ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w06 12/15 ojú ìwé 32
  • Ibo Lọ̀rọ̀ Kérésìmesì Ń Lọ?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ibo Lọ̀rọ̀ Kérésìmesì Ń Lọ?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
w06 12/15 ojú ìwé 32

Ibo Lọ̀rọ̀ Kérésìmesì Ń Lọ?

NÍ OṢÙ December ọdún 1996, àpilẹ̀kọ kan jáde nínú ìwé ìròyìn U.S.News & World Report tí wọ́n pe àkọlé rẹ̀ ní “Ìwádìí Nípa Kérésìmesì.” Àpilẹ̀kọ náà gbé ayẹyẹ Kérésìmesì yẹ̀ wò, láti wò ó bóyá ńṣe ló ń “sàn sí i, tí kò sì fi bẹ́ẹ̀ bọ́rọ̀ òwò lọ mọ́.” Ṣé ayẹyẹ Kérésìmesì sì ti wá ń sàn sí i lóòótọ́ tí kò sì fi bẹ́ẹ̀ bọ́rọ̀ òwò lọ mọ́?

Àpilẹ̀kọ inú ìwé ìròyìn náà jẹ́ ká rí ìdí tí kò fi yẹ ká máa retí pé kí ayẹyẹ Kérésì sàn sí i. Ó sọ pé: “Kò sí àkọsílẹ̀ kankan tó fi hàn pé àwọn èèyàn yan ọjọ́ kan láti máa ṣe ọjọ́ ìbí Kristi àfìgbà tó di ọ̀rúndún kẹrin, nígbà tí Kọnsitatáìnì . . . jẹ́ olú ọba Róòmù. Ìyẹn fi hàn pé “dé àyè kan, kò sẹ́ni tó lè sọ ní pàtó pé ìgbà báyìí ni wọ́n bí Jésù.” Àpilẹ̀kọ náà tún sọ pé “àwọn ìwé ìhìn rere ò sọ ọdún tí wọ́n bí i, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ ti oṣù tàbí ọjọ́ tó bọ́ sí gan-an.” Bí òpìtàn kan tó ń ṣiṣẹ́ ní Yunifásítì ti Texas ṣe sọ, “kò tiẹ̀ wá sọ́kàn àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ rárá láti máa ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí Jésù.”

Lábẹ́ ìsọ̀rí náà, “Ìméfò Lásán,” àpilẹ̀kọ náà sọ̀rọ̀ nípa “bí àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ṣe yan December 25.” Ó ní: “Ohun tí ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn mọ̀ ni pé ńṣe ni wọ́n dìídì sọ àjọ̀dún tí wọ́n ń pè ní Saturnalia àtàwọn ayẹyẹ Kèfèrí míì di ayẹyẹ ‘àwọn Kristẹni’ tí wọ́n ń pè ní Kérésìmesì.” Àpilẹ̀kọ náà fi kún un pé “ńṣe làwọn olórí ṣọ́ọ̀ṣì dìídì fi ayẹyẹ Kérésì sí apá ìparí oṣù December torí pé ó ti mọ́ àwọn èèyàn lára láti máa ṣe ayẹyẹ lákòókò náà, wọ́n sì mọ̀ pé ìyẹn á mú kí ayẹyẹ ọjọ́ ìbí Olùgbàlà di ohun táwọn èèyàn ń ṣe jákèjádò ayé.” Àmọ́ nígbà tó di ìdajì ọ̀rúndún kọkàndínlógún, nǹkan yí padà, ohun táwọn èèyàn wá ń fàkókò Kérésìmesì ṣe ni pé kí wọ́n máa ra ẹ̀bùn kí wọ́n sì máa fúnni lẹ́bùn. Àpilẹ̀kọ náà tún sọ pé: “Àṣà fífúnni lẹ́bùn lákòókò Kérésì tó bẹ̀rẹ̀ nígbà yẹn sọ àwọn èèyàn dolówó òjijì, kò sì pẹ́ táwọn oníṣòwò àtàwọn tó ń polówó ọjà fi bẹ̀rẹ̀ sí í gbé àkókò ayẹyẹ náà lárugẹ.”

Nítorí náà, bí ọ̀rọ̀ Kérésì ṣe ń lọ yìí, ó ti dájú pé kò lè bá ìsìn Kristẹni tòótọ́ mu, kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni yóò máa jìnnà sí i. Ká tiẹ̀ wá sọ pé òótọ́ lohun táwọn kan sọ pé òwò ṣíṣe àti èrè àjẹpajúdé ló ba ayẹyẹ Kérésì jẹ́ báyìí, òótọ́ ibẹ̀ ni pé Ọlọ́run ò tiẹ̀ sọ pé káwọn Kristẹni tòótọ́ máa ṣayẹyẹ ọjọ́ ìbí Jésù. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí Bíbélì kà sí pàtàkì jù ni ìràpadà tí Kristi pèsè nípasẹ̀ ikú àti àjíǹde rẹ̀ sí ọ̀run. (Mátíù 20:28) Ìyẹn ló ṣe pàtàkì jù, òun ló sì máa ṣe pàtàkì jù títí láé.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́