Ẹ̀mí Ìrẹ̀lẹ̀—Ànímọ́ Tí Ó Wu Jèhófà
ÀÌNÍ ìgbéraga tàbí ẹ̀mí ìjọra-ẹni-lójú; ìrẹ̀lẹ̀ èrò orí. Kì í ṣe àìlera bí kò ṣe ipò èrò inú tí ó wu Jèhófà.
Nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, a fa “ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀” yọ láti inú ọ̀rọ̀ ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà, (ʽa·nahʹ), tí ó túmọ̀ sí “ṣẹ́ níṣẹ̀ẹ́; rẹ̀ sílẹ̀; ni lára.” Àwọn ọ̀rọ̀ tí a fà yọ láti inú ọ̀rọ̀ ìpilẹ̀ṣẹ̀ yìí ni a tú ní onírúurú ọ̀nà sí “ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀,” “ọkàn tútù,” “ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́,” àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Àwọn ọ̀rọ̀ ìṣe Hébérù méjì mìíràn tí ó ní í ṣe pẹ̀lú “ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀” ni ka·naʽʹ (ní ṣangiliti, tẹ [ara ẹni] lórí ba) àti sha·phelʹ (ní ṣangiliti, di ẹni rírẹlẹ̀). Nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, a tú ọ̀rọ̀ náà, ta·pei·no·phro·syʹne, sí “ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀” àti “ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú.” A fà á yọ láti inú ọ̀rọ̀ náà, ta·pei·noʹo, “mu rẹlẹ̀,” àti phren, “èrò inú.”
Ẹnì kan lè ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ nípa ríronú lórí ipò ìbátan rẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run àti àwọn ènìyàn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ti lànà rẹ̀ sílẹ̀, lẹ́yìn náà, kí ó sì lo àwọn ìlànà tí ó kọ́. Ọ̀rọ̀ Hébérù náà, hith·rap·pesʹ, tú “rẹ ara rẹ sílẹ̀,” tí ó túmọ̀ ní ṣangiliti sí, “tẹ ara rẹ mọ́lẹ̀.” Ó ṣàlàyé dáradára ìgbésẹ̀ tí ọlọgbọ́n òǹkọ̀wé ìwé Òwe ṣàpèjúwe pé: “Ọmọ mi, bí ìwọ bá ti lọ ṣe onídùúró fún ọmọnìkejì rẹ, . . . bí àwọn àsọjáde ẹnu rẹ bá ti dẹkùn mú ọ, . . . o ti bọ́ sí àtẹ́lẹwọ́ ọmọnìkejì rẹ: Lọ, rẹ ara rẹ sílẹ̀ [tẹ ara rẹ mọ́lẹ̀], kí o sì bẹ ọmọnìkejì rẹ ní ẹ̀bẹ̀ àbẹ̀ẹ̀dabọ̀. . . . Dá ara rẹ nídè.” (Òwe 6:1-5) Ní ọ̀rọ̀ mìíràn, gbàgbé ìgbéraga, gba àṣìṣe rẹ, yanjú ọ̀ràn, kí o sì tọrọ àforíjì. Jésù ṣíni létí pé kí ènìyàn rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ níwájú Ọlọ́run bí ọmọ kékeré, kí ó sì ṣèránṣẹ́ fún àwọn arákùnrin rẹ̀ tàbí kí ó sìn wọ́n, dípò gbígbìyànjú láti yọrí ọlá.—Mátíù 18:4; 23:12.
Ẹnì kan sì lè kọ́ ìrẹ̀lẹ̀ nípa dídi ẹni tí a rẹ̀ sílẹ̀, tí ìrírí rẹ̀ sílẹ̀. Jèhófà sọ fún Ísírẹ́lì pé òun rẹ̀ wọ́n sílẹ̀ nípa mímú kí wọ́n rìn fún 40 ọdún nínú aginjù, kí ó lè dán wọn wò, kí ó lè mọ ohun tí ń bẹ nínú ọkàn-àyà wọn, kí ó sì mú kí wọ́n mọ̀ pé “ènìyàn kì í tipa oúnjẹ nìkan ṣoṣo wà láàyè, bí kò ṣe nípasẹ̀ gbogbo gbólóhùn ọ̀rọ̀ ẹnu Jèhófà ni ènìyàn fi ń wà láàyè.” (Diutarónómì 8:2, 3) Kò sí iyè méjì pé ọ̀pọ̀ nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jàǹfààní láti inú ìrírí líle koko yìí, wọ́n sì kọ́ ìrẹ̀lẹ̀ láti inú rẹ̀. (Fi wé Léfítíkù 26:41; 2 Kíróníkà 7:14; 12:6, 7.) Bí ẹnì kan tàbí orílẹ̀-èdè kan bá kọ̀ láti rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ tàbí láti gba ìbáwí tí ń rẹni sílẹ̀, irú ẹni bẹ́ẹ̀ yóò tẹ́ bópẹ́bóyá.—Òwe 15:32, 33; Aísáyà 2:11; 5:15.
Ó Wu Ọlọ́run
Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ ní ìníyelórí ńlá lójú Jèhófà. Bí Ọlọ́run kò tilẹ̀ jẹ aráyé ní gbèsè ohunkóhun, nítorí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí, ó ṣe tán láti fi àánú àti ojú rere hàn sí àwọn tí wọ́n ń rẹ ara wọn sílẹ̀ níwájú rẹ̀. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ fi hàn pé àwọn kò gbẹ́kẹ̀ lé ara wọn tàbí yangàn, ṣùgbọ́n wọ́n gbára lé e, wọ́n sì ń fẹ́ láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí Jákọ́bù àti Pétérù, àwọn Kristẹni òǹkọ̀wé tí a mí sí, ti sọ: “Ọlọ́run kọ ojú ìjà sí àwọn onírera, ṣùgbọ́n ó fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí fún àwọn onírẹ̀lẹ̀.”—Jákọ́bù 4:6; 1 Pétérù 5:5.
Àní àwọn tí ó ti hùwà búburú jáì sẹ́yìn pàápàá, bí wọ́n bá rẹ ara wọn sílẹ̀ ní tòótọ́ níwájú Jèhófà, tí wọ́n sì fi taratara bẹ̀ ẹ́ láti ṣíjú àánú wò wọn, òun yóò gbọ́ wọn. Nípa gbígbé ìjọsìn èké lárugẹ ní ilẹ̀ náà, Ọba Mánásè ti Júdà sún àwọn olùgbé Júdà àti Jerúsálẹ́mù dẹ́ṣẹ̀ “láti ṣe ohun tí ó burú ju ti àwọn orílẹ̀-èdè tí Jèhófà pa rẹ́ ráúráú kúrò níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.” Síbẹ̀, lẹ́yìn tí Jèhófà ti jẹ́ kí ọba Asíríà mú un ní ìgbèkùn, Mánásè “ń bá a nìṣó ní rírẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ gidigidi nítorí Ọlọ́run àwọn baba ńlá rẹ̀. Ó sì ń gbàdúrà sí I ṣáá, tí ó fi jẹ́ pé Ó jẹ́ kí ó pàrọwà sí òun, Ó sì gbọ́ ìbéèrè rẹ̀ fún ojú rere, ó sì mú un padà bọ̀ sípò ní Jerúsálẹ́mù sí ipò ọba rẹ̀; Mánásè sì wá mọ̀ pé Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́.” Mánásè tipa báyìí kọ́ ìrẹ̀lẹ̀.—2 Kíróníkà 33:9, 12, 13; fi wé 1 Àwọn Ọba 21:27-29.
Ó Ń Pèsè Ìtọ́sọ́nà Tí Ó Yẹ
Ẹni tí ó bá rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ níwájú Ọlọ́run lè retí àtirí ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run gbà. Ẹ́sírà ní ẹrù iṣẹ́ bàǹtàbanta kan ti ṣíṣamọ̀nà àwọn ọkùnrin tí ó lé ní 1,500, láìka àwọn àlùfáà, àwọn Nétínímù, àti àwọn obìnrin àti ọmọdé, láti Bábílónì sí Jerúsálẹ́mù. Ní àfikún sí i, wọ́n kó wúrà àti fàdákà rẹpẹtẹ dání fún ṣíṣe tẹ́ńpìlì ní Jerúsálẹ́mù lọ́ṣọ̀ọ́. Wọ́n nílò ààbò lórí ìrìn àjò wọn, ṣùgbọ́n Ẹ́sírà kò fẹ́ sọ fún ọba Páṣíà pé kí ó fi àwọn ọmọ ogun tì wọ́n lẹ́yìn, kí ó sì tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé agbára ènìyàn ni òun gbára lé. Yàtọ̀ sí ìyẹn, ó ti sọ fún ọba tẹ́lẹ̀ pé: “Ọwọ́ Ọlọ́run wa ń bẹ lára gbogbo àwọn tí ń wá a fún rere.” Nítorí náà, ó polongo ààwẹ̀, kí àwọn ènìyàn náà lè rẹ ara wọn sílẹ̀ níwájú Jèhófà. Wọ́n gbàdúrà sí Ọlọ́run, ó sì gbọ́ wọn, ó sì dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá tí ó ba dè wọ́n lọ́nà, débi pé wọ́n parí ìrìn àjò eléwu náà láìséwu. (Ẹ́sírà 8:1-14, 21-32) Nítorí tí wòlíì Dáníẹ́lì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ níwájú Ọlọ́run nínú wíwá ìtọ́sọ́nà àti òye kiri, Ọlọ́run fi ojú rere ńláǹlà hàn sí i ní ìgbèkùn ní Bábílónì, nípa fífi ìran kan rán áńgẹ́lì sí i.—Dáníẹ́lì 10:12.
Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ yóò ṣamọ̀nà ẹnì kan sí ọ̀nà tí ó yẹ, yóò sì mú un wá sínú ògo, nítorí Ọlọ́run ní ń gbé ẹnì kan ga, tí sì í rẹ ẹlòmíràn wálẹ̀. (Sáàmù 75:7) “Ṣáájú ìfọ́yángá, ọkàn-àyà ènìyàn a ga fíofío, ìrẹ̀lẹ̀ sì ni ó máa ń ṣáájú ògo.” (Òwe 18:12; 22:4) Nítorí náà, ẹni tí ń wá ògo nípa ìrera yóò ṣubú, gẹ́gẹ́ bí Ọba Ùsáyà ti Júdà, tí ó di oníkùgbù, tí ó sì gba ojúṣe àwọn àlùfáà ṣe láìbófin mu: “Gbàrà tí ó di alágbára, ọkàn-àyà rẹ̀ di onírera àní títí dé àyè tí ń fa ìparun, tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi ṣe àìṣòótọ́ sí Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀, tí ó sì wá sínú tẹ́ńpìlì Jèhófà láti sun tùràrí lórí pẹpẹ tùràrí.” Nígbà tí ó kún fún ìhónú sí àwọn àlùfáà fún títún ojú ìwòye rẹ̀ ṣe, ẹ̀tẹ̀ yọ sí i lára. (2 Kíróníkà 26:16-21) Àìní ìrẹ̀lẹ̀ ṣi Ùsáyà lọ́nà, sí ìṣubú rẹ̀.
Ó Ń Ranni Lọ́wọ́ Nígbà Ìpọ́njú
Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ lè ran ẹnì kan lọ́wọ́ gidigidi nínú kíkojú ìpèníjà tí ìpọ́njú ń mú wá. Bí àjálù bá ṣẹlẹ̀, ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ yóò ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti má bara jẹ́, kí ó sì fara dà á, kí ó sì máa bá iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ sí Ọlọ́run nìṣó. Ọba Dáfídì dojú kọ ọ̀pọ̀ ìpọ́njú. Ọba Sọ́ọ̀lù ń ṣọdẹ rẹ̀ kiri bí ìgárá. Ṣùgbọ́n, kò fìgbà kan rí ṣàròyé nípa Ọlọ́run tàbí kí ó gbé ara rẹ̀ ga ju ẹni àmì òróró Jèhófà. (1 Sámúẹ́lì 26:9, 11, 23) Nígbà tí ó dẹ́ṣẹ̀ sí Jèhófà ní ti panṣágà tí ó ṣe pẹ̀lú Bátí-ṣébà, tí Nátánì wòlíì Ọlọ́run sì bá a wí gidigidi, ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ níwájú Ọlọ́run. (2 Sámúẹ́lì 12:9-23) Lẹ́yìn náà, nígbà tí ọmọ ìran Bẹ́ńjámínì kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ṣíméì bẹ̀rẹ̀ sí í pe ibi wá sórí Dáfídì ní gbangba, tí Ábíṣáì, ọmọ ogun Dáfídì, sì fẹ́ láti pa ọkùnrin náà fún rírí ọba fín, Dáfídì fi ìrẹ̀lẹ̀ hàn. Ó dá Ábíṣáì lóhùn pé: “Kíyè sí i, ọmọkùnrin mi, ẹni tí ó jáde wá láti ìhà inú mi, ń wá ọkàn mi; mélòómélòó nísinsìnyí ni ọmọ Bẹ́ńjámínì kan! . . . Bóyá Jèhófà yóò fi ojú rẹ̀ rí i, ní ti tòótọ́, Jèhófà yóò sì mú ire padà bọ̀ sípò fún mi dípò ìfiré rẹ̀ lónìí yìí.” (2 Sámúẹ́lì 16:5-13) Lẹ́yìn náà, Dáfídì ka iye àwọn ènìyàn náà ní ìlòdì sí ìfẹ́ Jèhófà. Àkọsílẹ̀ náà kà pé: “Ọkàn-àyà Dáfídì sì bẹ̀rẹ̀ sí nà án lẹ́yìn tí ó ti ka iye àwọn ènìyàn náà. Nítorí náà, Dáfídì sọ fún Jèhófà pé: ‘Mo ti ṣẹ̀ gidigidi nínú ohun tí mo ti ṣe. . . . mo ti hùwà òmùgọ̀ gan-an.’” (2 Sámúẹ́lì 24:1, 10) Bí a tilẹ̀ jẹ ẹ́ níyà, a kò ṣí Dáfídì ládé; ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ rẹ̀ kó ipa ńlá nínú pípadà jèrè ojú rere Jèhófà.