Àwọn Ẹlẹ́rìí Ń Rí Àwọn Tó Jẹ́ Ìṣúra Iyebíye Nílẹ̀ Guinea
LÁTI ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́yìn làwọn èèyàn ti ń lọ láti ilẹ̀ kan dé òmíràn, tí wọ́n ń fi ẹ̀mí wọn wewu nítorí pé wọ́n ń wá àwọn ìṣúra iyebíye àtàwọn nǹkan àmúṣọrọ̀. Àwọn tó jẹ́ akíkanjú tí wọ́n dé orílẹ̀-èdè Guinea ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà rí oríṣi ìṣúra iyebíye méjì. Ìṣúra àkọ́kọ́ jẹ́ àwọn ohun àmúṣọrọ̀ inú ilẹ̀, nígbà tí ìṣúra kejì jẹ́ àwọn èèyàn. Àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè Guinea lé ní mílíọ̀nù mẹ́sàn-án, dáyámọ́ńdì, góòlù, kùsà, àti ògidì ayọ́ sì pọ̀ gan-an lórílẹ̀-èdè náà.
Ṣọ́ọ̀ṣì ò pọ̀ lórílẹ̀-èdè náà, àmọ́ àwọn èèyàn ò kóyán ẹ̀sìn kéré rárá, ọ̀pọ̀ nínú wọn ló fọwọ́ pàtàkì mú àwọn tó jẹ́ ìṣúra iyebíye nípa tẹ̀mí. Kí tiẹ̀ ni àwọn ìṣúra iyebíye yìí? Àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà ni, tí Hágáì 2:7 pè ní “àwọn ohun fífani-lọ́kàn-mọ́ra tí ń bẹ nínú gbogbo orílẹ̀-èdè.”
Àwọn Èèyàn Tó Jẹ́ Ìṣúra Iyebíye
Iṣẹ́ kékeré kọ́ lèèyàn máa ṣe o kó tó lè gbẹ́ ilẹ̀ débi táá ti rí àwọn ìṣúra iyebíye tó fara sin. Bákan náà lọ̀rọ̀ iṣẹ́ ìwàásù rí. Ó gba pé kéèyàn sapá gidigidi kó tó lè rí àwọn èèyàn tó jẹ́ ìṣúra iyebíye. Apá ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1950 ni iṣẹ́ ìwàásù nípa Ìjọba Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ ní àárín gbùngbùn orílẹ̀-èdè Guinea, ó sì tó ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1960 kí iṣẹ́ náà tó dé Conakry tí í ṣe olú ìlú orílẹ̀-èdè náà. Ní báyìí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lórílẹ̀-èdè náà tó nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún [900]. Ìjọ àtàwọn àwùjọ mọ́kànlélógún ló sì wà jákèjádò ibẹ̀.
Ọdún 1987 làwọn míṣọ́nnárì dé ilẹ̀ náà, ìjọ kan ṣoṣo tó wà ní Conakry ni wọ́n sì ń dara pọ̀ mọ́. Ní báyìí, àwọn míṣọ́nnárì tó wà ní olú ìlú yìí àti ní àárín gbùngbùn orílẹ̀-èdè náà ti lé ní ogún. Wọ́n ń fìtara gbé àwọn ìjọ wọ̀nyí ró, wọ́n sì ń fìtara bá àwọn ará ṣe iṣẹ́ ìwàásù.
Ayọ̀ ńlá ló jẹ́ fún Arákùnrin Luc tó ń gbé ní Conakry láti máa kọ́ ọ̀dọ́kùnrin dókítà kan tó ń jẹ́ Albert lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Lákòókò kan, ńṣe ni Albert ń lọ láti ṣọ́ọ̀ṣì kan sí ṣọ́ọ̀ṣì mìíràn nítorí pé ó ń wá ìsìn tòótọ́, ó sì tún máa ń yalé aláwo. Ó máa ń fi òrùka kan sọ́wọ́, èyí tí babaláwo kan fún un pé ó máa jẹ́ kó ṣoríire. Àmọ́ nígbà tí Albert rí i pé pàbó ni gbogbo ìsapá òun láti wá ìsìn tòótọ́ já sí, ó ju òrùka ọ̀hún nù, ó wá gbàdúrà pé: “Ọlọ́run, tó bá jẹ́ pé lóòótọ́ lo wà, jẹ́ kí n mọ̀ ọ́ kí n sì máa sìn ọ́. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, bó ṣe wù mí ni màá ṣe máa gbé ìgbésí ayé mi.” Láìpẹ́ sígbà yẹn, Albert lọ sọ́dọ̀ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ obìnrin tó wà nílé ọkọ. Níbẹ̀, ó fetí kọ́ ọ̀rọ̀ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bó ṣe ń kọ́ ọmọ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Kò pẹ́ sígbà yẹn ni Luc bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ Albert alára lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
Ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ni Luc máa ń fi tayọ̀tayọ̀ rin ohun tó lé ní kìlómítà márùn-ún ní láti lọ ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Albert. Arákùnrin Luc ò fi bẹ́ẹ̀ kàwé, àmọ́ Albert ti jáde yunifásítì ní tiẹ̀. Síbẹ̀ bí Luc ṣe nígbàgbọ́ tó lágbára nínú Ìwé Mímọ́ àti bó ṣe ń fi àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì sílò wú Albert lórí gan-an ni. Inú Albert dùn gan-an nígbà tó mọ̀ pé Ọlọ́run kọ́ ló fa ìyà tó ń jẹ ọmọ aráyé, àti pé dípò ìyẹn, Jèhófà ti pinnu láti fòpin sí gbogbo ìyà ọ̀hún kó sì sọ ayé di Párádísè. (Sáàmù 37:9-11) Ẹ̀kọ́ òtítọ́ tí Albert ń kọ́ àti ìwà ọmọlúwàbí tó rí táwọn ará ìjọ ń hù wú u lórí gan-an.
Àmọ́ o, gẹ́gẹ́ bó ṣe gba pé kí oníṣẹ́ ọnà kan ṣiṣẹ́ kára láti gé dáyámọ́ńdì kó sì fá a kó tó lè máa dán gbinrin, bákan náà, Albert ní láti jáwọ́ nínú àwọn ìwà àti ìṣe ayé kan kó lè mú ìgbésí ayé rẹ̀ bá ìlànà Bíbélì mu. Nígbà tó ṣe, Albert ò yalé aláwo mọ́, kò mutí àmupara mọ́, kò sì ta tẹ́tẹ́ mọ́. Sìgá mímu ló nira fún un jù láti fi sílẹ̀, àmọ́ nígbà tó gbàdúrà tọkàntọkàn sí Jèhófà fún ìrànlọ́wọ́, ó jáwọ́ nínú sìgá mímu. Oṣù mẹ́fà lẹ́yìn ìyẹn ló fi orúkọ ìgbéyàwó rẹ̀ sílẹ̀ lábẹ́ òfin. Ìyàwó rẹ̀ náà bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ní báyìí, àwọn méjèèjì ti di ìránṣẹ́ Jèhófà tó ti ṣèrìbọmi.
Ẹlòmíì tó tún jẹ́ ìṣúra iyebíye ni ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Martin. Àtọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ló ti bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nílùú Guéckédou. Ìjọ Kátólíìkì làwọn òbí rẹ̀ ń lọ, wọn ò sì fẹ́ kó máa lọ sípàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Wọ́n dáná sun àwọn ìwé tí Martin fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wọ́n lù ú, wọ́n sì lé e jáde nílé. Bó ṣe jẹ́ pé tí wọ́n bá fi iná yọ́ góòlù, ńṣe ni yóò máa dán gbinrin, bẹ́ẹ̀ náà ni inúnibíni tí wọ́n ṣe sí Martin ṣe mú kó túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀kọ́ Bíbélì. Nígbà tó yá, inú tó ń bí àwọn òbí rẹ̀ rọlẹ̀, Martin sì padà sílé. Kí ló yí àwọn òbí rẹ̀ lọ́kàn padà? Wọ́n rí i pé ìwà àti ìṣe Martin yàtọ̀ pátápátá sí tàwọn àbúrò rẹ̀ yòókù tí wọ́n ti yàyàkuyà tí wọ́n sì ń ṣèṣekúṣe kiri. Bàbá Martin rí i pé ẹ̀sìn tí Martin ń ṣe ti tún ayé ẹ̀ ṣe, ìyẹn ló mú kó gba àwọn ará ìjọ láyè láti máa wá sílé wọn. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni ìyá Martin máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ará fún ìrànlọ́wọ́ tí wọ́n ti ṣe fọ́mọ òun. Martin ṣèrìbọmi ní ọmọ ọdún méjìdínlógún, nígbà tó sì yá, ó lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́. Ó ti di aṣáájú ọ̀nà àkànṣe báyìí.
Àwọn Èèyàn Tó Jẹ́ Ìṣúra Iyebíye Tí Wọ́n Wá Látilẹ̀ Ibòmíì
Nígbà tó jẹ́ pé ńṣe ni orílẹ̀-èdè Guinea máa ń kó púpọ̀ lára àwọn ìṣúra wọn lọ sórílẹ̀-èdè míì, ilẹ̀ ibòmíràn ni àwọn kan lára àwọn èèyàn tó jẹ́ ìṣúra iyebíye ibẹ̀ ti wá. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló wá síbẹ̀ láti orílẹ̀-èdè míì nílẹ̀ Áfíríkà, ọ̀rọ̀ àtijẹ-àtimu sì ni ohun tó sábà ń gbé wọn wá síbẹ̀. Àmọ́ ogun àjàkú akátá ló lé àwọn míì wá ní tiwọn.
Obìnrin ọmọ ilẹ̀ Kamẹrúùn kan tó ń jẹ́ Ernestine wá sílẹ̀ Guinea ní ọdún méjìlá sẹ́yìn. Obìnrin yìí ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó sì ń lọ sípàdé wọn fún ọ̀pọ̀ ọdún àmọ́ kò ṣèrìbọmi. Nígbà tó lọ sí àpéjọ àyíká àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́dún 2003 tó rí bí wọ́n ṣe ń ṣèrìbọmi fáwọn èèyàn, ńṣe ni omijé bẹ̀rẹ̀ sí í dà lójú rẹ̀. Ó gbà pé ẹ̀bi òun ni pé òun ò tíì ṣèrìbọmi, ìyẹn ló mú kó gbàdúrà sí Jèhófà pé: “Ọmọ ọdún mọ́kànléláàádọ́ta ni mí báyìí o, Ọlọ́run, mi ò sì tíì ṣe nǹkan kan tó jọjú fún ọ. Ìwọ ni mo sì fẹ́ sìn o.” Lẹ́yìn ìyẹn, ó bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ìgbésẹ̀ láti sin Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bó ṣe sọ nínú àdúrà rẹ̀. Ó sọ fún ọkùnrin tí wọ́n jọ ń gbé pọ̀ pé tó bá fẹ́ káwọn ṣì jọ máa gbé pọ̀, àwọn méjèèjì ní láti ṣègbéyàwó lábẹ́ òfin, ọkùnrin náà sì gbà pẹ̀lú rẹ̀. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, Ernestine da omijé ayọ̀ lójú nígbà tóun alára ṣèrìbọmi ní November 2004.
Láti ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1990, ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn, títí kan àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà, ni ogun ti lé wá sí Guinea láti orílẹ̀-èdè Làìbéríà àti Sierra Leone. Kété lẹ́yìn táwọn ará dé àgọ́ kan tí wọ́n pa fáwọn tí ogun lé kúrò nílùú, wọ́n ṣètò bí wọn yóò ṣe máa ṣe ìpàdé ìjọ déédéé àti bí wọn yóò ṣe máa wàásù, wọ́n sì tún kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba kan. Àwọn èèyàn kan di ìránṣẹ́ Jèhófà ní àwọn àgọ́ náà. Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Isaac wà lára àwọn tó di ìránṣẹ́ Jèhófà. Lẹ́yìn tí Isaac ṣèrìbọmi, ó ní àǹfààní láti padà síbi tó ti ń ṣiṣẹ́ tẹ́lẹ̀ ní ilé iṣẹ́ ńlá kan ní Làìbéríà. Àmọ́ dípò táá fi lọ, ó gbà láti máa bá iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà nìṣó ní àgọ́ Lainé tí wọ́n wà. Ó sọ pé: “Níbi tí mo wà yìí, kò sí pé màá máa tọrọ àyè lọ́wọ́ ọ̀gá kan pé mo fẹ́ lọ sípàdé ìjọ tàbí ìpàdé àyíká. Kò sóhun tó ń dí mi lọ́wọ́ láti sin Jèhófà níbí.” Ní December 2003, àádọ́jọ [150] Ẹlẹ́rìí tó wà láàárín ọ̀kẹ́ kan àtààbọ̀ [30,000] èèyàn tí ń bẹ ní àgọ́ tó jìnnà gan-an sí àárín ìlú náà ṣe àpéjọ àgbègbè kan. Ohun ayọ̀ ló jẹ́ pé ẹgbẹ̀ta ó dín mẹ́sàn-án [591] èèyàn ló wá síbi àpéjọ náà. Lára wọn ni àwọn adití mẹ́sàn-án tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ àpéjọ náà ní èdè àwọn adití. Àwọn méjìlá ló ṣèrìbọmi ní àpéjọ náà. Àwọn ará mọrírì akitiyan tí ètò Ọlọ́run ṣe láti fi oúnjẹ tẹ̀mí tó dọ́ṣọ̀ bọ́ wọn.
“Àwọn Ohun Fífani-Lọ́kàn-Mọ́ra” Ṣe Ìyípadà Tó Yẹ
Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé kò sóhun táwọn tó ń wa góòlù àti dáyámọ́ńdì nínú ilẹ̀ kò lè ṣe láti rí i pé ọwọ́ àwọn tẹ̀ ẹ́. Bákan náà, ohun ayọ̀ ló jẹ́ láti rí ipa táwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ ń sà láti lè borí ohunkóhun tó bá lè dí wọn lọ́wọ́ láti sin Jèhófà. Wo ìrírí ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Zainab.
Ọmọ ọdún mẹ́tàlá ni Zainab nígbà tí wọ́n ti mú un lẹ́rú. Orílẹ̀-èdè kan ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà ló ń gbé tẹ́lẹ̀, ibẹ̀ sì ni wọ́n ti mú un lọ sórílẹ̀-èdè Guinea. Ọmọ ogún ọdún ló jẹ́ nígbà tó gbọ́ nípa ẹ̀kọ́ Bíbélì. Ó sì ń fi àwọn ohun tó ń kọ́ sílò láìjáfara.
Kò rọrùn rárá fún Zainab láti máa lọ sípàdé ìjọ fún ìjọsìn. Àmọ́, ó mọyì àwọn ìpàdé wọ̀nyí gan-an, ó sì pinnu pé òun ò ní pa ìpàdé kankan jẹ. (Hébérù 10:24, 25) Ohun tó máa ń ṣe ni pé, á lọ tọ́jú àwọn ìwé rẹ̀ pa mọ́ síbì kan lójú ọ̀nà ìpàdé. Tó bá wá ń lọ, á kàn kó wọn dání ni. Ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn tó fi í ṣẹrú lù ú nílùkulù nítorí lílọ tó ń lọ sípàdé ìjọ.
Nígbà tó yá, ipò nǹkan yí padà, Zainab sì bọ́ nínú ìsìnrú tó wà. Láìjáfara, ó bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí gbogbo ìpàdé, èyí tó ràn án lọ́wọ́ láti tètè tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí. Nígbà tí wọ́n fi iṣẹ́ kan táá ti lè máa gbowó ńlá lọ̀ ọ́, kò gbà á nítorí pé iṣẹ́ náà kò ní jẹ́ kó lè máa lọ sípàdé níbi táá ti máa gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ó forúkọ sílẹ̀ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ó di akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi, nígbà tó sì yá, ó ṣèrìbọmi. Kété lẹ́yìn ìyẹn, ó ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́. Oṣù mẹ́fà lẹ́yìn náà, ó gba fọ́ọ̀mù, ó sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà déédéé.
Lẹ́yìn tí ọkùnrin kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ sípàdé ìjọ mélòó kan, ó sọ pé: “Nígbàkigbà tí mo bá wà nípàdé, mi ò kì í rí ara mi bíi tálákà.” Àwọn ìṣúra inú ilẹ̀ tó wà ní Guinea ni ọ̀pọ̀ èèyàn nífẹ̀ẹ́ sí, àmọ́ ohun táwọn èèyàn Jèhófà ń fìtara wá kiri ni àwọn èèyàn tó jẹ́ ìṣúra iyebíye. Bẹ́ẹ̀ ni o, “àwọn ohun fífani-lọ́kàn-mọ́ra tí ń bẹ nínú gbogbo orílẹ̀-èdè” ń wá sínú ìjọsìn Jèhófà tí í ṣe ìjọsìn mímọ́ lónìí!
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 8]
GUINEA-2005
Iye àwọn Ẹlẹ́rìí tó pọ̀ jù lọ: 883
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: 1,710
Àwọn tó wá síbi Ìrántí Ikú Kristi: 3,255
[Àwọn àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 8]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
GUINEA
Conakry
SIERRA LEONE
LÀÌBÉRÍÀ
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Albert àti Luc rèé
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Gbọ̀ngàn Ìjọba kan nílùú Conakry
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Martin
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Ernestine nìyí
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Zainab
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 8]
USAID