Pápá Oko fún Àwọn Ẹni Bí Àgùntàn ní Ilẹ̀ Navajo
HÓZHÓNÍ, túmọ̀ sí “ẹlẹ́wà” lédè àwọn Àmẹ́ríńdíà ti ilẹ̀ Navajo, bí àwọn ará Navajo sì ṣe ṣàpèjúwe ilẹ̀ wọn nìyẹn. Láti ọdún 1868 ni ìjọba United States ti pín ilẹ̀ tí a yà sọ́tọ̀ tí ó tó 62,000 kìlómítà níbùú lóròó fún àwọn ará Navajo ní àríwá ìlà oòrùn Arizona, nítòsí ibi tí a pè ní igun mẹ́rin, níbi tí àwọn ìpínlẹ̀ mẹ́rin náà, Arizona, Colorado, New Mexico, àti Utah ti pàdé. Àfonífojì Ìrántí, tí àwọn sinimá Ìwọ̀ Oòrùn ayé mú kí ó di olókìkí, ni a ti pa mọ́ báyìí gẹ́gẹ́ bí Ọgbà Ìtura Ẹ̀yà Navajo, ó sì ń fa àwọn arìnrìn-àjò afẹ́ wá jákèjádò ayé. Àfonífojì náà ní àwọn òkìtì yangí pupa àrímálèlọ ràgàjìràgàjì, tí ó ga ní 300 mítà, tí ó dá yọ sókè lọ́nà fífani mọ́ra láàárín aṣálẹ̀ títẹ́jú tí ó wà lórí òkè. Lọ́nà yíyẹ, ohun tí àwọn ará Navajo ń pe àfonífojì náà túmọ̀ sí “àlàfo àárín àwọn àpáta.”
A mọ àwọn ará Navajo lápapọ̀ fún ìwà ìrẹ̀lẹ̀, ìṣaájò àlejò tọ̀yàyàtọ̀yàyà, àti ìdè ìdílé amẹ́bí-múbàátan tímọ́tímọ́. Àwọn 170,000 tí ń gbé ilẹ̀ tí a yà sọ́tọ̀ náà wà ní àdádó gátagàta, ní títẹ̀lé àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ wọn. Àwọn kan ṣì ń sin àgùntàn, wọ́n sì ń gbé inú àwọn ahéré tí a fi igi kọ́ tí a sì fi amọ̀ mọ, tí a ń pè ní hogan. Àwọn iṣẹ́ ọnà láti Navajo ti gbajúmọ̀ jìnnà. Àwọn èyí tí ó níye lórí gan-an ni àwọn rọ́ọ̀gì àti àwọn kúbùsù wọn aláwọ̀ mèremère tí a ṣe ọnà aláràbarà tàbí ti ìbílẹ̀ sí, tí a fi òwú àgùntàn hun. Ohun ọ̀ṣọ́ onífàdákà tí a fi bàbà àti àwọn èròjà míràn tí a hú nílẹ̀ ṣe láti Navajo pẹ̀lú gbajúmọ̀ dáradára.
Mímú Ìhìn Rere Wá sí Ilẹ̀ Navajo
Ó ti lé ní 30 ọdún tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti wá sí ilẹ̀ Navajo, kì í ṣe láti wá wòran gbígbádùnmọ́ni nìkan ni ṣùgbọ́n láti mú ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run wá sọ́dọ̀ àwọn ènìyàn tí wọ́n wà ní àgbègbè àdádó yìí pẹ̀lú. (Mátíù 24:14) Àwọn aṣáájú ọ̀nà déédéé àti àkànṣe tí wọ́n jẹ́ òjíṣẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti mú ipò iwájú nínú iṣẹ́ ìwàásù. Púpọ̀ lára wọn wá ní ìdáhùn sí ìpè àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò àti Àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n wà ládùúgbò pé kí wọ́n wá ṣèrànwọ́ níbi tí àìní gbé pọ̀. Àwọn kan wá láti àwọn ìjọ ìtòsí, nígbà tí àwọn mìíràn, títí kan àwọn kan lára àwọn ẹ̀yà Àmẹ́ríńdíà, wá láti onírúurú ibòmíràn ní United States.
Àwọn ọkùnrin àti obìnrin ẹlẹ́mìí ìfara-ẹni-rúbọ wọ̀nyí ti fi iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn níhìn-ín wé iṣẹ́ àyànfúnni míṣọ́nnárì. Èé ṣe? Lákọ̀ọ́kọ́ ná, àwọn èdè ìbílẹ̀ ibẹ̀ ṣòro gan-an láti kọ́ nítorí àwọn ìró, ìgbékalẹ̀, àti gbólóhùn ọ̀rọ̀ wọn dídíjú. Lẹ́yìn náà, èyí tí ó pọ̀ jù lọ lára àwọn ènìyàn ìbílẹ̀ náà rọ̀ pinpin mọ́ àwọn àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ wọn ní ti ọ̀nà ìjọsìn, ìgbékalẹ̀ ìdílé, àti fífi iṣẹ́ àgbẹ̀ ṣe iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ wọn. Ní àfikún, ilé gbígbé àti iṣẹ́ ṣọ̀wọ́n fún àwọn tí kì í ṣe Àmẹ́ríńdíà, tí ń mú kí ó ṣòro fún àwọn tí wọ́n kó wá síbẹ̀ láti wà níbẹ̀ fún ìgbà pípẹ́. Ní paríparí rẹ̀, ìtàn àtayébáyé nípa ìyà tí àwọn aláwọ̀ funfun fi jẹ àwọn ènìyàn wọ̀nyí ti gbin ìwọ̀n àìnígbẹkẹ̀lé nínú àwọn àjèjì sí wọn lọ́kan lọ́nà tí ó ṣeé lóye.a
Lákọ̀ọ́kọ́, nígbà tí Àwọn Ẹlẹ́rìí ń kàn sí àwọn ènìyàn láti ilé dé ilé pẹ̀lú aṣọ àti táì lọ́rùn gbágbáágbá, a fi wọ́n pe àwọn onísìn Mormon, ọ̀pọ̀ ènìyàn ni kò ṣílẹ̀kùn fún wọn. Nígbà tí wọ́n yí pa dà sí wíwọ aṣọ tí kò fi bẹ́ẹ̀ jọjú, a ké sí wọn wọlé, lọ́pọ̀ ìgbà, fún wákàtí kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ. Wàyí o, àwọn ènìyàn náà ti wá mọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn tún ti pa dà sí wíwọ aṣọ gidi nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn.
Láti dé ọ̀dọ̀ àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ Navajo tí a yà sọ́tọ̀ náà jẹ́ ìṣòro gidi kan. Ó wọ́pọ̀ kí a wakọ̀ gba àwọn ọ̀nà ojúgbó tí ó lè jẹ́ olókùúta, oníyanrìn, àti ẹlẹ́rẹ̀ fún ọ̀pọ̀ kìlómítà. Bí ó ti sábà máa ń rí, èyí ń jẹ́ kí ọkọ̀ tètè bà jẹ́, ó sì ń kó àárẹ̀ bá àwọn èrò ọkọ̀. Ọkọ̀ tún lè rì, àmọ́ àwọn tí ń kọjá sábà máa ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti bá wọn yọ ọ́. Kíkàn sí àwọn olùfìfẹ́hàn, lílọ ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé, tàbí mímú ẹnì kan lọ sí ìpàdé Kristẹni sábà máa ń gba pípààrà ọ̀nà kan náà fún wákàtí mélòó kan. Ṣùgbọ́n Àwọn Ẹlẹ́rìí máa ń ṣe é tinútinú, wọ́n sì ń tipa bẹ́ẹ̀ fi ìfẹ́ wọn fún àwọn ènìyàn ìbílẹ̀ náà hàn kedere.—Fi wé Tẹsalóníkà Kíní 2:8.
Àwọn ará Navajo ń gbádùn ìjíròrò Bíbélì. Wọ́n sábà máa ń kó gbogbo ìdílé jọ—àwọn ọmọ, àwọn òbí, àti àwọn òbí àgbà—láti gbọ́ nípa ìrètí Párádísè ọjọ́ ọ̀la kan tí ó jẹ́ ilé ìran ènìyàn. Nígbà tí a bi ọkùnrin ọmọ Navajo kan nípa èrò rẹ̀ lórí bí Párádísè yóò ṣe rí, ó dáhùn pé, “Yóò jẹ́ pápá oko tútù, tí ó kún fún àgùntàn rẹpẹtẹ,” èyí ń gbé ìfẹ́ tí wọ́n ní fún ilẹ̀ àti àwọn agbo ẹran wọn yọ. Wọ́n tún mọrírì àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wọ́n máa ń fi èyí hàn nígbà míràn nípa fífi iyùn, ọ̀pá ọṣẹ, wàrà alágolo àti irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ Ìjọba náà. Aṣáájú ọ̀nà àkànṣe kan gba àsansílẹ̀-owó 200 fún ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! lọ́dún kan, tí méjì nínú wọ́n jẹ́ èyí tí ó gbà lọ́wọ́ ọkùnrin kan tí ó wà lórí ẹṣin.
Kíkọ́ “Àgọ́ Àgùntàn” Kan
Bí ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn ti ń dé, ó tó àkókò fun olùṣọ́ àgùntàn kan tí ó jẹ́ ará Navajo láti kó agbo ẹran rẹ̀ lọ sí àgọ́ àgùntàn kan. Ilé tí a ń kó àwọn àgùntàn sí ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn yí, tí a yàn nítorí pé ó sún mọ́ pápá oko tútù àti orísun omi tí ó dára, ń ṣàǹfààní fún agbo ẹran láti gbèrú. Lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, a lè fi Gbọ̀ngàn Ìjọba kan wé irú àgọ́ bẹ́ẹ̀—pápá oko tẹ̀mí àti orísun omi òtítọ́. Àwọn tí wọ́n bá wá lè rí oúnjẹ tẹ̀mí tí yóò jẹ́ kí wọ́n ní okun àti agbára nípa tẹ̀mí.
Fún àwọn àkókò kan, a ń ṣe àwọn ìpàdé ní yàrá ìkẹ́kọ̀ọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ kan ní Kayenta, Arizona. Lẹ́yìn náà ní August 1992, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ ọgọ́rọ̀ọ̀rún Àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n yọ̀ǹda ara wọn láti àwọn ìpínlẹ̀ bíi mélòó kan, a kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba kan sí Kayenta. Gbọ̀ngàn Ìjọba yìí àti àwọn bíi mélòó kan mìíràn ní ẹkùn náà gbin èrò wíwà pẹ́ títí iṣẹ́ ìwàásù náà sọ́kàn àwọn ènìyàn ibẹ̀. Àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba mìíràn tí a ń lò ní àgbègbè ìṣiṣẹ́ títóbi yìí ní àwọn tí wọ́n wà ní Ìlú Ńlá Tuba àti Chinle nínú, àwọn méjèèjì wà lórí ilẹ̀ tí a yà sọ́tọ̀ náà, ọ̀kan ní Keams Canyon lórí ilẹ̀ ẹ̀yà Hopi láàárín ilẹ̀ Navajo tí a yà sọ́tọ̀ náà, àti àwọn bíi mélòó kan ní àwọn ìlú tí ó wà ní ààlà ilẹ̀ tí a yà sọ́tọ̀ náà. Kí ní ti jẹ́ àbájáde rẹ̀?
Ìdáhùnpadà Kíkọyọyọ sí Ìhìn Iṣẹ́ Ìjọba Náà
Ní Kayenta, àwọn ènìyàn ìbílẹ̀ náà tí wọ́n ti ṣèrìbọmi láti ìgbà tí a ti kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba náà lé ní 12, èyí sì ń fi ìbùkún Jèhófà lórí ibi ìjọsìn tòótọ́ yìí hàn. Gbọ̀ngàn náà ń fi ẹ̀rí hàn pé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti wá fìdí kalẹ̀ síhìn-ín, ó sì gbé ìgbẹ́kẹ̀lé ró nínú ìhìn rere Ìjọba tí wọ́n ń wàásù rẹ̀. Láìpẹ́ yìí, a sọ àwíyé Bíbélì lédè Navajo fún ìgbà àkọ́kọ́ níbẹ̀. Ó jẹ́ ìdùnnú àwọn 40 tí wọ́n jẹ́ mẹ́ńbà ìjọ náà láti kí 245 ènìyàn káàbọ̀ síbi àwíyé náà tí ó dá lórí ẹrù iṣẹ́ àwọn òbí. Pẹ̀lú ẹ̀mí ìmoore, ìdílé ẹlẹ́nimẹ́jọ kan rin ìrìn wákàtí mẹ́ta ní àlọ, àti iye kan náà ní àbọ̀ láti wá gbọ́ ọ̀rọ̀ yí—ìgbà àkọ́kọ́ tí wọ́n bẹ Gbọ̀ngàn Ìjọba kan wò.
Irin iṣẹ́ wíwúlò míràn tí Jèhófà ti pèsè ni ìwé pẹlẹbẹ náà, Gbádùn Iwalaaye lori Ilẹ Ayé Titilae! ní èdè Navajo. Títúmọ̀ ìwé pẹlẹbẹ náà sí èdè Navajo, èdè kan tí ó díjú gan-an, gbé ìpèníjà apániláyà dìde. Lápapọ̀, àwọn olùtúmọ̀ lo ohun tí ó lé ní 1,000 wákàtí láti rí i dájú pé ìwé pẹlẹbẹ náà gbé ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà kalẹ̀ lọ́nà yíyẹ. Láti ìgbà tí a ti mú un jáde ní apá ìparí ọdún 1995, Àwọn Ẹlẹ́rìí ní àdúgbò ti fi ẹgbẹ̀rún mélòó kan síta, tí èyí sì yọrí sí bíbá ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn tí wọ́n ń wá òtítọ́ kiri ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
A túbọ̀ ń lo èdè Navajo lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ bí àwọn akéde Ìjọba ti ń kọ́ ọ. Àwọn ìjọ tí ó wà ní àgbègbè náà ti bẹ̀rẹ̀ sí í lo èdè Navajo ní Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run, a sì dá kíláàsì tí a ti ń kọ́ èdè Navajo sílẹ̀ láti dá àwọn akéde lẹ́kọ̀ọ́. Ní àfikún sí i, a máa ń tú àwọn àpéjọ àdúgbò pẹ̀lú sí èdè Navajo. Dájúdájú, gbogbo ìsapá wọ̀nyí yóò ṣamọ̀nà sí ìdáhùnpadà tí ó túbọ̀ pọ̀ sí i ní ilẹ̀ tí a yà sọ́tọ̀ náà.
Ohun tí a kò ní gbójú fò dá láàárín àwọn èso Ìjọba tí ó so lórí ilẹ̀ àwọn Àmẹ́ríńdíà tí a ti yà sọ́tọ̀ yí ni àwọn ànímọ́ tẹ̀mí gíga lọ́lá tí àwọn arákùnrin wa tí wọ́n jẹ́ ọmọ Navajo fi hàn. Fún ọdún méje, Jimmy àti Sandra ń kó àwọn ọmọ wọn márààrún wá sí àwọn ìpàdé ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ láti ibi tí ó jìnnà tó 120 kìlómítà ní àlọ, àti iye kan náà ní àbọ̀. Inú ìdílé náà máa ń dùn tí wọ́n bá rántí kíkọ orin Ìjọba àti kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pọ̀ nígbà àwọn ìrìn àjò gígùn wọn. Ìfẹ́ àti ìtara tí àwọn òbí náà ní fún òtítọ́ sún àwọn ọmọ wọn láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn ní dídi olùṣe ìyàsímímọ́ olùyin Jèhófà. Mẹ́rin lára wọn ń sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà déédéé nísinsìnyí, alàgbà sì ni Jimmy. Láti fi kún ayọ̀ ìdílé yìí, Elsie, ẹ̀gbọ́n Jimmy obìnrin, láìpẹ́ yìí di ẹni àkọ́kọ́ tí ó ṣèrìbọmi lára àwọn tí ń sọ èdè Navajo nìkan.
Àwọn olùṣọ́ àgùntàn ládùúgbò àti àwọn agbo ẹran wọn fi ipò ìparọ́rọ́ agbo àgùntàn kún àwọn òkúta ìrántí tó ṣe ilẹ̀ Navajo tí a yà sọ́tọ̀ náà lọ́ṣọ̀ọ́. Tipẹ́tipẹ́ ni wòlíì Aísáyà ti sọ tẹ́lẹ̀ nípa Jèhófà pé: “Òun óò bọ́ ọ̀wọ́ ẹran rẹ̀ bí olùṣọ́ àgùntàn: yóò sì fi apá rẹ̀ kó àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn, yóò sì kó wọn sí àyà rẹ̀, yóò sì rọra da àwọn tí ó lóyún.” (Aísáyà 40:11) Nípasẹ̀ Olùṣọ́ Àgùntàn Rere rẹ̀, Jésù Kristi, Jèhófà ń kó gbogbo àwọn tí wọ́n wà lórí ilẹ̀ Navajo tí a yà sọ́tọ̀ náà, tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ àtigbọ́ ìhìn rere Ìjọba, kí wọ́n sì wà ní ojú ọ̀nà fún ìbùkún ayérayé rẹ̀ wọnú pápá oko rẹ̀ tẹ̀mí.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo ìtẹ̀jáde Jí!, May 8, 1948 (Gẹ̀ẹ́sì); February 22, 1952 (Gẹ̀ẹ́sì); June 22, 1954 (Gẹ̀ẹ́sì); àti September 8, 1996.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Obìnrin tí ó jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn ní Navajo ń gbọ́ ìhìn rere