Ohun Tí Bíbélì Sọ
Ǹjẹ́ àkókò kan ń bọ̀ tí gbogbo èèyàn á máa ṣe ìdájọ́ òdodo?
Kí ni ìdáhùn rẹ?
- Bẹ́ẹ̀ ni 
- Bẹ́ẹ̀ kọ́ 
- Kò dá mi lójú 
Ohun tí Bíbélì sọ
“Èmi mọ̀ dunjú pé Jèhófà yóò ṣe ẹ̀tọ́ lábẹ́ òfin fún ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́, èyíinì ni ìdájọ́ àwọn òtòṣì.” (Sáàmù 140:12) Ìjọba Ọlọ́run máa jẹ́ kí ìdájọ́ òdodo wà láyé.
Kí làwọn nǹkan míì tí Bíbélì sọ?
- Ọlọ́run ń rí bí ìdájọ́ òdodo ò ṣe sí láyé mọ́, ó sì máa ṣe àtúnṣe sí i.—Oníwàásù 5:8. 
- Tí Ọlọ́run bá mú ìdájọ́ òdodo wá, àlàáfíà àti ààbò máa wà láyé.—Aísáyà 32:16-18. 
Ṣé Ọlọ́run ka àwọn èèyàn kan sí pàtàkì ju àwọn míì lọ?
Èrò àwọn kan ni pé Ọlọ́run bù kún àwùjọ àwọn èèyàn pàtó kan, ó sì ti gégùn-ún fún àwọn kan. Àwọn míì sì gbà pé bákan náà ni gbogbo èèyàn ṣe rí lójú Ọlọ́run. Kí lèrò rẹ?
Ohun tí Bíbélì sọ
“Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, ṣùgbọ́n ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.” (Ìṣe 10:34, 35) Bákàn náà ni gbogbo èèyàn ṣe rí lójú Ọlọ́run.
Kí làwọn nǹkan míì tí Bíbélì sọ?
- “Gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ahọ́n àti ènìyàn” ni “ìhìn rere” tàbí ìròyìn ayọ̀ tó wà nínú Bíbélì wà fún.—Ìṣípayá 14:6.