ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w98 2/15 ojú ìwé 32
  • Ọlọ́run Yóò Ha Pa Ayé Run Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọlọ́run Yóò Ha Pa Ayé Run Bí?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
w98 2/15 ojú ìwé 32

Ọlọ́run Yóò Ha Pa Ayé Run Bí?

GẸ́GẸ́ bí Póòpù John Paul Kejì ṣe wí, ẹ̀dá ènìyàn lè ní ìdánilójú nípa ọjọ́ ọ̀la. Ó sọ pé, jálẹ̀ ìtàn, “àwọn ènìyàn ń dẹ́ṣẹ̀ nìṣó, bóyá, tí ó tilẹ̀ pọ̀ ju èyí ti a ṣàpèjúwe pé wọ́n dá ṣáájú ìkún omi.” Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, póòpù ṣàlàyé pé, “láti inú ọ̀rọ̀ májẹ̀mú tí Ọlọ́run bá Nóà dá, a mọ̀ pé kò sí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó lè mú kí Ọlọ́run pa ayé tí òun fúnra rẹ̀ ti dá run nísinsìnyí.”

Ṣé òtítọ́ ni pé Ọlọ́run kì yóò pa ayé run nígbà kankan? Bíbélì sọ pé, lẹ́yìn Àkúnya náà, Ọlọ́run sọ fún Nóà pé: “A kì yóò fi àkúnya omi ké gbogbo ẹran ara kúrò mọ́, àkúnya omi kì yóò sì ṣẹlẹ̀ mọ́ láti run ilẹ̀ ayé.” (Jẹ́nẹ́sísì 9:11) Póòpù sọ pé, nípasẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, Ọlọ́run “fi ara rẹ̀ sábẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe láti dáàbò bo [ilẹ̀ ayé] lọ́wọ́ ìparun.”

Bíbélì mú un ṣe kedere pé Ẹlẹ́dàá kì yóò yọ̀ǹda pé kí a pa pílánẹ́ẹ̀tì wa run. Bíbélì wí pé: “Ilẹ̀ ayé dúró àní fún àkókò tí ó lọ kánrin.” (Oníwàásù 1:4) Àmọ́ ẹ̀kọ́ mìíràn ṣì wà láti kọ́ nínú Àkúnya náà—ohun kan tí póòpù kò mẹ́nu bà.

Jésù sọ pé àwọn ipò nǹkan lórí ilẹ̀ ayé nígbà wíwàníhìn-ín òun lọ́jọ́ iwájú yóò rí “gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn ọjọ́ Nóà ti rí,” nígbà tí àwọn ènìyàn “kò . . . fiyè sí i títí ìkún omi fi dé, tí ó sì gbá gbogbo wọn lọ.” (Mátíù 24:37-39) Lọ́nà kan náà, àpọ́sítélì Pétérù kọ̀wé pé, gan-an gẹ́gẹ́ bí ‘ayé ìgbà yẹn ṣe jìyà ìparun nígbà tí a fi àkúnya omi bò ó mọ́lẹ̀,’ náà ni “ọjọ́ ìdájọ́ àti ti ìparun àwọn ènìyàn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run” ṣe ń rọ̀ dẹ̀dẹ̀ sórí ayé ìsinsìnyí.—Pétérù Kejì 3:5-7.

Jésù àti Pétérù ha gbàgbé nípa májẹ̀mú tí Ọlọ́run bá Nóà dá bí? Wọn kò gbàgbé rárá! Gan-an gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti wí nínú májẹ̀mú tí ó bá Nóà dá, òun kì yóò lo ìkún omi láti mú ètò àwọn nǹkan búburú ìsinsìnyí wá sópin. Kàkà bẹ́ẹ̀, òun yóò lo agbára “Ọba àwọn ọba àti Olúwa àwọn olúwa,” Jésù Kristi. (Ìṣípayá [Àpókálíìsì] 19:11-21) Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ti sọ, a kì yóò pa ilẹ̀ ayé run, ṣùgbọ́n, “ayé” ìran ènìyàn oníwà búburú yóò wá sópin dájúdájú. (Òwe 2:21, 22; Ìṣípayá 11:18) Lẹ́yìn náà, “àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.”—Sáàmù 37:29.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́