Títan Ìhìn Rere Kálẹ̀ ní Haiti Orílẹ̀-Èdè Ẹlẹ́wà
ORÍLẸ̀-ÈDÈ Haiti àti orílẹ̀-èdè Dominican Republic jọ wà ní erékùṣù olóoru kan tó ń jẹ́ Hispaniola ni, níbi táwọn òkè tó ga jù lọ ní àgbègbè òkun Caribbean wà. Àwọn òkè kan ga ju egbèjìlá [2,400] mítà lọ. Nígbà òtútù, ńṣe ni ìrì dídì àti yìnyín máa ń gbá jọ sí ojú àwọn adágún omi kéékèèké tó wà láwọn òkè ibẹ̀.
Igbó táwọn ewéko rẹ̀ tutù yọ̀yọ̀ ló bo gbogbo àwọn òkè àti àfonífojì tó wà ní gúúsù orílẹ̀-èdè Haiti. Àmọ́ àwọn òkè tó wà lápá ibòmíì lórílẹ̀-èdè náà kò ní igbó kankan mọ́ nítorí pé àwọn èèyàn ti pa gbogbo rẹ̀ run. Téèyàn bá lọ sí àríwá tàbí gúúsù orílẹ̀-èdè Haiti, èèyàn á rí i pé orílẹ̀-èdè náà lẹ́wà gan-an. Téèyàn bá wá gba àwọn ọ̀nà tóóró tó rí kọ́lọkọ̀lọ tó gba ẹgbẹ́ àwọn òkè kọjá, èèyàn lè tibẹ̀ rí bí gbogbo ilẹ̀ náà àti òkun tó wà níbẹ̀ ṣe rí. Ibi gbogbo sì làwọn òdòdó tó ní onírúurú àwọ̀ wà.
Iye àwọn èèyàn tó ń gbé lórílẹ̀-èdè ẹlẹ́wà yìí jẹ́ mílíọ̀nù mẹ́jọ ó lé ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [8,300,000], ilẹ̀ Áfíríkà sì ni ọ̀pọ̀ jù lọ wọn ti ṣẹ̀ wá. Lóòótọ́, tálákà ni ọ̀pọ̀ jù lọ wọn, àmọ́ wọ́n ṣèèyàn gan-an, wọ́n sì lẹ́mìí àlejò ṣíṣe. Ó ti tó nǹkan bí àádọ́ta ọdún báyìí táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń wàásù ìhìn rere nípa Ìjọba Ọlọ́run fún wọn, tayọ̀tayọ̀ ni wọ́n sì fi ń gbọ́ ìwàásù náà.—Mátíù 24:14.
Iṣẹ́ Ìwàásù ní Ìlú Kékeré Kan
Ìrírí tí arábìnrin kan tó jẹ́ míṣọ́nnárì ní nígbà àkọ́kọ́ tó lọ wàásù nílùú kékeré kan fi hàn pé àwọn èèyàn ibẹ̀ máa ń fetí sílẹ̀ sí ìwàásù.
Arábìnrin náà kọ̀wé pé: “Lọ́jọ́ kan lóṣù March ọdún 2003, a lọ wàásù nílùú kékeré kan tó ń jẹ́ Casale. Ìrìn ìlú kékeré yìí sí ìlú Cabaret níbi tí ilé àwa míṣọ́nnárì wà báyìí tó nǹkan bí ọgbọ̀n ìṣẹ́jú, ìyẹn téèyàn bá gbé mọ́tò lọ. Ìlú Carabet yìí sì jẹ́ ọgbọ̀n kìlómítà sí àríwá ìlú Port-au-Prince tí í ṣe olú ìlú orílẹ̀-èdè Haiti. Ọdún 1999 làwa Ẹlẹ́rìí ti wàásù nílùú Casale gbẹ̀yìn, ìdí nìyẹn tára wa fi wà lọ́nà láti lọ síbẹ̀, aago méje àárọ̀ la sì gbéra lọ́jọ́ náà. Gbogbo àwọn ará ìjọ wa ló fẹ́rẹ̀ẹ́ lọ tán nítorí pé àwa méjìlélógún la lọ. Ọkọ̀ méjì la gbé lọ. Bá a sì ṣe ń lọ lójú ọ̀nà eléruku tó dà gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ là ń sọ̀rọ̀ tá a sì ń para wa lẹ́rìn-ín títí tá a fi dé àfonífojì kan tí igi ńláńlá pọ̀ sí. Odò kan ń ṣàn gba inú àfonífojì náà kọjá, ìlú Casale sì wà ní ìhà méjèèjì odò náà.
“Apá ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún kẹtàdínlógún ni wọ́n tẹ ìlú tó parọ́rọ́ yìí dó. Nígbà yẹn, àwọn sójà ará Poland kan wá sílẹ̀ Haiti láti wá ran àwọn tó jẹ́ ẹrú nígbà kan rí lọ́wọ́ láti jà fún òmìnira. Àwọn sójà yìí àtàwọn ọmọ ilẹ̀ Haiti tí wọ́n fi ṣaya wá bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ní àfonífojì ọlọ́ràá náà. Fífi tí wọ́n fi àwọn ọmọ ilẹ̀ Haiti ṣaya yìí mú kí wọ́n bí àwọn ọmọ tó jẹ́ pé òmíràn lára wọn jẹ́ aláwọ̀ funfun, òmíràn jẹ́ aláwọ̀ dúdú, àwọn míì mọ́ lára díẹ̀, ẹyinjú àwọn míì jẹ́ aláwọ̀ ewé tàbí àwọ̀ ilẹ̀ tàbí àwọn àwọ̀ mìíràn bẹ́ẹ̀. Ó máa ń wúni lórí gan-an láti rí onírúurú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ lórílẹ̀-èdè náà.
“Nílé tá a kọ́kọ́ dé, ẹni tá a bá ò nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wa rárá. Bá a ṣe kúrò níbẹ̀ ni ọkùnrin kan wá bá wa. Ó fẹ́ mọ̀ bóyá a gbà gbọ́ pé Jésù yàtọ̀ sí Ọlọ́run. A sọ fún un pé kó lọ mú Bíbélì rẹ̀ wá, ó sì ṣe bẹ́ẹ̀. Lẹ́yìn tá a wá ṣàlàyé ọ̀rọ̀ náà fún un látinú Ìwé Mímọ́, ó gbà pé Ọmọ Ọlọ́run ni Jésù, àti pé Jèhófà ni ‘Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà.’ (Jòhánù 17:3) Ọ̀pọ̀ èèyàn ló pè wá pé ká wá wàásù fáwọn. Àwọn kan bi wá pé, ‘Ìgbà wo lẹ máa padà wá kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?’
“Nígbà tó di ọ̀sán, a lọ jókòó sábẹ́ ibòji kan láti jẹ oúnjẹ ọ̀sán. Àwọn arábìnrin méjì kan ló bá wa fi ẹja se oúnjẹ ìkòkò ńlá méjì tá a gbé dání lọ. Oúnjẹ náà dùn gan-an ni! Bá a ṣe wà níbẹ̀ tá à ń jẹun tá a sì ń sọ̀rọ̀ là tún ń wàásù fáwọn tó ń kọjá. Nígbà tá a wá ṣe tán, a sọdá odò yẹn sí apá kejì ìlú náà. Inú wa dùn gan-an ni bá a ṣe ń wàásù fáwọn èèyàn tí wọ́n jókòó sábẹ́ igi lẹ́gbẹ̀ẹ́ ilé wọn alábọ́ọ́dé. Ó mà dùn mọ́ wa o láti máa gbọ́ ìró àwọn ọmọdé tó ń ṣeré àti láti rí àwọn obìnrin tó ń fọṣọ lódò àtàwọn màmá àgbàlagbà tó ń lọ èso kọfí!
“Kò pẹ́ ni aago mẹ́rin ìrọ̀lẹ́ lù, gbogbo àwa tá a lọ sì fayọ̀ lọ sídìí ọkọ̀ ká lè padà sílùú Cabaret. Ìgbà àkọ́kọ́ nìyẹn tí èmi àti ọkọ mi máa lọ sílùú Casale táwọn èèyàn ti máa ń yá mọ́ni gan-an. A gbádùn lílọ tá a lọ síbẹ̀ púpọ̀.”
Látìgbà táwọn míṣọ́nnárì àkọ́kọ́ tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti dé ilẹ̀ Haiti lọ́dún 1945 ni iye àwọn Ẹlẹ́rìí ti ń pọ̀ sí i tó fi jẹ́ pé, ní báyìí, wọ́n ti tó nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlá [14,000], wọ́n sì ń kọ́ àwọn èèyàn tó lé ní ẹgbàá mọ́kànlá [22,000] lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Iṣẹ́ ìwàásù àwọn Ẹlẹ́rìí wọ̀nyí ti ṣe àwọn èèyàn tó lé ní ọ̀kẹ́ mẹ́ta ó dín ẹgbẹ̀ta àti méjìdínlọ́gbọ̀n [59,372] tí wọ́n wá síbi Ìrántí Ikú Kristi lóṣù March ọdún 2005 láǹfààní, tilé-toko ni wọ́n sì ti ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fáwọn èèyàn. Ẹ jẹ́ ká wo onírúurú ọ̀nà tí iṣẹ́ ìwàásù táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe gbà ń nípa lórí àwọn èèyàn.
Fífi Àwòrán Aláwọ̀ Mèremère Wàásù Ìhìn Rere
Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ará ilẹ̀ Haiti ló fẹ́ràn àwọn ohun tó ní àwọ̀ mèremère. Èyí máa ń hàn nínú aṣọ tí wọ́n ń wọ̀, ọ̀dà tí wọ́n fi kun ilé, oríṣiríṣi òdòdó tí wọ́n gbìn sí ọgbà wọn, àti iṣẹ́ ọnà wọn. Àwọn iṣẹ́ ọnà kan wà tí wọ́n ń pè ní L’Art Haitien, èyí tó fi àṣà ìbílẹ̀ àwọn ará Haiti hàn. Àwọn iṣẹ́ ọ̀nà wọ̀nyí wà káàkiri ìgboro ìlú Port-au-Prince. Onírúurú ibi lágbàáyé làwọn èèyàn sì ti máa ń wá láti rà wọ́n.
Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n tún máa ń yàwòrán sára àwọn nǹkan míì. Téèyàn bá wọ ìgboro ìlú Port-au-Prince, èèyàn á rí oríṣiríṣi bọ́ọ̀sì akérò tí wọ́n ń pè ní camionettes tàbí tap-taps tí wọ́n ya onírúurú àwòrán sí. Wọ́n sábà máa ń yàwòrán àwọn ìtàn tó wà nínú Bíbélì sára àwọn ọkọ̀ wọ̀nyí.
Téèyàn bá ń lọ láàárín ìgboro, èèyàn lè dédé rí àwọn àwòrán kan téèyàn mọ̀, irú bí àwòrán Ádámù àti Éfà nínú ọgbà Édẹ́nì. Èèyàn tiẹ̀ lè rí irú àwòrán bẹ́ẹ̀ lára wíńdò tó wà lẹ́yìn ọkọ̀ camionette. Wọ́n sì sábà máa ń kọ ọ̀rọ̀ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí orúkọ Jèhófà wà tàbí gbólóhùn tí orúkọ Jèhófà wà sára àwọn ọkọ̀ tàbí kí wọ́n kọ ọ́ mọ́ ara orúkọ okòwò wọn.
Wíwàásù Ìhìn Rere Nílé Ìwé
Àwọn àǹfààní kan máa ń ṣí sílẹ̀ fáwọn ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí ní orílẹ̀-èdè Haiti láti kọ́ àwọn ọmọ ilé ìwé ẹlẹgbẹ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ohun tí ọmọbìnrin ọlọ́dún mẹ́tàdínlógún kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí kọ fi èyí hàn. Ó ní:
“Lọ́jọ́ kan, ọmọkùnrin kan tá a jọ wà ní kíláàsì wá bá mi, ó ní kí n sọ ohun tí ọ̀rọ̀ náà ‘àgbèrè’ túmọ̀ sí fóun. Èrò ọkàn mi ni pé ńṣe ló kàn fẹ́ dọ́gbọ́n fa ojú mi mọ́ra, ni mi ò bá dá a lóhùn. Àmọ́ bó ṣe tún lọ bi ọmọ kíláàsì wa kan tó jẹ́ ọkùnrin ní ìbéèrè kan náà mú kí gbogbo àwọn ọmọ kíláàsì fẹ́ láti mọ ìdáhùn sí ìbéèrè náà. Èyí mú kí n lọ ṣe ìwádìí sí i lórí ọ̀rọ̀ náà, nígbà tó sì di ọ̀sẹ̀ tó tẹ̀ lé e, mo ṣàlàyé ọ̀rọ̀ náà fáwọn ọmọ kíláàsì. Mo jẹ́ kí wọ́n mọ ìdí táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń yẹra fún ìṣekúṣe àti ohunkóhun tó bá lè sọ ìjọsìn wa di ẹlẹ́gbin àti ìdí tá a fi jẹ́ onímọ̀ọ́tótó.
“Wọ́n bi mí ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbéèrè, wọ́n sì fara mọ́ ìdáhùn tí mo fún wọn látinú Bíbélì. Kódà ọ̀gá àgbà ilé ìwé wa tí kò fẹ́ dá sí ọ̀rọ̀ náà tẹ́lẹ̀ béèrè ọ̀pọ̀ ìbéèrè lọ́wọ́ mi, ó sì ṣètò pé kí n ṣe àlàyé tí mo ṣe lórí ọ̀rọ̀ náà ní àwọn kíláàsì yòókù. Mo fi ìwé náà Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́a hàn wọ́n, ọ̀pọ̀ nínú wọn sì nífẹ̀ẹ́ sí i. Lọ́jọ́ kejì, iye ìwé yìí tí mo fún àwọn ọmọ ilé ìwé mi jẹ́ márùndínláàádọ́ta. Kò pẹ́ rárá tí ọ̀pọ̀ nínú wọn fi parí ìwé náà, ọ̀pọ̀ lára wọn làwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n jọ wà ládùúgbò kan náà ti ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì báyìí. Ọmọ ilé ìwé wa kan tó ń gbé ládùúgbò wa sì ti ń wá sí gbogbo ìpàdé báyìí.”
Fífi Èdè Creole Wàásù
Bó ṣe jẹ́ pé onírúurú èèyàn ló wà nílẹ̀ Haiti, àti aláwọ̀ dúdú, àti aláwọ̀ pupa, àtàwọn tó ní àwọ̀ mìíràn, tí àwọn ohun tó wà níbẹ̀ sì fani mọ́ra, bẹ́ẹ̀ náà ni èdè Creole tí wọ́n ń sọ níbẹ̀ ṣe jẹ́ èdè tó wuni láti gbọ́. Èdè náà jẹ́ àdàpọ̀ èdè Faransé àti èdè tí wọ́n ń sọ ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà. Òun ni èdè àbínibí àwọn ọmọ ilẹ̀ Haiti, òun sì léèyàn lè fi bá wọn sọ̀rọ̀ táá wọ̀ wọ́n lọ́kàn jù lọ. Èdè yìí làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lò jù láti fi wàásù níbẹ̀, ètò sì ti ń lọ lọ́wọ́ báyìí láti rí i pé a tẹ àwọn ìwé tó ń ṣàlàyé Bíbélì púpọ̀ sí i ní èdè Creole ti ilẹ̀ Haiti.
Lọ́dún 1987, wọ́n túmọ̀ ìwé pẹlẹbẹ náà Gbádùn Iwalaaye lori Ilẹ Ayé Titilae! sí èdè Creole ti ilẹ̀ Haiti, lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n túmọ̀ ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun, nígbà tó sì yá, wọ́n túmọ̀ ìwé pẹlẹbẹ náà Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa? Àwọn ìwé wọ̀nyí ti ran àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́wọ́ gan-an láti lóye àwọn ẹ̀kọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dé àyè kan. Ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ ti September 1, 2002 la fi bẹ̀rẹ̀ títẹ Ilé Ìṣọ́ jáde ní èdè Creole ti ilẹ̀ Haiti. Òótọ́ ni pé wọ́n ṣì máa ń ka àwọn ìwé tó wà ní èdè Faransé, àmọ́ ìwé tó wà ní èdè àbínibí wọn ni ọ̀pọ̀ lára wọn fẹ́ràn jù lọ.
Wíwàásù Ìhìn Rere Ní Ọgbà Ẹ̀wọ̀n
Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sáwọn ọgbà ẹ̀wọ̀n láti wàásù ìhìn rere fáwọn tó wà níbẹ̀ lọ́kùnrin àti lóbìnrin. Ohun ayọ̀ ló jẹ́ fáwọn Ẹlẹ́rìí tó ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù yìí láti máa sọ ọ̀rọ̀ ìtùnú fáwọn tó wà nírú ipò ìbànújẹ́ yẹn. Arákùnrin kan kọ̀wé pé:
“Nígbà àkọ́kọ́ tá a lọ sọ́gbà ẹ̀wọ̀n kan, wọ́n pe àádọ́ta ẹlẹ́wọ̀n wá sínú yàrá ńlá kan tá a ti lè bá wọn sọ́rọ̀. A ò mọ ohun tó máa jẹ́ ìṣarasíhùwà wọn. Àmọ́, nígbà tá a sọ fún wọn pé tìtorí àtiràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì la ṣe wá, inú gbogbo wọn dùn. A fi ìwé pẹlẹbẹ tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Apply Yourself to Reading and Writing àti Gbádùn Iwalaaye lori Ilẹ Ayé Titilae! tó wà ní èdè Creole hàn wọ́n, a sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n lára wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àwọn mẹ́wàá nínú wọn ò mọ̀wé, àmọ́ nígbà tá a jẹ́ kí wọ́n mọ bí wọ́n ṣe lè lo àwọn àwòrán tó wà nínú ìwé náà láti fi lóye àwọn ọ̀rọ̀ ibẹ̀, wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí i.
Nígbà táwọn Ẹlẹ́rìí padà lọ sọ́gbà ẹ̀wọ̀n náà, ọkùnrin ẹlẹ́wọ̀n kan sọ pé: “Mo ti ka ìwé tẹ́ ẹ fún mi lákàtúnkà. Mi ò yéé ronú lórí ohun tí ìwé náà sọ, mo sì ti ń fojú sọ́nà láti rí yín.” Ọkùnrin kan tó ń ṣẹ̀wọ̀n níbẹ̀ nítorí pé ó lọ digun jalè sọ pé òun fẹ́ yí padà, ó sì ní káwọn Ẹlẹ́rìí bá òun ṣètò bí ẹnì kan yóò ṣe lọ máa kọ́ ìyàwó òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bákan náà, ọkùnrin kan tó ní ọmọ méjì tóun náà ń ṣẹ̀wọ̀n sọ pé káwọn Ẹlẹ́rìí lọ máa kọ́ ìyàwó òun náà lẹ́kọ̀ọ́ kó lè mọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín ẹ̀kọ́ tòótọ́ àti ẹ̀kọ́ èké. Olórí ìjọ Pùròtẹ́sítáǹtì kan tí wọ́n sọ sẹ́wọ̀n nítorí pé ó lu àwọn ọmọ ìjọ rẹ̀ ní jìbìtì sọ pé òun ti rí òtítọ́ báyìí, ó ní tóun bá kúrò lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, òun máa ran àwọn ọmọ ìjọ òun lọ́wọ́ láti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
Ẹlẹ́wọ̀n kan tí kò ní ìwé pẹlẹbẹ Béèrè lédè Creole yá ìwé pẹlẹbẹ náà lọ́wọ́ ẹlẹ́wọ̀n mìíràn, ó da ìwé náà kọ látòkèdélẹ̀, ó sì há gbogbo rẹ̀ sórí. Obìnrin ẹlẹ́wọ̀n kan bẹ̀rẹ̀ sí í sọ ohun tó ń kọ́ fáwọn obìnrin mẹ́sàn-án kan tí wọ́n jọ ń ṣẹ̀wọ̀n, àní ó tiẹ̀ tún ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́. Ọkùnrin ẹlẹ́wọ̀n kan kẹ́kọ̀ọ́ ìwé pẹlẹbẹ Béèrè parí, lẹ́yìn ìyẹn ó tẹ̀ síwájú sínú ìwé Ìmọ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù fáwọn tí wọ́n jọ ń ṣẹ̀wọ̀n. Kò sì pẹ́ tó fi bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn mẹ́rin lára wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
Nígbà kan rí, ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Merconyb ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì ní àwọn mọ̀lẹ́bí tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó máa ń gba àwọn ẹlẹ́wọ̀n yòókù níyànjú pé kí wọ́n máa ka àwọn ìwé tó ń ṣàlàyé Bíbélì táwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ fún un. Ó sọ pé: “Nígbà tí mo bá fi àwọn ìwé náà lọ àwọn tá a jọ wà lẹ́wọ̀n, Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wọ́n máa ń pè mí. Àmọ́, mo máa ń sọ fún wọn pé Ẹlẹ́rìí kọ́ ni mí torí pé ìwà mi ò bá tiwọn mu. Ṣùgbọ́n ní báyìí, mi ò fẹ́ fọ̀rọ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ ṣeré mọ́ rárá, mo fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ kí n sì ṣèrìbọmi. Ká ní mo ti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin nígbà tí mo wà ní kékeré ni, ǹ bá má dèrò ẹ̀wọ̀n.”
Ọ̀kan lára àwọn ẹlẹ́wọ̀n tó gbàwé lọ́wọ́ Mercony sọ fún Ẹlẹ́rìí tó wá sọ́dọ̀ rẹ̀ pé: “Kẹ́ ẹ tó wá sọ́dọ̀ mi lọ́jọ́ Monday tó kọjá, ayé ti sú mi débi pé mo ti pinnu láti para mi. Àmọ́ lẹ́yìn tí mo ka àwọn ìwé ìròyìn yẹn, mo gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kó dárí jì mí fún nǹkan burúkú tí mo ti ṣe, mo sì ní kó rán ẹnì kan sí mi láti fi ohun tó yẹ kí n ṣe hàn mí. Ẹ wò ó, inú mi dùn gan-an ni bẹ́ ẹ ṣe wá lọ́jọ́ kejì tẹ́ ẹ sì lẹ́ ẹ fẹ́ máa kọ́ àwa ẹlẹ́wọ̀n lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì! Màá fẹ́ kẹ́ ẹ kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ nípa bí mo ṣe lè máa sin Jèhófà.”
Ìwé Ìròyìn Jí! Jẹ́ Kí Ọ̀pọ̀ Èèyàn Mọ̀ Nípa Ìhìn Rere
Ìwé ìròyìn Jí! ti November 8, 2000 sọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ nọ́ọ̀sì. Obìnrin kan gba ẹgbẹ̀rún méjì ẹ̀dà ìwé ìròyìn náà, ó sì pín in fáwọn nọ́ọ̀sì tó wá síbi ìdálẹ́kọ̀ọ́ kan nílùú Port-au-Prince. Bákan náà, àwọn ará pín ìwé ìròyìn Jí! ti July 8, 2002 tó sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọlọ́pàá àti iṣẹ́ wọn fáwọn ọlọ́pàá jákèjádò ìlú Port-au-Prince. Àwọn ọlọ́pàá náà gbádùn ìwé ìròyìn ọ̀hún débi pé títí di ìsinsìnyí, táwọn kan lára wọn bá ṣì rí àwọn Ẹlẹ́rìí lójú ọ̀nà, wọ́n máa ń ní kí wọ́n fún àwọn sí i.
Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, obìnrin kan tó ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Àjọ Ìlera Àgbáyé ṣètò bí àwọn èèyàn ṣe máa gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ nípa àrùn éèdì. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ fún obìnrin náà pé kó wá sí ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn. Níbẹ̀, wọ́n fi àwọn ohun tí wọ́n ti tẹ̀ jáde nínú ìwé ìròyìn Jí! lórí ọ̀rọ̀ náà han obìnrin yìí. Inú rẹ̀ dùn gan-an láti rí ìwé tó fi Bíbélì ṣàlàyé àwọn nǹkan téèyàn lè ṣe láti dènà àrùn éèdì àti ìrànlọ́wọ́ táwọn míì lè ṣe fáwọn tó ní àrùn náà. Obìnrin yìí sọ pé ìwé ìròyìn Jí! ló ń mú ipò iwájú nínú kíkọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ lórí ọ̀rọ̀ yìí.
Bẹ́ẹ̀ ni o, ọ̀pọ̀ ọ̀nà làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà ń tan ìhìn rere kálẹ̀ ní Haiti tó jẹ́ ilẹ̀ ẹlẹ́wà, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ń ṣe ní igba ó lé mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n [234] ilẹ̀ mìíràn jákèjádò ayé. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń fetí sílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ tí ń fúnni nírètí yìí, àwọn Ẹlẹ́rìí sì ń gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n má ṣe jẹ́ kí àwọn ìṣòro tó wà nínú ayé ìsinsìnyí gbà wọ́n lọ́kàn, àmọ́ kí wọ́n máa fojú sọ́nà fún ayé tuntun níbi tí gbogbo àwọn tó bá ń jọ́sìn Ọlọ́run tòótọ́ náà Jèhófà yóò ti gbé ìgbé ayé pípé.—Ìṣípayá 21:4.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe àwọn ìwé tá a dárúkọ rẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ́ yìí.
b A ti yí orúkọ rẹ̀ padà.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 9]
Àwòrán òkun tó wà lẹ́yìn: ©Adalberto Rios Szalay/photodisc/age fotostock