ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w06 6/15 ojú ìwé 3-4
  • Báwo ni Ayọ̀ Rẹ Ṣe Pọ̀ Tó?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Báwo ni Ayọ̀ Rẹ Ṣe Pọ̀ Tó?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ǹjẹ́ Ohun Tó Lè Jẹ́ Kéèyàn Láyọ̀ Wà?
  • Àwọn Èèyàn Ń Wá Ohun Tó Máa Fún Wọn Láyọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Aláyọ̀ Ni Àwọn Tó Ń Sin “Ọlọ́run Aláyọ̀”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2018
  • Ki Ni Ó Beere fun Lati Mú Ọ Layọ?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Bí A Ṣe Lè Láyọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
w06 6/15 ojú ìwé 3-4

Báwo ni Ayọ̀ Rẹ Ṣe Pọ̀ Tó?

O LÈ bi ara rẹ pé, ‘Báwo ni ayọ̀ mi ṣe pọ̀ tó?’ Àwọn onímọ̀ nípa ìbágbépọ̀ ẹ̀dá ń gbìyànjú lójú méjèèjì láti mọ ohun tó máa jẹ́ ìdáhùn tìrẹ àti tàwọn mìíràn, àmọ́ èyí kì í ṣe iṣẹ́ kékeré o. Ńṣe ni dídíwọ̀n bí ayọ̀ ẹnì kan ṣe pọ̀ tó dà bí ìgbà tẹ́nì kan bá ń gbìyànjú láti díwọ̀n ìfẹ́ tí ọkùnrin kan ní sí aya rẹ̀ tàbí ẹ̀dùn ọkàn tẹ́nì kan ní nígbà téèyàn rẹ̀ kú. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé bí ọ̀ràn ṣe máa ń rí lára kò ṣeé díwọ̀n. Àmọ́, ohun kan dá àwọn onímọ̀ nípa ìbágbépọ̀ ẹ̀dá lójú, òun ni pé kò sẹ́ni tí kò lè láyọ̀.

Ọlọ́run dá wa lọ́nà tó máa fi ṣeé ṣe fún wa láti láyọ̀, àmọ́ àwọn ìṣòro kan máa ń kó ìbànújẹ́ ńláǹlà bá àwa èèyàn. Wo àpẹẹrẹ yìí: Láwọn ìlú ńlá kan, àwọn tí àìsàn éèdì ń gbẹ̀mí wọn pọ̀ débi pé kò sáyè mọ́ níbi tí wọ́n máa ń sin àwọn òkú sí. Àwọn aláṣẹ wá sọ fún àwọn tó ń gbẹ́ ilẹ̀ ìsìnkú pé kí wọ́n máa sin àwọn tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ kú sórí ibi tí wọ́n ti sin òkú sí tẹ́lẹ̀. Láwọn ibì kan nílẹ̀ Áfíríkà, àwọn tó ń fi pósí kíkàn ṣiṣẹ́ ṣe pọ̀ gan-an. Ibì yòówù kó o sì máa gbé, wàá ti rí i pé inú ìbànújẹ́ làwọn tó lárùn burúkú lára àtàwọn tí ìbátan tàbí ọ̀rẹ́ wọn kú máa ń wà.

Àwọn orílẹ̀-èdè tí nǹkan ti rọ̀ṣọ̀mù ńkọ́? Tí ipò nǹkan bá yí padà lójijì níbẹ̀, àwọn tí kò múra sílẹ̀ fún irú ipò àìròtẹ́lẹ̀ bẹ́ẹ̀ lè di ẹdun arinlẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ọ̀pọ̀ lára àwọn tó ti fẹ̀yìn tì ló tún ti padà sẹ́nu iṣẹ́ nítorí pé wọ́n fi owó ìfẹ̀yìntì wọn dù wọ́n. Àwọn ìdílé kan ti fi gbogbo owó wọn wo àìsàn. Amòfin kan sọ pé: “Tẹ́ ẹ bá rí bí àwọn èèyàn wọ̀nyí ṣe ń wá sọ́dọ̀ mi fún ìmọ̀ràn tí wọ́n sì ń sọ gbèsè tó wà lọ́rùn wọn àti àìsàn tó ń ṣe wọ́n, àánú wọn á ṣe yín. Lọ́pọ̀ ìgbà, ohun tí mo máa ń sọ fún wọn ni pé, ‘Kò sọ́gbọ́n kẹ́ ẹ má talé yín o.’” Àmọ́, àwọn tí owó kì í ṣe ìṣòro wọn ńkọ́? Ǹjẹ́ ìbànújẹ́ máa ń bá àwọn náà?

Àwọn èèyàn kan dà bí gbajúmọ̀ olórin kan tó ń jẹ́ Richard Rodgers. Ohun táwọn èèyàn sọ nípa olórin yìí ni pé: “Àwọn tó ṣe ohun tó ń múnú ọ̀pọ̀ èèyàn dùn bíi tirẹ̀ kò tó nǹkan.” Òótọ́ ni pé àwọn èèyàn ń gbádùn àwọn orin tó kọ, àmọ́ ìdààmú ọkàn tó lékenkà kò jẹ́ kí òun alára gbádùn. Ọwọ́ rẹ̀ ti tẹ ohun méjì tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń lépa, ìyẹn owó àti òkìkí. Ṣùgbọ́n, ayọ̀ ńkọ́? Ọ̀gbẹ́ni kan tó máa ń kọ ìtàn ìgbésí ayé àwọn èèyàn sọ pé: “[Rodgers] rọ́wọ́ mú gan-an nídìí iṣẹ́ rẹ̀, gbajúmọ̀ ni láwùjọ, ẹ̀ẹ̀mejì lòun àtẹnì kan sì jọ gba Ẹ̀bùn Ẹ̀yẹ Pulitzer. Síbẹ̀ náà, ọ̀pọ̀ ìgbà ni kì í láyọ̀, ó sì máa ń sorí kọ́.”

Ó ṣeé ṣe kí ìwọ náà ti ṣàkíyèsí pé ńṣe lẹni tó bá ń gbára lé ọrọ̀ gẹ́gẹ́ bí ohun tó lè fún un láyọ̀ ń tanra ẹ̀ jẹ. Ẹnì kan tó ń kọ ìròyìn nípa ọrọ̀ ajé fún ilé iṣẹ́ ìwé ìròyìn The Globe and Mail nílùú Toronto, lórílẹ̀-èdè Kánádà sọ pé ọ̀pọ̀ àwọn tó rí towó ṣe ló níṣòro “ìdánìkanwà, wọn ò sì mọ ibi tí ìgbésí ayé wọn dorí kọ.” Ọkùnrin agbaninímọ̀ràn kan lórí ọ̀rọ̀ tó jẹ mọ́ ìṣúnná owó sọ pé táwọn ọlọ́rọ̀ bá ń bu owó lu àwọn ọmọ wọn tí wọ́n sì ń fi ọ̀pọ̀ ohun ìní dá wọn lọ́lá, “ohun tó máa pa àwọn ọmọ ọ̀hún lẹ́kún lẹ́yìn ọ̀la ni wọ́n ń ṣe yẹn.”

Ǹjẹ́ Ohun Tó Lè Jẹ́ Kéèyàn Láyọ̀ Wà?

Kí òdòdó kan tó lè hù dáadáa, ó nílò ilẹ̀ tó dára, omi, àti ojú ọjọ́ tí kò tutù jù tí kò sì gbóná jù. Bákan náà, àwọn olùṣèwádìí mọ̀ pé àwọn ohun kan wà tó máa ń jẹ́ kéèyàn láyọ̀. Lára àwọn nǹkan ọ̀hún ni ìlera ara; iṣẹ́ gidi, kéèyàn ní ilé, aṣọ àti oúnjẹ tó tó; kọ́wọ́ èèyàn tẹ ohun tọ́kàn rẹ̀ fẹ́; àti ojúlówó ọ̀rẹ́.

Ó ṣeé ṣe kí ìwọ náà gbà láìjanpata pé àwọn nǹkan wọ̀nyẹn lè jẹ́ kéèyàn láyọ̀. Àmọ́ ohun kan wà tó ṣe pàtàkì ju gbogbo ìwọ̀nyẹn lọ. Ohun náà ni ìmọ̀ nípa “Ọlọ́run aláyọ̀” tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà. (1 Tímótì 1:11) Báwo ni ìmọ̀ nípa Ọlọ́run yìí ṣe lè jẹ́ kéèyàn láyọ̀? Jèhófà ni Ẹlẹ́dàá wa, ó sì dá wa lọ́nà tó máa fi ṣeé ṣe fún wa láti jẹ́ aláyọ̀. Torí náà, Jèhófà mọ ohun tó lè jẹ́ ká ní ojúlówó ayọ̀. Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí ṣàlàyé ọ̀nà tí Jèhófà gbà ń fún àwọn èèyàn ní ìtọ́sọ́nà níbi yòówù kí wọ́n wà àti nínú ipòkípò tí wọn ì báà wà, kí wọ́n lè ní ayọ̀ tó wà títí lọ.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

Bí òdòdó ṣe ń fẹ́ ibi tó dára kó tó lè hù dáadáa, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ohun pàtàkì kan wà tó máa ń jẹ́ kéèyàn láyọ̀

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]

© Gideon Mendel/CORBIS

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́