Rírí Ojúlówó Àlàáfíà ní Orílẹ̀-Èdè Tó Kún fún Wàhálà
Ìròyìn kan tó jáde lọ́dún 1969 sọ pé: “Àǹjọ̀nnú tó ń dá rúkèrúdò sílẹ̀ láàárín àwọn ẹ̀ya ẹ̀sìn ti bẹ́ sígboro.” Ìyẹn ni ìgbà tí Wàhálà bẹ̀rẹ̀ sí í peléke sí i ní Northern Ireland, ìgbà àìsinmi àti àìbalẹ̀ ọkàn.
RÚKÈRÚDÒ láàárín àwọn ẹ̀ya ẹ̀sìn àti ìpànìyàn ti wá di ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lójoojúmọ́ bí àwọn panipani Pùròtẹ́sítáǹtì àti Kátólíìkì ṣe ń bá a nìṣó láti máa jà fún jíjẹ gàba léni lórí nílẹ̀ Ireland, àwọn tí à ń sọ yìí ni “àwọn ẹhànnà èèyàn tó wà ní ìhà méjèèjì,” àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú àti ti ẹ̀sìn. Ìwé ìròyìn The Irish Times sọ pé, láti ìgbà yẹn, “ó ti lé ní egbèjìdínlógún ènìyàn tí wọ́n ti pa, tí ọ̀pọ̀ sì ti di abirùn láàárín ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọgbọ̀n ọdún tí ìrúkèrúdò náà fi wà.”
Kò ṣẹ̀ṣẹ̀ láà ń sọ pé irú jíjà fitafita láti jẹ gàba léni lórí yìí kò jẹ́ tuntun. Ó ti ń yọ Ireland lẹ́nu fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún. Láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, Northern Ireland làwọn èèyàn ti mọ̀ ọ́n lára jù lọ, àmọ́, ẹ̀tanú àti ìjà tó ti dá sílẹ̀ ti ba ayé ọ̀pọ̀lọpọ̀ jẹ́ jákèjádò Ireland.
Bí ọ̀ràn náà ti le tó yìí, ó ti lé ní ọgọ́rùn-ún ọdún tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń tọ́ka sí ojúlówó ojútùú tó wà fún àwọn ìṣòro tó dojú kọ orílẹ̀-èdè tó kún fún wàhálà yìí. Ojútùú yẹn ni Ìjọba Ọlọ́run táa gbé lé Jésù Kristi lọ́wọ́. (Mátíù 6:9, 10) Nígbà tí Wàhálà náà bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 1969, Ẹlẹ́rìí Jèhófà ẹgbẹ̀rin ó lé mẹ́rìndínlọ́gọ́rin péré ló wà ní Ireland. Ní báyìí, wọ́n ti lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́rin àtààbọ̀ ní àwọn ìjọ tó lé lọ́gọ́rùn-ún. Àwọn ìrírí díẹ̀ nìyí látọ̀dọ̀ àwọn kan tí wọn ò bá wọn lọ́wọ́ sí ètò ìṣèlú, tí wọn ò sì gbaṣẹ́ ológun.
“Tí Mo Bá Dàgbà, Máa Di Sójà Ilẹ̀ Olómìnira Ireland!”
Inú ìjọ Kátólíìkì ni Michaela dàgbà sí ní Ilẹ̀ Olómìnira Ireland. Nígbà tó wà ní ilé ìwé, wọ́n kọ́ ọ ni ohun kan nípa ìtàn Ireland àti ìforígbárí tó ti wà láàárín ilẹ̀ náà àti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún. Nígbà tó wà lọ́mọdé, ó kórìíra àwọn Gẹ̀ẹ́sì gan-an, nítorí pé ó kà wọ́n sì “àwọn tó ń ni àwọn ará Ireland lára.” Nígbà tó wà lọ́mọ ọdún mẹ́wàá, ó sọ fún ìyá rẹ̀ àgbà pé, “Tí mo bá dàgbà, màá di sójà [Ilẹ̀ Olómìnira Ireland]!” Ó ní: “Mo gba ìgbájú kan tí mo ṣì ń rántí di oní olónìí.” Ìgbẹ̀yìn gbẹ́yín ló ṣẹ̀ṣẹ̀ wá gbọ́ pé baba òun àgbà wà nínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní. Ìgbà kan tiẹ̀ wà tí ìyá rẹ̀ àgbà ní láti dúró síwájú baba rẹ̀ àgbà kí àwọn sójà Ilẹ̀ Olómìnira Ireland má bàa yìnbọn pa á.
Síbẹ̀, nígbà tí Michael dàgbà tán, ó fẹ́ ṣe nǹkan kan láti ṣèrànwọ́ fún àwọn Kátólíìkì ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ní Northern Ireland. Ó sọ pé: “Lójú tèmi, ó dà bí ẹni pé àwọn sójà Ilẹ̀ Olómìnira Ireland nìkan ló ń ṣe nǹkankan láti ran àwọn Kátólíìkì tó wà ní Northern Ireland lọ́wọ́.” Nítorí ohun tó rí, tó sì rò pé bẹ́ẹ̀ lọ̀ràn rí yìí, ó di sójà Ilẹ̀ Olómìnira Ireland, wọ́n sì kọ́ ọ bí wọ́n ṣe ń lo ohun ìjà. Mẹ́ta lára àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ làwọn ọmọ ogun Pùròtẹ́sítáǹtì yìnbọn pa ní Northern Ireland.
Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, ìjà àjàkú-akátá táwọn ọmọ ogun ń jà kiri yìí sú Michael pátápátá, fún àpẹẹrẹ, ẹ̀tanú burúkú tó wà láàárín ẹgbẹ́ ọmọ ogun kan sí èkejì tún ń dà á láàmú. Nígbà tó wà lẹ́wọ̀n nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ kan tó ní í ṣe pẹ̀lú ìgbòkègbodò àwọn sójà Ilẹ̀ Olómìnira Ireland, ó gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kó ran òun lọ́wọ́ láti rí ojúlówó ọ̀nà sí àlàáfíà pípẹ́ títí àti àìṣègbè. Nígbà tó ṣe díẹ̀ lẹ́yìn ìyẹn, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣèbẹ̀wò sí ilé rẹ̀. Àmọ́, ẹ̀tanú tó ti ní tẹ́lẹ̀ kò jẹ́ kó fara balẹ̀. Ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì làwọn Ẹlẹ́rìí náà. Ìkórìíra burúkú tó wà ní ọkàn rẹ̀ mú kó ṣòro fún un láti fetí sílẹ̀. Ó ní: “Inú mi kì í sábà dùn láti rí wọn, àmọ́, wọn ò dẹ́kun wíwá sọ́dọ̀ mi, bẹ́ẹ̀ ni wọn ò dákẹ́ bíbá mi sọ̀rọ̀, mo wá bẹ̀rẹ̀ sí í rí i pé Ìjọba Ọlọ́run ni yóò fòpin sí gbogbo àìṣègbè tó wà nínú ìṣèlú àti ti àárín ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà tí mo ń jà fitafita láti mú kúrò.”—Sáàmù 37:10, 11; 72:12-14.
Ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kan ni ọ̀rọ̀ wá dójú ẹ gan-an, nígbà tí Michael pàdé ọ̀gágun rẹ̀ tí wọ́n jọ wà nínú sójà Ilẹ̀ Olómìnira Ireland, tó sọ pé, “A ní iṣẹ́ kan fún ọ láti ṣe.” Michael sọ pé: “Mo rí i pé mo ní láti ṣèpinnu ní kíákíá yẹn, bí mo ṣe mí kanlẹ̀ nìyẹn tí mo sì sọ pé ‘Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni mí báyìí,’ bó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò tíì ṣèrìbọmi nígbà yẹn. Mo ṣáà mọ̀ pé mo fẹ́ di ìránṣẹ́ Jèhófà.” Ohun tí ọ̀gágun náà fi fèsì ni pé: “Ṣe ló yẹ kí wọ́n fi ẹ̀yìn ẹ ti ògiri, kí wọ́n sì yìnbọn pa ọ.” Láìfi gbogbo ìhàlẹ̀ rẹ̀ pè, Michael fi sójà Ilẹ̀ Olómìnira Ireland sílẹ̀. Ohun tó fún un níṣìírí láti ṣe èyí ni ọ̀rọ̀ Jèhófà tó jẹ́ kó nípa lórí èrò inú àti ọkàn òun. “Nígbà tó yá, ìyàwó mi àti àwọn kan lára àwọn ọmọ mi ya ìgbésí ayé wọn sí mímọ́ fún Jèhófà. A ti wá ní ojúlówó àlàáfíà nínú ọkàn wa báyìí. Gbogbo ìgbà la ó sì máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún mímú kí ó ṣeé ṣe fún wa láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ àti láti nípìn-ín nínú sísọ ìhìn iṣẹ́ àlàáfíà fáwọn èèyàn ní orílẹ̀-èdè kan tó kún fún wàhálà.”—Sáàmù 34:14; 119:165.
Ààbò Gidi Ló Jẹ́ Láti Wà Láìdásí-Tọ̀tún-Tòsì
Patrick sọ pé: “Àgbègbè àrọko kan ni wọ́n ti tọ́ mi dàgbà ní Àgbègbè Derry ní Northern Ireland. N kò dá ohunkóhun mọ̀ nígbà tí mo wà lọ́mọdé ju àwọn Wàhálà tó ń ṣẹlẹ̀ lọ. Kò sí àní-àní pé àyíká yẹn nípa lórí ojú ìwòye mi àti bí mo ṣe ń ronú.” Èrò òdì pátápátá ló wà lọ́kàn Patrick nísinsìnyí, nítorí pé ó nífẹ̀ẹ́ orílẹ̀-èdè rẹ̀ kọjá ààlà, ó sì kórìíra àwọn Gẹ̀ẹ́sì ju nǹkan míì lọ. Ó rí àwọn tí wọ́n jẹ́ onísìn nínú ẹgbẹ́ òṣèlú méjèèjì tí wọn ò pa àwọn ìlànà tí ìsìn Kristẹni gbé kalẹ̀ mọ́, tí wọn ò sì ní ìwà tó yẹ ọmọlúwàbí. Nípa bẹ́ẹ̀, ó kẹ̀yìn sí ìsìn, níkẹyìn ó di ẹni tí kò gba Ọlọ́run gbọ́ ló bá di ọ̀kan lára àwọn olójú ìwòye Marx, ẹni tí kò gbọlọ́run gbọ́.—Fi wé Mátíù 15:7-9; 23:27, 28.
Patrick sọ pé: “Àwọn ohun tí mo lè tètè rántí pé ó ṣẹlẹ̀ nígbà yẹn lọ́hùn-ún ni bí àwọn ẹlẹ́wọ̀n ẹgbẹ́ Republic ṣe ń febi para wọn ní ìhà Àríwá. Wọ́n nípa lórí mi gan-an ni. Mo rántí bí mo ṣe gbé àsíá Ireland, tí mo sì ń kọ ìkọkúkọ nípa àwọn Gẹ̀ẹ́sì sí gbogbo ibi tí mo lè kọ ọ́ sí. Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, mo ṣiṣẹ́ olùṣọ́ níbi ààtò ìsìnkú ọ̀kan lára àwọn tó febi para wọn kú sọ́gbà ẹ̀wọ̀n.” Bíi tí ọ̀pọ̀ àwọn mìíràn tí wọn ò rọ́nà àbáyọ nínú pákáǹleke àti ìdàrúdàpọ̀ tó ń lọ lọ́wọ́ nígbà yẹn, Patrick bá wọn dá rúgúdù sílẹ̀, ó bá wọn wọ́de, kó ṣáà lè rí i pé a ń fi ẹ̀tọ́ báni lò lọ́gbọọgba, láàárín ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà. Ó wá ń bá ọ̀pọ̀ lára àwọn tó nífẹ̀ẹ́ orílẹ̀-èdè lánìíjù dọ́rẹ̀ẹ́, àwọn tó jẹ́ pé ọ̀pọ̀ lára wọn ni àwọn aláṣẹ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì sọ sẹ́wọ̀n.
Patrick sọ pé: “Lẹ́yìn náà ni mo wá lọ lo àkókò díẹ̀ ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì nítorí ìṣúnná owó. Ìgbà tí mo wà níbẹ̀ ni àwọn ọlọ́pàá Gẹ̀ẹ́sì mú ọ̀kan lára àwọn ọ̀rẹ́ mi tó gbaṣẹ́ jíju bọ́ǹbù kiri.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Patrick ṣì ní ìfẹ́ orílẹ̀-èdè rẹ̀, síbẹ̀ ìṣarasíhùwà rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í yí padà. Ó bẹ̀rẹ̀ sí í rí i pé ẹ̀tanú tí òun ní sí gbogbo ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ rárá. Ó ní: “Mo wá bẹ̀rẹ̀ sí í rí i pé ìgbòkègbodò àwọn ọmọ ogun kò lè yanjú àwọn ìṣòro tó wà nílẹ̀, kó sì fòpin sí ẹ̀mí ìṣègbè tó ń bà mí nínú jẹ́. Ìwà ìbàjẹ́ àti àwọn ìwà burúkú mìíràn ti pọ̀ jù láàárín àwọn tó ń darí ètò ọmọ ogun.”—Oníwàásù 4:1; Jeremáyà 10:23.
Níkẹyìn, Patrick padà sí Nothern Ireland. “Nígbà tí mo padà dé ni ọ̀rẹ́ mi kan mú mi mọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.” Inú ẹ̀kọ́ Bíbélì tí àwọn Ẹlẹ́rìí ń kọ́ Patrick ló ti wá bẹ̀rẹ̀ sí í rí ojúlówó ojútùú sí ìforígbárí àti àìsí ìrẹ́pọ̀ láàárín ẹ̀dá ènìyàn. Kíá ló tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí nítorí ipa tí àwọn ìlànà Bíbélì ní lórí èrò inú àti ọkàn-àyà rẹ̀. (Éfésù 4:20-24) Ó sọ pé: “Ní báyìí, dípò kí n máa dìtẹ̀ nípa bí n ó ṣe yí ètò tó ń lọ lọ́wọ́ padà, mo wá rí ara mi tí mò ń wàásù ìhìn iṣẹ́ àlàáfíà láti inú Bíbélì, kódà mò ń wàásù ní àgbègbè àwọn tó fara mọ́ ètò tó ń lọ lọ́wọ́ pàápàá, níbi tí n kì í fẹ́ dé rárá tẹ́lẹ̀. Àní, ní àkókò kan tí ìpànìyàn ẹ̀ya ẹ̀sìn pọ̀ gan-an ní Belfast, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nìkan ṣoṣo ló lè rìn fàlàlà ní àgbègbè àwọn tó fara mọ́ ìjọba àtàwọn tó ń jà fún ìlú wọn láìsí pé wọ́n fara pa mọ́ sínú ọkọ̀ ogun.” Bíi ti àwọn Ẹlẹ́rìí mìíràn ní Northern Ireland láàárín àkókò yìí, ó wá rí i pé wíwà láìdásí-tọ̀tún-tòsì bíi ti àwọn Kristẹni ìjímìjí jẹ́ ààbò ní tòótọ́. (Jòhánù 17:16; 18:36) Ó parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ báyìí pé: “Ó jẹ́ ohun tó tuni lára gan-an láti rí i pé Jèhófà yóò tipasẹ̀ Jésù Kristi pèsè ojúlówó àìṣègbè àti òmìnira kúrò nínú ìnilára fún gbogbo ẹ̀dá ènìyàn.”—Aísáyà 32:1, 16-18.
“Àwọn Ìbọn Mi Nìkan Ni Ààbò Mi”
“William sọ pé: “Òdì kejì ibi tí ìṣèlú àti ìsìn ti fa ìpínyà ni wọ́n ti tọ́ mi dàgbà. Bí mo ṣe di Pùròtẹ́sítáǹtì tó lẹ́tanú gan-an nìyẹn, mo wá kórìíra ohunkóhun tó bá jẹ́ ti Kátólíìkì dọ́ba. Kódà n kì í lọ sílé ìtajà èyíkéyìí tó bá jẹ́ ti Kátólíìkì, ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo péré ni mo ṣèbẹ̀wò sí Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Ireland. Mo kópa nínú onírúurú ẹgbẹ́ Pùròtẹ́sítáǹtì àti àwọn àjọ oríṣiríṣi, bí ẹgbẹ́ Orange Order—ẹgbẹ́ kan tó fi ara rẹ̀ fún dídáàbò bo ìsìn Pùròtẹ́sítáǹtì àti ọ̀nà ìgbésí ayé wọn.” Nígbà tí William di ọmọ ọdún méjìlélógún, ó dara pọ̀ mọ́ Àwọn Ọmọ Ogun Olùgbèjà, tó jẹ́ apá kan ẹgbẹ́ ọmọ ogun ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tí wọ́n ń gbà síṣẹ́ ládùúgbò. Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn mẹ́ńbà rẹ̀ ló jẹ́ ẹlẹ́sìn Pùròtẹ́sítáǹtì. Ó ṣe tán láti pànìyàn kó sì gbèjà ohun tó jogún bá yìí. “Àwọn ìbọn tí mo ní pọ̀ gan-an ni, kò sì sí nǹkan tó lè ní kí n má lò wọ́n bí àyè rẹ̀ bá yọ. Mo máa ń fi ọ̀kan sábẹ́ ìrọ̀rí mi lálẹ́.”
Àmọ́, àkókò ìyípadà ńlá kan wá dé. “Mo wá bẹ̀rẹ̀ síí rí i pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ohun àrà ọ̀tọ̀ kan nígbà tí mo bá ọ̀kan lára wọn ṣiṣẹ́ níbi táa ti lọ tún ilé àtijọ́ kan kọ́. Òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ mi yìí ní ipa tó jinlẹ̀ lórí mi. Ibi táa ti jọ ń ṣiṣẹ́ yẹn ni mo ti ráyè béèrè ọ̀pọ̀ ìbéèrè tó ń dà mí láàmú nípa àwọn Wàhálà tó ń ṣẹlẹ̀ káàkiri, ọ̀rọ̀ ìsìn, àti Ọlọ́run. Ìdáhùn rẹ̀ tó rọrùn, tó sì ṣe kedere ràn mí lọ́wọ́ láti rí ohun tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ gan-an—ẹgbẹ́ kan tó wà ní ìṣọ̀kan, tí kì í ṣe oníjàgídí-jàgan, tí kì í sì í dá sí tọ̀tún tòsì nínú ọ̀ràn ìṣèlú ni wọ́n, ohun tí a sì fi ń dá wọn mọ̀ ni ìfẹ́ tí wọ́n ní sí Ọlọ́run àti aládùúgbò wọn.”—Jòhánù 13:34, 35.
Láàárín oṣù mẹ́rin tí William bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó kọ̀wé fi gbogbo ìsìn àti àwọn òṣèlú tó ń dara pọ̀ mọ́ sílẹ̀. Ó rántí pé: “Ìgbésẹ̀ pàtàkì lèyí jẹ́ fún mi, nítorí pé mo ní láti fi ọ̀pọ̀ àwọn àṣà àtọwọ́dọ́wọ́, tó ti wà tipẹ́ tí mo ti ń gbé gẹ̀gẹ̀ sílẹ̀.” Síbẹ̀, àdánwò ńlá ṣì wà níwájú rẹ̀. “Nítorí bí ipò nǹkan ṣe rí ní Northern Ireland, mo gbà pé àwọn ìbọn tí mo ní nìkan ló lè dáàbò bò mí. Èmi ni àwọn Sójà Ilẹ̀ Olómìnira Ireland kà sí ‘ẹni tí a yàn sọjú gan-an.’ Nípa bẹ́ẹ̀, ó wá ṣòro fún mi láti pa àwọn ohun ìjà wọ̀nyí tì.” Àmọ́, ni kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ìmọ̀ràn Bíbélì, bí irú èyí tó wà nínú Aísáyà 2:2-4, yí èrò rẹ̀ padà. Níkẹyìn, ó wá rí i pé Jèhófà ni ojúlówó ààbò òun, gẹ́gẹ́ bí Ó ṣe jẹ́ fún àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní. Bí William ṣe kó gbogbo ìbọn rẹ̀ sílẹ̀ nìyẹn o.
William sọ pé: “Ọ̀kan lára ohun tó ń múnú mi dùn jù báyìí ni pé, mo ti wá ní àjọṣe tó jinlẹ̀, tó sì wà pẹ́ títí pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí ǹ bá ti kà sí ọ̀tá paraku tẹ́lẹ̀. Bákan náà ló tún jẹ́ orísun ojúlówó ayọ̀ fún mi pé ó ṣeé ṣe fún mi láti mú ìhìn iṣẹ́ ìrètí tó wà nínú Bíbélì lọ sí àwọn ibi tó ti fìgbà kan rí jẹ́ ‘ibi tí n kò gbọ́dọ̀ dé.’ Bí mo ṣe ń ronú lórí ohun tí òtítọ́ ti ṣe fún èmi àti ìdílé mi ni mó ń kún fún ọpẹ́ sí Jèhófà àti ètò àjọ rẹ̀.”
“Àwọn Nǹkan Ò Tiẹ̀ Yé Mi Mọ́”
Ipò àtilẹ̀wá Robert àti Teresa yàtọ̀ síra pátápátá. Robert sọ pé: “Ìdílé Pùròtẹ́sítáǹtì paraku ni mo ti wá. Àwọn kan lára àwọn ìbátan mi ti lọ́wọ́ nínú ìgbòkègbodò tó ní í ṣe pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun. Èmi pàápàá dara pọ̀ mọ́ Àwọn Ọmọ Ogun Olùgbèjà ti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì lọ́mọ ọdún mọ́kàndínlógún. Ìgbà tó pọ̀ jù lọ lákòókò yẹn la fi ń lọ káàkiri àgbègbè tí Teresa ń gbé. Lálẹ́ ọjọ́ kan, wọ́n yí iṣẹ́ mi padà, n kò sí lára àwọn tó máa ń pààrà àárín ìgboro mọ́. Alẹ́ ọjọ́ yẹn ni wọ́n fi bọ́ǹbù fọ́ ọkọ̀ arinkòtò-rin-gegele tó yẹ kí n máa fi pààrà ìgboro. Sójà méjì ló kú, àwọn méjì mìíràn sì fara pa.”
Robert wá bẹ̀rẹ̀ sí ṣe kàyéfì nípa ohun tí ìgbésí ayé túmọ̀ sí. “Àtìbẹ̀rẹ̀ ni mo ti gba Ọlọ́run gbọ́, àmọ́ nígbà tí mo wá wo gbogbo Northern Ireland yí ká, àwọn nǹkan ò wá yé mi mọ́. Mo wá bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà sí Ọlọ́run. Mo bẹ Ọlọ́run pé tó bá jẹ́ pé lóòótọ́ ló wà, kó jọ̀wọ́ fi ọ̀nà tí mo lè gbà gbé ìgbésí ayé mi hàn mí. Mo rántí pé mo sọ fún Ọlọ́run pé ìsìn tòótọ́ kan ní láti wà níbì kan!” Ọjọ́ díẹ̀ lẹ́yìn ìyẹn gan-an ni ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ Robert tó sì fí àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ díẹ̀ sílẹ̀ fún un. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ilẹ̀ ti ṣú kí Robert tó padà sílé láti ibi tó ti lọ ṣiṣẹ́ lálẹ́ ọjọ́ yẹn, síbẹ̀ ó bẹ̀rẹ̀ sí ka ìwé náà, ó sì parí rẹ̀ láago márùn-ún òwúrọ̀. Ó sọ pé: “Kíá ni mo rí òtítọ́ tó wà níbẹ̀, tí mo sì wá rí i pé àtinú Bíbélì tààrà ni gbogbo rẹ̀ ti ń wá.” (2 Tímótì 3:16) Ó bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kò sì pẹ́ tó fi ya ìgbésí ayé rẹ̀ sí mímọ́ fún Ọlọ́run.
“Àwọn Ẹlẹ́rìí Sábà Máa Ń Darí Wa sí Bíbélì”
Ní òdìkejì, ìdílé Kátólíìkì ni wọ́n ti tọ́ Teresa dàgbà ní tirẹ̀, ó sì ní ìmí ẹ̀dùn tó jinlẹ̀ fún orílẹ̀-èdè rẹ̀. Teresa sọ pé: “Gẹ́gẹ́ bí ọmọbìnrin kékeré, mo dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ Sinn Féin.b Èyí ló mú kí n bẹ̀rẹ̀ sí í lọ́wọ́ nínú àwọn ìgbòkègbodò ẹgbẹ́ ọmọ ogun. Mo bá wọn kó owó tí wọ́n máa lò fún ogun jọ. Mo ń fi ohun tó ń lọ lágbègbè tí mo wà tó àwọn Sójà Ilẹ̀ Olómìnira Ireland létí. Mo tún bá wọn lọ́wọ́ nínú dídá rúgúdù sílẹ̀ àti ká máa ju òkúta lu àwọn ọlọ́pàá àti àwọn ọmọ ogun tó ń lọ káàkiri.”
Ìgbà tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn kan lára àwọn ìdílé Teresa ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ni òun náà wá bẹ̀rẹ̀ sí í nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀kọ́ náà. Agbára Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nípa lórí rẹ̀ gan-an ni. Ó sọ pé: “Àwọn Ẹlẹ́rìí sábà máa ń darí wa sínú Bíbélì láti rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wa. Ojúlówó ìlàlóye ni ìlérí tó wà nínú Dáníẹ́lì 2:44 jẹ́. Mó wá rí i pé Ìjọba Ọlọ́run ni ojúlówó ọ̀nà láti mú gbogbo ẹ̀mí ìṣègbè tí mo ń jà lé lórí kúrò.” Àwọn kan lára ìwà ìkà bíburú jáì tí àwọn ẹgbẹ́ ológun ń hù ń bí i nínú gan-an ni. Fún àpẹẹrẹ, Teresa ò rí ìdí tí ẹnì kan tó lẹ́mìí ìyọ́nú, tó sì jẹ́ ọmọlúwàbí ṣe lè máa yọ̀ nígbà tó bá ń gbọ́ itú tí àwọn apániláyà ń pa, níbi tí wọ́n ti ń pa àwọn sójà tàbí àwọn ẹlòmíràn tàbí tí wọ́n ti ń sọ wọ́n di abirùn, tí ìbànújẹ́ àti làásìgbò sì ti ń da àwọn ìdílé lọ́kàn rú. Lòun náà ba tẹ́wọ́ gba òtítọ́ Bíbélì, tó sì gbà kí àwọn ìlànà Ọlọ́run yí èrò òun padà. Ó ya ìgbésí ayé rẹ̀ sí mímọ́ fún Ọlọ́run, kò sì pẹ́ tó fi ṣe ìrìbọmi.—Òwe 2:1-5, 10-14.
Teresa bá Robert pàdé nígbà tí àwọn méjèèjì wá sípàdé ní ọ̀kan lára ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Northern Ireland. Ohun tó sọ ni pé: “Nígbà tí mo kọ́kọ́ bá Robert pàdé, ó ṣòro fún mi gan-an láti rí ará mi tí mò ń fi pẹ̀lẹ́tù àti ẹ̀mí àlàáfíà bá ẹni yìí sọ̀rọ̀, ẹni tó jẹ́ pé títí di àìpẹ́ sí àkókò yẹn, ara ẹgbẹ́ ọmọ ogun ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ni mo kà á sí. Dájúdájú, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti ràn mí lọ́wọ́ láti mú ìkórìíra àti ẹ̀tanú tó ti wọ̀ mí lọ́kàn ṣinṣin kúrò.” Òun àti Robert wá rí i pé dípò kí ìkórìíra àti ẹ̀tanú tí àṣà àti ìṣẹ̀dálẹ̀ tó yàtọ̀ síra máa ń mú wá pín àwọn níyà, ọ̀pọ̀ nǹkan làwọn fi bára mu báyìí. Èyí tó lágbára jù lọ nínú nǹkan wọ̀nyí ni ìfẹ́ tí wọ́n ní fun Jèhófà Ọlọ́run. Wọ́n ṣègbéyàwó. Ní báyìí, wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ pọ̀ láti mú ìhìn iṣẹ́ àlàáfíà ti Ọlọ́run lọ sọ́dọ̀ àwọn ènìyàn látinú gbogbo àṣà àti onírúurú ìgbàgbọ́ ni orílẹ̀-èdè tó kún fún wàhálà yìí.
Àwọn mìíràn tún ti ní irú ìrírí kan náà ní Ireland. Bí wọ́n ṣe fetí sí àwọn ẹ̀kọ́ tó wà nínú Ọ̀rọ̀ onímìísí ti Ọlọ́run, tí wọ́n sì tẹ́wọ́ gbà á ti mú kí wọ́n bọ́ lọ́wọ́ ‘ìmọ̀ ọgbọ́n orí àti àwọn ẹ̀tàn òfìfo’ ènìyàn. (Kólósè 2:8) Ní báyìí, wọ́n gbé ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún tí wọ́n ní karí àwọn ìlérí Ọlọ́run tí a kọ sínú Bíbélì. Inú wọn ń dùn láti bá ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ gbọ́ sọ̀rọ̀ nípa ìrètí ọjọ́ iwájú alálàáfíà tí wọ́n ní—nínú èyí tí kò ti ní sí ọ̀ràn ẹ̀ya ìsìn àti àwọn ìwà ipá mìíràn mọ́.—Aísáyà 11:6-9.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí àwọn orúkọ padà.
b Ẹgbẹ́ òṣèlú kan tó ń ṣiṣẹ́ ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú àwọn Sójà Ilẹ̀ Olómìnira Ireland Tó Wà fún Ìgbà Díẹ̀.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Wọ́n ń fi àwọn àwòrán tó wà lára ògiri jákèjádò Northern Ireland gbé ìjà tí àwọn ẹgbẹ́ ológun ń jà kiri lárugẹ