Àwọn Ìfilọ̀
◼ Àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a óò fi lọni ní April àti May: Gbogbo èdè—Àsansílẹ̀ owó fún Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Jẹ́ kí ìwé pẹlẹbẹ Béèrè wà lárọ̀ọ́wọ́tó fún àwọn tí ó fi ìfẹ́ hàn, kí o sì sapá láti bẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé. June: Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun.
◼ Kí akọ̀wé ìjọ rí i pé ìjọ ní àwọn fọ́ọ̀mù aṣáájú ọ̀nà tí ó tẹ̀ lé e wọ̀nyí tí ó tó lọ́wọ́: Ìwé Ìwọṣẹ́ fún Iṣẹ́ Ìsìn Aṣáájú Ọ̀nà Déédéé (S-205), Ìwé Ìwọṣẹ́ Iṣẹ́ Ìsìn Aṣáájú Ọ̀nà Olùrànlọ́wọ́ (S-205b), àti Notification for Discontinuing Regular Pioneer Service (S-206). A lè béèrè fún èyí lórí Literature Request Form (S-14). Ó kéré tán kí ẹ ní èyí tí ẹ lè lò fún ọdún kan lọ́wọ́. Kí ẹ yẹ àwọn fọ́ọ̀mù ìforúkọsílẹ̀ fún iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà déédéé wò láti rí i dájú pé ó pé. Bí àwọn tí ń forúkọ sílẹ̀ kò bá rántí ọjọ́ tí wọ́n ṣe ìrìbọmi, kí wọ́n fojú bu déètì kan kí wọ́n sì tọ́jú rẹ̀ pa mọ́.
◼ Ní Saturday, May 29, a óò ti ilé Bẹ́tẹ́lì pa. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ má ṣe wá ṣèbẹ̀wò, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe wá ra ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ ní déètì yìí.