Kí Ni Ìdí Kan Ṣoṣo Tí Ìwé Mímọ́ Fara Mọ́, Tí Ìkọ̀sílẹ̀ Fi Lè Wáyé Láàárín Àwọn Kristẹni?
NÍNÚ Ìwàásù Jésù Kristi Lórí Òkè, ó wí pé: “Síwájú sí i, a sọ ọ́ pé, ‘Ẹnì yòówù tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀, kí ó fún un ní ìwé ẹ̀rí ìkọ̀sílẹ̀.’ Bí ó ti wù kí ó rí, mo wí fún yín pé olúkúlùkù ẹni tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀, bí kò ṣe ní tìtorí àgbèrè, sọ ọ́ di olùdojúkọ ewu panṣágà, ẹnì yòówù tí ó bá sì gbé obìnrin tí a kọ̀ sílẹ̀ níyàwó, ṣe panṣágà.” (Mátíù 5:31, 32) Bákan náà, lẹ́yìn tí Jésù ti jẹ́ kó yé àwọn Farisí pé, gbígbà tí Mósè gbà fún wọn pé, wọ́n lè kọ aya wọn sílẹ̀, kò rí bẹ́ẹ̀ “láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀,” ó wí pé: “Mo wí fún yín pé ẹnì yòówù tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀, bí kò ṣe lórí ìpìlẹ̀ àgbèrè, tí ó sì gbé òmíràn níyàwó, ṣe panṣágà.” (Mátíù 19:8, 9) Lónìí, ní gbogbo gbòò, a máa ń fìyàtọ̀ sáàárín “àwọn àgbèrè” àti “àwọn panṣágà.” Gẹ́gẹ́ bí a ṣe ń lò ó lóde òní, àwọn tí wọ́n ń jẹ̀bi ẹ̀sùn àgbèrè ni àwọn tí kò tíì ṣègbéyàwó, tí wọ́n sì dìídì ń ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹnì kan tó jẹ́ ẹ̀yà òdìkejì. Àwọn panṣágà sì ni àwọn tí wọ́n ti ṣègbéyàwó tí wọ́n dìídì ń ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹnì kan tó jẹ́ ẹ̀yà òdìkejì, àmọ́ tí kì í ṣe ọkọ tàbí aya wọn. Àmọ́ ṣá o, ọ̀rọ̀ náà, “àgbèrè,” jẹ́ ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ èdè Gíríìkì náà, por·neiʹa, ó sì jẹ́ àkópọ̀ gbogbo oríṣi ìbálòpọ̀ tí kò tọ́, tí ó lè wáyé lẹ́yìn òde ìgbéyàwó tó bá Ìwé Mímọ́ mu. Nítorí náà, ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ nínú Mátíù 5:32 àti Mátíù 19:9 ni pé, ohun kan ṣoṣo tó lè mú kí ìkọ̀sílẹ̀ já ìdè ìgbéyàwó ni bí ọ̀kan lára àwọn tọkọtaya náà bá jẹ̀bi ẹ̀sùn por·neiʹa. Ẹnì kan tó jẹ́ ọmọlẹ́yìn Kristi lè lo irú ẹ̀tọ́ ìkọ̀sílẹ̀ bẹ́ẹ̀ tí ó ní, ìyẹn bó bá fẹ́ bẹ́ẹ̀ o, irú ìkọ̀sílẹ̀ bẹ́ẹ̀ yóò sì mú kí ó lómìnira láti fẹ́ Kristẹni mìíràn tó tóótun.—1 Kọ́ríńtì 7:39.
Bí ẹnì kan tó ti ṣègbéyàwó bá wá lọ ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹni tí wọ́n jọ jẹ́ ẹ̀yà kan náà (ìbẹ́yà-kannáà-lòpọ̀), èyí burú jáì, ó sì kóni nírìíra. Ẹnikẹ́ni tó bá hu irú ìwà yìí, tí kò sì ronú pìwà dà, kò lè jogún Ìjọba Ọlọ́run. Bákan náà pẹ̀lú, Ìwé Mímọ́ dẹ́bi fún ìwà ìbẹ́ranko-lòpọ̀. (Léfítíkù 18:22, 23; Róòmù 1:24-27; 1 Kọ́ríńtì 6:9, 10) Àwọn ìwà burúkú bùrùjà wọ̀nyí wà lára ohun tí a pè ní por·neiʹa. Ó tún yẹ fún àfiyèsí pé, lábẹ́ Òfin Mósè, ẹjọ́ ikú ní a ń dá fún ẹnikẹ́ni tó bá lọ́wọ́ nínú ìwà ìbẹ́yà-kannáà-lòpọ̀ àti ìbẹ́ranko-lòpọ̀, èyí sì jẹ́ kí ọkọ tàbí aya tí kò mọwọ́ mẹsẹ̀ nínú ọ̀ràn náà lómìnira ṣíṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú ẹlòmíràn.—Léfítíkù 20:13, 15, 16.
Jésù Kristi mẹ́nu kàn án pé “olúkúlùkù ẹni tí ń bá a nìṣó ní wíwo obìnrin kan láti ní ìfẹ́ onígbòónára sí i, ti ṣe panṣágà pẹ̀lú rẹ̀ ná nínú ọkàn-àyà rẹ̀.” (Mátíù 5:28) Àmọ́ ṣá o, Jésù kò sọ pé a wá lè tìtorí ohun tó wà nínú ọkàn-àyà, tí a kò tíì hù níwà, jáwèé ìkọ̀sílẹ̀ fúnni. Àwọn ọ̀rọ̀ Kristi fi hàn pé ó yẹ kí a jẹ́ kí ọkàn-àyà wa mọ́, kí a máà sì fàyè gba ìròkurò àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́.—Fílípì 4:8; Jákọ́bù 1:14, 15.
Òfin àwọn Rábì tí àwọn Júù ń tẹ̀ lé tẹnu mọ́ ọn pé dandan ni fún tọkọtaya láti máa ṣe ojúṣe lọ́kọláya fún ara wọn, ó sì yọ̀ǹda fún ọkọ láti kọ aya rẹ̀ sílẹ̀ bí aya náà kò bá bímọ. Àmọ́ ṣá o, Ìwé Mímọ́ kò fún àwọn Kristẹni lẹ́tọ̀ọ́ láti kọ aya tàbí ọkọ wọn sílẹ̀ nítorí irú ìdí bẹ́ẹ̀. Nígbà tí Sárà yàgàn fún ọ̀pọ̀ ọdún, ìyẹn kò mú kí Ábúráhámù kọ ọ́ sílẹ̀, ìgbà tí Rèbékà yàgàn Ísákì kò torí bẹ́ẹ̀ kọ̀ ọ́, Jékọ́bù pẹ̀lú kò kọ Rákélì nítorí pé ó yàgàn, bẹ́ẹ̀ sì ni àlùfáà Sekaráyà kò tìtorí pé Èlísábẹ́tì yàgàn kó wá kọ̀ ọ́ sílẹ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 11:30; 17:17; 25:19-26; 29:31; 30:1, 2, 22-25; Lúùkù 1:5-7, 18, 24, 57.
Kò sí ọ̀rọ̀ kankan nínú Ìwé Mímọ́ tó yọ̀ǹda fún Kristẹni kan láti kọ ẹni tó ti fẹ́ sílẹ̀ nítorí pé onítọ̀hún kò lè ṣe ìṣe lọ́kọláya, tàbí torí pé ẹni tó fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí sínwín tàbí nítorí pé ó kó àrùn tí kò gbóògùn tàbí tó kóni nírìíra. Ìfẹ́ tí a béèrè pé kí àwọn Kristẹni fi hàn yóò sún ọkọ tàbí aya náà láti fi àánú bá ẹni tó ti fẹ́ lò, kì í ṣe pé kó kọ̀ ọ́ sílẹ̀. (Éfésù 5:28-31) Bákan náà pẹ̀lú, Bíbélì kò fún àwọn Kristẹni lẹ́tọ̀ọ́ láti kọ ẹni tí wọ́n ti fẹ́ sílẹ̀ nítorí pé ẹ̀sìn wọn kò bára mu; kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó sọ ni pé bí Kristẹni kan bá ń gbé pẹ̀lú ọkọ tàbí aya tó jẹ́ aláìgbàgbọ́, ó lè jèrè irú ẹni bẹ́ẹ̀ sínú ìgbàgbọ́ tòótọ́.—1 Kọ́ríńtì 7:12-16; 1 Pétérù 3:1-7.
Nínú Ìwàásù rẹ̀ Lórí Òkè, Jésù wí pé “ẹni tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀, bí kò ṣe ní tìtorí àgbèrè, sọ ọ́ di olùdojúkọ ewu panṣágà, ẹnì yòówù tí ó bá sì gbé obìnrin tí a kọ̀ sílẹ̀ níyàwó, ṣe panṣágà.” (Mátíù 5:32) Nípa èyí, Kristi fi hàn pé bí ọkùnrin kan bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀ fún ìdí mìíràn tó yàtọ̀ sí “àgbèrè” (por·neiʹa), ṣe ni irú ọkọ bẹ́ẹ̀ ń ti aya rẹ̀ láti ṣe panṣágà ní ọjọ́ iwájú. Ìyẹn rí bẹ́ẹ̀ nítorí pé irú ìkọ̀sílẹ̀ bẹ́ẹ̀ kò pín aya tí kò ṣe panṣágà náà níyà kúrò lọ́dọ̀ ọkọ rẹ̀ lọ́nà tí ó tọ́, kò sì fún un lómìnira láti fẹ́ ọkùnrin mìíràn, kí ó sì máa ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ọkọ mìíràn. Nígbà tí Kristi wí pé ẹnikẹ́ni “tí ó bá . . . gbé obìnrin tí a kọ sílẹ̀ níyàwó, ṣe panṣágà,” obìnrin tí a kọ̀ sílẹ̀ fún ìdí mìíràn tó yàtọ̀ sí “àgbèrè” (por·neiʹa) ló ní lọ́kàn. Irú obìnrin bẹ́ẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé lábẹ́ òfin, a ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀, ṣùgbọ́n, lójú ìwòye Ìwé Mímọ́, a kò tíì kọ̀ ọ́ sílẹ̀.
Gẹ́gẹ́ bíi ti Mátíù, Máàkù ṣàkọsílẹ̀ ọ̀rọ̀ tí Jésù bá àwọn Farisí sọ nípa ìkọ̀sílẹ̀, ó sì fa ọ̀rọ̀ Kristi yọ ní sísọ pé: “Ẹnì yòówù tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀, tí ó sì gbé òmíràn níyàwó ṣe panṣágà lòdì sí i, bí obìnrin kan, lẹ́yìn kíkọ ọkọ rẹ̀ sílẹ̀, bá sì ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú òmíràn pẹ́nrẹ́n, ó ṣe panṣágà.” (Máàkù 10:11, 12; Mátíù 19:3-9) Gbólóhùn kan náà yìí wà nínú Lúùkù 16:18, èyí tó kà pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀, tí ó sì gbé òmíràn níyàwó ṣe panṣágà, ẹni tí ó bá sì gbé obìnrin tí ọkọ kan kọ̀ sílẹ̀ níyàwó ṣe panṣágà.” Bí a bá gbé gbólóhùn yìí nìkan ṣoṣo yẹ̀ wò, ó jọ pé ẹsẹ wọ̀nyí ń ka gbogbo ìkọ̀sílẹ̀ léèwọ̀ fún àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi, tàbí ó kéré tán, ó ń sọ pé ẹnì kan tí a kọ̀ sílẹ̀ tàbí tí ó kọni sílẹ̀ kò ní lẹ́tọ̀ọ́ láti fẹ́ ẹlòmíràn àyàfi lẹ́yìn tí ẹni tó kọ̀ sílẹ̀ tàbí ẹni tí a kọ̀ sílẹ̀ bá kú. Àmọ́ ṣá o, a gbọ́dọ̀ lo ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ gbólóhùn mìíràn tí Mátíù ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ láti lè lóye àwọn ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ tí Máàkù àti Lúùkù kọ sílẹ̀. Mátíù fi àpólà ọ̀rọ̀ náà “bí kò ṣe lórí ìpìlẹ̀ àgbèrè” kún tirẹ̀, èyí fi hàn pé àkọsílẹ̀ Máàkù àti Lúùkù, tó ṣàyọlò ọ̀rọ̀ Jésù lórí ìkọ̀sílẹ̀ kan ọ̀ràn tó jẹ́ pé, kì í ṣe “àgbèrè” (por·neiʹa) ni ọkọ tàbí aya tó jẹ́ aláìṣòótọ́ náà ṣe táa fi kọ̀ ọ́ sílẹ̀.—Mátíù 19:9; tún wo Mátíù 5:32.
Àmọ́ ṣá o, Ìwé Mímọ́ kò sọ pé ó pọndandan kí ẹnì kan kọ ọkọ tàbí aya rẹ̀ tó ṣe panṣágà sílẹ̀, bí onítọ̀hún bá ronú pìwà dà. Kristẹni ọkọ tàbí aya lè nawọ́ àánú síni nínú irú ọ̀ràn bẹ́ẹ̀, àní gẹ́gẹ́ bí ó ṣe jọ pé Hóséà gba Gómérì, aya rẹ̀, tó ṣe panṣágà padà, àti bí Jèhófà ṣe nawọ́ àánú sí Ísírẹ́lì tó ronú pìwà dà, tó ti jẹ̀bi panṣágà nípa tẹ̀mí.—Hóséà orí 3.
A Mú Ọ̀pá Ìdiwọ̀n Ọlọ́run Ní Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ Padà Bọ̀ Sípò
Ó ṣe kedere pé gbólóhùn Jésù Kristi ń tọ́ka sí pípadà sí ọ̀pá ìdiwọ̀n gíga tí Jèhófà Ọlọ́run ti gbé kalẹ̀ fún ìgbéyàwó ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀, ó sì fi hàn pé àwọn tó bá fẹ́ di ọmọlẹ́yìn Jésù ní láti fara mọ́ ọ̀pá ìdiwọ̀n gíga yẹn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Òfin Mósè ṣì gbà fún wọn, síbẹ̀ àwọn tí yóò jẹ́ ọmọlẹ́yìn tòótọ́ fún Jésù, tí wọ́n ń ṣe ìfẹ́ Baba rẹ̀, tí wọ́n ‘ń tẹ̀ lé’ àwọn ọ̀rọ̀ Jésù, kò ní sọ pé torí pé wọ́n gbà fàwọn, fún ìdí yìí àwọn ṣì lè fi ‘ọkàn líle’ bá ọkọ tàbí aya wọn lò. (Mátíù 7:21-29; 19:8) Gẹ́gẹ́ bí ojúlówó ọmọlẹ́yìn, wọn kò ní rú àwọn ìlànà Ọlọ́run tó ń darí ìgbéyàwó nípa kíkọ ọkọ tàbí aya wọn sílẹ̀ lórí ìdí èyíkéyìí ju èyí tí Jésù mẹ́nu kàn pàtó, ìyẹn ni “àgbèrè” (por·neiʹa).
Àpọ́n kan tó lọ ṣe àgbèrè pẹ̀lú aṣẹ́wó ti sọ ara rẹ̀ di “ara kan” pẹ̀lú onítọ̀hún. Bákan náà, panṣágà náà sọ ara rẹ̀ di “ara kan” pẹ̀lú oníṣekúṣe tó bá lò pọ̀, kì í ṣe pẹ̀lú aya rẹ̀ tó fẹ́ sílé. Nípa báyìí, panṣágà náà kò ṣẹ̀ sí ara rẹ̀ nìkan, ṣùgbọ́n ó tún ṣẹ̀ sí ara aya rẹ̀ tó fẹ́ sílé, ẹni tó ṣì jẹ́ “ara kan” pẹ̀lú ọkọ rẹ̀, títí di ìgbà tí ọ̀ràn yẹn ṣẹlẹ̀. (1 Kọ́ríńtì 6:16-18) Nítorí ìdí èyí, panṣágà mú kí ìdí tòótọ́ wà fún títú ìdè ìgbéyàwó ká ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà Ọlọ́run, ibi tí irú ìdí bẹ́ẹ̀ bá sì ti wà, ìwé ìkọ̀sílẹ̀ tí ẹnì kan bá já ti tú ìdè ìgbéyàwó náà ká pátápátá lábẹ́ òfin, ó sì fún ọkọ tàbí aya tí kò mọwọ́ mẹsẹ̀ nínú ọ̀ràn náà ní òmìnira láti fẹ́ ẹlòmíràn pẹ̀lú ọlá.—Hébérù 13:4.