ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w97 12/15 ojú ìwé 30
  • Ìwọ Ha Rántí Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìwọ Ha Rántí Bí?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àpẹẹrẹ Ìfara-Ẹni-Rúbọ àti Ìdúróṣinṣin
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • ‘Ẹ Máa Bá a Lọ Ní Dídáríji Ara Yín Lẹ́nì Kíní Kejì’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Èlíṣà Rí Kẹ̀kẹ́ Ẹṣin Oníná—Ṣé Ìwọ Náà Rí I?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
w97 12/15 ojú ìwé 30

Ìwọ Ha Rántí Bí?

Ìwọ ha ti mọrírì kíka àwọn ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ ti lọ́ọ́lọ́ọ́ bí? Tóò, wò ó bóyá o lè dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí:

◻ Kí ni ète pàtàkì ìmọ̀ ẹ̀kọ́ fún èwe Kristẹni?

Ó yẹ kí ète pàtàkì ìmọ̀ ẹ̀kọ́ jẹ́ láti mú èwe kan gbára dì láti jẹ́ ọ̀jáfáfá òjíṣẹ́ Jèhófà. Ìmọ̀ ẹ̀kọ́ tẹ̀mí sì ni ìmọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó ṣe pàtàkì jù lọ láti ṣe ìyẹn.—8/15, ojú ìwé 21.

◻ Kí ni àwọn ìdí fún fífẹjọ́ Kristẹni ẹlẹgbẹ́ ẹni tí ó hùwà àìtọ́ búburú jáì sun àwọn alàgbà?

Ìdí tí a fi ń fẹjọ́ ẹnì kan tí ó hùwà àìtọ́ búburú jáì sùn ni pé, ó ń pa ìjẹ́mímọ́ ìjọ mọ́. Ìdí mìíràn ni pé ṣíṣe bẹ́ẹ̀ jẹ́ ìwà ìfẹ́ Kristẹni tí a gbé karí ìlànà, tí a fi hàn sí Ọlọ́run, tí a fi hàn sí ìjọ, àti sí oníwà àìtọ́ náà.—8/15, ojú ìwé 28, 30.

◻ Kí ni ó túmọ̀ sí láti ‘fi wíwàníhìn-ín ọjọ́ Jèhófà sọ́kàn pẹ́kípẹ́kí’? (Pétérù Kejì 3:12)

Èyí túmọ̀ sí pé a kò mọ́kàn wa kúrò lórí “ọjọ́ Jèhófà.” A kò gbọ́dọ̀ gbàgbé pé ọjọ́ náà tí Jèhófà yóò pa ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan ti ìsinsìnyí run ti sún mọ́lé. Ó yẹ kí ó jẹ́ gidi sí wa tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí a óò fi lè rí i kedere, bí ẹni pé ó wà gẹ́rẹ́ níwájú wa. (Sefanáyà 1:7, 14)—9/1, ojú ìwé 19.

◻ Èé ṣe tí àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ètò ìgbékalẹ̀ búburú ìsinsìnyí fi gùn ju bí ọ̀pọ̀ ti retí lọ?

Jèhófà máa ń gba ohun tí ó ṣàǹfààní jù lọ fún gbogbo ẹ̀dá ènìyàn yẹ̀ wò. Ẹ̀mí àwọn ènìyàn ni ó jẹ ẹ́ lógún. (Ìsíkẹ́ẹ̀lì 33:11) A lè ní ìdánilójú pé òpin yóò dé ní àkókò gan-an tí ó yẹ kí ó dé láti lè mú ète Ẹlẹ́dàá wa onífẹ̀ẹ́, ọlọ́gbọ́n gbogbo ṣẹ.—9/1, ojú ìwé 22.

◻ Báwo ni àwọn tí ó wà nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún ṣe lè máa bá a lọ ní jíjẹ́ aláyọ̀ láìka àwọn ìṣòro tí ó lè dojú kọ wọ́n sí?

Ó yẹ kí wọ́n ronú nípa ọ̀pọ̀ ìbùkún tí wọ́n ní, kí wọ́n sì mọ̀ pé ẹgbẹẹgbẹ̀rún mìíràn ń bẹ tí ń jìyà àwọn ìnira tí ó ju tiwọn lọ. (Pétérù Kíní 5:6-9)—9/15, ojú ìwé 24.

◻ Kí ni góńgó William Tyndale nígbà tí ó ń tú Bíbélì?

Góńgó Tyndale jẹ́ láti mú kí Ìwé Mímọ́ wà lárọ̀ọ́wọ́tó fún àwọn gbáàtúù, ní èdè tí ó pé pérépéré tí ó sì rọrùn láti lóye.—9/15, ojú ìwé 27.

◻ Báwo ni a ṣe lè fi hàn pé a jẹ́ adúróṣinṣin alágbàwí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?

A ń fi ìdúróṣinṣin wa sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run hàn nípa fífi ìtara wàásù rẹ̀ fún àwọn ẹlòmíràn. Gẹ́gẹ́ bí olùkọ́, a gbọ́dọ̀ fi ìṣọ́ra lo Bíbélì, ní ṣíṣàìlọ́ ọ lọ́rùn tàbí fẹ ohun tí ó sọ lójú láti bá èrò tiwa mu. (Tímótì Kejì 2:15)—10/1, ojú ìwé 20.

◻ Báwo ni ẹ̀mí ayé onímájèlé ṣe lè ba ìwà títọ́ wa jẹ́?

Ẹ̀mí ayé lè ba ìwà títọ́ wa jẹ́ nípa mímú kí a máà ní ìtẹ́lọ́rùn mọ́ pẹ̀lú ohun tí a ní, kí a sì máa ṣàníyàn láti fi àìní wa àti ire wa ṣáájú ti Ọlọ́run. (Fi wé Mátíù 16:21-23.)—10/1, ojú ìwé 29.

◻ Kí ni ó túmọ̀ sí láti sin Jèhófà tọkàntọkàn?

“Ọkàn” tọ́ka sí ènìyàn lódindi, pẹ̀lú gbogbo agbára rẹ̀ nípa tara àti ti èrò orí. Sísin Jèhófà tọkàntọkàn túmọ̀ sí fífi ara wa fún un, ní lílo gbogbo agbára wa àti dídarí gbogbo okun wa sínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run dé ìwọ̀n kíkúnrẹ́rẹ́ bí ó bá ti ṣeé ṣe tó. (Máàkù 12:29, 30)—10/15, ojú ìwé 13.

◻ Kí ni àṣírí jíjẹ́ atẹ̀lélànà Ọlọ́run?

Àṣírí náà ni láti mọ Jèhófà dunjú, kí a mọ ohun tí ó fẹ́, àti ohun tí kò fẹ́, àti àwọn ète rẹ̀. Nígbà tí a bá jẹ́ kí àwọn ìlànà wọ̀nyí nípa Ọlọ́run darí ìgbésí ayé wa, ní ti gidi, wọn yóò di ìlànà tí ó wà láàyè. (Jeremáyà 22:16; Hébérù 4:12)—10/15, ojú ìwé 29.

◻ Ìṣarasíhùwà tí ó wà déédéé wo ni àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ní sí ìṣàkóso ẹ̀dá ènìyàn?

Wọn kì í dá sí tọ̀tún tòsì nínú ọ̀ràn ìṣèlú nítorí wọ́n jẹ́ ikọ̀ tàbí òjíṣẹ́ aṣojú Ìjọba Ọlọ́run. (Kọ́ríńtì Kejì 5:20) Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, wọ́n ń fi tọkàntọkàn tẹrí ba fún àwọn aláṣẹ.—11/1, ojú ìwé 17.

◻ Ẹ̀kọ́ wo ni a lè kọ́ láti inú ọ̀nà tí wòlíì Èlíṣà tọ̀?

Nígbà tí a nawọ́ ìkésíni láti ṣe iṣẹ́ ìsìn àkànṣe pẹ̀lú Èlíjà sí i, ojú ẹsẹ̀ ni Èlíṣà fi pápá rẹ̀ sílẹ̀ láti ṣe ìránṣẹ́ fún Èlíjà, bí díẹ̀ nínú iṣẹ́ rẹ̀ kò tilẹ̀ fi bẹ́ẹ̀ jọjú. (Àwọn Ọba Kejì 3:11) Àwọn kan nínú àwọn òjíṣẹ́ Ọlọ́run lónìí ti fi irú ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ bẹ́ẹ̀ hàn nípa fífi iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ wọn sílẹ̀ láti wàásù ìhìn rere ní àwọn ìpínlẹ̀ jíjìnnà réré.—11/1, ojú ìwé 31.

◻ Ìmọ̀ràn tí ń ṣeni láǹfààní wo ni lẹ́tà Jákọ́bù ní?

Ó fi bí a ṣe lè kojú àwọn àdánwò hàn wá, ó gbà wá nímọ̀ràn nípa yíyẹra fún ìṣègbè, ó sì rọ̀ wá láti lọ́wọ́ nínú àwọn iṣẹ́ rere. Jákọ́bù rọ̀ wá láti ṣàkóso ahọ́n wa, láti dènà ipa tí ayé lè ní lórí ẹni, kí a sì gbé àlàáfíà lárugẹ. Àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ tún lè ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ onísùúrù, kí a sì kún fún àdúrà.—11/15, ojú ìwé 24.

◻ Èé ṣe tí Jèhófà fi “múra àtidáríjì”? (Orin Dáfídì 86:5)

Jèhófà ń múra àtidáríjì nítorí pé kì í gbàgbé pé ẹ̀dá erùpẹ̀, tí ó ní àìlera, tàbí ìkù-díẹ̀-káàtó ni wá, gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí àìpé. (Orin Dáfídì 103:12-14)—12/1, ojú ìwé 10, 11.

◻ Èé ṣe tí a fi ní láti ṣe tán láti dárí ji àwọn ẹlòmíràn?

Bí a bá kọ̀ láti dárí ji àwọn ẹlòmíràn nígbà tí ìdí wà fún fífi àánú hàn, ó lè nípa búburú lórí ipò ìbátan wa pẹ̀lú Ọlọ́run. (Mátíù 6:14, 15)—12/1, ojú ìwé 17.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́