Ìṣọ̀kan Ayé—Yóò Ha Wáyé Ní Tòótọ́ Láé Bí?
“BÍ A bá lè ṣàṣeyọrí nínú àwọn ìran bíi mélòó kan tí ń bọ̀ láti yí ayé ọlọ́pọ̀ orílẹ̀-èdè tí ó dá dúró, tí a ń gbé, pa dà di oríṣi ojúlówó àwùjọ àgbáyé kan, . . . nígbà náà, yóò ti ṣeé ṣe fún wa láti fi òpin sí ogun, tí ó jẹ́ àṣà àtayébáyé, lọ́nà gbígbéṣẹ́ . . . Ṣùgbọ́n, bí a bá kùnà, bóyá ni . . . ọ̀làjú yóò wà.” Ohun tí Gwynne Dyer, òpìtàn ogun, sọ nínú ìwé rẹ̀ tí a pe àkọlé rẹ̀ ní War nìyẹn.
Dyer sọ pé ojú ìwé ìtàn kún fọ́fọ́ fún ìròyìn nípa àwọn orílẹ̀-èdè àti àwọn àwùjọ alágbára mìíràn tí ó yíjú sí ogun láti yanjú aáwọ̀ tí ó wà láàárín wọn. Àìwàníṣọ̀kan wọn da ìgbésí ayé àràádọ́ta ọ̀kẹ́ tí kò mọwọ́ mẹsẹ̀ rú. Àpèjúwe tí Ọba Sólómọ́nì ṣe nípa bí èyí ti nípa lórí àwọn ènìyàn ọjọ́ rẹ̀ ṣì bá a mu rẹ́gí lónìí. Ó kọ̀wé pé: “Mo pa dà, mo sì ro ìnilára gbogbo tí a ń ṣe lábẹ́ oòrùn; mo sì wo omijé àwọn tí a ń ni lára, wọn kò sì ní olùtùnú; àti lọ́wọ́ aninilára wọn ni ipá wà; ṣùgbọ́n wọn kò ní olùtùnú.”—Oníwàásù 4:1.
Lóde òní, gẹ́gẹ́ bí òpìtàn tí a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lókè ti sọ, yàtọ̀ sí níní ìyọ́nú fún “omijé àwọn tí a ń ni lára,” ìdí mìíràn tún wà fún wíwá ọ̀nà kan láti yí ayé ọlọ́pọ̀ orílẹ̀-èdè tí ó dá dúró pa dà di oríṣi ojúlówó àwùjọ àgbáyé kan: Wíwà ọ̀làjú pàápàá wà nínú ewu! Ogun òde òní mú ìparun gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó bá yíjú sí i dájú, kò sì ní sí ajagunmólú pàápàá.
Ìṣọ̀kan Ayé Ha Sún Mọ́lé Bí?
Ìrètí wo ni ó wà fún ìṣọ̀kan ayé? Àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn ha lè ṣẹ́pá ipá adárúgúdù sílẹ̀ tí ń wu wíwà ilẹ̀ ayé léwu bí? Àwọn kan rò bẹ́ẹ̀. John Keegan, olóòtú ọ̀ràn ààbò àti ológun nínú ìwé agbéròyìnjáde Daily Telegraph ti ilẹ̀ Britain, kọ̀wé pé: “Láìka ìdàrúdàpọ̀ àti àìdánilójú sí, ó dà bíi pé ó ṣeé ṣe láti kófìrí ayé kan tí kò sí ogun, tí ń wá sí ojútáyé.”
Kí ní mú kí ó ní ojú ìwòye ìfojúsọ́nà fún rere yìí? Èé ṣe tí ó fi dà bíi pé ọ̀pọ̀ nírètí láìka ìtàn rẹpẹtẹ tí ó wà nípa ogun tí aráyé ti jà sí, àti jíjọ tí ó jọ pé ènìyàn kò lè ṣàṣeyọrí nínú ṣíṣàkóso ara rẹ̀? (Jeremáyà 10:23) Nígbà kan, àwọn kan jiyàn pé: ‘Aráyé ń tẹ̀ síwájú. Ìtàn ń fi ọ̀nà ìtẹ̀síwájú tí ń bá a lọ hàn.’ Àní lónìí pàápàá, ọ̀pọ̀ gbà gbọ́ pé, lọ́nà kan ṣáá, ire tí a dá mọ́ ènìyàn yóò borí ibi. Ìrètí yẹn ha lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ bí? Àbí ó wulẹ̀ jẹ́ ẹ̀tàn kan tí yóò yọrí sí ọ̀pọ̀ ìjákulẹ̀ sí i? Nínú ìwé rẹ̀, Shorter History of the World, òpìtàn J. M. Roberts kọ̀wé ní sísọ ojú abẹ níkòó pé: “Ó ṣòro láti sọ pé ọjọ́ ọ̀la ayé fi ọkàn ẹni balẹ̀. Bẹ́ẹ̀ sì ni òpin ìjìyà ẹ̀dá ènìyàn kò sún mọ́lé rárá, kò sì sí ìdí èyíkéyìí láti gbà gbọ́ pé yóò wá sí òpin.”
Ìdí gidi ha wà láti gbà gbọ́ pé àwọn ènìyàn àti orílẹ̀-èdè yóò ṣẹ́pá àìnígbẹkẹ̀lé nínú ara wọn àti aáwọ̀ tí ń pínni níyà tí wọ́n ní bí? Àbí a nílò ju ìsapá ẹ̀dá ènìyàn lọ? Àpilẹ̀kọ tí ó tẹ̀ lé e yóò gbé àwọn ìbéèrè wọ̀nyí yẹ̀ wò.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 2]
Àwòrán àgbáyé tí ó wà nínú àwòrán ẹ̀yìn ìwé: Mountain High Maps® Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 1995 Digital Wisdom, Inc.