ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w99 12/15 ojú ìwé 32
  • “Báwo La Ó Ṣe Ta Àwọn Ìjọ Wa Tó Wà Káàkiri Jí?”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Báwo La Ó Ṣe Ta Àwọn Ìjọ Wa Tó Wà Káàkiri Jí?”
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
w99 12/15 ojú ìwé 32

“Báwo La Ó Ṣe Ta Àwọn Ìjọ Wa Tó Wà Káàkiri Jí?”

Ọ̀PỌ̀ ènìyàn ni kò yà lẹ́nu pé ìwé ìròyìn Kátólíìkì ní èdè Faransé Famille Chrétienne (Ìdílé Kristẹni), béèrè ìbéèrè yẹn lẹ́nu àìpẹ́ yìí. Kádínà Hume ti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tilẹ̀ pe àwọn ìjọ wọn tó wà káàkiri ní “alágbára tó sàsùnpara.” Wọ́n ti ṣètò pé kí àwọn kan lára àwọn ìjọ tó wà káàkiri lọ máa wàásù fún àwọn ìjọ yòókù, kí oorun lè dá lójú wọn. Àlùfáà ará Ítálì kan pè é ní: “Lílo ọ̀nà tuntun láti jíhìn rere lọ́nà tó ṣe tààràtà.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹnu àìpẹ́ yìí ni póòpù pàápàá fọwọ́ sí lílo irú ọgbọ́n bẹ́ẹ̀, síbẹ̀ kì í ṣe gbogbo ènìyàn ló rí ìjẹ́pàtàkì sísọ ìgbàgbọ́ wọn fún àwọn ẹlòmíràn.

Pigi Perini, àlùfáà tó ń bójú tó ìjọ àgbègbè kan ní Ítálì, wá sí Áfíríkà lẹ́nu àìpẹ́ yìí, níbi tí obìnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ànìkàngbé kan ti sọ fún un pé: “Ogójì ọdún tí mo ti wà níbí rèé, n kò dárúkọ Jésù rí nítorí n kò fẹ́ pa àṣà ìbílẹ̀ Áfíríkà run.” Àlùfáà náà parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “A ò sọ̀rọ̀ nípa Jésù mọ́, a ò ní nǹkankan ṣe pẹ̀lú Jésù mọ́, bẹ́ẹ̀ la ò wàásù ìhìn rere náà mọ́!” Àmọ́ ṣá o, ọ̀pọ̀ ló wà tó jẹ́ pé iṣẹ́ ìwàásù ló kó ipa tó ṣe pàtàkì jù nínú ìgbésí ayé wọn, òun sì ni ọ̀nà tí wọ́n fi ń wà lójúfò nípa tẹ̀mí. Pigi Perini sọ pé: “Tóò bá bá àwọn méjì pàdé tí wọ́n ń sọ̀rọ̀ nípa Kristi lọ́jà, tàbí tí wọ́n gbé Bíbélì sí abíyá wọn, ohun tó máa wá sí ẹ lọ́kàn ni pé: Wò ó, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà rèé!”

Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn ló ń gbádùn jíjíròrò Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Kò sí àní-àní pé àwọn Ẹlẹ́rìí ti ṣètò fún ìjíròrò Bíbélì ní àgbègbè tìẹ náà. Ní ìbámu pẹ̀lú bó ṣe rí ní ọ̀rúndún kìíní, àwọn Kristẹni onítara wọ̀nyí ń gba ara wọn níyànjú láti sọ ìgbàgbọ́ wọn fún àwọn ẹlòmíràn. Àwọn ibi tí wọ́n ti ń pàdé (tí wọ́n ń pè ní Gbọ̀ngàn Ìjọba) jẹ́ ibi tí ìfẹ́ àti ọ̀yàyà wà. Èé ṣe tóò fi lọ sí ọ̀kan lára àwọn ìpàdé tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣètò, kóo sì rí bóo ṣe lè gbógun ti títòògbé nípa tẹ̀mí?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́