Máa Kàwé Pẹ̀lú Àwọn Ọmọ rẹ
Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn ilẹ̀ Brazil náà, Veja, ti sọ, ọmọ àwọn tó láápọn àtikàwé sábà máa ń mú ẹ̀mí àtikàwé dàgbà ju àwọn ọmọ tí kò rí irú àpẹẹrẹ bẹ́ẹ̀ kọ́ nínú ìdílé wọn. Martha Hoppe, ògbóǹtagí nínú ìdàgbàsókè ọmọ sọ pé: “Jíjọ kàwé pọ̀ máa ń mú kí àwọn òbí pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn túbọ̀ sún mọ́ra pẹ́kípẹ́kí, ó sì ń jẹ́ kí ọmọ náà túbọ̀ lóye ìwé náà dáadáa.”
Kíkàwé sókè ketekete sétígbọ̀ọ́ ọmọ rẹ tún ń fún ọ láǹfààní láti dáhùn ìbéèrè. O lè jíròrò àwòrán èyíkéyìí tó bá wà lójú ìwé náà. Hoppe sọ pé: “Bí ọmọ kan bá ṣe ń lóye àwọn ohun tó wà nínú ìwé kan sí, bẹ́ẹ̀ ni yóò ṣe máa fẹ́ láti ka ìwé náà sí nígbà tó bá fẹ́ tẹ́ ìyánhànhàn rẹ̀ lọ́rùn.”
Ọ̀pọ̀ òbí láàárín Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ń gbádùn kíkàwé pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn. Wọn lè máa ka àwọn ìtẹ̀jáde bí Iwe Itan Bibeli Mi, Fifetisilẹ si Olukọ Nla na, àti Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí.a Kì í ṣe kìkì pé àwọn ìwé báwọ̀nyí ń ran ọmọdé lọ́wọ́ láti di òǹkàwé tó jáfáfá nìkan ni ṣùgbọ́n ó tún ń mú kí ìfẹ́ tó ní nínú ìwé tó tà jù lọ lágbàáyé—Bíbélì Mímọ́—túbọ̀ pọ̀ sí i ni. Nítorí náà, bóo bá jẹ́ òbí, fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fún àwọn ọmọ rẹ nípa jíjẹ́ ẹni tó kúndùn kíka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Jóṣúà 1:7, 8) Ní gbogbo ọ̀nà, wá àkókò láti kàwé pẹ̀lú wọn!
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., ló tẹ̀ wọ́n jáde