Ṣúnémù—A Mọ̀ Ọ́n fún Ìfẹ́ àti Ìwà Ipá Rẹ̀
NÍ GÚÚSÙ Gálílì, ní ìlà oòrùn pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jésíréélì, ni ìlú Ṣúnémù wà. Ìlú kékeré yìí nírìírí méjì nínú àwọn ogun pàtàkì jù lọ nínú ìtàn Bíbélì, ṣùgbọ́n a tún mọ̀ ọ́n bí ẹní mowó sí ìlú ìbílẹ̀ àwọn obìnrin méjì tí wọ́n fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn.
Òkè kékeré tí a rò pé ó jẹ́ òkè Mórè wà lẹ́yìn Ṣúnémù, nígbà tí Òkè Gíbóà sì wà ní nǹkan bíi kìlómítà mẹ́jọ, ní òdì kejì pẹ̀tẹ́lẹ̀ náà. Ilẹ̀ ọlọ́ràá, tí ó lómi dáadáa—ọ̀kan nínú ilẹ̀ tí ń méso jáde jù lọ ní gbogbo Ísírẹ́lì—wà láàárín àwọn òkè kékeré méjì wọ̀nyẹn.
Àgbègbè àrọko yìí, nítòsí Ṣúnémù, jẹ́ ibi tí a gbé ọ̀kan lára àwọn ìtàn eléré ìfẹ́ tí ó lárinrin jù lọ tí a tí ì sọ rí kà—Orin Sólómọ́nì. Orin yìí sọ nípa arẹwà ọmọbìnrin kan tí ń gbé ní àrọko, tí ó yàn láti fẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀ olùṣọ́ àgùntàn dípò títẹ́wọ́gba ohun tí Ọba Sólómọ́nì fi lọ̀ ọ́, ìyẹn ni pé kí ó di ọ̀kan nínú àwọn aya rẹ̀. Sólómọ́nì ta gbogbo ọgbọ́n rẹ̀, ó sì lo gbogbo ọrọ̀ rẹ̀ láti lè rí ọmọbìnrin náà fẹ́. Ó yìn ín léraléra pé: “Ta ni ẹni tí ń tàn jáde bí òwúrọ̀, tí ó ní ẹwà bí òṣùpá, tí ó mọ́ bí oòrùn?” Ó sì ṣèlérí láti fi gbogbo ohun ọ̀ṣọ́ tí ó lè ronú kàn ṣìkẹ́ rẹ̀.—Orin Sólómọ́nì 1:11; 6:10.
Láti jẹ́ kí ó mọ bí ìgbésí ayé ọba ti rí, Sólómọ́nì mú kí ó tẹ̀ lé òun lọ sí Jerúsálẹ́mù gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára ẹmẹ̀wà òun, tí 60 nínú àwọn ọmọ ogun rẹ̀ dídára jù lọ ń tẹ̀ lé lẹ́yìn. (Orin Sólómọ́nì 3:6-11) Ó mú un wọ̀ sí ààfin rẹ̀, ààfin tí ó pinminrin débi pé nígbà tí ayaba Ṣébà rí i, “kò ku agbára kan fún un mọ́.”—Àwọn Ọba Kìíní 10:4, 5.
Ṣùgbọ́n ọmọbìnrin Ṣúnémù náà jẹ́ adúróṣinṣin sí ọ̀dọ́mọkùnrin olùṣọ́ àgùntàn náà. Ó sọ pé: “Bí igi eléso láàárín àwọn igi ìgbẹ́, bẹ́ẹ̀ ni olùfẹ́ mi rí.” (Orin Sólómọ́nì 2:3) Jẹ́ kí Sólómọ́nì máa gbádùn ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọgbà àjàrà rẹ̀ lọ. Ọgbà àjàrà kan—pẹ̀lú olólùfẹ́ rẹ̀—ti tẹ́ ẹ lọ́rùn. Ìfẹ́ rẹ̀ kò lè yẹ̀.—Orin Sólómọ́nì 8:11, 12.
Arẹwà obìnrin mìíràn gbé ní Ṣúnémù. A kò mọ ohunkóhun nípa ìrísí rẹ̀, ṣùgbọ́n dájúdájú ó rẹwà ní ọkàn àyà. Bíbélì sọ pé, ó “ṣàníyàn”—tàbí ṣòpò púpọ̀—láti lè pèsè oúnjẹ déédéé fún wòlíì Èlíṣà àti láti pèsè ilé gbígbé fún un.—Àwọn Ọba Kejì 4:8-13.
A lè finú wòye bí Èlíṣà ti ń pa dà bọ̀ tọpẹ́tọpẹ́ lẹ́yìn ìrìn àjò gígùn, tí ń káàárẹ̀ báni, tí ó sì wọnú yàrá kékeré tí obìnrin náà àti ọkọ rẹ̀ ti pèsè sílẹ̀ fún un. Ó ṣeé ṣe kí ó ṣèbẹ̀wò sí ilé wọn lọ́pọ̀ ìgbà, níwọ̀n bí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ ti gùn tó 60 ọdún. Èé ṣe tí obìnrin Ṣúnémù yí fi rin kinkin mọ́ ọn pé kí Èlíṣà wọ̀ sí ilé wọn ní gbogbo ìgbà tí ó bá gba ọ̀nà yẹn kọjá? Nítorí tí ó mọyì iṣẹ́ Èlíṣà. Wòlíì onírẹ̀lẹ̀, tí kò mọ ti ara rẹ̀ nìkan yìí, ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí ọkàn orílẹ̀-èdè náà, ní rírán àwọn ọba, àlùfáà, àti àwọn gbáàtúù ènìyàn létí ojúṣe wọn láti sin Jèhófà.
Kò sí iyè méjì pé obìnrin Ṣúnémù náà wà lára àwọn tí Jésù ní lọ́kàn nígbà tí ó sọ pé: “Ẹni tí ó bá gba wòlíì kan nítorí pé ó jẹ́ wòlíì yóò gba èrè ẹ̀san wòlíì.” (Mátíù 10:41) Jèhófà san èrè àkànṣe kan fún obìnrin olùbẹ̀rù Ọlọ́run yìí. Bí ó tilẹ̀ ti yàgàn fún ọ̀pọ̀ ọdún, ó bí ọmọkùnrin kan. Ó tún rí ìrànwọ́ àtọ̀runwá gbà ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, nígbà tí ọ̀dá ọdún méje run ilẹ̀ náà. Ìròyìn arùmọ̀lárasókè yí rán wa létí pé Bàbá wa ọ̀run kì í gbàgbé inú rere tí a fi hàn sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.—Àwọn Ọba Kejì 4:13-37; 8:1-6; Hébérù 6:10.
Àwọn Ogun Àjàmọ̀gá Méjì
Bí a tilẹ̀ rántí Ṣúnémù gẹ́gẹ́ bí ìlú àwọn obìnrin adúróṣinṣin méjì wọ̀nyí, ó tún nírìírí ogun méjì tí ó yí ìtàn Ísírẹ́lì pa dà. Ibì kan tí ó dára fún ogun jíjà wà nítòsí—pẹ̀tẹ́lẹ̀ tí ó wà láàárín òkè kékeré Mórè àti Gíbóà. Àwọn ọ̀gágun ní àkókò tí a kọ Bíbélì sábà máa ń dó sí ibi tí omi bá wà dáradára, ilẹ̀ tí ó ga sókè nítorí ààbò, àti, bí ó bá ṣeé ṣe, orí òkè títẹ́jú tí a ti lè máa wo aṣálẹ̀ àfonífojì nísàlẹ̀, tí ó sì fẹ̀ tó láti rí àyè fọgbọ́n darí ogunlọ́gọ̀ ọmọ ogun, ẹṣin, àti kẹ̀kẹ́ ẹṣin. Ṣúnémù àti Gíbóà pèsè irú àwọn àǹfààní bẹ́ẹ̀.
Nígbà ayé àwọn onídàájọ́, àwọn ọmọ ogun 135,000 ará Mídíánì, Ámálékì, àti àwọn mìíràn dó sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ tí ó wà níwájú Mórè. Àwọn ràkúnmí wọ́n dà “bí iyanrìn tí ń bẹ létí òkun ní ọ̀pọ̀lọpọ̀.” (Onídàájọ́ 7:12) Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lábẹ́ Onídàájọ́ Gídéónì, tí ó ní àwọn ọmọ ogun 32,000 péré, dojú kọ wọ́n ní òdì kejì pẹ̀tẹ́lẹ̀ náà, nítòsí kànga Háródù, ní ẹsẹ̀ Òkè Gíbóà.
Ní àwọn ọjọ́ tí ó ṣáájú ogun kan, ìhà kọ̀ọ̀kan yóò gbìyànjú láti mú àyà òdìkejì pami. Ogunlọ́gọ̀ ọmọ ogun tí ń hó gèè, àwọn ràkúnmí ogun, àwọn kẹ̀kẹ́ ogun, àti àwọn ẹṣin lè kópayà bá àwọn ọmọ ogun tí ó wà nísàlẹ̀. Kò sì iyèméjì pé àwọn ará Mídíánì—tí wọ́n ti wà ní sẹpẹ́ nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń kóra jọ—jẹ́ ìran akópayàbáni. Nígbà tí Gídéónì béèrè pé, “Ta ní ń bẹ níbẹ̀ tí ń fòyà tí ó sì ń wárìrì?” ìdáméjì nínú mẹ́ta àwọn ọmọ ogun rẹ̀ dáhùn pa dà nípa fífi ojú ogun sílẹ̀.—Onídàájọ́ 7:1-3, NW.
Wàyí o, kìkì 10,000 ọmọ ogun Ísírẹ́lì ní ń wo ọmọ ogun 135,000 ọ̀tá lójú ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ náà, kò sì pẹ́ tí Jèhófà fi dín iye ọmọ ogun Ísírẹ́lì kù sí 300 péré. Gẹ́gẹ́ bí àṣà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, wọ́n pín ẹgbẹ́ ọmọ ogun kékeré yìí sí mẹ́ta. Nínú òkùnkùn, wọ́n fọ́nká, wọ́n sì dúró sí ipò wọn ní igun mẹ́ta ibùdó ọ̀tá. Lẹ́yìn náà, lábẹ́ àṣẹ Gídéónì, àwọn 300 náà fọ́ ìṣà tí ó ti bo òtùfù wọn, wọ́n gbé àwọn òtùfù wọ̀nyẹn sókè, wọ́n sì kígbe ní ohùn rara pé, “Idà OLÚWA, àti ti Gídéónì.” Wọ́n fun ipè wọn láìdánudúró. Nínú òkùnkùn, ogunlọ́gọ̀ ọmọ ogun tí jìnnìjìnnì bò rò pé 300 ọmọ ogun ń kọ lù wọ́n. Jèhófà dojú èkíní kọ èkejì, “gbogbo ogun náà sì súré, wọ́n sì kígbe, wọ́n sì sá.”—Onídàájọ́ 7:15-22; 8:10.
Ogun kejì ṣẹlẹ̀ nítòsí Ṣúnémù, ní àkókò Ọba Sọ́ọ̀lù. Bíbélì ròyìn pé “àwọn Filísínì sì kó ara wọn jọ, wọ́n wá, wọ́n sì dó sí Ṣúnémù: Sọ́ọ̀lù sì kó gbogbo Ísírẹ́lì jọ, wọ́n sì tẹ̀dó ní Gíbóà,” gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ ọmọ ogun Gídéónì ti ṣe ní ọ̀pọ̀ ọdún ṣáájú. Ṣùgbọ́n Sọ́ọ̀lù, láìdàbí Gídéónì, kò fi bẹ́ẹ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ó yàn láti tọ ìyálóde lẹ́nu ìbẹ́mìílò kan lọ ní Ẹ́ń-dórì. Nígbà tí ó rí ibùdó àwọn Filísínì, “òun . . . bẹ̀rù, àyà rẹ̀ sì wárìrì gidigidi.” Nínú ogun tí ó tẹ̀ lé e, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fẹsẹ̀ fẹ, a sì ṣẹ́gun wọn tí wọn kò sì rọ́wọ́ mú. Sọ́ọ̀lù àti Jónátánì pàdánù ẹ̀mí wọn.—Sámúẹ́lì Kíní 28:4-7; 31:1-6.
Bí ìtàn Ṣúnémù ṣe di èyí tí a mọ̀ fún ìfẹ́ àti ìwà ipá rẹ̀ fún ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Jèhófà àti gbígbára lé àwọn ẹ̀mí èṣù, nìyẹn. Ní àfonífojì pẹ̀tẹ́lẹ̀ yí, àwọn obìnrin méjì fi ìfẹ́ tí kò yẹ̀ àti aájò àlejò hàn, àwọn aṣáájú Ísírẹ́lì méjì sì ja ogun àjàmọ̀gá. Gbogbo àpẹẹrẹ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì gbígbáralé Jèhófà, tí kì í kùnà láé láti san èrè fún àwọn tí ó bá sìn ín.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Abúlé Sulam òde òní níbi tí Ṣúnémù àtijọ́ wà tẹ́lẹ̀, Mórè ni ó wà lẹ́yìn
[Credit Line]
Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.