Alexander Kẹfà—Póòpù Tí Róòmù Ò Lè Gbàgbé
“LÓJÚ àwọn Kátólíìkì, kò sí ọ̀rọ̀ búburú téèyàn lè sọ tó lè fi bí iṣẹ́ ọwọ́ Alexander Kẹfà ṣe burú tó hàn.” (Geschichte der Päpste seit dem Ausgang des Mittelalters [Ìtàn Àwọn Póòpù Láti Òpin Sànmánì Ojú Dúdú]) “Ohun tó ń dán wò lábẹ́lẹ̀ ò ṣeé fẹnu sọ rárá . . . A ní láti gbà pé póòpù yìí ò bọlá fún Ṣọ́ọ̀ṣì náà rárá. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé rírí irú ìwà ibi bẹ́ẹ̀ kì í ṣohun tuntun sáwọn tó gbé ayé lákòókò kan náà pẹ̀lú ìdílé Borgia, síbẹ̀ wọ́n rí i pé ìwà ọ̀daràn tí póòpù yìí àti ìdílé rẹ̀ hù bùáyà, ó burú débi pé ohun tó fà ó kúrò nílẹ̀ títí di ohun tó lé ní ọ̀rúndún mẹ́rin lẹ́yìn àkókò yẹn.”—L’Église et la Renaissance (1449 sí 1517) (Ṣọ́ọ̀ṣì àti Ìgbà Ìmúsọjí Ọ̀làjú).
Kí nìdí tí ìwé táwọn èèyàn ò kóyán rẹ̀ kéré rárá lórí ìtàn Ṣọ́ọ̀ṣì Roman Kátólíìkì fi sọ irú ọ̀rọ̀ tó burú jáì báyẹn nípa póòpù kan àti ìdílé rẹ̀? Kí ni wọ́n ṣe táwọn èèyàn fi ń ṣe àríwísí wọn tó bẹ́ẹ̀? Àfihàn sójútáyé kan tí wọ́n ṣe ní Róòmù (October 2002 sí February 2003), tí wọ́n pe àkọlé rẹ̀ ní I Borgia—l’arte del potere (Ìdílé Borgia—Bí Wọ́n Ṣe Lo Agbára Wọn), tún mú káwọn èèyàn rántí bí àwọn póòpù ṣe ṣi agbára lò, àgàgà bí Rodrigo Borgia, tàbí Alexander Kẹfà (póòpù 1492 sí 1503) ṣe ṣi agbára rẹ̀ lò.
Agbára Tẹ̀ Ẹ́ Lọ́wọ́
Ọdún 1431 ni wọ́n bí Rodrigo Borgia sínú ìdílé kan tó lókìkí ní Játiva, nínú ìjọba Aragon, tó ti di Sípéènì báyìí. Ẹ̀gbọ́n ìyá rẹ̀, ìyẹn Alfonso de Borgia, tó jẹ́ bíṣọ́ọ̀bù Valencia, bójú tó ẹ̀kọ́ ọmọ àbúrò rẹ̀, ó sì rí i pé àtìgbà tí Rodrigo ti wà ní ọ̀dọ́langba ló ti ń rọ́wọ́ mú nídìí oyè ṣọ́ọ̀ṣì (ìyẹn àwọn ipò oyè ṣọ́ọ̀ṣì tó máa ń mówó wọlé). Nígbà tí Rodrigo wà lọ́mọ ọdún méjìdínlógún, ó lọ sí Ítálì, níbi tó ti lọ kẹ́kọ̀ọ́ nípa òfin lábẹ́ àbójútó Alfonso, tó ti di kádínà nígbà yẹn. Nígbà tí Alfonso di Póòpù Calixtus Kẹta, ó sọ Rodrigo àti ọmọ àbúrò rẹ̀ mìíràn di kádínà. Ó sì sọ Pere Lluís Borgia di gómìnà ní onírúurú ìlú. Láìpẹ́, wọ́n fi Rodrigo ṣe igbá kejì gíwá ṣọ́ọ̀ṣì náà, ó sì wá nípò yìí lábẹ́ onírúurú póòpù, tó fi ráyè rí nǹkan kó jẹ gan-an, ó kó ọrọ̀ jọ, ó lo agbára bó ṣe fẹ́, ó sì gbé ìgbésí ayé ọlọ́lá bí ọba.
Orí Rodrigo pé gan-an, sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ ni, ó tún jẹ́ baba ìsàlẹ̀ iṣẹ́ ọnà, kò sì sí ohun tó ń fẹ́ tọ́wọ́ rẹ̀ ò lè tẹ̀. Àmọ́, ó bá àwọn obìnrin bíi mélòó kan ṣe panṣágà, obìnrin kan tí wọ́n sì jọ wà pa pọ̀ fúngbà pípẹ́ bímọ mẹ́rin fún un, àwọn obìnrin mìíràn sì tún bímọ fún un pẹ̀lú. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Póòpù Pius Kejì bá a wí nítorí “ìṣekúṣe àṣeèdábọ̀ rẹ̀,” tó ń kà sí ìgbádùn àti “fàájì àṣejù” tó ń ṣe, síbẹ̀ Rodrigo kò yí àwọn ìṣe rẹ̀ padà.
Nígbà tí Póòpù Innocent Kẹjọ kú ní 1492, àwọn kádínà ṣọ́ọ̀ṣì ṣèpàdé láti yan ẹni tó máa rọ́pò rẹ̀. Ó hàn gbangba pé owó rẹpẹtẹ tí Rodrigo Borgia gbé sílẹ̀, àti ọ̀pọ̀ ìlérí tó ṣe ló mú kí ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn kádínà dìbò fún un níbi ìpàdé wọn tó fi wá di pé òun ni wọ́n sọ di Póòpù Alexander Kẹfà. Kí ló wá san fáwọn kádínà tó dìbò fún un yìí? Ó fi oyè ṣọ́ọ̀ṣì dá wọn lọ́lá, ó fún wọn ní àwọn ààfin, àwọn ilé aláruru, àwọn ìlú, àwọn ṣọ́ọ̀ṣì ńláńlá, àti oyè bíṣọ́ọ̀bù pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ìjẹ tó wà níbẹ̀. O lè wá lóye ìdí tí ẹnì kan tó ń sọ ìtàn ṣọ́ọ̀ṣì fi pe ìṣàkóso Alexander Kẹfà ní “àwọn àkókò tí wọ́n kó ìtìjú àti ẹ̀gàn bá Ṣọ́ọ̀ṣì Róòmù.”
Kò Yàtọ̀ Sáwọn Ọba Ayé
Nítorí agbára tí Alexander Kẹfà ní lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn níwọ̀n bó ti jẹ́ pé òun ni olórí àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì, ó parí ìjà tó wà láàárín Sípéènì àti ilẹ̀ Potogí tó wà láwọn ìpínlẹ̀ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣàwárí rẹ̀ nílẹ̀ Amẹ́ríkà. Agbára tó ní nínú ayé ló mú kó di olórí gbogbo orílẹ̀-èdè táwọn póòpù ń ṣàkóso títí kan àwọn ìpínlẹ̀ tó wà ní àárín gbùngbùn Ítálì, ó sì ṣàkóso ìjọba rẹ̀ bíi tàwọn Ọba mìíràn gẹ́lẹ́. Ìjọba Alexander Kẹfà ò yàtọ̀ sí tàwọn póòpù tó ṣáájú rẹ̀ àtàwọn tó jẹ lẹ́yìn rẹ̀ o, gbogbo èèyàn ló mọ̀ ọ́n mọ́ rìbá gbígbà, ṣíṣe ojúsàájú fún mọ̀lẹ́bí ẹni, àti ìpànìyàn bíi mélòó kan táwọn èèyàn fura sí.
Àwọn mìíràn tó tún jẹ́ alágbára bíi tirẹ̀ ń já lórí àwọn ìpínlẹ̀ tó jẹ́ ti àwọn ará Ítálì lákòókò onírúkèrúdò yẹn, ipa tí póòpù yìí kó nínú ìjà náà kì í sì í ṣe kékeré rárá. Ó fi ìṣèlú darí àwọn nǹkan, ó sì báwọn kan lẹ̀dí àpò pọ̀ lọ́nà tó máa jẹ́ kí agbára rẹ̀ pọ̀ sí i, tí ẹ̀kọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ á tẹ̀ síwájú, tá á sì gbé ìdílé Borgia ga ju ìdílé èyíkéyìí mìíràn lọ. Juan, ọmọkùnrin rẹ̀ fi mọ̀lẹ́bí ọba Castile ṣaya, wọ́n sì fi jẹ ọba Gandía, ní ilẹ̀ Sípéènì. Ọmọ rẹ̀ mìíràn tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jofré fi ọmọ ọmọ ọba Naples ṣaya.
Nígbà tí póòpù náà ń wá ẹni tó máa mú sòdí láti mú kí àjọṣe àárín òun àti ilẹ̀ Faransé lè dán mọ́rán sí i, ó yẹ àdéhùn tó ti ṣe pé kí ọ̀tọ̀kùlú kan ní Aragonese fi Lucrezia, ọmọbìnrin òun tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàlá ṣaya, ó wá mú ọmọbìnrin rẹ̀ yìí fún mọ̀lẹ́bí ọba Milan. Nígbà tó wá rí i pé ìgbéyàwó náà kò ní í ṣe ètò ìṣèlú òun lóore kankan, ó dá ọgbọ́n awúrúju kan tó fi di pé ìgbéyàwó náà ò ṣeé ṣe, Lucrezia sì wá fẹ́ ẹni kan tó jẹ́ ara ìlà ọba ibòmíràn, ìyẹn ni Alfonso ti Aragon. Àkókò yìí náà ni ẹ̀gbọ́n Lucrezia, tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Cesare Borgia, tó ń wá ipò gíga fún ara rẹ̀ tí ò sì lójú àánú rárá, lọ bá Louis Kejìlá ti ilẹ̀ Faransé lẹ̀dí àpò pọ̀, ìyẹn sì jẹ́ kí ìgbéyàwó tí àbúrò rẹ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe pẹ̀lú ará Aragonese yẹn di ọ̀ràn ìtìjú. Kí wá ni ojútùú sí ọ̀ràn náà? Ìtàn kan sọ pé Alfonso, ọkọ rẹ̀ tí kò ní olùgbèjà, “ṣèṣe gan-an nígbà tó bọ́ sọ́wọ́ àwọn mẹ́rin tí wọ́n fẹ́ pa á níbi àtẹ̀gùn Ṣọ́ọ̀sì Pétérù Mímọ́. Nígbà tí ara rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí yá díẹ̀díẹ̀ ni ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ Cesare wá lọ́ ọ lọ́rùn pa.” Nítorí pé póòpù náà tún fẹ́ lo àkọ̀tun ọgbọ́n láti fi bá ẹlòmíran lẹ̀dí àpò pọ̀, ó tún ṣètò ìgbéyàwó ẹlẹ́ẹ̀kẹta fún Lucrezia, tó ti di ọmọ ọdún mọ́kànlélógún lákòókò yẹn, ìyẹn sì wá fẹ́ ọmọ ọba kan tó lágbára gan-an nílẹ̀ Ferrara.
Àwọn èèyàn ṣàpèjúwe ìgbà Cesare gẹ́gẹ́ bí “ìtàn ìwà búburú jáì, tó kún fún ìtàjẹ̀sílẹ̀.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún ni Cesare nígbà tí baba rẹ̀ fi í ṣe kádínà, síbẹ̀ ó mọ̀ nípa ogun jíjà ju ọ̀ràn ṣọ́ọ̀ṣì lọ, nítorí pé ó gbọ́n ọgbọ́n wàyó, ó sì ń fẹ́ ipò gíga fún ara rẹ̀, ó sì tún ní ìwàkiwà lọ́wọ́ bíi táwọn díẹ̀ mìíràn. Nígbà tó kọ̀wé fiṣẹ́ oyè ṣọ́ọ̀ṣì sílẹ̀, ó fi ọmọ ọbabìnrin ilẹ̀ Faransé ṣaya, ìyẹn ló wá jẹ́ kó di ọba Valentinois. Lẹ́yìn ìyẹn, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ Faransé, ó bẹ̀rẹ̀ sí múra ogun, ó sì ń yọ́ kẹ́lẹ́ pa àwọn èèyàn kí apá àríwá ilẹ̀ Ítálì lè di tirẹ̀.
Láti rí i dájú pé àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ Faransé túbọ̀ ṣètìlẹ́yìn fún ohun tí Cesare ń ṣe yìí, Póòpù náà fọwọ́ sí ìkọ̀sílẹ̀ kan tó máa mú kí nǹkan rọrùn àmọ́ tí ò bójú mu rárá, èyí tí Louis Kejìlá ti ilẹ̀ Faransé fẹ́ ṣe kó lè ráyè fẹ́ Anne ti Brittany, kí ilẹ̀ ọba obìnrin náà sì lè di ara ìjọba rẹ̀. Ní ṣókí, ìwé kan sọ pé, póòpù náà “gbé ipò iyì Ṣọ́ọ̀ṣì náà wọ́lẹ̀, ó sì gbé àwọn ìlànà kan kalẹ̀ nítorí pé ó fẹ́ káwọn tó wà nínú ìdílé òun rọ́wọ́ mú láwùjọ.”
Àríwísí Táwọn Èèyàn Ṣe sí Àṣejù Póòpù Náà
Àṣejù ìdílé Borgia yìí mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn bá wọn ṣọ̀tá, ó sì tún jẹ́ káwọn èèyàn ṣe àríwísí wọn. Póòpù náà mọ̀ọ́mọ̀ foju di àwọn tó ń ṣe lámèyítọ́ rẹ̀, àmọ́ ẹnì kan tí ò lè fojú di ni Girolamo Savonarola. Tó jẹ́ ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé ara Dominica, oníwàásù tí kì í bẹ̀rù ni, ó sì tún jẹ́ aṣáájú òṣèlú ní ìlú Florence. Ó dẹ́bi fún ìwà abèṣe táwọn tó ń bá póòpù náà ṣiṣẹ́ ń hù, ó tún dẹ́bi fún póòpù náà fúnra rẹ̀ àti ètò ìṣèlú rẹ̀. Ó sọ pé kí wọ́n yọ ọ́ lóyè ṣọ́ọ̀ṣì kí wọ́n sì ṣàtúnṣe gbogbo bí nǹkan ṣe ń lọ níbẹ̀. Savonarola lọgun pé: “Ẹ̀yin aṣáájú ṣọ́ọ̀ṣì, . . . ẹ ń lọ sílé àwọn àlè yín lórú, ẹ sì wá ń jẹ ara olúwa láàárọ̀.” Ó tún sọ níkẹyìn pé: “[Àwọn aṣáájú wọ̀nyẹn] ní ojú aṣẹ́wó, wọ́n sì ń fi òkìkí tí wọ́n ní pa Ṣọ́ọ̀ṣì lára. Ohun tí mò ń wí fún yín rèé o, ẹ má ṣe gba ẹ̀sìn Kristẹni gbọ́.”
Kí Savonarola lè dákẹ́ ariwo tó ń pa yìí, póòpù náà fún un ní oyè kádínà, àmọ́ ó sọ pé òun ò fẹ́. Bóyá ohun tó ń sọ nípa póòpù tàbí ìwàásù tó ń ṣe ló fa bi nǹkan ṣe wá dojú rú fún un, a ò lè sọ. Àmọ́ nígbà tó yá, wọ́n yọ Savonarola lẹ́gbẹ́, wọ́n fàṣẹ ọba mú un, wọ́n dá a lóró pé kó jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, wọ́n wá yẹgi fún un, wọ́n sì dáná sun ún.
Àwọn Ìbéèrè Tó Gbàrònú
Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tá a sọ̀tàn rẹ̀ yìí gbé àwọn ìbéèrè pàtàkì dìde. Báwo ni ká ṣe ṣàlàyé irú ìwà jìbìtì àti ìwà ibi tí póòpù hù yìí? Báwo làwọn òpìtàn ṣe ṣàlàyé wọn? Onírúurú ọ̀nà làwọn èèyàn gbà ṣàlàyé rẹ̀.
Àwọn kan sọ pé ojú bí nǹkan ṣe rí lákòókò tí Alexander Kẹfà gbé ayé ló yẹ ká fi wo ọ̀ràn náà. Ó ṣètò ìgbòkègbodò ìṣèlú àti ti ẹ̀sìn rẹ̀ lọ́nà tó máa mú kí àlàáfíà lè wà, kí àárín òun àtàwọn orílẹ̀-èdè mìíràn lè gún, kí ìdè ìbádọ́rẹ̀ẹ́ àárín òun àtàwọn tó bá lẹ̀dí àpò pọ̀ tí wọ́n máa gbèjà rẹ̀ lè nípọn sí i, kó sì lè mú kí àwọn olóyè nínú ẹ̀sìn Kristẹni wà ní ìṣọ̀kan láti kojú mọ̀huru-mọ̀huru tí ilẹ̀ Turkey ń dún mọ́ wọn.
Ìwà rẹ̀ ńkọ́? Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan sọ pé: “Gbogbo sànmánì tí Ṣọ́ọ̀ṣì náà fi wà la fi rí àwọn Kristẹni tó burú àtàwọn àlùfáà tí ò sunwọ̀n. Tó fi jẹ́ pé kò sẹ́ni tí ohun tó ṣe yẹn jẹ́ ìyàlẹ́nu fún, Jésù alára kúkú ti sọ ọ́ tẹ́lẹ̀; kódà ó fi Ṣọ́ọ̀ṣì rẹ̀ wé pápá kan tí àlìkámà àti èpò hù sí, tàbí àwọ̀n tí ẹja rere àti búburú bọ́ sí, gẹ́gẹ́ bó ṣe fàyè gba Júdásì kan láàárín àwọn àpọ́sítélì rẹ̀.”a
Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan náà ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, ó ní: “Bí okùn tó kù-díẹ̀-káàtó ò ṣe lè dín ìjójúlówó ohun ọ̀ṣọ́ tí wọ́n so mọ́ ọn lára kù, bẹ́ẹ̀ náà ni ẹ̀ṣẹ̀ àlùfáà kan kò lè kó àbààwọ́n bá ẹ̀kọ́ tó fi ń kọ́ni. . . . Wúra ni wúrà yóò máa jẹ́ lọ́jọ́kọ́jọ́, ì báà jẹ́ ọwọ́ tó mọ́ ni wọ́n fi mú un tàbí èyí tó léèérí.” Òpìtàn Kátólíìkì kan sọ pé ìlànà tó yẹ káwọn tó jẹ́ ojúlówó Kátólíìkì máa tẹ̀ lé nínú ọ̀ràn Alexander Kẹfà ni ìmọ̀ràn tí Jésù fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nípa àwọn akọ̀wé àtàwọn Farisí, èyí tó sọ pé: ‘Ṣe bí wọ́n ṣe sọ, àmọ́ má ṣe bí wọ́n ti ṣe.’ (Mátíù 23:2, 3) Àmọ́ ká sọ tòótọ́, ǹjẹ́ irú èrò bẹ́ẹ̀ tẹ́ ọ lọ́rùn?
Ṣé Ìsìn Kristẹni Tòótọ́ Lèyí?
Jésù fúnni ní ìlànà rírọrùn kan tá a fi lè mọ àwọn tó jẹ́ Kristẹni gidi, ó ní: “Nípa àwọn èso wọn ni ẹ ó fi dá wọn mọ̀. Àwọn ènìyàn kì í kó èso àjàrà jọ láti ara ẹ̀gún tàbí ọ̀pọ̀tọ́ láti ara òṣùṣú, wọ́n ha ń ṣe bẹ́ẹ̀ bí? Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, gbogbo igi rere a máa mú eso àtàtà jáde, ṣùgbọ́n gbogbo igi jíjẹrà a máa mú èso tí kò ní láárí jáde; igi rere kò lè so èso tí kò ní láárí, bẹ́ẹ̀ ni igi jíjẹrà kò lè mú èso àtàtà jáde. Ní ti tòótọ́, nígbà náà, nípa àwọn èso wọn ni ẹ ó fi dá àwọn ènìyàn wọnnì mọ̀.”—Mátíù 7:16-18, 20.
Lápapọ̀, báwo làwọn aṣáájú ìsìn ṣe mú ìlànà ìsìn Kristẹni tòótọ́ tí Jésù fi lélẹ̀ táwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tòótọ́ sì tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀ yìí ṣẹ láwọn ọ̀rúndún tó kọjá, báwo ni wọ́n sì ṣe ń mú un ṣẹ lóde òní pẹ̀lú? Ẹ jẹ́ ká gbé ọ̀nà méjì péré yẹ̀ wò—ọ̀ràn ìṣèlú àti ọ̀nà tí à ń gbà gbé ìgbésí ayé.
Jésù kì í ṣe ọba ayé. Ó gbé ìgbésí ayé rírẹlẹ̀ gan-an débí tóun fúnra rẹ̀ fi sọ pé òun ò tiẹ̀ ní ibì kankan ‘láti gbé orí òun lé.’ Ìjọba rẹ̀ “kì í ṣe apá kan ayé yìí,” àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ náà sì ní láti jẹ́ ẹni tí “kì í ṣe apá kan ayé, gan-an gẹ́gẹ́ bí [òun fúnra rẹ̀] kì í ti í ṣe apá kan ayé.” Ìdí nìyẹn tí Jésù fi kọ̀ láti lọ́wọ́ nínú ọ̀ràn ìṣèlú ìgbà ayé rẹ̀.—Mátíù 8:20; Jòhánù 6:15; 17:16; 18:36.
Àmọ́, ṣé kì í ṣe òótọ́ ni pé láti ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún wá làwọn ètò ìsìn ti sọ ọ́ dàṣà láti máa bá àwọn olóṣèlú da nǹkan pọ̀ nítorí àtigba agbára àti ọrọ̀ lọ́dọ̀ wọn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé èyí ti yọrí sí ìjìyà fáwọn gbáàtúù? Ṣé kì í tún ṣe òótọ́ ni pé ọ̀pọ̀ lára àwọn àlùfáà wọn ló ń gbé ìgbésí ayé ọlọ́lá, tó sì jẹ́ pé ògìdìgbó àwọn tí wọ́n sọ pé àwọn ń ṣe òjíṣẹ́ fún ló wà nípò òṣì?
Jákọ́bù tó jẹ́ iyèkan Jésù sọ pé: “Ẹ̀yin panṣágà obìnrin, ẹ kò ha mọ̀ pé ìṣọ̀rẹ́ pẹ̀lú ayé jẹ́ ìṣọ̀tá pẹ̀lú Ọlọ́run? Nítorí náà, ẹnì yòówù tí ó bá fẹ́ láti jẹ́ ọ̀rẹ́ ayé ń sọ ara rẹ̀ di ọ̀tá Ọlọ́run.” (Jákọ́bù 4:4) Kí nìdí tó fi jẹ́ “ọ̀tá Ọlọ́run”? Ìwé 1 Jòhánù 5:19 sọ pé: “Gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.”
Ohun tí òpìtàn kan tó gbé ayé nígbà ayé Borgia kọ nípa ìwà Alexander Kẹfà ni pé: “Ìgbésí ayé aláìníjàánu ló gbé. Kò mọ ohun tó ń jẹ́ ìtìjú tàbí òótọ́ inú, kò mọ ìgbàgbọ́ tàbí ìsìn. Ẹ̀mí ìwọra wọ̀ ọ́ lẹ́wù, ipò ọlá ló máa ń lépa ṣáá, ìwà òǹrorò rẹ̀ ò ṣeé fẹnu sọ, bí ọ̀pọ̀ ọmọ tó bí jọ ṣe máa yọrí ọlá ló ká a lára.” Àmọ́ ṣá o, kì í se kìkì Borgia ni aláṣẹ ṣọ́ọ̀ṣì náà tó hùwà lọ́nà yẹn.
Kí ni Ìwé Mímọ́ sọ nípa irú ìwà bẹ́ẹ̀? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù béèrè pé: “Ẹ kò ha mọ̀ pé àwọn aláìṣòdodo kì yóò jogún ìjọba Ọlọ́run? Kí a má ṣì yín lọ́nà. Kì í ṣe àwọn àgbèrè, tàbí . . . àwọn panṣágà, tàbí . . . àwọn oníwọra . . . ni yóò jogún ìjọba Ọlọ́run.”—1 Kọ́ríńtì 6:9, 10.
Ọ̀kan lára àwọn ète tí wọ́n fi ṣe àfihàn sójútáyé tí wọ́n ṣe nípa ìdílé Borgia ní Róòmù lẹ́nu àìpẹ́ yìí ni “káwọn èèyàn lè fojú bí nǹkan ṣe rí lákòókò tí wọ́n gbé ayé wò wọ́n . . . , kí wọ́n lóye wọn àmọ́ kí wọ́n má ṣe dá wọn láre rárá, bẹ́ẹ̀ ni wọn ò sì gbọ́dọ̀ dá wọn lẹ́bi.” Kòdá, ńṣe ni wọ́n sọ pe káwọn tó wá ṣèbẹ̀wò parí èrò síbi tó bá wù wọ́n. Ibo lo wá parí èrò tìẹ sí?
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún ẹ̀kún rẹ́rẹ́ àlàyé lórí àpèjúwe yìí, wo Ilé Ìṣọ́, February 1, 1995, ojú ìwé 5 sí 6, àti June 15, 1992, ojú ìwé 17 sí 22.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Rodrigo Borgia, Póòpù Alexander Kẹfà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]
Bàbá Lucrezia Borgia lò ó láti wá agbára kún agbára rẹ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Cesare Borgia lépa ipò ọlá, iṣẹ́ ibi sì wà lọ́wọ́ rẹ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Nítorí pé wọn ò lè pa Girolamo Savonarola lẹ́nu mọ́, wọ́n yẹgi fún un, wọ́n sì dáná sun ún