Gbogbo ohun ìjà ogun ni kò ní sí mọ́
Ohun Tí Bíbélì Sọ
Ṣé àlááfíà ṣì máa wà láyé?
Kí ni ìdáhùn rẹ?
- Bẹ́ẹ̀ ni 
- Bẹ́ẹ̀ kọ́ 
- Kò dá mi lójú 
Ohun tí Bíbélì sọ
Nígbà tí Jésù Kristi bá ń ṣàkóso, ‘ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà yóò wà títí òṣùpá kì yóò fi sí mọ́,’ àní títí láé.—Sáàmù 72:7.
Kí làwọn nǹkan míì tí Bíbélì sọ?
- Àwọn èèyàn burúkú kò ní sí mọ́ láyé, àwọn èèyàn rere máa “rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.”—Sáàmù 37:10, 11. 
- Ọlọ́run máa mú gbogbo ogun kúrò pátápátá.—Sáàmù 46:8, 9. 
Ṣé ó ṣeé ṣe ká ní ìfọ̀kànbalẹ̀ báyìí?
Èrò àwọn kan ni pé . . . kò ṣeé ṣe káwa èèyàn ní ìfọ̀kànbalẹ̀ torí pé ìyà àti ìwà ìrẹ́jẹ ló kún inú ayé. Kí lèrò rẹ?
Ohun tí Bíbélì sọ
Lónìí, àwọn tó sún mọ́ Ọlọ́run máa ń ní “àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ.”—Fílípì 4:6, 7.
Kí làwọn nǹkan míì tí Bíbélì sọ?
- Ọlọ́run ṣèlérí pé òun máa fòpin sí ìyà àti ìwà ìrẹ́jẹ, òun á sì sọ “ohun gbogbo di tuntun.”—Ìṣípayá 21:4, 5. 
- A máa ní ìfọ̀kànbalẹ̀ tá a bá sapá láti ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run.—Mátíù 5:3.