Ilẹ̀ Àwọn Venda Abèso Wọ̀ǹtìwọnti
ỌDÚN kẹwàá rèé tí èmi àtìyàwó mi ti ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ajíhìnrere alákòókò kíkún láàárín àwọn èèyàn kan táa ń pè ní Venda. Àwọn Venda ń gbé ní gúúsù Odò Limpopo ní àríwá Gúúsù Áfíríkà, orílẹ̀-èdè wọn sì jẹ́ àpapọ̀ àwọn ẹ̀yà mélòó kan tí wọ́n sọdá Odò Limpopo ní àwọn ọ̀rúndún tó kọjá. Àwọn Venda kan sọ pé baba ńlá àwọn dó síhìn-ín ní ohun tó ju ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn.
Ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé, nígbà kan rí, ẹkùn ilẹ̀ yìí jẹ́ apá kan ilẹ̀ àwọn èèyàn ìgbàanì kan táa ń pè ní Ilẹ̀ Mapungubwe. Èyí ni àgbègbè ńlá tí ọ̀làjú kọ́kọ́ dé ní Gúúsù Áfíríkà, ìkáwọ́ wọn sì ni àfonífojì salalu ti Odò Limpopo wà, láti orílẹ̀-èdè Botswana ní ìwọ̀ oòrùn títí dé orílẹ̀-èdè Mòsáńbíìkì ní ìlà oòrùn. Láti nǹkan bí ọdún 900 Sànmánì Tiwa títí dé ọdún 1100 Sànmánì Tiwa, ilẹ̀ Mapungubwe ló ń pèsè eyín erin, ìwo ìmàdò, awọ ẹranko, bàbà, àti góòlù pàápàá fún àwọn oníṣòwò Lárúbáwá. Àwọn ohun táa gbẹ́ mèremère, táa wá fi góòlù bò, ni a ti wú jáde lórí òkè kékeré kan táa ń pè ní Mapungubwe, níbi tí wọ́n ń sin àwọn ọba sí. Ìwé gbédègbéyọ̀ kan sọ pé ìwọ̀nyí wà lára “àwọn ẹ̀rí tí ó kọ́kọ́ fi hàn pé wọ́n ń wa góòlù ní gúúsù Áfíríkà.”
Wọn ò wa góòlù níbí mọ́ o. Àmọ́ lónìí, ilẹ̀ àwọn Venda ṣì gbajúmọ̀ nítorí pé ó jẹ́ ilẹ̀ eléso. Ní gúúsù Àwọn Òkè Soutpansberg ni àfonífojì ẹlẹ́tù lójú kan wà, níbi tí àwọn èso bí afokádò, ọ̀gẹ̀dẹ̀ wẹẹrẹ, máńgòrò, àti gúáfà ti ń so wọ̀ǹtìwọnti. Yàtọ̀ sí àwọn ẹ̀pà bí pecan àti macadamia, àwọn ewébẹ̀ tún pọ̀ lọ rẹ́kẹrẹ̀kẹ. Ọ̀kan lára irú ewébẹ̀ náà ni muroho inú ìgbẹ́, tó rí bí ẹ̀fọ́ tẹ̀tẹ̀ lẹ́nu, àwọn èèyàn àdúgbò yìí sì kúndùn rẹ̀ gan-an.
Àwọn Venda jẹ́ ẹni àlàáfíà, wọ́n sì tún ń ṣaájò àlejò. Ohun tó wọ́pọ̀ dáadáa ni pé kí baálé ilé sọ pé kí wọ́n pa adìyẹ, kí wọ́n sì fi sebẹ̀ fún àlejò tí a kò retí tẹ́lẹ̀. Vhuswa, tí a ń fi àgbàdo ṣe, tí í ṣe oúnjẹ tó wọ́pọ̀ jù lọ ní ilẹ̀ náà, ni wọ́n fi ń jẹ irú ọbẹ̀ bẹ́ẹ̀. Lẹ́yìn àbẹ̀wò náà, baálé ilé yóò wá sin àlejò rẹ̀ dọ́nà. Báyìí ni wọ́n ṣe ń yẹ́ àlejò sí. Wọ́n máa ń kọ́ àwọn ọmọ ní bí wọ́n ṣe ń kí àlejò tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ nípa títẹríba, kí wọ́n sì gbé ọwọ́ wọn kan lé èkejì. Lójú ìwé yìí, o lè rí àwọn obìnrin Venda méjì tí wọ́n ń kí ara wọn gẹ́gẹ́ bí àṣà ilẹ̀ wọn.
Èdè Tó Ṣòroó Sọ
Èdè Venda kò rọrùn-ún sọ fún àwọn èèyàn tó bá ṣẹ̀ wá láti Yúróòpù. Ọ̀kan lára ohun tó jẹ́ kó ṣòroó sọ fún wọn ni pé ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ ni sípẹ́lì wọn bára mu, ṣùgbọ́n tó jẹ́ pé ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni pípè wọn. Lọ́jọ́ kan, nígbà tí mo ń sọ àsọyé Bíbélì nínú ìjọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí ń sọ èdè Venda, mo ń gbìyànjú láti rọ àwùjọ pé kí wọ́n máa bá olúkúlùkù sọ̀rọ̀. Ṣe ni ẹnì kan láwùjọ kàn ṣàdédé bú sẹ́rìn-ín nítorí mo sọ pé “olúkúlùkù ìka ọwọ́” kàkà tí ǹ bá fi sọ pé “olúkúlùkù ènìyàn.”
Nígbà tí mo kọ́kọ́ gbìyànjú láti sọ èdè Venda nínú iṣẹ́ ìjẹ́rìí ní gbangba, obìnrin Venda kan fèsì pé: “Mi ò gbọ́ Òyìnbó o.” Àṣé gbogbo èyí tí mo ń sọ, tí mo rò pé èdè Venda ni mo ń sọ kùlà, èdè Òyìnbó lobìnrin náà rò pé mo ń sọ! Ní àkókò mìíràn, bí mo ṣe dé ilé kan, mo ní kí ọmọ kan lọ pe olórí ìdílé wá. Ọ̀rọ̀ tí Venda ń lò fún olórí ìdílé ni thoʹho. Láìmọ̀, ohun tí mo sọ ni thohoʹ, tó túmọ̀ sí pé mo fẹ́ bá ọ̀bọ ilé yìí sọ̀rọ̀! Àṣìṣe báwọ̀nyí kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá mi, ṣùgbọ́n nípasẹ̀ ìforítì, èmi àti ìyàwó mi ti lè sọ èdè Venda dáadáa báyìí.
Èso Tẹ̀mí
Ilẹ̀ àwọn Venda jẹ́ eléso nípa tẹ̀mí. Láàárín ọdún 1950 sí 1960, a dá ìjọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sílẹ̀ láàárín àwọn èèyàn tó ṣí wá láti àwọn orílẹ̀-èdè tó wà nítòsí láti wá ṣiṣẹ́ níbi tí wọ́n ti ń wa bàbà ní ìlú Messina. Ìgbòkègbodò onítara wọn jẹ́ kí ọ̀pọ̀ Venda mọ̀ nípa àwọn òtítọ́ Bíbélì. Ọdún mẹ́wàá lẹ́yìn náà, àwùjọ Àwọn Ẹlẹ́rìí tí í ṣe Venda bẹ̀rẹ̀ sí ṣèpàdé ní ilé àdáni ní ìlú Sibasa.
Láti fi kún ìbísí náà, ẹ̀ka ilé iṣẹ́ Watch Tower Society tó wà ní Gúúsù Áfíríkà, fi àwọn ajíhìnrere alákòókò kíkún ránṣẹ́ sí pápá eléso yìí. Láìpẹ́ láìjìnnà, àwùjọ tó wà ní Sibasa yìí ti di ìjọ ńlá. Inú kíláàsì kan ni wọ́n ti ń ṣè àwọn ìpàdé Kristẹni nígbà yẹn. Àmọ́ ṣá o, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lágbègbè Pietersburg, tó jẹ́ nǹkan bí ọgọ́jọ [160] kìlómítà lápá gúúsù sí Sibasa, a kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba kan sí Thohoyandou, ìlú kan tó wà nítòsí Sibasa.
Àwọn èèyàn tí ń sọ èdè Venda ní àríwá Gúúsù Áfíríkà lé ní ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [500,000]. Kò sí Venda kankan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí nígbà tí iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1950. Wọ́n ti lé ní àádọ́jọ [150] báyìí. Ṣùgbọ́n àgbègbè púpọ̀ ṣì wà tí a kò tíì dé, iṣẹ́ púpọ̀ sì wà láti ṣe. Ọdún 1989 la bẹ̀rẹ̀ sí ṣèbẹ̀wò sí abúlé Venda náà táa ń pè ní Hamutsha. Ẹlẹ́rìí kan ṣoṣo ló ń gbé ibẹ̀ nígbà yẹn. Ní báyìí, àwọn olùpòkìkí Ìjọba náà tí ń gbé ní abúlé yẹn ti lé ní ogójì. Píparí Gbọ̀ngàn Ìjọba wa tí a ń kọ́ mú kí ọwọ́ wa dí. Lẹ́ẹ̀kan sí i, ọpẹ́lọpẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí láti àwọn ìjọ Pietersburg àti owó tí àwọn ará dá fún wa láti àwọn ilẹ̀ aláásìkí.
Inú ọkọ̀ àfiṣelé kan là ń gbé nínú oko kan. Nípa gbígbé ìgbé ayé oníwọ̀ntúnwọ̀nsì, a ní àkókò púpọ̀ láti mú ìhìn rere tọ àwọn èèyàn àdúgbò wa lọ. (Máàkù 13:10) Ìyọrísí rẹ̀ ni pé, a ti rí ìbùkún jìngbìnnì gbà, ìbùkún ti níní àǹfààní láti ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ láti ya ìgbésí ayé wọn sí mímọ́ sí Jèhófà Ọlọ́run. Àpẹẹrẹ kan ni tọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Michael, tó rí ìwé náà, Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye nílé ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan.a Ó bẹ̀rẹ̀ sí kà á, ojú ẹsẹ̀ ló sì rí i pé òótọ́ nìyí. Ó wá kọ̀wé sí Watch Tower Society fún ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì púpọ̀ sí i. Nínú lẹ́tà rẹ̀, Michael ṣàlàyé pé ẹnu àìpẹ́ yìí lòun ṣèrìbọmi gẹ́gẹ́ bí mẹ́ńbà ṣọ́ọ̀ṣì Apostolic tó wà ládùúgbò. Ó ń bá a lọ láti sọ pé: “Mo ti wá rí i báyìí pé mo ti ṣìnà Ìjọba Ọlọ́run. Mo sì ti pinnu pé màá di ọ̀kan lára mẹ́ńbà yín, ṣùgbọ́n n kò mọ ọ̀nà tí mo lè gbé e gbà.” Ó wá kọ àdírẹ́sì rẹ̀, ó sì ní kí wọ́n rán ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sóun, kó wá ran òun lọ́wọ́. Nígbà tí mo jàjà rí Michael, mo bẹ̀rẹ̀ sí bá a ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nínú ilé rẹ̀. Báa ti ń wí yìí o, ó mà ti di Ẹlẹ́rìí tó ti ṣèrìbọmi, ó sì ń fi ìdúróṣinṣin sin Jèhófà.
Ní December 1997, a lọ sí Àpéjọpọ̀ Àgbègbè ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà táa pe ẹṣin ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní “Ìgbàgbọ́ Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run,” a ṣe àpéjọpọ̀ ọ̀hún ní pápá ìṣiré kan nílùú Thohoyandou. Èèyàn ẹgbẹ̀ta ó lé mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n [634] ló pésẹ̀, ẹni tuntun méjìlá la batisí. Ó jẹ́ ayọ̀ mi pé mo sọ àsọyé méjì lédè Venda. Ìṣẹ̀lẹ̀ mánigbàgbé gidi ló jẹ́ láàárín ọdún mẹ́wàá aláyọ̀ táa ti lò ní ilẹ̀ abèso wọ̀ǹtìwọnti yìí!—Àkọránṣẹ́ ni.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc, ló tẹ ìwé yìí jáde.