ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w99 5/15 ojú ìwé 7-9
  • Ìbẹ̀wò Pàtàkì Mú Erékùṣù Kan Yọ̀ Ṣẹ̀ṣẹ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìbẹ̀wò Pàtàkì Mú Erékùṣù Kan Yọ̀ Ṣẹ̀ṣẹ̀
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ìsọ̀rí
  • Pípadà Wàpọ̀ Lọ́nà Tó Mú Ayọ̀ Wá
  • Àwọn Kókó Pàtàkì Inú Àpéjọpọ̀
  • “Àwọn Nǹkan Tí A Kò Ní Gbàgbé Láé”
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
w99 5/15 ojú ìwé 7-9

Ìbẹ̀wò Pàtàkì Mú Erékùṣù Kan Yọ̀ Ṣẹ̀ṣẹ̀

Cuba, erékùṣù kan tó jẹ́ àrímáleèlọ ní ilẹ̀ Caribbean, gbádùn àkókò ìtura tẹ̀mí tí kò ṣẹlẹ̀ níbẹ̀ rí láìpẹ́ yìí. Ìparí ọdún 1998 mú ìbùkún táa ti ń retí tipẹ́tipẹ́ wá fún Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n ń gbé ní orílẹ̀-èdè West Indies yìí. Fún ìgbà àkọ́kọ́ ní ohun tó lé ní ọgbọ̀n ọdún, àwọn mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣèbẹ̀wò síbẹ̀, àwọn aṣojú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ló sì bá wọn wá. Àwọn tó ṣèbẹ̀wò náà jẹ́ ọmọ Australia, Austria, Belgium, Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, Ítálì, New Zealand, àti Puerto Rico.

ÌṢẸ̀LẸ̀ mánigbàgbé lèyí jẹ́ fún ẹgbẹ̀rún lọ́nà méjìlélọ́gọ́rin àti igba ó lé méjìdínlọ́gọ́ta [82,258] akéde Ìjọba àti ẹgbẹ̀rún lọ́nà mẹ́tàdínláàádọ́rùn-ún, ẹgbẹ̀rin ó lé àádọ́rùn-ún [87,890], tí wọ́n dara pọ̀ mọ́ wọn láti ṣayẹyẹ Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn 1998.

Láti December 1 sí 7, 1998, Lloyd Barry, John Barr, àti Gerrit Lösch ti ṣèbẹ̀wò sí Ilé Bẹ́tẹ́lì ní Havana, wọ́n sì tún lọ sí díẹ̀ lára àwọn Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Ọ̀nà Ìgbésí Ayé Tí Ọlọ́run Fẹ́” tó wáyé ní Cuba. Inú wọn dùn láti bá àwọn alàgbà tí wọ́n jẹ́ arìnrìn àjò pàdé, wọ́n tún láyọ̀ pé àwọn túbọ̀ di ojúlùmọ̀ pẹ̀lú àwọn lọ́gàálọ́gàá lẹ́nu iṣẹ́ ọba ní Cuba.

John Barr wí pé: “Ọ̀kan pàtàkì nínú àwọn ìṣètò ìṣàkóso Ọlọ́run tó ṣẹlẹ̀ nígbà ayé wa lèyí jẹ́ fún èmi àti aya mi. Àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa ní Cuba mà ní ìtara púpọ̀ fún òtítọ́ o! Èyí wá jẹ́ kí n mọ̀ pé ẹgbẹ́ ara wa kárí ayé ṣeyebíye lóòótọ́!” Lloyd Barry fi kún un pé: “Ọ̀sẹ̀ mánigbàgbé yìí ràn mí lọ́wọ́ láti ní òye tó gún régé sí i nípa ipò tí àwọn arákùnrin wa wà níbẹ̀.”

Láàárín oṣù márùn-ún tó kọjá, a ti fún Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní àfikún òmìnira ẹ̀sìn ní Cuba, ohun tí àwọn aláṣẹ Cuba sọ sì jẹ́ ká mọ̀ pé wọ́n fẹ́ kó máa bá a lọ bẹ́ẹ̀.

Ní September 1994, a bẹ̀rẹ̀ sí tẹ̀wé jáde ní Ilé Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Havana. Lẹ́ẹ̀kan sí i, Àwọn Ẹlẹ́rìí lè máa pàdé ní gbangba, wọ́n sì láǹfààní láti máa jẹ́rìí láti ilé dé ilé. Lẹ́yìn náà, lọ́dún 1998, àwọn aláṣẹ yọ̀ǹda kí àwọn méjìdínlógún ṣèbẹ̀wò sí Cuba, àwọn èèyàn náà jẹ́ aṣojú jákèjádò ayé fún Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tí mẹ́ta lára wọ́n sì jẹ́ mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Pípadà Wàpọ̀ Lọ́nà Tó Mú Ayọ̀ Wá

Nígbà tí àwọn aṣojú náà gúnlẹ̀ sí pápákọ̀ òfuurufú José Martí ní Havana, àwùjọ àwọn lọ́gàálọ́gàá lẹ́nu iṣẹ́ ọba àti àwọn tó ti Ilé Bẹ́tẹ́lì wá, fi tẹ̀ríntẹ̀yẹ kí wọn káàbọ̀, lára wọn ni, arákùnrin kan tó rántí ìbẹ̀wò tí ọ̀kan lára àwọn mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso—Milton Henschel—ṣé gbẹ̀yìn sí Cuba lọ́dún 1961. Ọmọ ọdún méjìlá ni arákùnrin náà nígbà yẹn; ó ti di alábòójútó arìnrìn-àjò báyìí.

Nígbà tí àwọn aṣojú náà dé Ilé Bẹ́tẹ́lì náà, oríṣiríṣi òdòdó aláwọ̀ fífani mọ́ra, tí arákùnrin kan gbìn nítorí ayẹyẹ náà ni a fi kí wọn káàbọ̀. Bí àwọn mẹ́ńbà ìdílé Bẹ́tẹ́lì ṣe ń kí àwọn aṣojú náà káàbọ̀, bẹ́ẹ̀ ni omijé ń ṣàn lójú wọn. Lẹ́yìn náà, wọ́n jọ jẹun pọ̀, wọ́n jẹ ẹran ẹlẹ́dẹ̀ dídín báwọn ará Cuba ṣe ń dín tiwọn, wọ́n jẹ ìrẹsì àtẹ̀wà, sàláàdì, yucca àti mojo (ọbẹ̀ kan tí wọ́n ń fi atalẹ̀ àti òróró ólífì sè), àti èso táa ṣẹ̀ṣẹ̀ ká. Lẹ́yìn oúnjẹ náà, mẹ́ńbà kọ̀ọ̀kan ti Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso sọ ọ̀rọ̀ tí ń gbéni ró lórí bó ṣe yẹ ká gbé iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì gẹ̀gẹ̀. Ọ̀rọ̀ tí Arákùnrin Lösch sọ tani jí gan-an, nítorí èdè Spanish ló fi bá àwọn ará sọ̀rọ̀. Àwọn òṣìṣẹ́ déédéé tí wọ́n jẹ́ méjìdínláàádọ́ta, àti àwọn méjìdínlógún tí wọ́n jẹ́ òṣìṣẹ́ onígbà díẹ̀ ló para pọ̀ jẹ́ mẹ́ńbà ìdílé Bẹ́tẹ́lì.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ítálì ni a ti ń tẹ ìwé ńlá àti Bíbélì fún àwọn ará tó wà ní Cuba, orílẹ̀-èdè Cuba gan-an la ti ń fi ẹ̀rọ aṣẹ̀dà ìwé púpọ̀ tẹ àwọn ìwé ìròyìn aláwọ̀ dúdú àti funfun ti Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Ó ń béèrè ọ̀pọ̀ wákàtí àti iṣẹ́ àfọwọ́ṣe láṣetúnṣe nínú àwọn ilé tó há kí a tó lè tẹ gbogbo ìwé ìròyìn tí wọn nílò jáde. Àwọn tí wọ́n yọ̀ǹda ara wọn ka iṣẹ́ ìsìn wọn sí Jèhófà sí ohun ribiribi gan-an.—2 Kọ́ríńtì 4:7.

Àwọn Kókó Pàtàkì Inú Àpéjọpọ̀

A pin ìgbìmọ̀ aṣojú ẹlẹ́ni méjìdínlógún yìí sí ìsọ̀rí mẹ́ta láti lè wà ní àpéjọpọ̀ àgbègbè mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tó wáyé ní Havan, Camagüey, àti Holguín. Ní ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọjọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyí, a ké sí àwùjọ àwọn arákùnrin àti arábìnrin rẹpẹtẹ, tó fi mọ́ ọ̀pọ̀ alàgbà àti aṣáájú ọ̀nà, láti wá sí ibi tí a ó ti ṣe àpéjọpọ̀ kọ̀ọ̀kan. A ti sọ fún Àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ládùúgbò pé àkànṣe ni ìpàdé èyí máa jẹ́, ṣùgbọ́n wọn kò mọ̀ pé àwọn mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso yóò wà níbẹ̀. Wo bó ti yà wọ́n lẹ́nu tó láti rí àwọn arákùnrin ọ̀wọ́n wọ̀nyí àti àwọn aya wọn tí wọ́n ń sọ̀ kalẹ̀ láti inú bọ́ọ̀sì tí a háyà lówùúrọ̀ Friday!

Inú àwọn ilé àpéjọ tí àwọn ara kọ́ lábẹ́ ìyọ̀ǹda àwọn aláṣẹ la ti ṣe àpéjọpọ̀ náà. Ní àpéjọpọ̀ tí a ṣe ní Havana, a gbẹ́ ọ̀rọ̀ “Sáàmù 133:1” sára ọ̀kan lára àwọn òkúta tó wà ní àbáwọlé. Èyí rán àwọn ará létí ẹsẹ náà tó kà pé: “Wò ó! Ó mà dára o, ó mà dùn o, pé kí àwọn ará máa gbé pa pọ̀ ní ìṣọ̀kan!” Ó dájú pé, nígbà àpéjọpọ̀ yẹn, ìfararora Kristẹni tó dára, tó sì gbádùn mọ́ni wà ní ibẹ̀ yẹn.

Àwọn olùbẹ̀wò sọ̀rọ̀ nípa ọ̀nà gbígbámúṣé tí a gbà sọ àwọn àwíyé àti ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò, báa ṣe gbé àwòkẹ́kọ̀ọ́ náà kalẹ̀ sì wú wọn lórí, àwòkẹ́kọ̀ọ́ tí a gbé ka ìtàn inú Bíbélì ti Dáníẹ́lì orí 3, èyí tó wáyé ní Bábílónì ìgbàanì. Arábìnrin kan sọ pé: “Gbogbo àwọn tó kópa ló ṣe dáadáa, ìfaraṣàpèjúwe wọn sì bá ohùn tí a gbà sílẹ̀ mu tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tó fi jẹ́ pé o kò ní tètè mọ̀ pé wọ́n ti gba ohùn náà sílẹ̀ ṣáájú. . . . Àwọn tó ṣe olubi ará Bábílónì hùwà bí olubi gan-an, àwọn tó sì ṣe Hébérù mẹ́ta dúró gbọn-in, wọn ò sì mikàn.”

Àwọn aṣojú Ọ́fíìsì Tó Ń Mójú Tó Ọ̀ràn Ẹ̀sìn àti àwọn lọ́gàálọ́gàá mìíran lẹ́nu iṣẹ́ ọba tó wá sí àpéjọpọ̀ náà gbóríyìn fún àwọn ará fún ìmètòóṣe àti ìwà rere wọn. Arákùnrin Barry sọ ọ̀rọ̀ ìmoore àtọkànwá lórí ọ̀nà tó gbámúṣé tí àwọn aláṣẹ ilẹ̀ Cuba fi bá àwọn aṣojú tó wá ṣèbẹ̀wò náà lò. Láti fi ìmọrírì hàn fún àwọn àwíyé tí wọ́n ń gbọ́ àti fún yíyọ̀ǹda tí àwọn aláṣẹ yọ̀ǹda fún wọn láti ṣe àpéjọpọ̀ náà, ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn ará dìde dúró fún ìṣẹ́jú díẹ̀, pẹ̀lú àtẹ́wọ́ tí ń ró wàá-wàá-wàá. Ìdílé Kristẹni kan wí pé: “A kò mọ̀ pé ohun tí yóò tó báyìí ni—àpéjọpọ̀ àgbáyé kékeré lèyí! Èyí ga jù, ó ti jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ní agbára ńlá láti jẹ́ kí àwọn ìlérí òun ṣẹ.”

Àwọn àpéjọpọ̀ náà tún pèsè àǹfààní láti jẹ́ kí àwọn èèyàn túbọ̀ mọ Àwọn Ẹlẹ́rìí dáadáa. Ọ̀kan lára àwọn awakọ̀ èrò wá sí àpéjọpọ̀ náà lọ́jọ́ Saturday, ó tún wá lọ́jọ́ Sunday. Ó ní etí òun ti kún fún ọ̀pọ̀ nǹkan tí òun ti gbọ́ nípa Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó ní ṣùgbọ́n nísinsìnyí o, òun ti wá mọ̀ pé èèyàn rere, èèyàn àlàáfíà ni wọ́n.

“Àwọn Nǹkan Tí A Kò Ní Gbàgbé Láé”

Ìfẹ́ àti ọ̀yàyà àwọn ará Cuba wú àwọn aṣojú náà lórí púpọ̀. Àwọn ará Cuba kì í fiṣẹ́ wọn ṣeré rárá, wọ́n ní ìpinnu, wọ́n sì tún jẹ́ onínúure. Aṣojú kan sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ìgbà ni àwọn táà mọ̀ rí máa ń fẹ́ láti ràn wá lọ́wọ́.”

Ìgbàgbọ́, ayọ̀, àti ìfẹ́ tí Àwọn Ẹlẹ́rìí ẹlẹgbẹ́ wa tí wọ́n wà ní Cuba fi hàn wú àwọn aṣojú náà lórí gidigidi. Láìfi àwọn ìṣòro ńláǹlà pè, wọ́n fi Jèhófà ṣe odi agbára wọn. (Sáàmù 91:2) John Barr wí pé: “Ọ̀pọ̀ nǹkan ló yà mí lẹ́nu gidigidi nínú ìbẹ̀wò mi àkọ́kọ́ tí mo ṣe sí Cuba yìí—ẹwà orílẹ̀-èdè yìí, ìwà títunilára táwọn tí mo bá pàdé hù, èyí tó wá yà mí lẹ́nu jù lọ ni ayọ̀ ńláǹlà tí Àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ní Cuba ní. N kò tí ì gbọ́ orin Ìjọba Ọlọ́run táa kọ́ látọkànwá tó bẹ́ẹ̀ rí, bẹ́ẹ̀ sì ni n kò tí ì gbọ́ àtẹ́wọ́ tó ń dún ní mẹ́sàn-án mẹ́wàá nígbà tí ohun tẹ̀mí bá wọnú ọkàn àyà ẹni tó bẹ́ẹ̀ rí! A kò lè gbàgbé nǹkan wọ̀nyí láé. Títí ayé la óò máa ṣìkẹ́ wọn.”

Sáàmù 97:1 sọ pé: “Kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ erékùṣù máa yọ̀.” Ká sòótọ́, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí ń gbé ní erékùṣù Cuba ń yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ nítorí àfikún òmìnira láti jọ́sìn Ọlọ́run táa fún wọn báyìí, inú wọn tún dùn sí ìbẹ̀wò mánigbàgbé tí àwọn aṣojú káàkiri àgbáyé yìí ṣe.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

Ọ̀pọ̀ ídílé ló wá sí àkànṣe Àpéjọpọ̀ Àgbègbè ti “Ọ̀nà Ìgbésí Ayé tí Ọlọ́run Fẹ́” tó wáyé ní Cuba

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

A padà ṣí Ilé Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Havana lọ́dún 1994

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

Àwọn mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso fọwọ́ kọ̀wé sínú Bíbélì tí wọ́n fi ta àwọn lọ́gàálọ́gàá lẹ́nu iṣẹ́ ọba lọ́rẹ.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́