ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w99 3/15 ojú ìwé 26-28
  • Rashi—Ògúnnágbòǹgbò Alálàyé Bíbélì

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Rashi—Ògúnnágbòǹgbò Alálàyé Bíbélì
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ta Ni Rashi?
  • Èé Ṣe Táa Fi Nílò Ìwé Àlàyé?
  • Góńgó Rashi àti Ọ̀nà Tó Gbà
  • Ipò Nǹkan Nígbà Ayé Rẹ̀ Nípa Lórí Rẹ̀
  • Báwo Ló Ṣe Wá Jẹ́ Ògúnnágbòǹgbò Nínú Títúmọ̀ Bíbélì?
  • Ta ni Ó Tọ́ Kí A Pè ní Rábì?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Kí Ni Ìwé Àwọn Masorete?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Ṣó Pọn Dandan Kó O Kọ́ Èdè Hébérù àti Gíríìkì?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Ìtumọ̀ Bíbélì Tí Ó Yí Ayé Padà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
w99 3/15 ojú ìwé 26-28

Rashi—Ògúnnágbòǹgbò Alálàyé Bíbélì

ÌWÉ wo ló jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìwé táa kọ́kọ́ tẹ̀ jáde lédè Hébérù lórí ẹ̀rọ ìtẹ̀wé? Ìwé àlàyé lórí Pentateuch (ìwé márùn-ún tí Mósè kọ) ni. A tẹ̀ ẹ́ jáde nílùú Reggio Calabria, ní Ítálì, lọ́dún 1475. Ta ló ṣèwé náà? Ọkùnrin kan táa mọ̀ sí Rashi ni.

Kí ló fà á tí ìwé alálàyé kan fi rí àpọ́nlé tó ga tó báyìí gbà? Nínú ìwé rẹ̀, Rashi—The Man and His World, Esra Shereshevsky sọ pé ìwé àlàyé tí Rashi ṣe jáde “di ìwé pàtàkì nínú ilé àwọn Júù àti ní ilé ẹ̀kọ́ àgbà wọn. Kò sí ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ àwọn Júù táa gbé gẹ̀gẹ̀ tó báyìí rí . . . Àwọn ìwé aṣàtúpalẹ̀ tí a mọ̀ tó sọ̀rọ̀ nípa àlàyé Rashi lórí Pentateuch lé ní igba.”

Ṣé àwọn Júù nìkan ni àlàyé Rashi nípa lé lórí ni? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ kò mọ̀, àlàyé Rashi lórí Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù ti nípa lórí ìtumọ̀ Bíbélì fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún. Ṣùgbọ́n ta ni Rashi, báwo ló sì ṣe wá di ògúnnágbòǹgbò?

Ta Ni Rashi?

A bí Rashi ní Troyes, ní ilẹ̀ Faransé, ní ọdún 1040.a Gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́mọkùnrin, ó kàwé nílé ẹ̀kọ́ àwọn Júù tó wà ní Worms àti èyí tó wà ní Mainz ní Rhineland. Níbẹ̀ ló ti kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ àwọn Júù ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ tó gbajúmọ̀ jù lọ ní Yúróòpù. Nígbà tó wà ní nǹkan bí ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n, àwọn ipò tó yí i ká mú kó pọndandan fún un láti padà sí Troyes. Nítorí tí a ti mọ̀ ọ́n sí ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ tó tayọ, kíá ni Rashi di olórí ẹ̀sìn láwùjọ Júù tó wà ládùúgbò náà, ó sì dá ilé ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn tirẹ̀ sílẹ̀. Kò pẹ́ púpọ̀, ibùdó ẹ̀kọ́ àwọn Júù tuntun yìí di èyí tó tún wá lágbára ju èyí táwọn olùkọ́ Rashi dá sílẹ̀ ní Germany.

Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, àárín àwọn Júù tó wà nílẹ̀ Faransé àti àwọn aládùúgbò wọn tí wọ́n sọ pé Kristẹni làwọn gún, wọ́n sì ń ṣe nǹkan pọ̀, èyí ló fún Rashi lómìnira láti lépa ìmọ̀ ẹ̀kọ́ rẹ̀. Síbẹ̀, kì í ṣe ọ̀mọ̀wé tí kì í bẹ́gbẹ́ ṣe. Láìka ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ sí, tó sì tún jẹ́ olórí ilé ẹ̀kọ́ kan, Rashi tún ń pọn wáìnì tà. Ìmọ̀ tó ní nípa òwò tó jẹ́ ti gbáàtúù yìí jẹ́ kó ní ìfararora pẹ̀lú àwọn Júù tó jẹ́ mẹ̀kúnnù, ó ń ràn án lọ́wọ́ láti lóye ipò wọn, kí ó sì bá wọn kẹ́dùn. Ibi tí ìlú Troyes pàápàá wà tún fi kún òye jíjinlẹ̀ tí Rashi ní. Níwọ̀n bí ìlú ńlá náà ti wà ní ọ̀nà tí àwọn oníṣòwò sábà ń gbà, ó wá di ìlú gbogbo ayé, èyí ló ran Rashi lọ́wọ́ láti mọ ìṣesí àti àṣà onírúurú orílẹ̀-èdè.

Èé Ṣe Táa Fi Nílò Ìwé Àlàyé?

A mọ àwọn Júù sí àwọn tó ni ìwé náà. Ṣùgbọ́n èdè Hébérù ni a fi kọ “ìwé náà”, Bíbélì, ‘àwọn èèyàn náà’ sì wá ń sọ èdè Faransé, German, Lárúbáwá, Spanish, àti ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ èdè mìíràn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé láti kékeré ni a ti ń kọ́ ọ̀pọ̀ Júù ní èdè Hébérù, wọn kò lóye àwọn èdè táa fi kọ Bíbélì dáadáa. Ní àfikún sí i, fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún, ẹ̀kọ́ tí àwọn rábì ń rọ́ sí àwọn èèyàn lágbárí nípa ẹ̀sìn àwọn Júù mú kí wọn pa wíwá ìtumọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì tì. Ìtàn olówe àti ìtàn àtẹnudẹ́nu tó tan mọ́ àwọn ọ̀rọ̀ àti ẹsẹ inú Bíbélì wá pọ̀ súà. Ọ̀pọ̀ irú àlàyé àti ìtàn bẹ́ẹ̀ ni a kó jọ sínú àwọn ìwé bàǹbà-bàǹbà, tí a pe àpapọ̀ rẹ̀ ní Midrash.b

Ọmọ ọmọ Rashi, Rabbi Samuel ben Meir (Rashbam), pẹ̀lú jẹ́ ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀. Nínú àlàyé tó ṣe lórí Jẹ́nẹ́sísì 37:2, ó wí pé “àwọn alálàyé tó ti wà ṣáájú [ìyẹn ni ṣáájú Rashi] . . . fẹ́ràn àtimáa wàásù (derashot), èyí tí wọn kà sí ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ, [ṣùgbọ́n] kò mọ́ wọn lára láti máa wádìí ìtumọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì.” Nígbà tó ń ṣàlàyé lórí ìwà yìí, Ọ̀mọ̀wé A. Cohen (olóòtú àgbà fún Soncino Books of the Bible) kọ̀wé pé: “Òótọ́ ni pé àwọn Rábì fòfin lélẹ̀ pé kò sẹ́ni tó gbọ́dọ̀ gba ìtumọ̀ kan gbọ́ bí kò bá ti bá ti peshat mu tàbí tí kò bá ìtumọ̀ olówuuru mu bó ti wà nínú ẹsẹ náà gan-an; àmọ́ wọn kàn sọ ọ́ lẹ́nu lásán ni wọn kò ka òfin yìí sí.” Ní ti bí ọ̀ràn ẹ̀sìn ṣe wá rí yìí, bí Júù kan bá ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, ó ṣòro fún un láti lóye rẹ̀, èyí sì mú kó nílò ohun kan tí yóò lè ṣàlàyé ọ̀rọ̀ náà fún un.

Góńgó Rashi àti Ọ̀nà Tó Gbà

Góńgó Rashi tipẹ́tipẹ́ ni láti mú kí ẹsẹ Bíbélì yé gbogbo Júù. Láti lè lé góńgó yìí bá, ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣàkójọ àwọn ìwé tó wà lórí àlàyé àwọn ọ̀rọ̀ àti ẹsẹ kan pàtó, tó rí i pé yóò ṣòro fún òǹkàwé láti lóye. Àkọsílẹ̀ Rashi mẹ́nu kan àlàyé àwọn olùkọ́ rẹ̀, ó sì tún fa ọ̀rọ̀ yọ láti inú àká ìmọ̀ tó ní nípa ọ̀wọ́ àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ àwọn rábì. Nígbà tó ń ṣèwádìí nípa èdè, gbogbo ìsọfúnni tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó ni Rashi lò. Ó kíyè sí bí lílo àmì ìdánudúró àti àmì ohùn tí àwọn Masorete lò ṣe nípa lórí lílóye ìwé náà. Kó lè fọ́ ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ kan sí wẹ́wẹ́, àlàyé rẹ̀ lórí Pentateuch sábà máa ń tọ́ka sí ìtumọ̀ ti èdè Árámáíkì (Ìtumọ̀ tí Onkelos ṣe). Nígbà tí Rashi ń ṣàyẹ̀wò àwọn ohun tó ṣeé ṣe, ṣùgbọ́n, tí àwọn èèyàn kò fìgbà kan gbé yẹ̀ wò rí, ọ̀nà tó gbà ṣàlàyé àwọn ọ̀rọ̀ atọ́kùn, àwọn ọ̀rọ̀ àsopọ̀, ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ ìṣe, àti àwọn apá mìíràn nínú gírámà àti ìṣètò ọ̀rọ̀ nínú èdè náà fi hàn pé kì í rinkinkin àti pé ó lóye ìlò ọ̀rọ̀ èdè náà dáadáa. Irú àwọn àlàyé bẹ́ẹ̀ kó ipa pàtàkì ní mímú kí àwọn èèyàn lè lóye ìlò ọ̀rọ̀ àti gírámà èdè Hébérù.

Ní ìyàtọ̀ sí ẹ̀mí tó gbòde kan tí àwọn rábí tàn kálẹ̀ nípa ẹ̀sìn àwọn Júù, Rashi sábà máa ń tẹnu mọ́ ìtumọ̀ àláìlábùlà tó rọrùn, tí ẹsẹ kan bá ní. Àmọ́ ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ìwé Midrash tí àwọn Júù mọ̀ bí ẹní mowó, kò ṣeé pa tì. Apá títayọ nínú ìwé àlàyé Rashi ni ọ̀nà tó gbà tọ́ka sí àwọn ìwé Midrash gan-an, àwọn ìwé tí wọ́n ti fìgbà gbogbo fi ìtumọ̀ aláìlábùlà ti àwọn ẹsẹ Bíbélì pa mọ́.

Nínú àlàyé rẹ̀ lórí Jẹ́nẹ́sísì 3:8, Rashi ṣàlàyé pé: “Ọ̀pọ̀ ìwé Midrash alálàyé ni àwọn Amòye wa ti kó jọ dáadáa sínú Bereshit Rabbah àti àwọn ìwé ìtàn mìíràn. Ní tèmi o, ìtumọ̀ tó ṣe tààrà (peshat) tí a fún àwọn ẹsẹ náà nìkan, àti irú àlàyé tí a ṣe ní ìbámu pẹ̀lú àyíká ọ̀rọ̀ inú ẹsẹ Ìwé Mímọ́, ló jẹ mí lógún.” Nípa ṣíṣe àṣàyàn àwọn ìwé Midrash tí òun gbà pé ó yanjú ìtumọ̀ tàbí àyíká ọ̀rọ̀ ẹsẹ kan àti ṣíṣàyẹ̀wò wọn, Rashi ṣàtúnṣe, tàbí yọ àwọn ìwé Midrash tó fa ìtakora àti ìdàrúdàpọ̀ kúrò. Ìyọrísí ìṣàyẹ̀wò náà ni pé, àwọn ìran Júù tó tẹ̀ lé e wá di ojúlùmọ̀ àwọn ojúlówó àṣàyàn ti ìwé Midrash tí Rashi ṣe.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Rashi kò lè ṣe kò máà gbédìí fún àwọn olùkọ́ rẹ̀, síbẹ̀ ẹ̀rù kì í bà á láti takò wọ́n tó bá rí i pé àlàyé wọn kò bá lájorí èrò tó wà nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan mu. Bó bá ṣẹlẹ̀ pé kò lóye àyọkà kan tàbí tó bá rí i pé bí òun ṣe ṣàlàyé rẹ̀ tẹ́lẹ̀ kọ́ ni ọ̀ràn náà rí, ó ṣe tán láti gba àṣìṣe rẹ̀, àní ó tilẹ̀ mẹ́nu kan àwọn àkókò kan tó jẹ́ pé àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ rẹ̀ ló ràn án lọ́wọ́ láti mú èrò rẹ̀ tọ́.

Ipò Nǹkan Nígbà Ayé Rẹ̀ Nípa Lórí Rẹ̀

Lògbàlògbà gidi ni Rashi jẹ́. Òǹṣèwé kan ṣàkópọ̀ rẹ̀ báyìí: “Ipa pàtàkì tí [Rashi] kó nínú ìgbésí ayé àwọn Júù ni ọ̀nà tó gbà tún àlàyé ṣe lórí àwọn àyọkà pàtàkì-pàtàkì ní èdè ìbílẹ̀ tí a ń sọ nígbà ayé rẹ̀, ó ṣàlàyé ọ̀hún lọ́nà tó ṣe kedere, ó lo ọ̀rọ̀ tí kò díjú, àlàyé rẹ̀ fi ìfẹ́ àti ìgbatẹnirò hàn, ó fi òye títayọ àti ìmọ̀ ẹ̀kọ́ tó ní hàn, tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ táa fi wá ń tọ́ka sí ìwé àlàyé tó ṣe gẹ́gẹ́ bí ìwé mímọ́, ìwé náà sì wá di èyí tí àwọn èèyàn gbádùn láti máa kà. Rashi kọ èdè Hébérù lọ́nà tó fi làákàyè hàn, tó tún gbádùn mọ́ni, àfi bí ẹni pé èdè Faransé ló fi kọ ọ́. Nígbà tí kò bá rí ọ̀rọ̀ Hébérù pàtó tó ṣe wẹ́kú pẹ̀lú ọ̀rọ̀ kan, yóò fi ọ̀rọ̀ tó jẹ́ ti èdè Faransé rọ́pò rẹ̀, ṣùgbọ́n yóò fi lẹ́tà èdè Hébérù kọ ọ́.” Àwọn ọ̀rọ̀ èdè Faransé tó pa lẹ́tà rẹ̀ dà wọ̀nyí—irú rẹ̀ tí Rashi lò ju egbèjìdínlógún ó dín ọgọ́rùn-ún [3,500]—ti wá di orísun pàtàkì fún àwọn àkẹ́kọ̀ọ́ Èdè Faransé tí ń kọ́ nípa ọ̀nà tí a gbà ń kọ èdè náà látijọ́ àti ọ̀nà tí a gbà ń pe ọ̀rọ̀.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìgbésí ayé Rashi bẹ̀rẹ̀ ní àgbègbè kan tí ó pa rọ́rọ́, àwọn ọdún tó lò kẹ́yìn kún fún wàhálà púpọ̀ láàárín àwọn Júù àti àwọn tí wọ́n sọ pé Kristẹni làwọn. Ní ọdún 1096, Ogun Ẹ̀sìn Àkọ́kọ́ sọ àwùjọ àwọn Júù tó wà ní Rhineland dahoro, ibẹ̀ sì ni Rashi ti kẹ́kọ̀ọ́. Wọ́n pa ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Júù. Ó jọ pé ìròyìn nípa ìpakúpa náà nípa lórí ìlera Rashi (èyí tó jó rẹ̀yìn díẹ̀díẹ̀ kó tó di pé ó kú lọ́dún 1105). Láti ìgbà yẹn ni àyípadà pàtàkì ti bá àwọn àlàyé Ìwé Mímọ́ tó ṣe nínú àwọn ìwé rẹ̀. Ọ̀kan tó tayọ ni ti Aísáyà orí kẹtàléláàádọ́ta, tó sọ̀rọ̀ nípa ìránṣẹ́ Jèhófà tí ń jìyà. Ṣáájú àkókò yìí, Rashi lo ẹsẹ yìí fún Mèsáyà náà, gẹ́gẹ́ bí ìwé Talmud ṣe lò ó. Ṣùgbọ́n ó dà bíi pé lẹ́yìn tí Ogun Ẹ̀sìn jà, ó wá rò pé àwọn Júù tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ jìyà lọ́nà àìtọ́ yìí ni ẹsẹ yìí ń bá wí. Èyí wá mú àyípadà pàtàkì bá ọ̀nà tí àwọn Júù gbà ń ṣàlàyé àwọn ẹsẹ wọ̀nyí.c Nípa báyìí, ìwà tí kò bá ìlànà Kristẹni mu, tí Kirisẹ́ńdọ̀mù ń hù, mú kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ kẹ̀yìn sí òtítọ́ nípa Jésù, tó fi mọ́ àwọn Júù pàápàá.—Mátíù 7:16-20; 2 Pétérù 2:1, 2.

Báwo Ló Ṣe Wá Jẹ́ Ògúnnágbòǹgbò Nínú Títúmọ̀ Bíbélì?

Kò pẹ́ tí àwọn tí kì í ṣe ẹlẹ́sìn àwọn Júù pàápàá fi nímọ̀lára ipa tí Rashi kó. Nicholas Lyra (1270-1349), tó jẹ́ mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Friars Minor ti Ilẹ̀ Faransé, tó tún jẹ́ alálàyé Bíbélì sábà máa ń tọ́ka sí ojú ìwòye “Rabbi Solomon [Rashi]” tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi fún un ní orúkọ náà, “Aláfarawé Sólómọ́nì.” Lyra pàápàá tún wá nípa lórí ọ̀pọ̀ àwọn alálàyé àti àwọn atúmọ̀ èdè, títí kan àwọn tó palẹ̀ ọ̀nà mọ́ fún àwọn atúmọ̀ Bíbélì King James Version ti èdè Gẹ̀ẹ́sì àti alátùn-únṣe Martin Luther, ẹni tó mú ìyípadà ńláǹlà dé bá ìtumọ̀ Bíbélì ní Germany. Luther gbára lé Lyra tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ọ̀rọ̀ tó lókìkí náà fi wà pé: “Lyra ló lùlù fún Luther jó.”

Èrò àwọn rábì tí kò bá òtítọ́ Kristẹni mu nípa púpọ̀ lórí Rashi. Síbẹ̀, nítorí òye jíjinlẹ̀ tó ní nínú àwọn ọ̀rọ̀ èdè Hébérù tí Bíbélì lò, àwọn ìlò ọ̀rọ̀ èdè náà, àti gírámà rẹ̀, pẹ̀lú akitiyan rẹ̀ ìgbà gbogbo láti mọ ìtumọ̀ kedere àti ti olówuuru tí ẹsẹ kan ní, Rashi pèsè orísun kan tó ṣe gúnmọ́, tó ṣeé lò fún àwọn olùṣèwádìí Bíbélì àti àwọn atúmọ̀ èdè tí wọ́n bá fẹ́ ṣàfiwéra ọ̀rọ̀ èdè.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a “Rashi” jẹ́ ìkékúrú orúkọ lédè Hébérù táa fàyọ láti inú àwọn lẹ́tà tó bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ náà, Rabbi Shlomo Yitzḥaqi [Rabbi Solomon ben Isaac].”

b Ọ̀rọ̀ náà, “Midrash,” wá láti inú gbòǹgbò ọ̀rọ̀ Hébérù náà tó túmọ̀ sí “láti ṣèwádìí, láti tanlẹ̀ ọ̀rọ̀, láti ṣàyẹ̀wò rẹ̀ fínnífínní,” tí a bá tún fẹ̀ ẹ́ lójú, ó túmọ̀ sí “láti wàásù.”

c Fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé lórí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí, wo àpótí náà, “My Servant”—Who Is He?, ní ojú ìwé 28 ìwé pẹlẹbẹ náà, Will There Ever Be a World Without War?, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 26]

Ọ̀rọ̀ inú ìwé: Per gentile concessione del Ministero dei Beni Culturali e Ambientali

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́