ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w06 6/15 ojú ìwé 8-11
  • Àwọn Tó Ń Di Ẹlẹ́rìí Ń Pọ̀ Sí I Nílẹ̀ Uganda Tí Onírúurú Èèyàn Wà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Tó Ń Di Ẹlẹ́rìí Ń Pọ̀ Sí I Nílẹ̀ Uganda Tí Onírúurú Èèyàn Wà
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Ìsọ̀rí
  • “Péálì” Náà Ń Dán Gbinrin Lóde Òní
  • Bí Wọ́n Ṣe Borí Ìṣòro Èdè
  • Àwọn Aṣáájú-Ọ̀nà Ń Múpò Iwájú Nínú Iṣẹ́ Ìwàásù
  • Àwọn Onítara Míì Tó Ń Ṣe Iṣẹ́ Ìwàásù
  • “Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ti Fìdí Múlẹ̀ Níbí”
  • Ìdààmú Pọ̀ Lóòótọ́, Àmọ́ Ẹ̀rí Wà Pé Wọ́n Máa Pọ̀ Sí I
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
w06 6/15 ojú ìwé 8-11

Àwọn Tó Ń Di Ẹlẹ́rìí Ń Pọ̀ Sí I Nílẹ̀ Uganda Tí Onírúurú Èèyàn Wà

UGANDA jẹ́ orílẹ̀-èdè tó fani mọ́ra gan-an. Àárín ibi tí wọ́n ń pè ní Àfonífojì Ńlá ní ìlà oòrùn Áfíríkà, lápá ibi tó jẹ́ agbedeméjì ilẹ̀ ayé ló wà. Ó láwọn òkè, gegele, pẹ̀tẹ́lẹ̀, odò, ewéko tútù yọ̀yọ̀ àti onírúurú ẹranko tó fani mọ́ra. Ojú ọjọ́ ibẹ̀ kò gbóná jù kò sì tutù jù torí ibi tó jẹ́ òkè ńlá tí orí ẹ̀ tẹ́jú lorílẹ̀-èdè náà wà ní Áfíríkà, ó sì tún láwọn òkè kéékèèké fífani mọ́ra tó lọ rabidun, àní débi tó tó ọgọ́rọ̀ọ̀rún kìlómítà.

Orílẹ̀-èdè kékeré tó ní àgbègbè oníyìnyín àti àgbègbè olóoru bí Uganda ò pọ̀. Lápá ìwọ̀ oòrùn, ó láwọn òkè ńláńlá oníyìnyín tí wọ́n ń pè ní Òkè Ruwenzori tàbí Òkè Òṣùpá, àmọ́ apá ìlà oòrùn ilẹ̀ náà fẹ́rẹ̀ẹ́ má yàtọ̀ sí aṣálẹ̀. Erin, ẹfọ̀n àti kìnnìún wà láwọn ọ̀dàn ibẹ̀ nígbà táwọn ìnàkí, ọṣà àti oríṣi ẹyẹ tó ju ẹgbẹ̀rún lọ ń gbé lórí òkè àtàwọn igbó kìjikìji. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀gbẹlẹ̀ àti ìyàn ń han ọ̀pọ̀ jù lọ orílẹ̀-èdè léèmọ̀ ní Áfíríkà, Uganda ò màlá ní tiẹ̀, torí odò pọ̀ níbẹ̀ ó sì tún ní adágún omi ńláńlá, irú bí Adágún Omi Victoria, tó jẹ́ adágún omi aláìníyọ̀ tó tóbi ṣìkejì láyé. Adágún Omi Victoria yìí ń ṣàn lọ sínú Odò Náílì tó wà lápá àríwá rẹ̀. Abájọ tí àgbà òṣèlú ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì nì, Winston Churchill, fi pe Uganda ní “péálì ilẹ̀ Áfíríkà”!

“Péálì” Náà Ń Dán Gbinrin Lóde Òní

Àmọ́, ohun tó mú ilẹ̀ Uganda wuni jù làwọn èèyàn ibẹ̀. Onírúurú ẹ̀yà ni wọ́n. Wọ́n kóni mọ́ra, wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ àlejò. Àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ló pọ̀ jù níbẹ̀, ó sì jẹ́ ibi tí onírúurú ẹ̀yà tí wọ́n ní oríṣiríṣi àṣà ìbílẹ̀ para pọ̀ sí. Kódà, èèyàn lè fi àṣà wọn àti ọ̀nà ìgbàwọṣọ wọn dá wọn mọ̀ lóde òní.

Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ọ̀pọ̀ èèyàn ilẹ̀ Uganda ti bẹ̀rẹ̀ sí i kọbi ara sí ìhìn rere tí Bíbélì sọ nípa ìgbà tí àlàáfíà yóò jọba jákèjádò ayé títí láé. (Sáàmù 37:11; Ìṣípayá 21:4) Kò rọrùn rárá láti mú ìhìn rere yìí dé ọ̀dọ̀ gbogbo èèyàn lórílẹ̀-èdè tó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ déédéé ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì yìí.

Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, látorí ẹni àkọ́kọ́ lára àwọn ọmọ ìbílẹ̀ ibẹ̀ tó ya ara rẹ̀ sí mímọ́ tó sì ṣèrìbọmi gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwa Ẹlẹ́rìí nínú Adágún Omi Victoria lọ́dún 1955, “ẹni tí ó kéré” di ẹgbẹ̀rún kan lóòótọ́ lọ́dún 1992. Látìgbà náà ni wọ́n ti ń pọ̀ sí i, bí Ọlọ́run ṣe sọ pé yóò rí nígbà tó ní: “Èmi tìkára mi, Jèhófà, yóò mú un yára kánkán ní àkókò rẹ̀.”—Aísáyà 60:22.

Bí Wọ́n Ṣe Borí Ìṣòro Èdè

Èdè Gẹ̀ẹ́sì lèdè àjùmọ̀lò ní Uganda, òun sì ni wọ́n ń lò níbi púpọ̀, pàápàá láwọn ilé ìwé gbogbo. Àmọ́, èdè Gẹ̀ẹ́sì kọ́ lèdè àbínibí ọ̀pọ̀ jù lọ ọmọ ilẹ̀ Uganda. Ìdí nìyẹn táwọn Ẹlẹ́rìí fi tún máa ń lo àwọn èdè ìbílẹ̀ tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń sọ láti lè rí ọ̀pọ̀ wọn wàásù fún. Èyí ṣe pàtàkì nítorí pé àwọn tó pọ̀ jù lọ nínú mílíọ̀nù mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n èèyàn tó wà níbẹ̀ ló ń gbé láwọn ìgbèríko tàbí àwọn ìlú kékeré. Èdè àbínibí wọn sì ni wọ́n fi máa ń bára wọn sọ̀rọ̀. Ó gba ìsapá gan-an láti wàásù fáwọn tó ń sọ onírúurú èdè yìí kí wọ́n lè kọ́ ẹ̀kọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

Àmọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà níbẹ̀ ti borí ìṣòro yìí ní ti pé wọ́n ń fi èdè wọn wàásù fún wọn, wọ́n sì ń tẹ ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jáde lóríṣiríṣi èdè. Ní ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà ní Kampala tó jẹ́ olú ìlú Uganda, wọ́n ní àwùjọ atúmọ̀ èdè tó ń ṣètumọ̀ sí oríṣi èdè mẹ́rin. Àwọn èdè náà ni: Acholi, Lhukonzo, Luganda àti Runyankore. Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń wá sáwọn ìpàdé àkànṣe, àyíká àti àgbègbè táwa Ẹlẹ́rìí ń ṣe ní onírúurú èdè jákèjádò ilẹ̀ náà, débi pé àpapọ̀ àwọn tí wọ́n ń pésẹ̀ sáwọn ìpàdé náà ju ìlọ́po méjì àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà níbẹ̀. Èyí fi hàn pé sísapá táwọn Ẹlẹ́rìí ń sapá láti wàásù fáwọn èèyàn onírúurú èdè ń jẹ́ kí iye àwọn Ẹlẹ́rìí pọ̀ sí i kíákíá níbẹ̀. Àmọ́ ìyẹn nìkan kọ́ ló ń jẹ́ kí wọ́n yára máa pọ̀ sí i o.

Àwọn Aṣáájú-Ọ̀nà Ń Múpò Iwájú Nínú Iṣẹ́ Ìwàásù

Àwọn ìjọ tó wà ní Uganda máa ń fi tinútinú kọ́wọ́ ti àkànṣe iṣẹ́ ìwàásù tí wọ́n ń ṣe fún nǹkan bí oṣù mẹ́ta lọ́dọọdún. Wọ́n ń fi àsìkò náà lọ wàásù láwọn ibi tó jẹ́ àdádó. (Ìṣe 16:9) Àwọn ọ̀dọ́ aṣáájú-ọ̀nà tí iye wọn túbọ̀ ń pọ̀ sí i ń múpò iwájú nínú iṣẹ́ náà. Wọ́n máa ń lọ wàásù láwọn eréko tó jẹ́ pé, nígbà míì àwọn èèyàn ibẹ̀ lè má tíì gbọ́ ìhìn rere rí.

Ètò Ọlọ́run rán arábìnrin méjì lọ ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe fún oṣù mẹ́ta ní ìlú kékeré kan tó ń jẹ́ Bushenyi lápá ìwọ̀ oòrùn ilẹ̀ Uganda. Àwọn àti obìnrin Ẹlẹ́rìí kan ṣoṣo tó wà nílùú náà wá jọ ń wàásù, wọ́n sì jọ ń ṣètò fún ìpàdé ìjọ. Láàárín oṣù kan péré, aṣáájú-ọ̀nà méjèèjì ti ń kọ́ ogójì èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, mẹ́tàdínlógún lára wọn sì ń wá sípàdé. Àwọn aṣáájú-ọ̀nà yìí ròyìn pé: “Àwọn kan tá a fún ní ìwé pẹlẹbẹ Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa?a wá sílé wa lẹ́yìn ọjọ́ mélòó kan. Wọ́n mú abala ìwé mélòó kan dání tí wọ́n ti kọ ìdáhùn àwọn ìbéèrè inú ìwé pẹlẹbẹ náà sí ká lè sọ fún wọn bóyá wọn gba àwọn ìdáhùn náà.” Lónìí, ìjọ kan ti wà nílùú náà, wọ́n sì ti ní Gbọ̀ngàn Ìjọba.

Aṣáájú-ọ̀nà méjì kan lọ síbì kan táwa Ẹlẹ́rìí ò tíì wàásù dé ní ìwọ̀ oòrùn Uganda. Àwọn aṣáájú-ọ̀nà yìí kọ̀wé pé: “Òǹgbẹ òtítọ́ Bíbélì ń gbẹ àwọn èèyàn gan-an níbí. Láàárín oṣù mẹ́ta tá a débí, a ti ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mẹ́rìndínláàádọ́rùn-ún [86].” Kò pẹ́ sígbà náà ló di pé àwùjọ àwọn Ẹlẹ́rìí kan wà níbẹ̀.

Àwọn Onítara Míì Tó Ń Ṣe Iṣẹ́ Ìwàásù

Àwọn kan lára àwọn aṣáájú-ọ̀nà onítara yìí ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Arákùnrin Patrick jẹ́ ọ̀kan lára wọn. Kó tó di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, fèrè clarinet ló máa ń fọn nínú ẹgbẹ́ olórin àwọn ọmọ ogun ojú òfuurufú ilẹ̀ Uganda nígbà ìjọba Idi Amin. Ó ṣèrìbọmi lọ́dún 1983, lẹ́yìn oṣù mẹ́fà ó sì di aṣáájú-ọ̀nà, ìyẹn àwọn tó ń fi ọ̀pọ̀ àkókò jíhìn rere. Ní báyìí ó ti di alábòójútó arìnrìn-àjò tó ń bẹ ìjọ wò láti gbé wọn ró.

Ọdún 1962 ni arábìnrin Margaret ṣèrìbọmi. Ọjọ́ orí rẹ̀ ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọgọ́rin ọdún, ìgbáròkó tó ń dùn ún ò sì jẹ́ kó lè rìn dáadáa, síbẹ̀ lóṣooṣù ó ń fi àádọ́rin wákàtí wàásù ọ̀rọ̀ Bíbélì tó ń fúnni nírètí fáwọn aládùúgbò rẹ̀. Ó máa ń to àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sórí ìjókòó gbọọrọ kan níwájú ilé rẹ̀, ó sì máa ń wàásù nípa ayé àlàáfíà tó ń bọ̀ fẹ́ni tó bá fẹ́ gbọ́ lára àwọn tó bá ń kọjá.

Àgbẹ̀ kan tó ń jẹ́ Simon ní ìlà oòrùn Uganda ti ń wá òtítọ́ kiri fún ọdún mẹ́rìndínlógún káwọn ìwé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó tẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́ lọ́dún 1995. Ohun tó kà nínú àwọn ìwé náà jẹ́ kó fẹ́ mọ̀ sí i nípa Ìjọba Ọlọ́run àtàwọn ohun àgbàyanu tí Jèhófà fẹ́ ṣe sí ayé yìí. Kò sí Ẹlẹ́rìí kankan ní abúlé Kamuli tí Simon ń gbé, ló bá wá wọn lọ sí ìlú Kampala tó wà ní nǹkan bí ogóje kìlómítà sí abúlé rẹ̀. Lónìí, ìjọ kan ti wà lábúlé ẹ̀ yẹn.

“Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ti Fìdí Múlẹ̀ Níbí”

Ilé ìjọsìn tó bójú mu ni ọ̀pọ̀ èèyàn nílẹ̀ Uganda retí pé káwọn onísìn ní, bó sì ṣe rí láwọn ibòmíì ní Áfíríkà nìyẹn. Ó jẹ́ òkè ìṣòro fáwọn ìjọ kan lára ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí láti ní ibi ìjọsìn tó bójú mu torí pé wọn ò lówó tí wọ́n lè fi kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tó dáa. Inú àwọn ará dùn gan-an nígbà tí ètò Ọlọ́run dá ètò kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba lẹ́yẹ-ò-sọkà sílẹ̀ káàkiri ayé lápá ìparí ọdún 1999. Láàárín ọdún márùn-ún, wọ́n ti kọ́ ogójì Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun parí ní Uganda. Lónìí, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo ìjọ ló ní Gbọ̀ngàn Ìjọba tiwọn tó bójú mu. Ohun táwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tí wọ́n ń kọ́ náà ń jẹ́ káwọn aráàlú mọ̀ ni pé, “Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti fìdí múlẹ̀ níbí.” Èyí sì wà lára ohun tó ń jẹ́ káwọn akéde pọ̀ sí i.

Abẹ́ àwọn igi máńgòrò kan tó ní ibòji dáadáa ni ìjọ kékeré kan tó wà ní àríwá Uganda ti ń ṣèpàdé tẹ́lẹ̀. Bí wọ́n ṣe rí ilẹ̀ tí wọ́n á fi kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba ni iṣẹ́ bẹ̀rẹ̀ ní pẹrẹu. Àwọn ará tó yọ̀ǹda ara wọn fún iṣẹ́ ìkọ́lé wá bá àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà nínú ìjọ yẹn, wọ́n sì jọ ń kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba náà. Iṣẹ́ náà wú gbajúgbajà olóṣèlú kan tó wà lágbègbè náà lórí gan-an. Ló bá fún wọn níbi ìgbọ́kọ̀sí rẹ̀ kí wọ́n máa ṣèpàdé níbẹ̀ kí wọ́n tó kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba náà tán. Ó tún gbà kí ọ̀kan lára àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn fún iṣẹ́ ìkọ́lé máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ọkùnrin tá à ń wí yìí ti di akéde onítara tó ti ṣèrìbọmi báyìí, ó sì ń fi ìdùnnú sin Jèhófà nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun tó lẹ́wà náà!

Nígbà tí iṣẹ́ kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba kan ń lọ lọ́wọ́ lápá gúúsù ìlà oòrùn Uganda, bíríkìlà kan ládùúgbò ibẹ̀ rí ẹ̀mí ìfẹ́, ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àti ìwà-bí-ọ̀rẹ́ tó wà láàárín àwọn ará, èyí sì wú u lórí débi pé ó wá báwọn ṣiṣẹ́ níbẹ̀ lọ́fẹ̀ẹ́. Àní, nígbà tí iṣẹ́ náà fẹ́ parí ó báwọn ṣiṣẹ́ mọ́jú káwọn ará lè ṣe ìyàsímímọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba náà láàárọ̀ ọjọ́ kejì. Ó ní: “Ẹ̀yin nìkan lẹ fẹ́ràn ara yín dénú, tí kì í ṣe pé ẹnu lásán lẹ fi ń sọ ọ́.”

Ìdààmú Pọ̀ Lóòótọ́, Àmọ́ Ẹ̀rí Wà Pé Wọ́n Máa Pọ̀ Sí I

Bí iṣẹ́ ìwàásù ṣe ń dé àwọn ibi tí kò tíì dé tẹ́lẹ̀ ní Uganda, bẹ́ẹ̀ ni iye àwọn Ẹlẹ́rìí túbọ̀ ń pọ̀ sí i, tí ọ̀pọ̀ àwọn olùfìfẹ́hàn sì ń wá sípàdé ìjọ. Àmọ́ ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èèyàn tó ti sá wá sí Uganda nítorí ogun tí wọ́n ń jà láwọn orílẹ̀-èdè tó wà lágbègbè ibẹ̀ ń fẹ́ àfiyèsí ní kánjúkánjú. Àwọn ogun yẹn ṣàkóbá fáwọn èèyàn Jèhófà bákan náà. Àmọ́ báwọn Ẹlẹ́rìí tó wà nínú ibùdó àwọn tí ogun lé kúrò lórílẹ̀-èdè wọn ṣe gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà wúni lórí. Ọ̀gbẹ́ni kan jẹ́ ọ̀gá lẹ́nu iṣẹ́ ìjọba tẹ́lẹ̀ rí lórílẹ̀-èdè kan nítòsí Uganda, ó sì ti báwọn ṣenúnibíni sáwọn Ẹlẹ́rìí nígbà tí ìjọba ilẹ̀ wọn fòfin de àwọn Ẹlẹ́rìí. Ọ̀gbẹ́ni yìí sọ pé nǹkan rọ̀ṣọ̀mù fóun tẹ́lẹ̀ rí. Nígbà táwọn Ẹlẹ́rìí wá kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní ibùdó àwọn tí ogun lé kúrò lórílẹ̀-èdè wọn, tó sì di Ẹlẹ́rìí, ó ní: “Pé èèyàn jẹ́ ọlọ́rọ̀ ó sì tún wà nípò gíga nínú ayé yìí kò láyọ̀lé rárá. Lóòótọ́ tálákà ni mí báyìí, ara mi ò sì le, àmọ́ ayé mi dáa ju bó ṣe wà tẹ́lẹ̀. Mo mọ Jèhófà, mo sì dúpẹ́ pé mo láǹfààní láti máa gbàdúrà sí i. Yàtọ̀ sí pé mo nírètí tó dájú nípa ọjọ́ ọ̀la, mo tún ti mọ ìdí tí ìṣòro fi ń bá wa fínra láyé ìsinsìnyí. Nítorí náà, ní báyìí, mo ní ìfọ̀kànbalẹ̀ tí mi ò ní rí láyé mi.”

Láti fi hàn bí ilẹ̀ Uganda ṣe lọ́ràá tó, wọ́n máa ń pa á láṣamọ̀ níbẹ̀ pé tó o bá ti igi lásán bọ ilẹ̀ Uganda lálẹ́, tó bá fi máa dàárọ̀ yóò ti ta gbòǹgbò. Bí àwọn èèyàn Jèhófà ṣe ń pọ̀ sí i ní ilẹ̀ náà fi hàn pé ibẹ̀ jẹ́ ilẹ̀ ọlọ́ràá nípa tẹ̀mí pẹ̀lú. A dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà Ọlọ́run pé ó ṣì fàyè sílẹ̀ kí púpọ̀ sí i lára àwọn èèyàn onírúurú ẹ̀yà tó wà ní Uganda lè gbọ́ nípa Ìjọba rẹ̀. Jésù fi bí Ìjọba Ọlọ́run ṣe ṣeyebíye tó wé “péálì kan tí ìníyelórí rẹ̀ ga.” Ńṣe làwọn tí òye èyí ń yé sì túbọ̀ ń pọ̀ sí i nílẹ̀ Uganda báyìí.—Mátíù 13:45, 46.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe ìwé pẹlẹbẹ náà.

[Àwọn àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 8]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

SUDAN

UGANDA

Odò Náílì

Kamuli

Tororo

Kampala

Bushenyi

Adágún Omi Victoria

KẸ́ŃYÀ

TANSANÍÀ

RÙWÁŃDÀ

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Mẹ́ta rèé lára ọ̀pọ̀ aṣáájú-ọ̀nà onítara tó wà níbẹ̀

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Patrick

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Margaret

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Simon

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Àpéjọ àgbègbè ní ìlú Tororo

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 8]

Àwòrán tó wà lẹ́yìn: © Uganda Tourist Board

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́