẹgbẹ́ wa bí wọ́n ṣe ń ronú lórí ẹ̀kọ́ àtọwọ́dọ́wọ́ wa ti ìdájọ́ tí a gbé ka ìwádìí.” Ó fi kún un pé, ní àwọn ọdún àìpẹ́ yìí, ìdààmú náà yí pa dà di iyè méjì bí àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ sí í “gbé ìbéèrè dìde sí ọ̀pọ̀ nínú kókó ẹ̀rí àlàyé wa nípa ibi mímọ́.” Ẹ jẹ́ kí a ṣàyẹ̀wò méjì nínú wọn nísinsìnyí.
Kókó ẹ̀rí kìíní: A so Dáníẹ́lì orí 8 pọ̀ mọ́ Léfítíkù orí 16. Ìṣòro pàtàkì méjì ni ó sọ ẹ̀rí yìí di èyí tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀—èdè àti àyíká ọ̀rọ̀. Lákọ̀ọ́kọ́, gbé èdè tí a lò yẹ̀ wò. Àwọn ẹlẹ́sìn Adventist gbà gbọ́ pé ‘ibi mímọ́ tí a yà sí mímọ́’ nínú Dáníẹ́lì orí 8 jẹ́ ìmúṣẹ alásọtẹ́lẹ̀ ti ‘ibi mímọ́ tí a yà sí mímọ́’ nínú Léfítíkù orí 16. Ó dà bí ẹni pé a tẹ́wọ́ gba ìjọra yìí títí di ìgbà tí àwọn olùtumọ̀ rí i pé “yà sí mímọ́” nínú Bíbélì King James Version jẹ́ àṣìtúmọ̀ ẹ̀yà ọ̀rọ̀ ìṣe èdè Hébérù náà, tsa·dhaqʹ, (tí ó túmọ̀ sí “jíjẹ́ olódodo”) tí a lò nínú Dáníẹ́lì 8:14. Ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ẹ̀kọ́ ìsìn Anthony A. Hoekema sọ pé: “Ó ṣeni láàánú pé a túmọ̀ ọ̀rọ̀ náà sí yà sí mímọ́, níwọ̀n bí a kò ti lo ọ̀rọ̀ ìṣe èdè Hébérù náà [ta·herʹ] tí a sábà máa ń tú sí yà sí mímọ́ níhìn-ín rárá.”a A lò ó nínú Léfítíkù orí 16 níbi tí Bíbélì King James Version ti tú àwọn ẹ̀yà ọ̀rọ̀ náà, ta·herʹ, sí “yà á sí mímọ́” àti ‘wẹ̀ mọ́.’ (Léfítíkù 16:19, 30) Nítorí náà, Ọ̀mọ̀wé Hoekema dé ìparí èrò tí ó tọ́ pé: “Bí ó bá jẹ́ irú ìwẹ̀mọ́ tí a ń ṣe ní Ọjọ́ Ètùtù ni Dáníẹ́lì fẹ́ tọ́ka sí, ì bá ti lo taheer [ta·herʹ] dípò tsadaq [tsa·dhaqʹ].” Síbẹ̀, kò sí tsa·dhaqʹ nínú Léfítíkù, bẹ́ẹ̀ sì ni kò sí ta·herʹ nínú Dáníẹ́lì. Kò sí ìsopọ̀ kankan nínú èdè tí a lò.
Kí Ni Àyíká Ọ̀rọ̀ Náà Fi Hàn?
Nísinsìnyí gbé àyíká ọ̀rọ̀ náà yẹ̀ wò. Àwọn ẹlẹ́sìn Adventist gbà gbọ́ pé Dáníẹ́lì 8:14 jẹ́ “ẹsẹ tí ó dá dúró,” tí kò ní ìsopọ̀ kankan pẹ̀lú àwọn ẹsẹ tí ó ṣáájú rẹ̀. Ṣùgbọ́n èrò yẹn ha wá sí ọ lọ́kàn nígbà tí o ka Dáníẹ́lì 8:9-14 nínú àpótí tí ó bá àpilẹ̀kọ yìí rìn, tí a pè ní “Dáníẹ́lì 8:14 Nínú Àyíká Ọ̀rọ̀ Rẹ̀” bí? Ẹsẹ 9 fi ẹni tí oníjàgídíjàgan, ìwo kékeré náà, jẹ́ hàn. Ẹsẹ 10 sí 12 fi hàn pé oníjàgídíjàgan yìí yóò kọ lu ibi mímọ́ náà. Ẹsẹ 13 béèrè pé, ‘Báwo ni jàgídíjàgan yìí yóò ti pẹ́ tó?’ Ẹsẹ 14 sì fèsì pé: “Títí di ẹ̀ẹ́dégbèjìlá alẹ́ àti òwúrọ̀; dájúdájú, a óò mú ibi mímọ́ náà wá sí ipò rẹ̀ tí ó tọ́.” Ó ṣe kedere pé, ẹsẹ 13 gbé ìbéèrè kan dìde tí a dáhùn ní ẹsẹ 14. Ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn náà, Desmond Ford, sọ pé: “Láti yọ Dán. 8:14 sọ́tọ̀ kúrò lára ìbéèrè yí [“Yóò ti pẹ́ tó?” tí ó wà ní ẹsẹ 13] dà bí títukọ̀ yàà lórí òkun láìsí ìdákọ̀ró.”b
Èé ṣe tí àwọn ẹlẹ́sìn Adventist fi yọ ẹsẹ 14 sọ́tọ̀ kúrò lára àyíká ọ̀rọ̀ náà? Láti yẹra fún ìparí èrò tí ó lè kó ìtìjú báni ni. Àyíká ọ̀rọ̀ náà so ìsọdẹ̀gbin ibi mímọ́ náà, tí a mẹ́nu kàn ní ẹsẹ 14, mọ́ àwọn ìgbòkègbodò ìwo kékeré náà. Ṣùgbọ́n, ẹ̀kọ́ “ìdájọ́ tí a gbé ka ìwádìí” so ìsọdẹ̀gbin ibi mímọ́ náà mọ́ àwọn ìgbòkègbodò Kristi. Wọ́n sọ pé ó tàtaré ẹ̀ṣẹ̀ àwọn onígbàgbọ́ sí ibi mímọ́ ní ọ̀run. Nítorí náà, kí ni yóò ṣẹlẹ̀ bí àwọn ẹlẹ́sìn Adventist bá tẹ́wọ́ gba ẹ̀kọ́ náà àti àwọn àyíká ọ̀rọ̀ náà? Ọ̀mọ̀wé Raymond F. Cottrell, ẹlẹ́sìn Seventh-Day Adventist, tí ó sì jẹ́ amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ olóòtú ìwé ìròyìn SDA Bible Commentary tẹ́lẹ̀ rí, kọ̀wé pé: “Láti tan ara wa jẹ pé ìtumọ̀ tí àwọn ẹlẹ́sìn SDA fún Dáníẹ́lì 8:14 bá àyíká ọ̀rọ̀ rẹ̀ mu yóò wulẹ̀ jẹ́ sísọ pé Kristi ni ìwo kékeré náà.” Ọ̀mọ̀wé Cottrell jẹ́wọ́ láìṣàbòsí pé: “A kò lè mú àyíká ọ̀rọ̀ náà bá ìtumọ̀ àwọn ẹlẹ́sìn Adventist mu.” Ní ti ẹ̀kọ́ “ìdájọ́ tí a gbé ka ìwádìí,” Ìjọ Adventist ní láti ṣe yíyàn kan—kí wọ́n fara mọ́ ẹ̀kọ́ náà tàbí kí wọ́n fara mọ́ àyíká ọ̀rọ̀ Dáníẹ́lì 8:14. Ó ṣeni láàánú pé, èyí àkọ́kọ́ ni wọ́n fara mọ́, wọ́n sì yan èyí èkejì ní ìpọ̀sì. Ọ̀mọ̀wé Cottrell sọ pé, abájọ tí àwọn ọ̀jáfáfá akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fi sọ pé àwọn ẹlẹ́sìn Adventist jẹ̀bi “fífún Ìwé Mímọ́ ní ìtumọ̀” tí a kò lè “rí fà yọ nínú Ìwé Mímọ́”!
Ní ọdún 1967, Ọ̀mọ̀wé Cottrell múra ẹ̀kọ́ tí a gbé ka ìwé Dáníẹ́lì sílẹ̀ fún ilé ẹ̀kọ́ sábáàtì, a sì fi ẹ̀kọ́ náà ránṣẹ́ sí àwọn ìjọ SDA jákèjádò ayé. Ó fi kọ́ni pé Dáníẹ́lì 8:14 ní í ṣe pẹ̀lú àyíká ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti pé kì í ṣe àwọn onígbàgbọ́ ni ‘yíyà sí mímọ́’ náà ń tọ́ka sí. Ó jọni lójú gidigidi pé, ẹ̀kọ́ náà kò mẹ́nu kan “ìdájọ́ tí a gbé ka ìwádìí” rárá.
Àwọn Èsì Tí Ó Pẹtẹrí
Báwo ni òye àwọn ẹlẹ́sìn Adventist ti pọ̀ tó láti mọ̀ pé kókó ẹ̀rí yìí kò lágbára tó láti gbe ẹ̀kọ́ “ìdájọ́ tí a gbé ka ìwádìí” lẹ́yìn? Ọ̀mọ̀wé Cottrell béèrè lọ́wọ́ àwọn òléwájú ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀sìn Adventist 27 pé, ‘Àwọn ìdí wo tí ó jẹ mọ́ ti èdè tàbí ti àyíká ọ̀rọ̀ ni ẹ lè fúnni fún ìsopọ̀ tí ó wà láàárín Dáníẹ́lì orí 8 àti Léfítíkù orí 16?’ Kí ni èsì wọn?
“Gbogbo àwọn mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n náà pátá fi ìdálójú sọ pé kò sí ẹ̀rí kankan tí ó jẹ mọ́ ti èdè tàbí ti àyíká ọ̀rọ̀ fún sísọ pé Dán. 8:14 jẹ́ ìmúṣẹ alásọtẹ́lẹ̀ fún ọjọ́ ètùtù àti ìdájọ́ tí a gbé ka ìwádìí.” Ó bi wọ́n pé, ‘Ẹ ha ní ìdí mìíràn fún gbígbé ìsopọ̀ yí kalẹ̀ bí?’ Ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ ẹlẹ́sìn Adventist náà sọ pé àwọn kò ní ìdí mìíràn, àwọn márùn-ún fèsì pé àwọn gbé ìsopọ̀ yí kalẹ̀ nítorí Ellen White ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn méjì sì sọ pé àwọn gbé ẹ̀kọ́ náà ka “èèṣì tí ó mú ire wá” nínú ìtumọ̀. Ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn náà, Ford, sọ pé: “Irú ìparí èrò tí àwọn ọ̀jáfáfá jù lọ nínú àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ wa dé fi hàn ní ti gidi pé ẹ̀kọ́ àtọwọ́dọ́wọ́ wa lórí Dán. 8:14 kò ṣeé tì lẹ́yìn rárá.”
Ìrànlọ́wọ́ Èyíkéyìí Ha Ti Inú Ìwé Hébérù Wá Bí?
Kókó ẹ̀rí kejì: A so Dáníẹ́lì 8:14 pọ̀ mọ́ Hébérù orí 9. Ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn náà, Ford, sọ pé: “Gbogbo iṣẹ́ wa ìjímìjí dá lórí Héb. 9 nígbà tí a bá ń ṣàlàyé Dán. 8:14.” Ìsopọ̀ yí wáyé lẹ́yìn “Ìjákulẹ̀ Ńláǹlà” ní 1844. Ní wíwá ìtọ́sọ́nà, Millerite Hiram Edson ju Bíbélì rẹ̀ sórí tábìlì kí ó baà lè ṣí sílẹ̀. Kí ni àbájáde rẹ̀? Hébérù orí 8 àti 9 ṣí sílẹ̀ níwájú rẹ̀. Ford sọ pé: “Kí ni ì bá tún jẹ́ ohun yíyẹ jù lọ àti àmì fún ìjẹ́wọ́ àwọn ẹlẹ́sìn Adventist pé inú àwọn orí wọ̀nyí ni ìtumọ̀ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ní ọdún 1844 àti Dán. 8:14 wà!”
Ọ̀mọ̀wé Ford fi kún un nínú ìwé rẹ̀, Daniel 8:14, the Day of Atonement, and the Investigative Judgment, pé: “Ìjẹ́wọ́ yẹn ṣe pàtàkì fún àwọn ẹlẹ́sìn Seventh-day Adventist. Inú Héb. 9 nìkan . . . ni a ti lè rí ẹ̀kún rẹ́rẹ́ àlàyé nípa ìjẹ́pàtàkì . . . ẹ̀kọ́ ibi mímọ́ tí kò ṣeé fi ṣeré fún wa.” Bẹ́ẹ̀ ni, Hébérù orí 9 ni orí náà nínú “Májẹ̀mú Tuntun” tí yóò ṣàlàyé ìtumọ̀ alásọtẹ́lẹ̀ Léfítíkù orí 16. Ṣùgbọ́n àwọn ẹlẹ́sìn Adventist tún sọ pé Dáníẹ́lì 8:14 ni ẹsẹ náà nínú “Májẹ̀mú Láéláé” tí ó ṣe bẹ́ẹ̀. Bí gbólóhùn méjèèjì bá jẹ́ òtítọ́, ìsopọ̀ kan gbọ́dọ̀ wà láàárín Hébérù orí 9 àti Dáníẹ́lì orí 8 pẹ̀lú.
Desmond Ford ṣàlàyé pé: “Àwọn ohun kan ṣe kedere gbàrà tí ẹnì kan bá ka Héb. 9. Kò sí ọ̀rọ̀ tí ó hàn gbangba pé ó ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ìwé Dáníẹ́lì, ó sì dájú pé kò sí èyíkéyìí tí ó ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Dán. 8:14. . . . Orí náà lódindi ní í ṣe pẹ̀lú Léf. 16.” Ó sọ pé: “A kò lè rí ẹ̀kọ́ wa nípa ibi mímọ́ nínú ìwé kan ṣoṣo náà, nínú Májẹ̀mú Tuntun, tí ó jíròrò ìjẹ́pàtàkì iṣẹ́ ìsìn ibi mímọ́. Àwọn ìlú-mọ̀ọ́ká òǹkọ̀wé ẹlẹ́sìn Adventist káàkiri àgbáyé ti jẹ́rìí sí èyí.” Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, nígbà náà, kókó ẹ̀rí kejì pẹ̀lú kò lágbára tó láti ti ẹ̀kọ́ dídíjú náà lẹ́yìn.
Bí ó ti wù kí ó rí, ìparí èrò yí kì í ṣe tuntun. Ọ̀mọ̀wé Cottrell sọ pé, fún ọ̀pọ̀ ọdún “àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ nínú Bíbélì tí wọ́n jẹ́ mẹ́ńbà ṣọ́ọ̀ṣì náà mọ̀ dájú nípa àwọn ìṣòro tí ìtumọ̀ àtọwọ́dọ́wọ́ tí a fún Dáníẹ́lì 8:14 àti Hébérù orí 9 bá pà dé.” Ní nǹkan bí 80 ọdún sẹ́yìn, E. J. Waggoner, ògúnná gbòǹgbò ẹlẹ́sìn Seventh-Day Adventist, kọ̀wé pé: “Ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn Adventist nípa ibi mímọ́, pẹ̀lú ẹ̀kọ́ rẹ̀ nípa ‘Ìdájọ́ Tí A Gbé Ka Ìwádìí’ . . . , jẹ́ sísẹ́ ètùtù pátápátá.” (Confession of Faith) Ní èyí tí ó lé ní 30 ọdún sẹ́yìn, a gbé irú àwọn ìṣòro bẹ́ẹ̀ kalẹ̀ níwájú Àpérò Gbogbogbòò, àwọn aṣáájú Ìjọ SDA.
Àwọn Ìṣòro àti Ìsúnkàngiri
Àpérò Gbogbogbòò yan “Ìgbìmọ̀ Tí Ń Rí Sí Ìṣòro Lórí Ìwé Dáníẹ́lì.” Iṣẹ́ rẹ̀ jẹ́ láti pèsè ìròyìn lórí bi a óò ṣe yanjú àwọn ìṣòro tí ó dá lórí Dáníẹ́lì 8:14. Ìgbìmọ̀ ẹlẹ́ni 14 náà yiiri ìbéèrè náà wò fún ọdún márùn-ún, ṣùgbọ́n, wọ́n kùnà láti fohùn ṣọ̀kan lórí ojútùú kan ṣoṣo. Ní ọdún 1980, Cottrell, tí ó jẹ́ ọmọ ìgbìmọ̀ náà, sọ pé ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ ìgbìmọ̀ náà ronú pé ìtumọ̀ tí ẹ̀sìn Adventist fún Dáníẹ́lì 8:14 ṣeé “fìdí rẹ̀ múlẹ̀ lọ́nà tí ó tẹ́ni lọ́rùn” nípa ọ̀wọ́ “àwọn ìméfò” àti pé “kí a gbàgbé” nípa àwọn ìṣòro náà. Ó fi kún un pé: “Ẹ rántí pé, orúkọ ìgbìmọ̀ náà ni Ìgbìmọ̀ Tí Ń Rí Sí Ìṣòrò Lórí Ìwé Dáníẹ́lì, ọ̀pọ̀ jù lọ nínú wọn sì ń dámọ̀ràn pé kí a gbàgbé àwọn ìṣòro náà, kí a má sì sọ ohunkóhun nípa wọn.” Ìyẹn ì bá ti yọrí sí “gbígbà pé a kò mọ ìdáhùn tí a lè pèsè.” Nítorí náà àwọn kéréje kọ̀ láti fara mọ́ ojú ìwòye ọ̀pọ̀ jù lọ, kò sì sí ìròyìn kan tí a pilẹ̀ kọ. Àwọn ìṣòro ẹ̀kọ́ náà ṣì wà láìní ojútùú.
Ní sísọ̀rọ̀ lórí ìsúnkàngiri yìí, Ọ̀mọ̀wé Cottrell sọ pé: “A kò tí ì yanjú ọ̀ràn Dáníẹ́lì 8:14 síbẹ̀ nítorí pé títí di ìsinsìnyí, a kò tí ì múra tán síbẹ̀ láti dojú kọ òtítọ́ náà pé ìṣòro ńlá kan tí ó ní í ṣe pẹ̀lú àlàyé ń bẹ. Bí a bá ṣì ń bá a nìṣó ní dídíbọ́n pé kò sí ìṣòro kankan, ọ̀ràn yẹn kò ní yanjú, níwọ̀n bí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa tàbí gbogbo wa lápapọ̀, bá ṣì ń dìrọ̀ pinpin mọ́ ojú ìwòye wa lórí èrò tí a ti gbìn sọ́kàn tẹ́lẹ̀.”—Spectrum, ìwé agbéròyìnjáde kan tí Ìgbìmọ̀ Ajíròrò Ti Adventist tẹ̀ jáde.
Ọ̀mọ̀wé Cottrell rọ àwọn ẹlẹ́sìn Adventist láti ṣe “àyẹ̀wò fínnífínní nípa àwọn ìméfò pàtàkì àti ìlànà àlàyé tí a gbé ìtumọ̀ àyọkà inú Ìwé Mímọ́ tí ó ṣe kókó—fún ìgbàgbọ́ ẹ̀sìn Adventist—yìí kà.” A óò rọ àwọn ẹlẹ́sìn Adventist láti ṣàyẹ̀wò ẹ̀kọ́ “ìdájọ́ tí a gbé ka ìwádìí” láti rí i bóyá àwọn kókó ẹ̀rí rẹ̀ fẹsẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in lórí Bíbélì tàbí bóyá a gbé ìpìlẹ̀ wọn karí iyanrìn lẹ́búlẹ́bú ti ẹ̀kọ́ àtọwọ́dọ́wọ́.c Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi ọgbọ́n rọni pé: “Ẹ máa wádìí ohun gbogbo dájú; ẹ di ohun tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ mú ṣinṣin.”—Tẹsalóníkà Kíní 5:21.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ìwé Wilson’s Old Testament Word Studies tú tsadaq (tàbí, tsa·dhaqʹ) sí “láti jẹ́ olódodo, láti dáni láre,” ó sì tú taheer (tàbí, ta·herʹ) sí “láti ṣe kedere, láti mọ́lẹ̀ yòò, àti láti tàn yinrinyinrin; láti mọ́ gaara, láti mọ́ tónítóní, láti fọ̀ mọ́; láti wẹ gbogbo ẹ̀gbin àti èérí kúrò lára rẹ̀.”
b Ọ̀mọ̀wé Ford jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìsìn ní Kọ́lẹ́ẹ̀jì Àjùmọ̀ṣe Pacific tí ṣọ́ọ̀ṣì ń ṣonígbọ̀wọ́ rẹ̀ ní U.S.A. Ní 1980, àwọn aṣáájú ìjọ SDA fún un ní ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́ fún oṣù mẹ́fà láti lọ ṣèwádìí lórí ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ náà, ṣùgbọ́n wọn kò tẹ́wọ́ gba ìwádìí rẹ̀. Ó tẹ ìwọ̀nyí jáde nínú ìwé náà, Daniel 8:14, the Day of Atonement, and the Investigative Judgment.
c Fún àlàyé tí ó bọ́gbọ́n mu lórí Dáníẹ́lì orí 8, wo ojú ìwé 175 sí 203 nínú ìwé “Ifẹ Tirẹ ni Ki A Ṣe Li Aiye,” tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 27]
Dáníẹ́lì 8:14 Nínú Àyíká Ọ̀rọ̀ Rẹ̀
DÁNÍẸ́LÌ 8:9 “Láti inú ọ̀kan lára wọn sì ni ìwo mìíràn ti jáde wá, ọ̀kan tí ó kéré, ó sì ń tóbi sí i gidigidi síhà gúúsù àti síhà yíyọ oòrùn àti síhà Ìṣelóge. 10 Ó sì tóbi sí i dé iyàn-níyàn ọ̀dọ̀ ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọ̀run, tí ó fi mú àwọn kan lára ẹgbẹ́ ọmọ ogun àti àwọn kan lára ìràwọ̀ já bọ́ sí ilẹ̀, ó sì ń tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀. 11 Àti dé iyàn-níyàn ọ̀dọ̀ Olórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun ni ó gbé àgbéré ńláǹlà, a sì mú apá pàtàkì ìgbà gbogbo kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, a sì wó ibi àfìdímúlẹ̀ ibùjọsìn rẹ̀ lulẹ̀. 12 Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ẹgbẹ́ ọmọ ogun kan ni a fi léni lọ́wọ́, pa pọ̀ pẹ̀lú apá pàtàkì ìgbà gbogbo, nítorí ìrélànàkọjá; ó sì ń bá a lọ láti wó òtítọ́ mọ́lẹ̀, ó gbé ìgbésẹ̀, ó sì kẹ́sẹ járí.
“13 Mo sì wá gbọ́ ẹni mímọ́ kan tí ó sọ̀rọ̀, ẹni mímọ́ mìíràn sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún ẹni náà gan-an tí ó ń sọ̀rọ̀ pé: ‘Ìran apá pàtàkì ìgbà gbogbo àti ti ìrélànàkọjá tí ń ṣokùnfà ìsọdahoro náà yóò ti pẹ́ tó, láti sọ ibi mímọ́ náà àti ẹgbẹ́ ọmọ ogun náà di ohun ìtẹ̀mọ́lẹ̀?’ 14 Nítorí náà, ó wí fún mi pé: ‘Títí di ẹ̀ẹ́dégbèjìlá alẹ́ àti òwúrọ̀; dájúdájú, a óò mú ibi mímọ́ náà wá sí ipò rẹ̀ tí ó tọ́.’”—New World Translation of the Holy Scriptures.