ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 4/99 ojú ìwé 2
  • Àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Oṣù April

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Oṣù April
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1999
  • Ìsọ̀rí
  • Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní April 5
  • Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní April 12
  • Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní April 19
  • Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní April 26
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1999
km 4/99 ojú ìwé 2

Àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Oṣù April

Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní April 5

Orin 55

10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Àwọn Ìfilọ̀ tí a yàn láti inú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Ké sí gbogbo àwọn olùfìfẹ́hàn láti wá gbọ́ àkànṣe àsọyé fún gbogbo ènìyàn ní April 18. Àkòrí àsọyé náà ni “Ìbádọ́rẹ̀ẹ́ Tòótọ́ Pẹ̀lú Ọlọ́run àti Aládùúgbò.”

15 min: “Fi Ìháragàgà Wàásù Ìhìn Rere Náà.” Fi nǹkan bí ìṣẹ́jú kan nasẹ̀ àpilẹ̀kọ náà, kí ìjíròrò lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn sì tẹ̀ lé e. Parí ìjíròrò náà pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ìṣírí tó wà nínú Iwe-Amọna Ile Ẹkọ, ojú ìwé 191 àti 192, ìpínrọ̀ 12 àti 13.

20 min: “Bí Àwọn Mẹ́ńbà Ìdílé Ṣe Máa Ń Fọwọ́ Sowọ́ Pọ̀ Láti Kópa Kíkún—Nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Náà.” Ìjíròrò tí agbo ìdílé kan ṣe. Ṣàgbéyẹ̀wò ìdí tí ìdílé fi ní láti ka iṣẹ́ ìsìn pápá si ìgbòkègbodò ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ tí gbogbo wọ́n ní láti kópa nínú rẹ̀ déédéé. Ṣàtúnyẹ̀wò ìṣírí tí a fúnni nínú Ilé-Ìṣọ́nà, September 1, 1993, ojú ìwé 17 sí 19, ìpínrọ̀ 9 sí 12. Ké sí àwọn òbí tó wà láwùjọ láti ṣàlàyé bí wọ́n ṣe ṣàṣeyọrí ní ṣíṣètò ìgbòkègbodò iṣẹ́ ìsìn ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ fún ìdílé wọn.

Orin 67 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní April 12

Orin 112

10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò.

15 min: Fọ̀rọ̀ Wá Àwọn Aṣáájú Ọ̀nà Olùrànlọ́wọ́ Lẹ́nu Wò. Alábòójútó iṣẹ́ ìsìn fọ̀rọ̀ wá àwọn akéde kan tí wọ́n ń ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ nínú oṣù yìí àti àwọn tí wọ́n ti ṣe bẹ́ẹ̀ tẹ́lẹ̀ lẹ́nu wò. Pè wọ́n láti sọ àwọn ìbùkún tí wọ́n ti gbádùn, àwọn àṣeyọrí tí wọ́n ti ṣe, àti ìdí tí wọ́n tún fi ń fojú sọ́nà láti tún ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́, ó kéré tán ní oṣù kan tàbí méjì lọ́dọọdún.

20 min: “Jíjáramọ́ Iṣẹ́ Ìjẹ́rìí bi Òpin Ti Ń Sún Mọ́lé.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Fọ̀rọ̀ wá akéde kan tàbí méjì lẹ́nu wò, àwọn tó jẹ́ pé nígbà kan, wọn kò lè finú wòye pé àwọn yóò kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù, àmọ́ tí wọ́n ń ṣe bẹ́ẹ̀ déédéé nísinsìnyí nítorí pé wọ́n ti wá mọrírì bí sísọ ìhìn rere Ìjọba náà ṣe jẹ́ kánjúkánjú tó. Bí àkókò bá ti yọ̀ǹda tó, fi àwọn ìrírí tí ó ṣe ṣókí kún un láti inú 1997 Yearbook, ojú ìwé 42 sí 48, tí ń fi bí àwọn akéde ṣe túbọ̀ ń járamọ́ iṣẹ́ ìjẹ́rìí tí wọ́n ń ṣe hàn nípa lílọ sí ibi tí àwọn ènìyàn wà.

Orin 93 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní April 19

Orin 79

10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Ìròyìn ìnáwó.

10 min: “O Ha Ní Iye Ìwé Ìròyìn Pàtó Tí O Ń Gbà Bí?” Àsọyé, ó sàn jù kó jẹ́ alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí ń bójú tó ìwé ìròyìn ni yóò sọ ọ́. Jẹ́ kí ìjọ mọ iye ìwé ìròyìn tí a ń gbà lóṣù kọ̀ọ̀kan àti ìpíndọ́gba iye tí a ń ròyìn pé a fi sóde. A kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìwé ìròyìn ṣòfò. Pèsè ìmọ̀ràn tí ń fi bí a ṣe lè fi àwọn ẹ̀dà tí ó ti pẹ́ sóde hàn.—Wo Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti July 1993, ojú ìwé 1.

25 min: “Iṣẹ́ Aṣáájú Ọ̀nà Jẹ́ Fífọgbọ́n Lo Àkókò Wa!” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Yan àwọn ẹni mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ láti sọ àwọn ìrírí tó wà ní ìpínrọ̀ 5 sí 7. Ní ìparí ọ̀rọ̀ rẹ, rọ gbogbo àwọn tí wọ́n bá lè ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ tàbí aṣáájú ọ̀nà déédéé láti gbé ṣíṣe bẹ́ẹ̀ yẹ̀ wò. Ìwé ìforúkọsílẹ̀ wà lárọ̀ọ́wọ́tó lọ́dọ̀ èyíkéyìí lára mẹ́ńbà Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn Ìjọ. Mẹ́nu bà á pé kò tí ì pẹ́ jù láti fìwé sílẹ̀ fún wíwọṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ni May.

Orin 165 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní April 26

Orin 70

10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Rán gbogbo gbòò létí láti fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn toṣù April sílẹ̀. Kéde orúkọ àwọn tí yóò ṣe iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ní oṣù May, kí o sì gba àwọn yòókù níyànjú láti forúkọ sílẹ̀. Fúnni ní àwọn àbá wíwúlò kan tí a lè lò láti fi àwọn ìwé ìròyìn lọ́ọ́lọ́ọ́ lọni.—Wo Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti October 1996, ojú ìwé 8.

15 min: “Kí Ni Kí N Ṣe?” Lẹ́yìn ṣíṣàyẹ̀wò àpilẹ̀kọ náà ní ṣókí pẹ̀lú àwùjọ, ṣàkíyèsí ọ̀dọ́langba kan tó ń bá àwọn òbí rẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa ìwéwèé rẹ̀ fún ọjọ́ iwájú nígbà tó bá jáde ní ilé ẹ̀kọ́ girama. Wọ́n jùmọ̀ ṣàtúnyẹ̀wò Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti July 1998, ojú ìwé 4. Òbí fún un nímọ̀ràn tó bá ìṣírí tó wà nínú Ilé-Ìṣọ́nà, February 1, 1996, ojú ìwé 14, àti ti December 1, 1996, ojú ìwé 17 sí 19 mu. Nísinsìnyí tí wákàtí tí a béèrè lọ́wọ́ aṣáájú ọ̀nà ti dín kù, ọ̀dọ́langba yìí ń ronú nípa bí ó ṣe lè ṣeé ṣe fún òun láti ṣe aṣáájú ọ̀nà nígbà tí òun ṣì wà ní ilé ẹ̀kọ́.

20 min: “Ìpinnu Wa—Láti Máa Rìn ní Ọ̀nà Ìgbésí Ayé Tí Jèhófà Fẹ́.” Àsọyé. Fi gbígba gbogbo ìjọ níyànjú láti máa wá sí àwọn ìpàdé márààrún tí ìjọ ń ṣe déédéé kún un.

Orin 173 àti àdúrà ìparí.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́