Báwo Lo Ṣe Lè Dáàbò Bo Àwọn Ọmọ Rẹ?
LẸ́YÌN tí Wernera lọ sí ilé ìwé kan ládùúgbò fún ọ̀pọ̀ ọdún, ó tẹ̀ síwájú sí ilé ìwé gíga pẹ̀lú 3,000 àwọn ọ̀dọ́ mìíràn ní ìlú São Paulo, Brazil. Fún ìgbà àkọ́kọ́, ó rí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ tí ń ta oògùn líle, tí wọ́n sì ń lò ó. Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ ẹni rírán, kò pẹ́ tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí ó jù ú lọ sọ ọ́ di ẹran ọdẹ àwọn ààtò ẹlẹ́gbin àti eléwu tí wọ́n fi ń múni wẹgbẹ́.
Eva àbúrò Werner pẹ̀lú níṣòro. Bí ó ti ń fẹ́ láti ṣàṣeyege, ó bẹ̀rẹ̀ sí kàwé àkàkúdórógbó, tó fi wá di pé agara dá a, orí rẹ̀ sì fẹ́rẹ̀ẹ́ dà rú. Bí àwọn ọ̀dọ́ tó kù, Werner àti Eva nílò ààbò nípa tara àti ti ìmọ̀lára. Irú ìrànlọ́wọ́ wo ni àwọn ọmọ rẹ nílò? Báwo lo ṣe lè múra wọn sílẹ̀ fún ìgbé-ayé àgbàlagbà? Àní, irú ọjọ́ ọ̀la wo lo fẹ́ fún àwọn ọmọ rẹ?
Ohun Ìgbẹ́mìíró Nìkan Kọ́ Ni Wọ́n Nílò
Ronú fún ìṣẹ́jú kan nípa òkè ìṣòro tí àwọn òbí dojú kọ nípa dídáàbòbo àwọn ọmọ wọn lónìí. Nítorí ipò ìdílé tí ń burú sí i àti ipò òṣì tí ń peléke sí i, ṣe ni àwọn ọmọ asùnta ń pọ̀ sí i ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀. Àwọn ògo wẹẹrẹ aṣiṣẹ́gbowó jẹ́ ìyọrísí ìkùnà láti dáàbò bo àwọn ọ̀dọ́mọdé lọ́wọ́ ìkóninífà. Ìjoògùnyó tún máa ń ba ayé ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́mọdé jẹ́. Fún àpẹẹrẹ, nígbà tí ọ̀dọ́langba ará Brazil kan di ajoògùnyó, àlàáfíà pòórá nínú ilé wọn. Yàtọ̀ sí àìrójú-ráyè tó bá àwọn òbí rẹ̀, àtirówó tọ́jú rẹ̀ di ẹtì, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn oníṣòwò oògùn olóró tí wọn kò lójú àánú ń wá sílé wọn láti wá sìn wọ́n lówó.
Bó ti wù kí ó rí, láìka hílàhílo ìgbésí ayé sí, ọ̀pọ̀ òbí ń bá a lọ ní títiraka, kì í ṣe láti pèsè kìkì oúnjẹ, aṣọ, àti ibùgbé nìkan, ṣùgbọ́n wọ́n tún ń pèsè ààbò fún àwọn ọmọ wọn kúrò lọ́wọ́ ìwà ipá, ìjoògùnyó, àti àwọn ìṣòro mìíràn. Èyí jẹ́ ìsapá wíwúnilórí, ṣùgbọ́n ǹjẹ́ ó tó? Ààbò lọ́wọ́ ọṣẹ́ ti èrò ìmọ̀lára àti tẹ̀mí ńkọ́? Ọ̀pọ̀ ló mọ̀ pé kíkógo já nínú ọmọ títọ́ wé mọ́ bíborí àwọn òkè ìṣòro bíi irú ọ̀rẹ́ tí ọmọ wọn ń bá rìn àti irú eré ìnàjú tí wọ́n ń ṣe. Àmọ́ ṣá o, báwo ni àwọn òbí ṣe lè jẹ́ kí àwọn ọmọ wọ́n rímú mí, síbẹ̀ kí wọ́n má gba ìgbàkugbà? Dákun, gbé àwọn ìdáhùn tí ó wà nínú àpilẹ̀kọ tí ó tẹ̀ lé e yìí yẹ̀ wò.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A lo àwọn orúkọ àfirọ́pò nínú àpilẹ̀kọ yìí.