ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w97 10/15 ojú ìwé 24-27
  • Ìhìn Rere Párádísè ní Tahiti

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìhìn Rere Párádísè ní Tahiti
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Ìbẹ̀rẹ̀ Kékeré
  • Iṣẹ́ Náà Tẹ̀ Síwájú
  • Tahiti Di Ẹ̀ka
  • Púpọ̀ Ṣì Wà Láti Ṣe
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
w97 10/15 ojú ìwé 24-27

Ìhìn Rere Párádísè ní Tahiti

TAHITI! Ó jọ pé orúkọ yẹn gbé ẹwà kan tí ó ṣàrà ọ̀tọ̀ rù. Àwọn ayàwòrán àti òǹkọ̀wé bíi Paul Gauguin, Robert Louis Stevenson, àti Herman Melville, tí àwòrán àti ìkọ̀wé wọn nípa ẹwà àti ìparọ́rọ́ ilẹ̀ olóoru ti àwọn Erékùṣù Òkun Gúúsù fa ọkàn ọ̀pọ̀ ènìyàn mọ́ra, ni ó sọ ọ́ di olókìkí.

Tahiti ni ó tóbi jù lọ nínú erékùṣù Polynesia ti Faransé, tí ó lé ní 120, tí ó wà ní Gúúsù Pàsífíìkì. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ní ọkàn ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn, erékùṣù Òkun Gúúsù yí fẹ́ jọ párádísè, àwọn ènìyàn Tahiti ṣì ní láti gbọ́ nípa párádísè míràn tí yóò dé láìpẹ́. (Lúùkù 23:43) Ọwọ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tí wọ́n tó 1,918 ní Tahiti lónìí, dí fọ́fọ́ fún sísọ fún àwọn ènìyàn tí ó tó 220,000 nípa ìhìn rere náà pé Ìjọba Ọlọ́run yóò mú ipò párádísè tòótọ́ wọlé wá láìpẹ́, kì í ṣe ní Tahiti nìkan ṣùgbọ́n ní gbogbo ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.—Mátíù 24:14; Ìṣípayá 21:3, 4.

Fún ọ̀pọ̀ ọdún, ọ́fíìsì ẹ̀ka Watch Tower Society ní Fiji, tí ó tó 3,500 kìlómítà síbẹ̀, ni ó ń bójú tó iṣẹ́ ìwàásù ní Tahiti. Nítorí ọ̀nà jíjìn, nǹkan kò rọrùn, ìtẹ̀síwájú sì falẹ̀. Nípa báyìí, ní April 1, 1975, a gbé ọ́fíìsì ẹ̀ka kan kalẹ̀ sí Tahiti, ìyẹn sì sàmì sí àkókò ìyípadà ńlá nínú ìgbòkègbodò àwọn Kristẹni tòótọ́ ní àgbègbè yí. Kí ni ó mú ìdàgbàsókè yí wá, báwo sì ni iṣẹ́ ìwàásù ṣe bẹ̀rẹ̀ ní Tahiti?

Ìbẹ̀rẹ̀ Kékeré

Ní àwọn ọdún 1930 ni a kọ́kọ́ gbọ́ ìhìn rere Ìjọba ní Tahiti, ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn erékùṣù náà, tí wọ́n ní ọ̀wọ̀ gíga fún Bíbélì, dáhùn pa dà tìfẹ́tìfẹ́. Ṣùgbọ́n, nítorí ìfòfindè ìjọba àti àwọn ìkálọ́wọ́kò míràn, kò sí Ẹlẹ́rìí kankan ní erékùṣù náà títí di àwọn ọdún 1950. Ní àkókò yẹn, Agnès Schenck, ọmọ ìbílẹ̀ Tahiti, tí ń gbé ní United States, pinnu láti pa dà sí Tahiti pẹ̀lú ọkọ rẹ̀ àti ọmọkùnrin rẹ̀. Ó ṣàlàyé bí gbogbo rẹ̀ ṣe ṣẹlẹ̀.

“Ní àpéjọpọ̀ àgbègbè ọdún 1957 ní Los Angeles, Arákùnrin Knorr [ààrẹ Watch Tower Society ìgbà náà] ṣàlàyé pé àìní ńlá wà fún àwọn akéde Ìjọba ní Tahiti. Ó ti tó ọdún kan tí mo ti ṣèrìbọmi nígbà náà, mo sì fi ìtara sọ pé, ‘Ẹ jẹ́ kí a lọ sí Tahiti nígbà náà!’ Ìdílé méjì, ìdílé Neill àti ti Carano, àwọn ọ̀rẹ́ wa àtàtà, gbọ́ ohun tí mo sọ. Wọ́n sọ pé àwọn yóò fẹ́ láti lọ pẹ̀lú wa, ṣùgbọ́n a kò lówó púpọ̀ lọ́wọ́. Ọkọ mi ti ń ṣàìsàn fún ìgbà tí ó ti pẹ́, ọmọkùnrin mi sì kéré púpọ̀. Nítorí náà, ó ṣòro fún wa láti filé sílẹ̀. Àwọn ọ̀rẹ́ nínú àwọn ìjọ àdúgbò gbọ́ nípa góńgó wa, wọ́n sì fi owó àti àwọn ẹrù ilé ránṣẹ́ sí wa. Lẹ́yìn náà, ní May 1958, a wọkọ̀ òkun lọ sí Tahiti, aṣọ bẹ́ẹ̀dì 36 sì wà lára àwọn nǹkan tí a kó dání!

“Nígbà tí a dé Tahiti, mo dà bí àjèjì pátápátá, nítorí tí ó ti tó 20 ọdún tí mo ti fi erékùṣù náà sílẹ̀. A bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù, ṣùgbọ́n a ní láti lo ìṣọ́ra, nítorí iṣẹ́ Kristẹni wa wà lábẹ́ ìfòfindè. A ní láti fi àwọn ìwé ìròyìn pa mọ́, a sì lo Bíbélì nìkan. Lákọ̀ọ́kọ́, àwọn ènìyàn tí wọ́n ti san àsansílẹ̀ owó fún ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! nìkan ni a wàásù fún.

“Clyde Neill àti David Carano, àti ìdílé wọn, dara pọ̀ mọ́ wa lẹ́yìn àpéjọpọ̀ àgbáyé ní New York City ní 1958. A jọ wàásù, a sì ké sí àwọn ènìyàn láti wá tẹ́tí sí àsọyé tí a ń sọ ní ilé àwọn ará. Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, nǹkan ń lójú, a sì bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú ènìyàn 15. Lẹ́yìn oṣù mẹ́ta, ìdílé Neill àti ti Carano ní láti fi ìlú sílẹ̀ nítorí ọjọ́ tí ó wà lórí òǹtẹ̀ àṣẹ ìwọ̀lú tí a fún wọn ti pé. Nítorí náà, àwọn arákùnrin pinnu pé ṣáájú kí wọ́n tó lọ, àwọn yóò batisí gbogbo olùfìfẹ́hàn tí ó tóótun. Mo láǹfààní láti jẹ́ ògbufọ̀ àsọyé ìbatisí àkọ́kọ́. Ní àkókò yí, àwọn ọmọ ìbílẹ̀ mẹ́jọ fi àmì ìyàsímímọ́ wọn hàn sí Jèhófà nípa ṣíṣe ìrìbọmi. Lẹ́yìn náà, ìdílé Neill àti ti Carano pa dà sí United States.

“Iṣẹ́ ìwàásù náà ń bá a lọ. A ṣètò ara wa sí àwọn àwùjọ kékeré, a sì ń kàn sí àwọn ènìyàn ní ìrọ̀lẹ́. Lọ́pọ̀ ìgbà, ìjíròrò pẹ̀lú àwọn olùfìfẹ́hàn máa ń bá a lọ títí di ọ̀gànjọ́ òru. Ní ìgbà míràn, àwọn òjíṣẹ́ Pùròtẹ́sítáǹtì pàápàá máa ń dara pọ̀ nínú ìjíròrò náà. Nígbà tí yóò fi di 1959, a ti dá ìjọ àkọ́kọ́ sílẹ̀. Lẹ́yìn náà, sí ìdùnnú ńlá wa, ní 1960, ìjọba fọwọ́ sí ẹgbẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àwọn ọdún àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ náà kún fún ayọ̀ àti ìwúrí nípa tẹ̀mí. Ní tòótọ́, Jèhófà bù kún ìpinnu wa láti ṣí lọ sí ibi ti àìní gbé pọ̀.” Ẹni ọdún 87 ni Arábìnrin Schenck nísinsìnyí, ó sì ń bá a lọ láti fi òtítọ́ sin Jèhófà nínú ìjọ rẹ̀.

Iṣẹ́ Náà Tẹ̀ Síwájú

Ní 1969, a yan Àwọn Ẹlẹ́rìí méjì, Jacques àti Paulette Inaudi, láti ilẹ̀ Faransé sí Tahiti gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà àkànṣe. Jacques rántí pé: “Nígbà tí a dé sí Tahiti, akéde 124 péré, ìjọ kan ṣoṣo ní Papeete, àti aṣáájú ọ̀nà àkànṣe méjì ní Vairao, níbi ìyawọlẹ̀ omi, ni ó wà níbẹ̀.” Ọ̀nà tóórótó kan ni ó so ìyawọlẹ̀ omi náà mọ́ Tahiti. Kò pẹ́ mọ́ tí a óò ṣe Àpéjọ Àgbáyé ti “Alafia Lori Ilẹ Aiye.” Jacques ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Ìrírí àkọ́kọ́ tí mo ní nìyẹn nínú ṣíṣètò àpéjọpọ̀ kan. A ní láti ṣètò ìtòlẹ́sẹẹsẹ ní èdè Gẹ̀ẹ́sì fún àwọn àlejò wa, kí a ṣètò ẹgbẹ́ akọrin láti kọ orin Ìjọba, kí a sì ṣèfidánrawò àwòkẹ́kọ̀ọ́ méjì. Àwọn akéde 126 péré ni ó ṣe gbogbo iṣẹ́ yìí. Ó dá mi lójú pé Jèhófà ni ó ṣe èyí tí ó pọ̀ jù lára iṣẹ́ náà.” Àwọn 488 tí ó pé jọ wú àwọn olùgbé erékùṣù náà lórí. Fún púpọ̀ nínú wọn, ìgbà àkọ́kọ́ nìyẹn láti bá Àwọn Ẹlẹ́rìí ẹlẹgbẹ́ wọn láti àwọn ilẹ̀ míràn pàdé.

Kò pẹ́ lẹ́yìn náà, a yan Jacques Inaudi sí iṣẹ́ alábòójútó arìnrìn-àjò. Bí ó ti ń ṣèbẹ̀wò sí onírúurú erékùṣù, ó rí i pé àwọn tí ó ní ìfẹ́ ọkàn pọ̀, ṣùgbọ́n àwọn akéde Ìjọba tí yóò bomi rin ìfẹ́ náà kò tó nǹkan. Jacques ṣàlàyé pé: “Ìdí nìyẹn tí mo fi fún ọ̀pọ̀ ìdílé níṣìírí láti ṣí lọ sí àwọn erékùṣù wọ̀nyí láti lọ sìn níbi tí àìní gbé pọ̀. Nítorí náà, ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, a tan ìhìn rere ká àwọn erékùṣù wọ̀nyẹn.” Arákùnrin Inaudi sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó àyíká láti 1969 sí 1974, òun sì jẹ́ alàgbà nínú ọ̀kan nínú àwọn ìjọ tí ó wà ní Tahiti lónìí.

Auguste Temanaha, ọ̀kan lára àwọn mẹ́jọ tí ó ṣèrìbọmi ní 1958, wà lára àwọn tí ó dáhùn pa dà sí ìṣírí Arákùnrin Inaudi. Ó ròyìn ohun tí ó ṣẹlẹ̀. “Ní 1972, alábòójútó àyíká, Jacques Inaudi, fún wa níṣìírí láti gbé ṣíṣílọ láti sìn ní Huahine, ọ̀kan lára àwọn Erékùṣù Leeward, tí ó wà lára apapọ̀ àwùjọ Society, yẹ̀ wò. Mo lọ́ tìkọ̀ nítorí Bíbélì kíkà nìkan ni iṣẹ́ tí mo ṣe rí nínú ìjọ, n kò sì rò pé mo tóótun láti tẹ́rí gba irú ẹrù iṣẹ́ bàǹtàbanta bẹ́ẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, Arákùnrin Inaudi sọ fún mi lemọ́lemọ́ pé, ‘Má da ara rẹ láàmú, o lè ṣeé!’ Lẹ́yìn àkókò díẹ̀, a ṣèpinnu. Nítorí náà, ní 1973, a ta gbogbo ohun tí a ní, a sì ṣí lọ sí Huahine pẹ̀lú àwọn ọmọ wa kéékèèké mẹ́tẹ̀ẹ̀ta.

“Nígbà tí a dé ibẹ̀, mo rí i pé mo ní láti bẹ̀rẹ̀ gbogbo nǹkan—Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́, Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Kò rọrùn rárá, ṣùgbọ́n, a nímọ̀lára ààbò àti ìrànwọ́ Jèhófà. Ní ọ̀pọ̀ ìgbà, ó ràn wá lọ́wọ́ láti rí ibùgbé. Lẹ́yìn náà, nígbà tí ẹgbẹ́ alátakò kan gbìdánwò láti lé Àwọn Ẹlẹ́rìí kúrò ní erékùṣù náà, òṣèlú kan ládùúgbò dìde láti gbèjà wa. Ní tòótọ́, Jèhófà dáàbò bò wá ní gbogbo àkókò yẹn.” Nísinsìnyí, ìjọ méjì ni ó wà ní Huahine—ìjọ èdè Faransé kan, tí ó ní akéde 23 àti ìjọ èdè Tahiti, tí ó ní akéde 55.

Ní 1969, a yan Hélène Mapu gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà àkànṣe láti ṣiṣẹ́ ní ibi ìyawọlẹ̀ omi. Hélène sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ènìyàn fi ìfẹ́ hàn ní ibi ìyawọlẹ̀ omi, kò sì pẹ́ ti mo fi bẹ̀rẹ̀ ọ̀pọ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.” Kò pẹ́ tí a fi dá ìjọ kékeré kan sílẹ̀ ní Vairao, ṣùgbọ́n a nílò àwọn alàgbà. Lẹ́yìn àkókò díẹ̀, ó ṣeé ṣe fún Colson Deane, tí ń gbé ní kìlómítà 35 ní Papara nígbà náà, láti ràn wá lọ́wọ́. Arákùnrin Deane ròyìn pé: “A ní láti ṣètò ara wa dáradára láti baà lè sìn ní Vairao. Faaa, 70 kìlómítà sí Vairao, ní òdì kejì erékùṣù náà, ni mo ti ń ṣiṣẹ́. Lẹ́yìn iṣẹ́, n óò sáré wá sílé láti kó àwọn ìdílé mi, a óò sì lọ sí Vairao. Nígbà tí ó yá, a ní láti ṣí lọ sí Faaa, nítorí iṣẹ́ mi. Yóò ha ṣì ṣeé ṣe fún wa láti ran Ìjọ Vairao lọ́wọ́ bí? Ó wù wá gan-an láti ran àwọn ará tí ó wà níbẹ̀ lọ́wọ́, nítorí náà, a pinnu láti máa bá a lọ. Ní ọjọ́ ìpàdé, a kì í délé títí di ọ̀gànjọ́ òru, nítorí a ní láti lọ lọ́pọ̀ ìgbà láti gbé àwọn tí kò lọ́kọ̀ lọ sí ilé. A ṣe èyí fún ọdún márùn-ún gbáko. Ìdùnnú ńlá ni ó jẹ́ nísinsìnyí láti rí ìjọ mẹ́rin ní apá erékùṣù yí, inú wa sì máa ń dùn nígbà tí a bá rántí àwọn ọdún wọ̀nyẹn.”

Tahiti Di Ẹ̀ka

Nígbà tí yóò fi di 1974, iye akéde Ìjọba ní Tahiti ti tó 199. Ní ọdún tí ó tẹ̀ lé e, nígbà tí N. H. Knorr àti F. W. Franz, ààrẹ àti igbákejì ààrẹ Watch Tower Society nígbà náà, ṣèbẹ̀wò sí Polynesia ti Faransé, wọ́n rí i pé yóò túbọ̀ gbéṣẹ́ láti máa darí iṣẹ́ ìwàásù Polynesia ti Faransé ní Tahiti, kì í ṣe ní Fiji, tí ó jìnnà tó 3,500 kìlómítà. Nítorí náà, ní April 1, 1975, ẹ̀ka Tahiti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní pẹrẹwu, a sì sọ alábòójútó àyíká náà, Alain Jamet, di alábòójútó ẹ̀ka.

Ní ọdún bíi mélòó kan sẹ́yìn, Arákùnrin Jamet láǹfààní láti ròyìn ìbùkún àgbàyanu tí ó ti wá láti ọ̀dọ̀ Jèhófà. “Láti 1975, a ti ṣe ìsapá gidi láti mú ìhìn rere lọ sí gbogbo erékùṣù àti àwùjọ erékùṣù tí ó wà ní ìpínlẹ̀ wa, tí ó fẹ̀ tó Ìwọ̀ Oòrùn Europe. Àbájáde rẹ̀ ti mú ayọ̀ wá. Nígbà tí yóò fi di 1983, iye akéde ti lọ sókè sí 538. Ní ọdún yẹn, a kọ́ ilé kan fún ọ́fíìsì ẹ̀ka àti Ilé Bẹ́tẹ́lì ní Paea. Nísinsìnyí, nǹkan bí akéde 1,900 ni wọ́n wà káàkiri nínú 30 ìjọ ní àwọn Erékùṣù Society, ìjọ kan àti àwùjọ àdádó kan ní àwọn Erékùṣù Austral, ìjọ kan àti àwùjọ àdádó méjì ní Marquesas, àti àwùjọ àdádó mélòó kan ní àwọn Erékùṣù Tuamotu àti Gambier. Ọ̀pọ̀ Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun ni a kọ́—mẹ́ta ní Marquesas àti méje ní Tahiti—láti bójú tó àwọn ẹni tuntun tí ń pọ̀ sí i tí wọ́n ń wá sí àwọn ìpàdé. Ní 20 ọdún tí ó kọjá, Jèhófà ti bù kún ìsapá wa ní tòótọ́ láti bomi rin pápá Tahiti.”

Púpọ̀ Ṣì Wà Láti Ṣe

Ìfojúsọ́nà fún ìbísí ní Polynesia ti Faransé pọ̀ rẹpẹtẹ. Ní March 23, 1997, àwọn ènìyàn tí ó tó 5,376 pé jọ pẹ̀lú Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jákèjádò Polynesia Faransé fún Ìṣe Ìrántí ikú Jésù Kristi. Láti bójú tó àìní tẹ̀mí àwọn olùfìfẹ́hàn wọ̀nyí, a mú àwọn ìtẹ̀jáde Bíbélì wa jáde ní onírúurú èdè ìbílẹ̀. Ní àfikún sí èdè Tahiti, a ti mú àwọn ìwé jáde ní èdè Paumotu, tí a ń sọ ní Erékùṣù Tuamotu àti ní Àríwá àti Gúúsù Marquesas.

Ìbísí tí ń lọ sòsé àti àwọn ìrírí gbígbádùnmọ́ni ti ran àwọn akéde Ìjọba ní Tahiti lọ́wọ́ láti túbọ̀ mọrírì ìfẹ́ àti sùúrù Jèhófà, “ẹni tí ó jẹ́ ìfẹ́ inú rẹ̀ pé kí a gba gbogbo onírúurú ènìyàn là kí wọn sì wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́,” àní ní àwọn erékùṣù jíjìnnà réré náà ní Òkun Gúúsù pàápàá. (Tímótì Kíní 2:4) Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Tahiti àti ní àwọn erékùṣù Polynesia ti Faransé yòó kù ní ìgbàgbọ́ kíkún nínú ìlérí Jèhófà pé: “Ọ̀dọ̀ mi ni àwọn erékùṣù pàápàá yóò fi ìrètí wọn sí, apá mi sì ni wọn yóò dúró dè.”—Aísáyà 51:5, NW.

[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 26]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

Ẹ̀ka Tahiti ni ó ń bójú tó àìní Polynesia ti Faransé

AUSTRALIA

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Láti òsì sí ọ̀tún: Alain Jamet, Mary-Ann Jamet, Agnès Schenck, Paulette Inaudi, àti Jacques Inaudi

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]

Ẹ̀ka ọ́fíìsì Tahiti

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́