Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọrun Fún 1996
ÀWỌN ÌTỌ́NI
Ní 1996, àwọn ohun tí ó tẹ̀ lé e yìí ni yóò jẹ́ ìṣètò fún dídarí Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọrun.
ÀWỌN ÌWÉ ÌKẸ́KỌ̀Ọ́: Bibeli, Isopọṣọkan ninu Ijọsin Ọlọrun Tootọ Kanṣoṣo Naa [uw-YR], Ilé-Ìṣọ́nà [w-YR], “Awọn Àkòrí Ọ̀rọ̀ Bibeli fún Ìjíròrò,” gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nínú Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki ní Ìtumọ̀ Ayé Titun [*td-YR], Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun [kl-YR], àti Iwe Itan Bibeli Mi [my-YR] ni a óò gbé àwọn iṣẹ́ àyànfúnni kà.
A gbọ́dọ̀ bẹ̀rẹ̀ ilé ẹ̀kọ́ náà LÁKÒÓKÒ pẹ̀lú orin, àdúrà àti àwọn ọ̀rọ̀ ìkíni káàbọ̀, kí a sì tẹ̀ síwájú báyìí:
IṢẸ́ ÀYÀNFÚNNI NO. 1: Ìṣẹ́jú 15. Alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ni yóò bójú tó ọ̀rọ̀ àsọyé yìí, a óò sì gbé e ka Isopọṣọkan ninu Ijọsin Ọlọrun Tootọ Kanṣoṣo Naa tàbí Ilé-Ìṣọ́nà. A ní láti ṣe iṣẹ́ àyànfúnni yìí gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ ìtọ́ni oníṣẹ̀ẹ́jú 10 sí 12, tí àtúnyẹ̀wò aláfẹnusọ oníṣẹ̀ẹ́jú 3 sí 5 yóò sì tẹ̀ lé e, ní lílo àwọn ìbéèrè tí ó wà nínú ìtẹ̀jáde náà. Ète wa kò gbọdọ̀ jẹ́ láti wulẹ̀ kárí àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ náà, ṣùgbọ́n láti pàfiyèsí sórí ìwúlò gbígbéṣẹ́ tí ó wà nínú ìsọfúnni tí a ń jíròrò, ní títẹnu mọ́ ohun tí yóò ṣe ìjọ láǹfààní jù lọ. A gbọ́dọ̀ lo ẹṣin ọ̀rọ̀ tí a fi hàn. A rọ gbogbo àwọn tí a ń yan iṣẹ́ yìí fún láti múra sílẹ̀ dáradára ṣáájú, kí àwùjọ baà lè jàǹfààní kíkún rẹ́rẹ́ láti inú àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ yìí.
Àwọn arákùnrin tí a ń yan ọ̀rọ̀ àsọyé yìí fún ní láti ṣọ́ra láti má kọjá àkókò tí a fún wọn. A lè fún olùbánisọ̀rọ̀ ní ìmọ̀ràn ìdákọ́ńkọ́ bí ó bá pọn dandan tàbí bí òun fúnra rẹ̀ bá béèrè fún un.
ÀWỌN KÓKÓ PÀTÀKÌ LÁTI INÚ BIBELI KÍKÀ: Ìṣẹ́jú 6. Èyí ni alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, tí yóò mú àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ náà bá àwọn àìní àdúgbò mu, lọ́nà tí ó gbéṣẹ́, yóò bójú tó. Èyí kò ní láti jẹ́ kìkì àkópọ̀ lórí ibi tí a yàn fún kíkà. A lè fi àtúnyẹ̀wò aláàbọ̀ ìṣẹ́jú sí ìṣẹ́jú kan, tí ó káríi gbogbo orí tí a yàn fúnni kún un. Bí ó ti wù kí ó rí, ète náà ní pàtàkì ni láti ran àwùjọ lọ́wọ́ láti lóye ìdí tí ìsọfúnni náà fi ṣeyebíye fún wa àti bí ó ti ṣeyebíye tó fún wa. Lẹ́yìn náà, alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ yóò yọ̀ọ̀da àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ láti lọ sí kíláàsì wọn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.
IṢẸ́ ÀYÀNFÚNNI NO. 2: Ìṣẹ́jú 5. Èyí jẹ́ Bibeli kíkà lórí àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ tí a yàn fúnni, tí arákùnrin kan yóò bójú tó. Èyí yóò rí bẹ́ẹ̀ ní ilé ẹ̀kọ́ kìíní àti ní àwọn àfikún àwùjọ yòókù. Ìwé kíkà tí a yàn fúnni sábà máa ń mọ níwọ̀n láti yọ̀ọ̀da fún akẹ́kọ̀ọ́ náà láti ṣe àlàyé ṣókí ní ìbẹ̀rẹ̀ àti ní ìparí ọ̀rọ̀ rẹ̀. A lè fi ìtàn tí ó yí àwọn ẹsẹ náà ká, ìjẹ́pàtàkì àsọtẹ́lẹ̀ tàbí ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ rẹ̀, àti bí àwọn ìlànà rẹ̀ ṣe kàn wá kún un. A gbọ́dọ̀ ka gbogbo ẹsẹ tí a yàn fúnni pátá, láìdánudúró lágbede méjì. Àmọ́ ṣá o, níbi tí àwọn ẹsẹ tí a óò kà kò bá ti tẹ̀ léra, akẹ́kọ̀ọ́ náà lè sọ ẹsẹ tí kíkà náà ti ń bá a lọ.
IṢẸ́ ÀYÀNFÚNNI NO. 3: Ìṣẹ́jú 5. A óò yan èyí fún arábìnrin. A óò gbé kókó ẹ̀kọ́ iṣẹ́ yìí karí “Awọn Àkòrí Ọ̀rọ̀ Bibeli fún Ìjíròrò,” gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nínú Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki ní Ìtumọ̀ Ayé Titun, tàbí Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. Akẹ́kọ̀ọ́ tí a yàn án fún gbọ́dọ̀ lè kàwé. Nígbà tí ó bá ń ṣiṣẹ́ yìí, akẹ́kọ̀ọ́ náà lè jókòó tàbí dúró. Arábìnrin tí a yan iṣẹ́ yìí fún yóò ní láti mú ẹṣin ọ̀rọ̀ àti àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ tí a fẹ́ gbé yẹ̀ wò bá ọ̀nà ìgbékalẹ̀ tí ó gbéṣẹ́ mu, yóò dára jù kí ó jẹ́ ọ̀kan tí ó jẹ mọ́ iṣẹ́ ìsìn pápá tàbí ìjẹ́rìí àìjẹ́-bí-àṣà. Nígbà tí a bá gbé iṣẹ́ náà karí ìwé Ìmọ̀, a lè gbé e kalẹ̀ ní ọ̀nà ìpadàbẹ̀wò tàbí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli inú ilé. Ọ̀nà tí àkẹ́kọ̀ọ́ náà gbà ran onílé lọ́wọ́ láti ronú lórí àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ náà kí ó sì lóye rẹ̀, àti bí ó ṣe lo àwọn ẹsẹ ìwé mímọ́, ni yóò jẹ alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ lọ́kàn jù lọ. Kò yẹ kí a ka àwọn ìpínrọ̀ ìwé náà. Alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ yóò ṣètò fún olùrànlọ́wọ́ kan ṣoṣo, ṣùgbọ́n a lè lo olùrànlọ́wọ́ mìíràn ní àfikún. Ọ̀nà tí ó gbéṣẹ́ tí a gbà lo àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ náà ni ó yẹ kí a fún ní àfiyèsí pàtàkì, kì í ṣe ọ̀nà tí a gbà gbé e kalẹ̀.
IṢẸ́ ÀYÀNFÚNNI NO. 4: Ìṣẹ́jú 5. A óò yan èyí fún arákùnrin tàbí arábìnrin. A óò gbé e karí Iwe Itan Bibeli Mi. Nígbà tí a bá yàn án fún arákùnrin, èyí gbọ́dọ̀ jẹ́ ọ̀rọ̀ àsọyé fún gbogbo àwùjọ pátá. Ó sábà máa ń dára jù lọ fún arákùnrin náà láti múra ọ̀rọ̀ àsọyé rẹ̀ sílẹ̀ ní níní àwùjọ inú Gbọ̀ngàn Ìjọba lọ́kàn, kí ó baà lè kún fún ẹ̀kọ́ ní tòótọ́, kí ó sì ṣe àwọn tí ń gbọ́ ọ láǹfààní ní ti gidi. Nígbà tí a bá yàn án fún arábìnrin, ó ní láti gbé àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ náà kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí a ti lànà rẹ̀ sílẹ̀ fún Iṣẹ́ Àyànfúnni No. 3.
ÌMỌ̀RÀN ÀTI ÀWỌN Ọ̀RỌ̀ ÀKÍYÈSÍ: Lẹ́yìn iṣẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ kọ̀ọ̀kan, alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ yóò fún wọn ní ìmọ̀ràn pàtó, kò pọn dandan pé kí ó tẹ̀ lé ìtòlẹ́sẹẹsẹ àwọn ìmọ̀ràn ìtẹ̀síwájú tí a tò sínú ìwé Imọran Ọrọ Sisọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ní láti pọkàn pọ̀ sórí àwọn àgbègbè tí ó yẹ fún akẹ́kọ̀ọ́ náà láti mú sunwọ̀n sí i. Bí ó bá jẹ́ “D” nìkan ni ó tọ́ sí akẹ́kọ̀ọ́ náà, tí kò sì sí ànímọ́ ọ̀rọ̀ sísọ mìíràn tí a kọ “S” tàbí “Ṣ” sí, nígbà náà, olùgbaninímọ̀ràn ní láti yí àmì róbótó yípo àpótí, níbi tí a máa ń kọ “D,” “S,” tàbí “Ṣ” sí, tí ó wà níwájú ànímọ́ ọ̀rọ̀ sísọ tí akẹ́kọ̀ọ́ náà yóò ṣiṣẹ́ lé lórí tẹ̀ lé e. Òun yóò fi èyí tó akẹ́kọ̀ọ́ náà létí ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ yẹn, yóò sì tún kọ ànímọ́ ọ̀rọ̀ sísọ yìí sórí ìwé Iṣẹ́-Àyànfúnni Ilé-Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́-Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọrun (S-89-YR) tí akẹ́kọ̀ọ́ náà yóò gbà tẹ̀ lé e. Àwọn tí ó níṣẹ́ ní láti jókòó ní apá iwájú gbọ̀ngàn náà. Èyí kì yóò jẹ́ kí a fi àkókò ṣòfò, yóò sì mú kí ó ṣeé ṣe fún alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ láti fún akẹ́kọ̀ọ́ kọ̀ọ̀kan nímọ̀ràn ní tààràtà. Bí àkókò bá ṣe yọ̀ọ̀da sí, lẹ́yìn fífúnni ní ìmọ̀ràn aláfẹnusọ tí ó pọn dandan, olùgbaninímọ̀ràn lè sọ̀rọ̀ lórí àwọn kókó tí ó kún fún ẹ̀kọ́ tí ó sì gbéṣẹ́, tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà kò mẹ́nu kàn. Alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ ní láti ṣọ́ra láti má ṣe lò ju ìṣẹ́jú méjì lọ fún ìmọ̀ràn àti àwọn ọ̀rọ̀ àkíyèsí ṣókí èyíkéyìí mìíràn, lẹ́yìn iṣẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ kọ̀ọ̀kan. Bí ìgbékalẹ̀ àwọn kókó pàtàkì láti inú Bibeli kò bá rí bí ó ṣe yẹ kí ó rí, a lè fúnni ní ìmọ̀ràn ìdákọ́ńkọ́.
MÍMÚRA ÀWỌN IṢẸ́ ÀYÀNFÚNNI SÍLẸ̀: Ṣáájú mímúra iṣẹ́ tí a yàn fún un sílẹ̀, akẹ́kọ̀ọ́ náà gbọ́dọ̀ fara balẹ̀ ka àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ inú Iwe-Amọna Ile Ẹkọ tí ó sọ̀rọ̀ nípa ànímọ́ ọ̀rọ̀ sísọ tí ó fẹ́ ṣiṣẹ́ lé lórí. Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí a fún ní Iṣẹ́ Àyànfúnni No. 2 lè yan ẹṣin ọ̀rọ̀ kan tí ó bá apá ibi tí wọ́n fẹ́ kà nínú Bibeli mu. Àwọn iṣẹ́ àyànfúnni yòókù ni a óò sọ ní ìbámu pẹ̀lú ẹṣin ọ̀rọ̀ tí a fi hàn lórí ìtòlẹ́sẹẹsẹ tí a tẹ̀.
ÌDÍWỌ̀N ÀKÓKÒ: Kò sí ẹni tí ó gbọ́dọ̀ kọjá àkókò, títí kan ìmọ̀ràn àti ọ̀rọ̀ àkíyèsí olùgbaninímọ̀ràn. A ní láti fi ọgbọ́n dá Iṣẹ́ Àyànfúnni No. 2 títí dé 4 dúró nígbà tí àkókò bá tó. Ẹni tí a yàn láti fúnni ní àmì ìdádúró ní láti ṣe bẹ́ẹ̀ ní kánmọ́. Nígbà tí àwọn arákùnrin tí ń bójú tó Iṣẹ́ Àyànfúnni No. 1 àti àwọn kókó pàtàkì láti inú Bibeli bá kọjá àkókò, a ní láti fún wọn ní ìmọ̀ràn ìdákọ́nkọ́. Olúkúlùkù ní láti ṣàkíyèsí ìdíwọ̀n àkókò rẹ̀ dáradára. Àròpọ̀ àkókò ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà jẹ́: ìṣẹ́jú 45, láìní orin àti àdúrà nínú.
ÀTÚNYẸ̀WÒ ALÁKỌSÍLẸ̀: A óò máa ṣe àtúnyẹ̀wò alákọsílẹ̀, láti ìgbà-dé-ìgbà. Ní mímúra sílẹ̀, ṣàtúnyẹ̀wò àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ tí a yàn, kí o sì parí Bibeli kíkà tí a là lẹ́sẹẹsẹ. Bibeli nìkan ni a lè lò lákòókò àtúnyẹ̀wò oníṣẹ̀ẹ́jú 25 yìí. Ìyókù àkókò náà ni a óò lò fún jíjíròrò àwọn ìbéèrè àti ìdáhùn. Akẹ́kọ̀ọ́ kọ̀ọ̀kan yóò máàkì ìwé tirẹ̀. Alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ yóò ṣàyẹ̀wò ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè àtúnyẹ̀wò náà pẹ̀lú àwùjọ, yóò sì pọkàn pọ̀ sórí àwọn ìbéèrè tí ó nira jù lọ, ní ríran gbogbo àwùjọ lọ́wọ́ láti lóye ìdáhùn náà dáradára. Fún ìdí kan, bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé àwọn àyíká ipò àdúgbò mú kí ó pọn dandan, a lè ṣe àtúnyẹ̀wò alákọsílẹ̀ náà ní ọ̀sẹ̀ kan lẹ́yìn àkókò tí a fi hàn lórí ìtòlẹ́sẹẹsẹ.
ÀWỌN ÌJỌ ŃLÁ: Àwọn ìjọ tí ó ní iye akẹ́kọ̀ọ́ tí ó tó 50 tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, tí ó forúkọ sílẹ̀ ní ilé ẹ̀kọ́, lè fẹ́ láti ṣètò fún àfikún àwùjọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ láti ṣe iṣẹ́ àyànfúnni wọn níwájú àwọn olùgbaninímọ̀ràn míràn. Gẹ́gẹ́ bí a ti lè retí, àwọn tí kò tí ì ṣe ìrìbọmi, tí ìgbésí ayé wọn wà ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà Kristian, lè forúkọ sílẹ̀ pẹ̀lú ní ilé ẹ̀kọ́, kí a sì fún wọn níṣẹ́.
ÀWỌN TÍ KÒ WÁ: Gbogbo àwọn tí ó wà nínú ìjọ lè fi ìmọrírì hàn fún ilé ẹ̀kọ́ yìí, nípa sísapá láti máa wà níbẹ̀ ní gbogbo àkókò ìjókòó ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀, nípa mímúra iṣẹ́ àyànfúnni wọn sílẹ̀ dáradára, àti nípa kíkópa nínú àwọn apá tí ó ní ìbéèrè nínú. A retí pé gbogbo àwọn akẹ́kọ̀ọ́ yóò jẹ́ kí iṣẹ́ àyànfúnni wọn jẹ wọ́n lọ́kàn. Bí akẹ́kọ̀ọ́ kan kò bá wá nígbà tí a ṣètò rẹ̀ sí, olùyọ̀ọ̀da ara ẹni kan lè gba iṣẹ́ náà ṣe, ní ṣíṣe àmúlò kókó èyíkéyìí tí ó rò pé òun tóótun láti lò láàárín irú àkókò ìfitónilétí kúkúrú bẹ́ẹ̀. Tàbí kẹ̀, alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ lè kárí àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ náà pẹ̀lú ìlọ́wọ́sí yíyẹ láti ọ̀dọ̀ àwùjọ.
ÌTÒLẸ́SẸẸSẸ
*td—“Awọn Àkòrí Ọ̀rọ̀ Bibeli fún Ìjíròrò,” gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nínú Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki ní Ìtumọ̀ Ayé Titun
Jan. 1 Bibeli kíkà: Jeremiah 13 sí 15
Orin No. 213
No. 1: Bí Ìṣọ̀kan Kristian Tòótọ́ Ṣe Ṣeé Ṣe (uw-YR ojú ìwé 5 sí 7 ìpínrọ̀ 1 sí 7)
No. 2: Jeremiah 14:10-22
No. 3: *td 40A Ohun Tí Ọkàn Jẹ́
No. 4: Ọlọrun Bẹrẹ Si Ṣe Awọn Nkan (my-YR Ìtàn 1)
Jan. 8 Bibeli kíkà: Jeremiah 16 sí 19
Orin No. 163
No. 1: Àwọn Ohun Tí Ó Ṣe Kókó fún Ìṣọ̀kan Kristian (uw-YR ojú ìwé 8 ìpínrọ̀ 8 sí 8[3])
No. 2: Jeremiah 18:1-17
No. 3: *td 40B Ìyàtọ̀ Tí Ó Wà Láàárín Ọkàn àti Ẹ̀mí
No. 4: Ọgbà Ẹlẹ́wà Kan (my-YR Ìtàn 2)
Jan. 15 Bibeli kíkà: Jeremiah 20 sí 22
Orin No. 186
No. 1: Àwọn Kókó Mìíràn Tí Ó So Àwọn Kristian Pọ̀ Ṣọ̀kan (uw-YR ojú ìwé 9 ìpínrọ̀ 8[4] sí 9)
No. 2: Jeremiah 20:1-13
No. 3: *td 13A Ohun Tí Ẹ̀mí Jẹ́
No. 4: Ọkunrin ati Obinrin Kinni (my-YR Ìtàn 3)
Jan. 22 Bibeli kíkà: Jeremiah 23 sí 25
Orin No. 89
No. 1: Yẹra fún Àwọn Agbára Ìdarí Onípinyà (uw-YR ojú ìwé 10 àti 11, ìpínrọ̀ 10 sí 12)
No. 2: Jeremiah 23:16-32
No. 3: *td 13B Ipá Ìwàláàyè ni A Ń Pè Ní Ẹ̀mí
No. 4: Idi Ti Wọn Fi Padanu Ile Wọn (my-YR Ìtàn 4)
Jan. 29 Bibeli kíkà: Jeremiah 26 sí 28
Orin No. 97
No. 1: Irú Ẹni Tí Jehofa Jẹ́ (uw-YR ojú ìwé 12 àti 13, ìpínrọ̀ 1 sí 4)
No. 2: Jeremiah 26:1-16
No. 3: *td 13D A Gbọ́dọ̀ Kọ Ìbẹ́mìílò Sílẹ̀ Bí Iṣẹ́ Àwọn Ẹ̀mí Èṣù
No. 4: Igbesi Aye Lile Koko Bẹrẹ (my-YR Ìtàn 5)
Feb. 5 Bibeli kíkà: Jeremiah 29 sí 31
Orin No. 35
No. 1: Fara Wé Àpẹẹrẹ Ìfẹ́ẹ Jehofa (uw-YR ojú ìwé 14 àti 15, ìpínrọ̀ 5 sí 7)
No. 2: Jeremiah 31:27-40
No. 3: *td 36A Ọlọrun, Baba Náà, Ẹni Kan, Tí Ó Tóbi Jù Lọ Ní Àgbáyé
No. 4: Ọmọ Rere ati Ọmọ Buburu Kan (my-YR Ìtàn 6)
Feb. 12 Bibeli kíkà: Jeremiah 32 àti 33
Orin No. 166
No. 1: Fi Òtítọ́ Nípa Ọlọrun Kọ́ Àwọn Ènìyàn (uw-YR ojú ìwé 15 sí 17, ìpínrọ̀ 8 sí 11[2])
No. 2: Jeremiah 33:1-3, 14-26
No. 3: *td 36B Ọmọkùnrin Rẹlẹ̀ Sí Baba Ṣáájú àti Lẹ́yìn Wíwá Sí Ilẹ̀ Ayé
No. 4: Ọkunrin Onigboya Kan (my-YR Ìtàn 7)
Feb. 19 Bibeli kíkà: Jeremiah 34 sí 37
Orin No. 85
No. 1: Jehofa Kan Ṣoṣo ni Ó Wà (uw-YR ojú ìwé 17 àti 18, ìpínrọ̀ 11[3] sí 12)
No. 2: Jeremiah 35:1-11, 17-19
No. 3: *td 36D Jíjẹ́ Ọ̀kan Ọlọrun àti Kristi
No. 4: Awọn Òmìrán Lí Ayé (my-YR Ìtàn 8)
Feb. 26 Bibeli kíkà: Jeremiah 38 sí 41
Orin No. 117
No. 1: Ohun Tí Rírìn Ní Orúkọ Ọlọrun Túmọ̀ Sí (uw-YR ojú ìwé 18 àti 19, ìpínrọ̀ 13 sí 15)
No. 2: Jeremiah 38:1-13
No. 3: *td 36E Ẹ̀mí Ọlọrun ni Ipá Agbéṣẹ́ṣe Rẹ̀
No. 4: Noa Kan Ọkọ̀ Kan (my-YR Ìtàn 9)
Mar. 4 Bibeli kíkà: Jeremiah 42 sí 45
Orin No. 44
No. 1: Ran Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́ Láti Gba Bibeli Gẹ́gẹ́ Bí Ọ̀rọ̀ Ọlọrun (uw-YR ojú ìwé 20 sí 22, ìpínrọ̀ 1 sí 6)
No. 2: Jeremiah 43:1-13
No. 3: *td 31A Ta ni Ń Fa Wàhálà Ayé?
No. 4: Ikun-Omi Nla Naa (my-YR Ìtàn 10)
Mar. 11 Bibeli kíkà: Jeremiah 46 sí 48
Orin No. 46
No. 1: Ka Bibeli Lójoojúmọ́ (uw-YR ojú ìwé 23 sí 25, ìpínrọ̀ 7 sí 11)
No. 2: Jeremiah 48:1-15
No. 3: *td 31B Ìdí Tí A Fi Fàyè Gba Ìwà Burúkú
No. 4: Oṣumare Kinni (my-YR Ìtàn 11)
Mar. 18 Bibeli kíkà: Jeremiah 49 àti 50
Orin No. 175
No. 1: Kẹ́kọ̀ọ́ Láti Mọ̀ Nípa Jehofa (uw-YR ojú ìwé 25 àti 26, ìpínrọ̀ 12 àti 12[1])
No. 2: Jeremiah 49:1-11, 15-18
No. 3: *td 31D Àkókò Òpin Tí A Fà Gùn Jẹ́ Ìpèsè Aláàánú
No. 4: Awọn Eniyan Kọ Ile-Iṣọ Nla (my-YR Ìtàn 12)
Mar. 25 Bibeli kíkà: Jeremiah 51 àti 52
Orin No. 70
No. 1: w-YR 4/1/88 ojú ìwé 15 sí 20
No. 2: Jeremiah 51:41-57
No. 3: *td 31E Àtúnṣe Sí Wàhálà Ayé Kì Í Ṣe Láti Ọwọ́ Ènìyàn
No. 4: Abrahamu—Ọ̀rẹ́ Ọlọrun (my-YR Ìtàn 13)
Apr. 1 Bibeli kíkà: Ẹkún Jeremiah 1 àti 2
Orin No. 170
No. 1: w-YR 9/1/88 ojú ìwé 26 àti 27 (láìfi àpótí kún un)
No. 2: Ẹkún Jeremiah 2:13-22
No. 3: *td 19A Gbogbo Kristian Gbọ́dọ̀ Jẹ́rìí
No. 4: Ọlọrun Dán Igbagbọ Abrahamu Wò (my-YR Ìtàn 14)
Apr. 8 Bibeli kíkà: Ẹkún Jeremiah 3 sí 5
Orin No. 140
No. 1: w-YR 9/1/88 ojú ìwé 27 (àpótí)
No. 2: Ẹkún Jeremiah 5:1-22
No. 3: *td 19B Àìní Wà fún Ìbẹ̀wò Léraléra, Ìjẹ́rìí Àìdabọ̀
No. 4: Aya Lọti Bojuwo Ẹhin (my-YR Ìtàn 15)
Apr. 15 Bibeli kíkà: Esekieli 1 sí 4
Orin No. 112
No. 1: w-YR 9/15/88 ojú ìwé 10 sí 12, ìpínrọ̀ 1 sí 11
No. 2: Esekieli 3:16-27
No. 3: *td 19D A Gbọ́dọ̀ Jẹ́rìí Kí A Lè Mórí Bọ́ Kúrò Nínú Ẹ̀bi Ẹ̀jẹ̀
No. 4: Isaaki Rí Aya Rere Kan Fẹ́ (my-YR Ìtàn 16)
Apr. 22 Bibeli kíkà: Esekieli 5 sí 8
Orin No. 180
No. 1: Gbé Ẹṣin Ọ̀rọ̀ Bibeli àti Àyíká Ọ̀rọ̀ Ìwé Mímọ́ Yẹ̀ Wò (uw-YR ojú ìwé 26, ìpínrọ̀ 12[2] àti 12[3])
No. 2: Esekieli 5:1-15
No. 3: *td 21A Ìjọsìn Àwọn Baba Ńlá Jẹ́ Asán
No. 4: Awọn Ibeji Ti Wọ́n Yatọ (my-YR Ìtàn 17)
Apr. 29 Àtúnyẹ̀wò Alákọsílẹ̀. Parí Jeremiah 13 sí Esekieli 8
Orin No. 113
May 6 Bibeli kíkà: Esekieli 9 sí 11
Orin No. 124
No. 1: Fi Àwọn Ohun Tí O Ń Kọ́ Sílò Kí O Sì Ṣàjọpín Rẹ̀ Pẹ̀lú Àwọn Ẹlòmíràn (uw-YR ojú ìwé 26 sí 28, ìpínrọ̀ 12[4] sí 13)
No. 2: Esekieli 9:1-11
No. 3: Ọlọrun Ń Fẹ́ Kí O Ní Ọjọ́ Ọ̀la Aláyọ̀ (kl-YR ojú ìwé 6 àti 7, ìpínrọ̀ 1 sí 5)
No. 4: Jakọbu Lọ Si Harani (my-YR Ìtàn 18)
May 13 Bibeli kíkà: Esekieli 12 sí 14
Orin No. 105
No. 1: Ohun Tí Àwọn Wòlíì Sọ Nípa Jesu (uw-YR ojú ìwé 29 sí 31, ìpínrọ̀ 1 sí 6)
No. 2: Esekieli 14:1-14
No. 3: Ìyè Àìnípẹ̀kun Nínú Paradise—Kì í Ṣe Àlá (kl-YR ojú ìwé 7 sí 9, ìpínrọ̀ 6 sí 10)
No. 4: Jakọbu Ní Idile Nla Kan (my-YR Ìtàn 19)
May 20 Bibeli kíkà: Esekieli 15 àti 16
Orin No. 149
No. 1: Fiyè Sí Àwọn Àwòkọ́ṣe Alásọtẹ́lẹ̀ (uw-YR ojú ìwé 32 àti 33, ìpínrọ̀ 7 sí 8[2])
No. 2: Esekieli 16:46-63
No. 3: Bí Ìgbésí Ayé Yóò Ṣe Rí Nínú Paradise (kl-YR ojú ìwé 9 àti 10, ìpínrọ̀ 11 sí 16)
No. 4: Dina Kó Sinu Ijọngbọn (my-YR Ìtàn 20)
May 27 Bibeli kíkà: Esekieli 17 sí 19
Orin No. 120
No. 1: Òjìji Ìṣáájú fún Àlùfáà Àgbà Wa (uw-YR ojú ìwé 33, ìpínrọ̀ 8[3] àti 8[4])
No. 2: Esekieli 18:21-32
No. 3: Ìdí Tí Ìmọ̀ Ọlọrun fi Ṣe Kókó (kl-YR ojú ìwé 10 àti 11, ìpínrọ̀ 17 sí 19)
No. 4: Awọn Ẹ̀gbọ́n Josẹfu Korira Rẹ̀ (my-YR Ìtàn 21)
June 3 Bibeli kíkà: Esekieli 20 àti 21
Orin No. 144
No. 1: Bí A Ṣe Lè Fi Ìgbàgbọ́ Wa Hàn Nínú Kristi (uw-YR ojú ìwé 33 sí 37, ìpínrọ̀ 9 sí 14)
No. 2: Esekieli 21:18-32
No. 3: Ìwé Tí Ó Ṣí Ìmọ̀ Ọlọrun Payá (kl-YR ojú ìwé 12 àti 13, ìpínrọ̀ 1 sí 6)
No. 4: A Ju Josẹfu Si Ẹ̀wọ̀n (my-YR Ìtàn 22)
June 10 Bibeli kíkà: Esekieli 22 àti 23
Orin No. 222
No. 1: Ìgbọràn Sí Ọlọrun Ń Mú Òmìnira Tòótọ́ Wá (uw-YR ojú ìwé 38 sí 40, ìpínrọ̀ 1 sí 5)
No. 2: Esekieli 22:17-31
No. 3: Ohun Tí Bibeli Ṣí Payá Nípa Ọlọrun (kl-YR ojú ìwé 13 sí 15, ìpínrọ̀ 7 sí 9)
No. 4: Awọn Àlá Farao (my-YR Ìtàn 23)
June 17 Bibeli kíkà: Esekieli 24 sí 26
Orin No. 160
No. 1: Ibi Tí A Ti Lè Rí Òmìnira Tòótọ́ Lónìí (uw-YR ojú ìwé 40 sí 42, ìpínrọ̀ 6 sí 9)
No. 2: Esekieli 26:1-14
No. 3: Ìdí Tí O Fi Lè Gbẹ́kẹ̀ Lé Bibeli (kl-YR ojú ìwé 15 àti 16, ìpínrọ̀ 10 sí 13)
No. 4: Josẹfu Dán Awọn Ẹ̀gbọ́n Rẹ̀ Wò (my-YR Ìtàn 24)
June 24 Bibeli kíkà: Esekieli 27 sí 29
Orin No. 159
No. 1: Ìsìnrú ni Òmìnira Ayé Jẹ́ Ní Ti Gidi (uw-YR ojú ìwé 42 àti 43, ìpínrọ̀ 10 sí 12)
No. 2: Esekieli 29:1-16
No. 3: Bibeli Péye Ó Sì Ṣeé Fọkàn Tẹ̀ (kl-YR ojú ìwé 17, ìpínrọ̀ 14, 15)
No. 4: Idile Naa Ṣí Lọ Si Egipti (my-YR Ìtàn 25)
July 1 Bibeli kíkà: Esekieli 30 sí 32
Orin No. 132
No. 1: Bí A Ṣe Lè Dá Ẹgbẹ́ Búburú Mọ̀ Yàtọ̀ (uw-YR ojú ìwé 44 àti 45, ìpínrọ̀ 13, 14)
No. 2: Esekieli 31:1-14
No. 3: Bibeli Jẹ́ Ìwé Àsọtẹ́lẹ̀ (kl-YR ojú ìwé 17 àti 18, ìpínrọ̀ 16 sí 18)
No. 4: Jobu Ṣe Olóòtọ́ Si Ọlọrun (my-YR Ìtàn 26)
July 8 Bibeli kíkà: Esekieli 33 àti 34
Orin No. 84
No. 1: Àríyànjiyàn Tí Gbogbo Ẹ̀dá Ní Láti Dojú Kọ (uw-YR ojú ìwé 46 àti 47, ìpínrọ̀ 1 sí 3)
No. 2: Esekieli 34:17-30
No. 3: Àwọn Àsọtẹ́lẹ̀ Bibeli Nípa Jesu (kl-YR ojú ìwé 19 sí 21, ìpínrọ̀ 19, 20)
No. 4: Ọba Buburu Kan Jẹ Ni Egipti (my-YR Ìtàn 27)
July 15 Bibeli kíkà: Esekieli 35 sí 37
Orin No. 38
No. 1: Fara Wé Ìgbàgbọ́ Àwọn Adúróṣinṣin (uw-YR ojú ìwé 47 sí 52, ìpínrọ̀ 4 sí 11)
No. 2: Esekieli 35:1-15
No. 3: Ní Ìyánhànhàn fún Ìmọ̀ Ọlọrun (kl-YR ojú ìwé 21 àti 22, ìpínrọ̀ 21 sí 23)
No. 4: Bi A Ṣe Gba Mose Ọmọ-Ọwọ Là (my-YR Ìtàn 28)
July 22 Bibeli kíkà: Esekieli 38 àti 39
Orin No. 26
No. 1: Bíbọlá fún Jehofa Nípa Ìwà Wa (uw-YR ojú ìwé 52 sí 54, ìpínrọ̀ 12 sí 15)
No. 2: Esekieli 38:1-4, 10-12, 18-23
No. 3: Ọlọrun Tòótọ́ Náà àti Orúkọ Rẹ̀ (kl-YR ojú ìwé 23 àti 24, ìpínrọ̀ 1 sí 5)
No. 4: Idi Rẹ̀ Ti Mose Fi Salọ (my-YR Ìtàn 29)
July 29 Bibeli kíkà: Esekieli 40 sí 44
Orin No. 67
No. 1: Ohun Tí Gbígbà Tí Ọlọrun Gba Ìwà Ibi Láàyè Fi Kọ́ Wa (uw-YR ojú ìwé 55 sí 57, ìpínrọ̀ 1 sí 7)
No. 2: Esekieli 40:1-15
No. 3: Ìdí Tí Ó Fi Yẹ Kí O Lo Orúkọ Ọlọrun (kl-YR ojú ìwé 24 àti 25, ìpínrọ̀ 6 sí 8)
No. 4: Igbó Naa Ti O Ńjó (my-YR Ìtàn 30)
Aug. 5 Bibeli kíkà: Esekieli 45 sí 48
Orin No. 63
No. 1: w-YR 9/15/88 ojú ìwé 22 sí 27
No. 2: Esekieli 47:1-12
No. 3: Bí Jehofa Ṣe Sọ Orúkọ Rẹ̀ Di Ńlá (kl-YR ojú ìwé 25 sí 27, ìpínrọ̀ 9 sí 13)
No. 4: Mose ati Aaroni Lọ Ri Farao (my-YR Ìtàn 31)
Aug. 12 Bibeli kíkà: Danieli 1 àti 2
Orin No. 102
No. 1: w-YR 12/1/88 ojú ìwé 11 sí 14
No. 2: Danieli 2:31-45
No. 3: Àwọn Ànímọ́ Ọlọrun Tòótọ́ Náà (kl-YR ojú ìwé 27 àti 28, ìpínrọ̀ 14 sí 16)
No. 4: Awọn Iyọnu Mẹ́wàá (my-YR Ìtàn 32)
Aug. 19 Bibeli kíkà: Danieli 3 àti 4
Orin No. 41
No. 1: Kò Sí Àìṣòdodo Pẹ̀lú Ọlọrun Rí (uw-YR ojú ìwé 58 sí 61, ìpínrọ̀ 8 sí 16)
No. 2: Danieli 3:16-30
No. 3: Jehofa Ọlọrun Jẹ́ Aláàánú àti Olóore Ọ̀fẹ́ (kl-YR ojú ìwé 28 àti 29, ìpínrọ̀ 17 sí 19)
No. 4: Líla Òkun Pupa Já (my-YR Ìtàn 33)
Aug. 26 Àtúnyẹ̀wò Alákọsílẹ̀. Parí Esekieli 9 sí Danieli 4
Orin No. 114
Sept. 2 Bibeli kíkà: Danieli 5 àti 6
Orin No. 56
No. 1: Yẹra fún Àwọn Agbo Ọmọ Ogun Ẹ̀mí Burúkú (uw-YR ojú ìwé 62 sí 64, ìpínrọ̀ 1 sí 5)
No. 2: Danieli 6:4-11, 16, 19-23
No. 3: Jehofa Lọ́ra Láti Bínú, Kì Í Ṣe Ojúsàájú, Ó Sì Jẹ́ Olódodo (kl-YR ojú ìwé 30, ìpínrọ̀ 20, 21)
No. 4: Iru Ounjẹ Titun Kan (my-YR Ìtàn 34)
Sept. 9 Bibeli kíkà: Danieli 7 àti 8
Orin No. 138
No. 1: Wà Lójúfò Sí Àwọn Ètekéte Eṣu (uw-YR ojú ìwé 64 sí 67, ìpínrọ̀ 6 sí 12
No. 2: Danieli 7:2-14
No. 3: Jehofa Ọlọrun Jẹ́ Ọ̀kan (kl-YR ojú ìwé 30 àti 31, ìpínrọ̀ 22, 23)
No. 4: Jehofah Fi Awọn Ofin Rẹ̀ Lelẹ (my-YR Ìtàn 35)
Sept. 16 Bibeli kíkà: Danieli 9 àti 10
Orin No. 123
No. 1: Gbé Gbogbo Ìhámọ́ra Ogun Láti Ọ̀dọ̀ Ọlọrun Wọ̀ (uw-YR ojú ìwé 67 sí 69, ìpínrọ̀ 13 sí 15)
No. 2: Danieli 9:20-27
No. 3: Jesu Kristi Ni Kọ́kọ́rọ́ Sí Ìmọ̀ Ọlọrun (kl-YR ojú ìwé 32 àti 33, ìpínrọ̀ 1 sí 3)
No. 4: Ère Ọmọ Maluu Oniwura (my-YR Ìtàn 36)
Sept. 23 Bibeli kíkà: Danieli 11 àti 12
Orin No. 88
No. 1: w-YR 12/1/88 ojú ìwé 15 sí 20
No. 2: Danieli 12:1-13
No. 3: Messia Tí A Ṣèlérí Náà (kl-YR ojú ìwé 33, ìpínrọ̀ 4, 5)
No. 4: Àgọ́ Kan fun Ijọsin (my-YR Ìtàn 37)
Sept. 30 Bibeli kíkà: Hosea 1 sí 5
Orin No. 50
No. 1: w-YR 3/1/89 ojú ìwé 14 àti 15
No. 2: Hosea 5:1-15
No. 3: Ìlà Ìran Jesu Fi Í Hàn Gẹ́gẹ́ Bí Messia (kl-YR ojú ìwé 33 àti 34, ìpínrọ̀ 6)
No. 4: Awọn Amí Mejila (my-YR Ìtàn 38)
Oct. 7 Bibeli kíkà: Hosea 6 sí 10
Orin No. 185
No. 1: Ìmọ̀, Ìgbàgbọ́, àti Àjíǹde (uw-YR ojú ìwé 70 sí 73, ìpínrọ̀ 1 sí 7)
No. 2: Hosea 8:1-14
No. 3: Àsọtẹ́lẹ̀ Tí Ó Ní Ìmúṣẹ Fi Jesu Hàn Gẹ́gẹ́ Bí Messia (kl-YR ojú ìwé 34 sí 36, ìpínrọ̀ 7, 8)
No. 4: Ọ̀pá Aaroni Yọ Òdòdó (my-YR Ìtàn 39)
Oct. 14 Bibeli kíkà: Hosea 11 sí 14
Orin No. 146
No. 1: w-YR 3/1/90 ojú ìwé 14, ìpínrọ̀ 17 sí 20
No. 2: Hosea 11:1-12
No. 3: Ẹ̀rí Síwájú Sí I Pé Jesu ni Messia (kl-YR ojú ìwé 36, ìpínrọ̀ 9)
No. 4: Mose Lu Àpáta (my-YR Ìtàn 40)
Oct. 21 Bibeli kíkà: Joeli 1 sí 3
Orin No. 143
No. 1: w-YR 3/1/89 ojú ìwé 30 àti 31
No. 2: Joeli 2:1-11, 28-32
No. 3: Jehofa Jẹ́rìí Sí Ọmọkùnrin Rẹ̀ (kl-YR ojú ìwé 38, ìpínrọ̀ 10, 11)
No. 4: Ejò Idẹ Naa (my-YR Ìtàn 41)
Oct. 28 Bibeli kíkà: Amosi 1 sí 5
Orin No. 151
No. 1: w-YR 4/1/89 ojú ìwé 22 àti 23 (láìfi àpótí kún un)
No. 2: Amosi 3:1-15
No. 3: Wíwàláàyè Jesu Ṣáájú Dídi Ènìyàn (kl-YR ojú ìwé 39, ìpínrọ̀ 12 sí 14)
No. 4: Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ Kan Sọrọ (my-YR Ìtàn 42)
Nov. 4 Bibeli kíkà: Amosi 6 sí 9
Orin No. 212
No. 1: w-YR 4/1/89 ojú ìwé 22 (àpótí)
No. 2: Amosi 8:1-14
No. 3: Ipa Ọ̀nà Ìgbésí Ayé Jesu Lórí Ilẹ̀ Ayé (kl-YR ojú ìwé 40 àti 41, ìpínrọ̀ 15 sí 17)
No. 4: Joṣua Di Aṣaaju (my-YR Ìtàn 43)
Nov. 11 Bibeli kíkà: Obadiah sí Jona 4
Orin No. 215
No. 1: w-YR 4/15/89 ojú ìwé 30 àti 31
No. 2: Jona 3:10; 4:1-11
No. 3: Jesu Wàláàyè Ó Sì Ń Ṣàkóso Gẹ́gẹ́ Bí Ọba (kl-YR ojú ìwé 41 àti 42, ìpínrọ̀ 18 sí 20)
No. 4: Rahabu Fi Awọn Amí Pamọ (my-YR Ìtàn 44)
Nov. 18 Bibeli kíkà: Mika 1 sí 4
Orin No. 139
No. 1: w-YR 5/1/89 ojú ìwé 14 àti 15 (láìfi àpótí kún un)
No. 2: Mika 4:1-12
No. 3: Ìjọsìn Tí Ọlọrun Tẹ́wọ́ Gbà (kl-YR ojú ìwé 43 sí 45, ìpínrọ̀ 1 sí 5)
No. 4: Líla Odò Jordani Kọja (my-YR Ìtàn 45)
Nov. 25 Bibeli kíkà: Mika 5 sí 7
Orin No. 162
No. 1: w-YR 5/1/89 ojú ìwé 14 (àpótí)
No. 2: Mika 6:1-16
No. 3: Ṣíṣe Ìfẹ́ Inú Ọlọrun (kl-YR ojú ìwé 46 àti 47, ìpínrọ̀ 6 sí 10)
No. 4: Awọn Odi Jeriko (my-YR Ìtàn 46)
Dec. 2 Bibeli kíkà: Nahumu 1 sí 3
Orin No. 168
No. 1: w-YR 5/15/89 ojú ìwé 24 àti 25
No. 2: Nahumu 1:2-14
No. 3: Jọ́sìn Ọlọrun Ní Ọ̀nà Tirẹ̀ (kl-YR ojú ìwé 47 àti 48, ìpínrọ̀ 11 sí 13)
No. 4: Olè Kan Ní Israeli (my-YR Ìtàn 47)
Dec. 9 Bibeli kíkà: Habakkuku 1 sí 3
Orin No. 47
No. 1: w-YR 5/15/89 ojú ìwé 25
No. 2: Habakkuku 1:12–2:8
No. 3: Ṣọ́ra fún Mímú Ọlọrun Bínú (kl-YR ojú ìwé 49 àti 50, ìpínrọ̀ 14 sí 17)
No. 4: Awọn Ara Gibeoni Ọlọgbọn (my-YR Ìtàn 48)
Dec. 16 Bibeli kíkà: Sefaniah 1 sí 3
Orin No. 172
No. 1: w-YR 6/1/89 ojú ìwé 30 àti 31
No. 2: Sefaniah 1:7-18
No. 3: Pa Àwọn Ọ̀pá Ìdiwọ̀n Gíga Ọlọrun Mọ́ (kl-YR ojú ìwé 50 àti 51, ìpínrọ̀ 18, 19)
No. 4: Oòrùn Duro Sojukan (my-YR Ìtàn 49)
Dec. 23 Bibeli kíkà: Haggai 1 àti 2
Orin No. 152
No. 1: w-YR 6/1/89 ojú ìwé 31
No. 2: Haggai 2:6-19.
No. 3: Jọ́sìn Jehofa Tọkàntọkàn (kl-YR ojú ìwé 51 àti 52, ìpínrọ̀ 20 sí 22)
No. 4: Awọn Obinrin Onigboya Meji (my-YR Ìtàn 50)
Dec. 30 Àtúnyẹ̀wò Alákọsílẹ̀. Parí Danieli 5 sí Haggai 2
Orin No. 34