ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w99 4/15 ojú ìwé 23-27
  • Àwọn Kọ́líjéètì—Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Mú Wọn Yàtọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Kọ́líjéètì—Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Mú Wọn Yàtọ̀
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ọ̀ràn Kádàrá
  • Ìbẹ̀rẹ̀ Àwọn Kọ́líjéètì àti Ìdàgbàsókè Wọn
  • Ìgbàgbọ́ Àwọn Kọ́líjéètì
  • Ìpàdé Ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀
  • Àpèjọ Gbogbo Gbòò
  • Ìdí Tí Wọ́n Fi Pòórá
  • Ọlọrun Ha Ti Pinnu Kádàrá Wa Tẹ́lẹ̀ Bí?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Mímọrírì Àwọn Ìpéjọpọ̀ Kristẹni
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Kí Ló Ti Jẹ́ Àbájáde Ẹ̀kọ́ Ìsìn Calvin Láti Ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta Ọdún?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Àwọn Ìpàdé Tó Ń Fún “Wa Níṣìírí Láti Ní Ìfẹ́ àti Láti Ṣe Àwọn Iṣẹ́ Rere”
    A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
w99 4/15 ojú ìwé 23-27

Àwọn Kọ́líjéètì—Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Mú Wọn Yàtọ̀

Ǹjẹ́ o ti gbọ́ nípa àwọn Kọ́líjéètì rí?

Àwùjọ ìsìn kéréje ti ilẹ̀ Germany yìí, tó bẹ̀rẹ̀ ní ọ̀rúndún kẹtàdínlógún yàtọ̀ sí àwọn ṣọ́ọ̀ṣì tó ti fẹsẹ̀ múlẹ̀ nígbà náà. Kí ló fà á, kí sì ni a lè rí kọ́ lára wọn? Láti mọ̀ ọ́n, ẹ jẹ́ ká tètè múrìn àjò wa pọ̀n sí ayé ìgbà yẹn.

NÍ ọdún 1587, Jacobus Arminius (tàbí, Jacob Harmensen) gúnlẹ̀ sílùú Amsterdam. Kò ṣòro fún un láti ríṣẹ́, nítorí àkọọ́lẹ̀ tó ní nípa iṣẹ́ tó kọ́ wúni lórí jọjọ. Ọmọ ọdún mọ́kànlélógún ni, nígbà tó gboyè jáde ní Yunifásítì Leiden, ní Holland. Nígbà tó kúrò níbẹ̀, ó lo ọdún mẹ́fà ní Switzerland, ó kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìsìn lábẹ́ Théodore de Bèze, ẹni tó gbapò lọ́wọ́ Pùròtẹ́sítáǹtì Alátùn-únṣe Ẹ̀sìn nì, John Calvin. Abájọ tí inú àwọn Pùròtẹ́sítáǹtì ní Amsterdam fi dùn láti yan Arminius, ẹni ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n gẹ́gẹ́ bíi pásítọ̀ wọn! Ṣùgbọ́n, ọdún díẹ̀ lẹ́yìn èyí, ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ ìjọ ló kábàámọ̀ yíyàn tí wọ́n yàn án lọ́jọ́sí. Kí ló dé?

Ọ̀ràn Kádàrá

Kò pẹ́ tí Arminius di pásítọ̀ ni wàhálà bẹ́ sílẹ̀ láàárín àwọn Pùròtẹ́sítáǹtì tó wà ní Amsterdam lórí ẹ̀kọ́ kádàrá. Ẹ̀kọ́ yìí ni lájorí Ìgbàgbọ́ Calvin, ṣùgbọ́n àwọn kan lára ọmọ ìjọ gbà pé Ọlọ́run tó kádàrá pé kí àwọn kan rígbàlà, tó sì wá kádàrá ègbé fún àwọn kan jẹ́ òǹrorò, kò sì ṣe ohun tó bá ìdájọ́ òdodo mu. Àwọn Ọmọlẹ́yìn Calvin retí pé kí Arminius yanjú ọ̀ràn náà láàárín àwọn tó fẹ́ yapa, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ọ̀dọ̀ Bèze ló ti kẹ́kọ̀ọ́. Ṣùgbọ́n, ìyàlẹ́nu ńláǹlà ló jẹ́ fún àwọn Ọmọlẹ́yìn Calvin pé ojú ìwòye àwọn tó fẹ́ yapa ni Arminius fara mọ́. Nígbà tí yóò fi di ọdún 1593, awuyewuye náà ti gbóná débi pé, ó pín àwọn Pùròtẹ́sítáǹtì tó wà nílùú náà sí méjì—àwọn tí wọ́n fara mọ́ ẹ̀kọ́ náà àti àwọn tí wọ́n ta kò ó, àwọn oníwọ̀ntúnwọ̀nsì.

Láàárín ọdún díẹ̀, awuyewuye tó wà láàárín ìlú yìí ti dá ìyapa ńlá sílẹ̀ láàárín Pùròtẹ́sítáǹtì tó wà káàkiri orílẹ̀-èdè náà. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, ní November 1618, eruku ti wá fẹ́ sọ lálá. Àwọn Ọmọlẹ́yìn Calvin, tí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun àti àwọn ará ìlú wà lẹ́yìn wọn, pe àwọn tó fẹ́ yapa (àwọn tí wọ́n ń pè ní Alákatakítía) lẹ́jọ́ sí ìgbìmọ̀ àpapọ̀, Ẹgbẹ́ Alákòóso Ìsìn Pùròtẹ́sítáǹtì ti Dordrecht. Nígbà tí ìpàdé náà parí, wọ́n sọ fún gbogbo àlùfáà Alákatakítí pé: Ẹ fọwọ́ síwèé pé ẹ kò tún ní wàásù mọ́, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀ kí ẹ gbà láti fi orílẹ̀-èdè yìí sílẹ̀. Ọ̀pọ̀ jù lọ gbà láti lọ sí ìgbèkùn. Àwọn Ọmọlẹ́yìn Calvin tí kò gba gbẹ̀rẹ́ sì gbapò àwọn àlùfáà Alákatakítí tó ti lọ sígbèkùn. Ìgbàgbọ́ Calvin ti borí—tàbí kó jẹ́ bí ẹgbẹ́ alákòóso ìsìn ti rò nìyẹn.

Ìbẹ̀rẹ̀ Àwọn Kọ́líjéètì àti Ìdàgbàsókè Wọn

Bó ti ṣẹlẹ̀ ní àwọn ibòmíràn, ìjọ àwọn Alákatakítí tó wà ní abúlé Warmond, nítòsí Leiden, pàdánù pásítọ̀ wọn. Ṣùgbọ́n o, láìdàbí ti ibòmíràn, ìjọ náà kò tẹ́wọ́ gba ẹni tí ẹgbẹ́ alákòóso ìsìn fi rọ́pò rẹ̀. Ní àfikún sí i, nígbà tó tún di ọdún 1620 tí àlùfáà Àwọn Alákatakítí kan fẹ̀mí ara rẹ̀ wewu láti padà sí Warmond láti bójú tó ìjọ náà, àwọn ọmọ ìjọ kan tún kọ̀ ọ́. Àwọn mẹ́ńbà ìsìn yìí ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìpàdé ìsìn wọn ní bòókẹ́lẹ́ láìsí ìrànlọ́wọ́ àlùfáà kankan. Lẹ́yìn náà wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí pé àwọn ìpàdé wọ̀nyí ní kọ́lẹ́ẹ̀jì, a sì ń pe àwọn tí ń lọ síbẹ̀ ní, Àwọn Kọ́líjéètì.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ipò tí Àwọn Kọ́líjéètì bá ara wọn ló fà á tí wọ́n fi dá ẹ̀sìn tiwọn sílẹ̀ kì í ṣe nítorí ìlànà ìsìn, kò pẹ́ tí ipò náà fi yí padà. Ọmọ ìjọ ọ̀hún, Gijsbert van der Kodde jiyàn pé ṣíṣèpàdé láìsí àlùfáà kankan tó ń darí ìsìn mú kí àwùjọ náà jẹ́ àwọn tí ń tẹ̀ lé Bíbélì, tí wọ́n sì tún ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn Kristẹni ìjímìjí lọ́nà tó túbọ̀ ṣe tímọ́tímọ́ ju ti àwọn ṣọ́ọ̀ṣì tó ti fẹsẹ̀ múlẹ̀ nígbà náà. Ó wí pé, lẹ́yìn ikú àwọn àpọ́sítélì la hùmọ̀ àwùjọ àlùfáà láti lè wáṣẹ́ fún àwọn ọkùnrin kan tí wọ́n kò fẹ́ kọ́ iṣẹ́ ọwọ́ kankan.

Lọ́dún 1621, Van der Kodde àti àwọn ọmọ ìjọ mìíràn tí wọ́n tẹ́wọ́ gba ojú ìwòye rẹ̀ gbé ìpàdé wọn lọ sí abúlé tó wà nítòsí ní Rijnsburg.b Ọdún díẹ̀ lẹ́yìn náà, nígbà tí inúnibíni ẹ̀sìn ti yọrí sí ìfàyègbẹ̀sìn mìíràn, òkìkí Àwọn Kọ́líjéètì kàn jákèjádò orílẹ̀-èdè náà, ó sì fa “onírúurú ènìyàn” mọ́ra, gẹ́gẹ́ bí òpìtàn, Siegfried Zilverberg, ti sọ ọ́. Àwọn Alákatakítí wà nínú wọn, bẹ́ẹ̀ náà sì ni Àwọn Mennonite, àti Àwọn Socinian, kódà àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn pàápàá wà lára wọn. Àwọn kan lára wọn jẹ́ àgbẹ̀. Àwọn mìíràn jẹ́ akéwì, òǹtẹ̀wé, dókítà, àti òǹtàjà. Ọlọ́gbọ́n èrò orí náà, Spinoza (Benedictus de Spinoza) àti olùkọ́ náà, Johann Amos Comenius (tàbí, Jan Komenský), àti gbajúgbajà oníṣẹ́ ọnà nì, Rembrandt van Rijn, tẹ́wọ́ gba ojú ìwòye ẹgbẹ́ náà. Ojú ìwòye ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí àwọn onítara ìsìn wọ̀nyí mú wá nípa lórí ìdàgbàsókè ìgbàgbọ́ Àwọn Kọ́líjéètì.

Lẹ́yìn ọdún 1640, ẹgbẹ́ yìí gbèrú lọ́nà yíyára kánkán. Kọ́lẹ́ẹ̀jì bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹ́yọ ní Rotterdam, Amsterdam, Leeuwarden, àti àwọn ìlú ńláńlá mìíràn. Ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìtàn nì, Andrew C. Fix, sọ pé láàárín ọdún 1650 sí 1700, “Àwọn Kọ́líjéètì . . . gbèrú di ọ̀kan lára ẹ̀sìn tó ṣe pàtàkì jù lọ, tó sì nípa ìdarí lórí ẹni jù lọ ní ọ̀rúndún kẹtàdínlógún ní Holland.”

Ìgbàgbọ́ Àwọn Kọ́líjéètì

Níwọ̀n bí àròjinlẹ̀, ìráragba-nǹkan, àti òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ ti jẹ́ ohun tí a fi ń dá ẹgbẹ́ Àwọn Kọ́líjéètì mọ̀, olúkúlùkù Ọmọ Kọ́lẹ́ẹ̀jì ló lómìnira láti ní ìgbàgbọ́ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Síbẹ̀, ìgbàgbọ́ kan so wọ́n pọ̀. Fún àpẹẹrẹ, gbogbo Àwọn Kọ́líjéètì ló mọrírì ìjẹ́pàtàkì dídá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ọmọ Kọ́lẹ́ẹ̀jì kan kọ̀wé pé, ẹnì kọ̀ọ̀kan yẹ “kó fúnra rẹ̀ ṣèwádìí, kì í ṣe kó wá tipasẹ̀ ẹlòmíràn mọ Ọlọ́run.” Wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí òpìtàn nípa ṣọ́ọ̀ṣì ti ọ̀rúndún kọkàndínlógún nì, Jacobus C. van Slee, ti sọ, a rí i pé Àwọn Kọ́líjéètì ní ìmọ̀ nípa Bíbélì ju àwọn àwùjọ ẹ̀sìn yòókù nígbà náà lọ. Kódà àwọn alátakò ń gbóṣùbà fún Àwọn Kọ́líjéètì fún bí wọ́n ṣe jáfáfá nínú lílo Bíbélì.

Ṣùgbọ́n, bí Àwọn Kọ́líjéètì ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sí, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n túbọ̀ ń ní ìgbàgbọ́ tó yàtọ̀ sí ti àwọn ṣọ́ọ̀ṣì tó ti fìdí múlẹ̀. Àwọn ìsọfúnni tó ti wà láti ọ̀rúndún kẹtàdínlógún sí ọ̀rúndún ogún ṣàpèjúwe díẹ̀ lára ìgbàgbọ́ yìí:

Ṣọ́ọ̀ṣì Ìjímìjí. Ọmọ Kọ́lẹ́ẹ̀jì, tó tún jẹ́ ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn, Adam Boreel, kọ̀wé ní ọdún 1644 pé, nígbà tí ṣọ́ọ̀ṣì ìjímìjí bẹ̀rẹ̀ sí lọ́wọ́ nínú ìṣèlú nígbà ayé Ọba Constantine, ó da májẹ̀mú tó dá pẹ̀lú Kristi, ó sì pàdánù ìmísí ẹ̀mí mímọ́. Ó fi kún un pé, ìyọrísí rẹ̀ ni pé, ẹ̀kọ́ èké pọ̀ sí i, ó sì ń bá a lọ títí di òní olónìí.

Ẹgbẹ́ Alátùn-ùnṣe Ìsìn. Ẹgbẹ́ Alátùn-únṣe Ìsìn tí Luther, Calvin, àti àwọn mìíràn jẹ́ aṣáájú fún ní ọ̀rúndún kẹrìndínlógún kò lọ jìnnà nínú títún ṣọ́ọ̀ṣì ṣe. Kàkà bẹ́ẹ̀, gẹ́gẹ́ bí òléwájú Ọmọ Kọ́lẹ́ẹ̀jì, tó tún jẹ́ dókítà, Galenus Abrahamsz (1622-1706), ti wí, Àtúnṣe Ìsìn náà mú kí ipò ìsìn náà burú sí i nípa fífa ìjà àti ìkórìíra. Ṣe ló yẹ kí àtúnṣe tòótọ́ yíni lọ́kàn padà, èyí sì ni Ẹgbẹ́ Alátùn-únṣe Ìsìn kùnà láti ṣe.

Ṣọ́ọ̀ṣì àti Àlùfáà. Ìwà ìbàjẹ́ ti jàrábà àwọn ṣọ́ọ̀ṣì tó ti fẹsẹ̀ múlẹ̀, wọ́n ń ṣèṣe ayé, kò tilẹ̀ sí àmì pé Ọlọ́run lọ́wọ́ sí ọ̀ràn wọn. Ẹnikẹ́ni tó bá fọwọ́ dan-indan-in mú ẹ̀sìn gbọ́dọ̀ pa ṣọ́ọ̀ṣì tì, kí ó má bàá pín nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Àwọn Kọ́líjéètì sọ pé, ipò àwọn àlùfáà ta ko Ìwé Mímọ́, “ó sì lè ṣe àkóbá fún ire tẹ̀mí ìjọ Kristẹni.”

Ìjọba àti Párádísè. Ọ̀kan lára àwọn tó dá kọ́lẹ́ẹ̀jì tó wà ní Amsterdam sílẹ̀, Daniel de Breen (1594-1664), kọ̀wé pé Ìjọba Kristi kì í ṣe ìjọba tẹ̀mí tí ń gbé nínú ọkàn-àyà ẹni. Olùkọ́, Jacob Ostens, Ọmọ Kọ́lẹ́ẹ̀jì kan ní Rotterdam, wí pé “àwọn baba ńlá ń wọ̀nà fún ìlérí ti orí ilẹ̀ ayé.” Bákan náà, Àwọn Kọ́líjéètì ń dúró de àkókò náà nígbà tí a óò sọ ilẹ̀ ayé di párádísè.

Mẹ́talọ́kan. Lára àwọn òléwájú nínú Àwọn Kọ́líjéètì tí ìgbàgbọ́ Socinia nípa lórí wọn, a rí àwọn kan tí wọn kò tẹ́wọ́ gba Mẹ́talọ́kan.c Fún àpẹẹrẹ, Daniel Zwicker (1621-78) kọ̀wé pé ẹ̀kọ́ èyíkéyìí tó bá ta ko ìrònú, irú bí Mẹ́talọ́kan, “ẹ̀kọ́ tí kò tọ̀nà ni, ẹ̀kọ́ èké ni.” Lọ́dún 1694, a mú ẹ̀dà Bíbélì kan tí Ọmọ Kọ́lẹ́ẹ̀jì, Reijnier Rooleeuw, túmọ̀, jáde. Ó túmọ̀ apá tó kẹ́yìn nínú Jòhánù 1:1 pé: “Ọ̀rọ̀ náà sì jẹ́ ọlọ́run kan” dípò ìtumọ̀ kárí ayé náà pé: “Ọlọ́run sì ni Ọ̀rọ̀ náà.”d

Ìpàdé Ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe gbogbo Àwọn Kọ́líjéètì ló gba ohun kan náà gbọ́, àwọn kọ́lẹ́ẹ̀jì wọn tó wà ní ìlú ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ń ṣe ohun tí kò fi bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ síra. Òpìtàn Van Slee ròyìn pé ní kùtùkùtù ìgbà tí ẹgbẹ́ Àwọn Kọ́líjéètì bẹ̀rẹ̀, wọn kì í sábà múra àwọn ìpàdé sílẹ̀. Àwọn Kọ́líjéètì gbà pé, bí a bá gbé e ka ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù nípa ìjẹ́pàtàkì “àsọtẹ́lẹ̀,” gbogbo àwọn mẹ́ńbà ẹgbẹ́ náà lọ́kùnrin ló lè bá kọ́lẹ́ẹ̀jì sọ̀rọ̀ fàlàlà. (1 Kọ́ríńtì 14:1, 3, 26) Ìyọrísí rẹ̀ ni pé, wọ́n máa ń ṣèpàdé wọn títí di òru, àwọn kan nínú àwùjọ á sì ti “sùn lọ.”

Nígbà tó yá, àwọn ìpàdé wọn di èyí táa ṣètò dáradára. Kì í ṣe ọjọ́ Sunday nìkan ni Àwọn Kọ́líjéètì máa ń ṣèpàdé, wọ́n tún ń ṣe é ní àárín ọ̀sẹ̀ pẹ̀lú. Kí olùbánisọ̀rọ̀ àti àwùjọ lè ti múra sílẹ̀ fún gbogbo ìpàdé tí wọn yóò ṣe lọ́dún náà, wọ́n a ti tẹ ìtòlẹ́sẹẹsẹ kan jáde, tí wọ́n to àwọn ẹsẹ Bíbélì tí wọn yóò gbé yẹ̀ wò nípàdé sí, orúkọ àwọn olùbánisọ̀rọ̀ sì ti wà níbẹ̀. Lẹ́yìn tí wọ́n bá ti fi orin àti àdúrà bẹ̀rẹ̀ ìpàdé, olùbánisọ̀rọ̀ kan yóò ṣàlàyé àwọn ẹsẹ Bíbélì náà. Nígbà tó bá parí ọ̀rọ̀ rẹ̀, yóò wá ní kí àwọn ọkùnrin ṣàlàyé bí ẹṣin ọ̀rọ̀ tí wọ́n jíròrò náà ti yé wọn sí. Lẹ́yìn èyí, olùbánisọ̀rọ̀ ṣèkejì yóò ṣàlàyé bí àwọn ẹsẹ náà ṣe kàn wọ́n. Àdúrà àti orin ni wọn yóò sì fi parí ìpàdé.

Àwọn Kọ́líjéètì tó wà nílùú Harlingen, ní ẹkùn Friesland, ní ọgbọ́n tí wọ́n ń dá tí wọ́n fi ń darí ìpàdé wọn lọ́nà tí wọn kò fi ní jẹ àkókò. Olùbánisọ̀rọ̀ tó bá jẹ àkókò yóò sanwó ìtanràn díẹ̀.

Àpèjọ Gbogbo Gbòò

Àwọn Kọ́líjéètì tún rí i pé ó dáa tí àwọn bá lè máa ní àpéjọ ńlá. Nípa báyìí, bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 1640, Àwọn Kọ́líjéètì jákèjádò orílẹ̀-èdè náà rìnrìn àjò nígbà méjì lọ́dún (ìgbà ìrúwé àti ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn) lọ sí Rijnsburg. Òpìtàn Fix kọ̀wé pé, àwọn àpéjọ wọ̀nyí fún wọn láǹfààní láti “túbọ̀ lóye èrò, ìmọ̀lára, ìgbàgbọ́, àti ìgbòkègbodò àwọn arákùnrin wọn láti ọ̀nà jíjìn.”

Àwọn kan lára Àwọn Kọ́líjéètì tí wọ́n wá sí àpéjọ náà háyà ilé lọ́wọ́ àwọn ará abúlé náà, àwọn mìíràn sì dé sí Groote Huis, tàbí Ilé Ńlá, ilé tó ní ọgbọ̀n yàrá tó jẹ́ ti Àwọn Kọ́líjéètì. Oúnjẹ ti ọgọ́ta sí àádọ́rin èèyàn ni wọ́n máa ń pèsè níbẹ̀. Lẹ́yìn tí wọ́n bá jẹun tán, àwọn àlejò lè gbatẹ́gùn lọ sí ọgbà kékeré tó wà láyìíká ilé náà láti gbádùn ‘iṣẹ́ Ọlọ́run, ìjíròrò wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́, tàbí kí wọ́n lọ ṣàṣàrò.”

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe gbogbo Àwọn Kọ́líjéètì ló gbà pé ìrìbọmi ṣe pàtàkì, ọ̀pọ̀ ló ṣèrìbọmi. Nípa báyìí, ìrìbọmi di ohun tó sábà ń ṣẹlẹ̀ nígbà àpéjọ ńlá. Òpìtàn Van Slee sọ pé, òwúrọ̀ Saturday ni ayẹyẹ náà sábà máa ń wáyé. Lẹ́yìn orin àti àdúrà, àwíyé lórí ìjẹ́pàtàkì ìrìbọmi ni yóò tẹ̀ lé e. Lẹ́yìn ìyẹn ni olùbánisọ̀rọ̀ yóò rọ àwọn àgbàlagbà tí wọ́n fẹ́ ṣèrìbọmi láti ṣe ìjẹ́wọ́ ìgbàgbọ́, irú bí “Mo gbà gbọ́ pé Jésù Kristi ni Ọmọ Ọlọ́run alààyè.” Lẹ́yìn tí wọ́n bá fi àdúrà parí àwíyé náà, gbogbo àwùjọ yóò wọ́ lọ sí odò ìrìbọmi, wọn yóò sì máa wo bí tọkùnrin tobìnrin ṣe ń kúnlẹ̀ sínú odò náà, kí omi bàa lè dé èjìká wọn. Olùbatisí náà yóò sì rọra fọwọ́ ti orí ẹni tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di onígbàgbọ́ náà síwájú, yóò rọra tì í sábẹ́ omi. Lẹ́yìn ayẹyẹ náà, gbogbo àwùjọ yóò padà sórí ìjókòó wọn fún àwíyé tó kàn.

Ní ọ̀sán Saturday, ní agogo márùn-ún ìrọ̀lẹ́, ìpàdé máa ń bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú kíka ẹsẹ Bíbélì díẹ̀, kíkọrin, àti gbígbàdúrà. Láti rí i dájú pé olùbánisọ̀rọ̀ yóò wà, àwọn kọ́lẹ́ẹ̀jì Rotterdam, Leiden, Amsterdam, àti Àríwá Holland, ló máa ń pèsè olùbánisọ̀rọ̀ fún àpéjọ kọ̀ọ̀kan. Òwúrọ̀ Sunday ni wọ́n yà sọ́tọ̀ fún ayẹyẹ Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa. Lẹ́yìn àwíyé, àdúrà, àti orin, àwọn ọkùnrin yóò kọ́kọ́ jẹ nínú búrẹ́dì àti wáìnì náà, lẹ́yìn èyí ni yóò tó kan àwọn obìnrin. Tó bá tún di ìrọ̀lẹ́ Sunday, àwọn àwíyé mìíràn yóò tẹ̀ lé e, tó bá sì wá di òwúrọ̀ Monday, gbogbo wọn yóò pé jọ fún ọ̀rọ̀ àsọparí. Gẹ́gẹ́ bí Van Slee ti sọ, ọ̀pọ̀ jù lọ ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń sọ ní àwọn àpéjọ wọ̀nyí, jẹ́ èyí tó ṣeé mú lò, kì í ṣe àlàyé nìkan ni wọ́n ń ṣe, àmọ́ wọ́n ń tẹnu mọ́ bí wọ́n ṣe lè mú un lò.

Inú àwọn ará abúlé Rijnsburg máa ń dùn jọjọ láti gba àwùjọ yìí lálejò. Olùṣàkíyèsí kan tó gbé ayé ní ọ̀rúndún kejìdínlógún kọ̀wé pé rírọ́ tí àwọn àlejò ń rọ́ wá, tí wọ́n sì ń ra oúnjẹ àti ohun mímu, mú kí owó wọlé fún àwọn ará abúlé náà. Ní àfikún sí i, lẹ́yìn àpéjọ kọ̀ọ̀kan Àwọn Kọ́líjéètì máa ń gbé owó kalẹ̀ fún àwọn tálákà tó wà ní Rijnsburg. Kò sí àní-àní pé, abúlé náà mọ̀ ọ́n lára nígbà tí wọn ò wá ṣèpàdé níbẹ̀ mọ́ ní ọdún 1787. Lẹ́yìn èyí ni ẹgbẹ́ Àwọn Kọ́líjéètì pòórá. Kí ló fà á?

Ìdí Tí Wọ́n Fi Pòórá

Ìgbà tí ọ̀rúndún kẹtàdínlógún fi máa parí, awuyewuye kan ti dìde nípa ipa tí àròjinlẹ̀ ń kó nínú ẹ̀sìn. Àwọn Kọ́líjéètì kan gbà pé ìrònú ènìyàn gbọ́dọ̀ gba ipò iwájú mọ́ ìṣípayá àtọ̀runwá lọ́wọ́, ṣùgbọ́n àwọn kan kò gbà bẹ́ẹ̀. Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, awuyewuye náà pín gbogbo ẹgbẹ́ Àwọn Kọ́líjéètì. Àfìgbà tí gbogbo àwọn tó jẹ́ alágbàwí ní ìhà méjèèjì kú tán ni Àwọn Kọ́líjéètì tó wà níṣọ̀kan lẹ́ẹ̀kan sí i. Síbẹ̀síbẹ̀, lẹ́yìn ìyapa yìí, ẹgbẹ́ náà “kò rí bíi ti àtẹ̀yìnwá mọ́,” òpìtàn Fix ló sọ bẹ́ẹ̀.

Ẹ̀mí ìráragba-nǹkan tó wá pọ̀ sí i láàárín àwọn ṣọ́ọ̀ṣì Pùròtẹ́sítáǹtì ní ọ̀rúndún kejìdínlógún tún wá pakún dídínkù tí Àwọn Kọ́líjéètì ń dín kù. Bó ṣe ń di pé ìlànà ìrònú àti ìráragba-nǹkan tí Àwọn Kọ́líjéètì dì mú ṣe túbọ̀ ń di ohun tí gbogbo àwùjọ tẹ́wọ́ gbà, “ìgbàgbọ́ Àwọn Ọmọ Kọ́lẹ́ẹ̀ji tí a fojú tẹ́ńbẹ́lú tẹ́lẹ̀ rí wá di orísun Ìlàlóye.” Ìgbà tó fi máa di òpin ọ̀rúndún kejìdínlógún, ọ̀pọ̀ jù lọ Àwọn Kọ́líjéètì ni àwọn Mennonite àti àwọn ẹlẹ́sìn mìíràn ti gbà mọ́ra.

Níwọ̀n bí Àwọn Kọ́líjéètì kò ti lọ́kàn àtimú èrò wọn ṣọ̀kan láàárín ẹgbẹ́ wọn, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé bí Àwọn Kọ́líjéètì ti pọ̀ tó náà ni ojú ìwòye wọn pọ̀ tó. Àwọn alára mọ̀ bẹ́ẹ̀, nítorí náà, wọn kò sọ pé àwọn “so . . . pọ̀ ṣọ̀kan rẹ́gírẹ́gí nínú èrò inú kan náà,” gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ti rọ àwọn Kristẹni láti ṣe. (1 Kọ́ríńtì 1:10) Àmọ́ ṣá o, lọ́wọ́ kan náà, Àwọn Kọ́líjéètì ń wọ̀nà fún àkókò náà nígbà tí lájorí ìgbàgbọ́ Kristẹni, irú bí ìṣọ̀kan ìrònú, yóò ṣeé ṣe.

Báa bá ronú nípa pé ìmọ̀ tòótọ́ kò tí ì pọ̀ rẹpẹtẹ ní ọjọ́ Àwọn Kọ́líjéètì, a óò gbà pé wọ́n fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ìsìn lónìí láti kíyè sí. (Fi wé Dáníẹ́lì 12:4.) Títẹnu tí wọ́n ń tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wà ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀ràn àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pé: “Ẹ máa wádìí ohun gbogbo dájú.” (1 Tẹsalóníkà 5:21) Ìdákẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kọ́ Jacobus Arminius àti àwọn mìíràn pé àwọn ẹ̀kọ́ ìsìn àti àṣà táwọn kan ti rọ̀ mọ́ tipẹ́tipẹ́, kò bá Bíbélì mu rárá. Nígbà tí wọ́n wá mọ èyí, wọn ní ìgboyà láti yàtọ̀ sí ẹ̀sìn tó ti fẹsẹ̀ múlẹ̀. Bó bá jẹ ìwọ ni, ṣé wàá ṣe bẹ́ẹ̀?

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Lọ́dún 1610 àwọn tó yapa fi ìwé àtakò kan ránṣẹ́ (ìwé yìí sọ ìdí tí wọ́n fi ń ṣàtakò) sí àwọn alákòóso Germany. Lẹ́yìn ìgbésẹ̀ yìí, ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí pè wọ́n ní Alákatakítí.

b Nítorí ibi tó wà yìí, a tún ń pe Àwọn Kọ́líjéètì ni àwọn Rijnsburger.

c Wo Jí!, May 22, 1989, ojú ìwé 19, “Àwọn Onísìn Socinus—Eeṣe Ti Wọn Fi Ṣá Mẹtalọkan Ti?”

d Het Nieuwe Testament van onze Heer Jezus Christus, uit het Grieksch vertaald door Reijnier Rooleeuw, M.D. (Májẹ̀mú Tuntun ti Jésù Kristi Olúwa Wa, tí a túmọ̀ láti inú èdè Gíríìkì láti ọwọ́ Reijnier Rooleeuw, M.D.)

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Rembrandt van Rijn

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Abúlé Warmond níbi tí Àwọn Kọ́líjéètì ti kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀, àti Odò De Vliet tí wọ́n ti ń ṣèrìbọmi

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 23]

Ọnà: Nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda onínúure ti American Bible Society Library, New York

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́