Àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Oṣù June
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní June 7
Orin 45
10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Àwọn Ìfilọ̀ tí a yàn láti inú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Jíròrò “Ran Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Jàǹfààní Láti Inú Ìwé Pẹlẹbẹ Kí Ní Ń Ṣẹlẹ̀ sí Wa Nígbà Tí A Bá Kú?”
15 min: “Jèhófà Ń Kọ́ Wa.” Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì mú kí ìjíròrò lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn tẹ̀ lé e. Ké sí àwùjọ láti sọ díẹ̀ nínú àwọn àǹfààní tí wọ́n ti jẹ láti inú Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run, Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Ìsìn Aṣáájú Ọ̀nà, Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Tẹnu mọ́ bí ìwọ̀nyí ti ṣe ran àwọn èèyàn Jèhófà lọ́wọ́ láti túbọ̀ gbéṣẹ́ sí i nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́.
20 min: “Lo Àkókò Rẹ Lọ́nà Gbígbéṣẹ́.” Ìjíròrò láàárín olùdarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ kan àti akéde kan tàbí méjì tí ó nírìírí tí wọ́n ṣàlàyé nípa bí wọ́n ṣe ń lo àkókò wọn láti nípìn-ín dáadáa bó bá ti lè ṣeé ṣe tó nínú iṣẹ́ ìsìn pápá. Wọ́n ṣàlàyé bí ìtòlẹ́sẹẹsẹ tó gbéṣẹ́ ti ṣe pàtàkì tó, wọ́n sì tẹnu mọ́ ọn pé ó yẹ kéèyàn ní irú rẹ̀. Wọ́n sọ bí wọ́n ṣe yẹra fún àwọn nǹkan tí ń fi àkókò ṣòfò, irú bíi pípẹ́ẹ́ bẹ̀rẹ̀, ìmúrasílẹ̀ tí kò mọ́yán lórí, tàbí títàkúrọ̀sọ jù lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́. Ní ṣíṣàgbéyẹ̀wò àyíká ipò ìjọ, dá àbá tó ṣeé mú lò nípa bí a ṣe lè lo àkókò lọ́nà gbígbéṣẹ́.
Orin 48 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní June 14
Orin 63
10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Ìròyìn Ìṣàkóso Ọlọ́run. Bí ìjọ bá ní ẹ̀dà ìwé Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè tàbí ìwé Igba Ewe lọ́wọ́, fi hàn bí a ṣe lè lò wọ́n lọ́nà gbígbéṣẹ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ní àwọn àkókò tí àwọn ọmọ ilé ìwé ti gba ọlidé, ìgbà tó túbọ̀ ṣeé ṣe láti bá àwọn ọ̀dọ́langba nílé.
15 min: Àwọn àìní àdúgbò.
20 min: “Ṣé O Lè Ṣèrànwọ́?” Kí alàgbà darí ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Fi àwọn àbá tí a dá nínú Jí!, October 8, 1995, ojú ìwé 8 àti 9, lórí ríran àwọn òbí anìkàntọ́mọ lọ́wọ́ kún un. Ké sí àwọn díẹ̀ láti sọ ìmọrírì tí wọ́n ní fún ìrànwọ́ onífẹ̀ẹ́ tí wọ́n ti rí gbà láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹlòmíràn nínú ìjọ.
Orin 53 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní June 21
Orin 72
10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Ìròyìn ìnáwó.
17 min: Lo Àwọn Fídíò àti Kásẹ́ẹ̀tì Àwòkẹ́kọ̀ọ́ Dáadáa. Lọ́nà tó túbọ̀ dára sí i, a ha lè lo àwọn fídíò mẹ́wàá àti kásẹ́ẹ̀tì àwòkẹ́kọ̀ọ́ mọ́kànlá tí Society ti ṣe? Ṣé ìwọ àti ìdílé rẹ ti wo gbogbo fídíò náà tàbí ṣé ẹ ti gbọ́ gbogbo kásẹ́ẹ̀tì náà? Ṣàyẹ̀wò àwọn àkọlé díẹ̀, sọ bí wọ́n ṣe lè mú kí Bíbélì kíkà wa sunwọ̀n sí i, bí wọ́n ṣe ń fún ipò tẹ̀mí wa lókun, tí wọ́n sì ń jẹ́rìí dáadáa sí òtítọ́. Sọ pé kí àwùjọ sọ nípa fídíò tàbí àwòkẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n rí i pé ó gbéṣẹ́ ní pàtàkì láti fún ìdílé wọn níṣìírí tàbí láti darí àwọn ẹni tuntun sínú ètò àjọ náà. Sọ àwọn ìrírí díẹ̀ tó fi àṣeyọrí hàn. (Wo ìwé Yearbook ti 1999, ojú ìwé 51 àti 52.) Fún gbogbo ìjọ níṣìírí láti lo àwọn fídíò àti kásẹ́ẹ̀tì àwòkẹ́kọ̀ọ́.
18 min: “Ṣé Ìrísí Nìkan Lo Máa Ń Wò?” Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Tẹnu mọ́ àwọn ìdí tí a kò fi gbọ́dọ̀ yára ní èrò kan nípa àwọn èèyàn tí a ń bá pàdé. Ní ṣókí, ṣàtúnyẹ̀wò ẹ̀kọ́ tí Jèhófà fi kọ́ Jónà, ẹni tó fi àìtọ́ dájọ́ àwọn tó rò pé wọ́n jẹ́ aláìyẹ. (Wo Ilé Ìṣọ́, August 15, 1997, ojú ìwé 21 àti 22, ìpínrọ̀ 17 sí 19.) Ké sí àwùjọ láti sọ nípa onírúurú èèyàn tí wọ́n ti bá pàdé ní ìpínlẹ̀ wọn, kí wọ́n sọ bí àwọn ṣe ní èrò rere nípa àwọn èèyàn náà, tí àwọn sì fi ìdájọ́ sílẹ̀ fún Jèhófà.
Orin 77 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní June 28
Orin 85
12 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Rán gbogbo akéde létí láti fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá toṣù June sílẹ̀. Ṣàyẹ̀wò ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a óò fi lọni ní oṣù July. Fi àwọn ìwé tí a óò fi lọni lákànṣe tí ìjọ yóò lò hàn, kí o sì dábàá ohun kan tàbí méjì tí a lè tẹnu mọ́ nínú ìgbékalẹ̀ wa. Fi àṣefihàn kan tí a ti fi dánra wò dáadáa kún un.
13 min: Èé Ṣe Tí Jèhófà Fi Ń Fàyè Gba Ṣíṣe Inúnibíni sí Àwọn Èèyàn Rẹ̀? Àsọyé tí alàgbà sọ, tí a gbé karí ìwé Jehovah’s Witnesses—Proclaimers of God’s Kingdom, ojú ìwé 676 àti 677. Gẹ́gẹ́ bí Jésù ti sọ tẹ́lẹ̀, ‘gbogbo orílẹ̀-èdè ló kórìíra wa.’ (Mát. 24:9) A lè kojú àtakò nígbà tí a bá ń nípìn-ín nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́, nígbà tí a bá ń ní àjọṣe pẹ̀lú àwọn ìbátan wa tó jẹ́ ẹni ayé, tàbí nígbà tí a bá ń ní àjọṣe pẹ̀lú àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí ní ibi iṣẹ́ àti ní ilé ẹ̀kọ́. Lọ́nà tó dára, olùbánisọ̀rọ̀ ṣàlàyé ìdí tí Jèhófà fi ń fàyè gba irú inúnibíni tàbí àtakò bẹ́ẹ̀ àti bí yóò ṣe yọrí sí ìbùkún nígbẹ̀yìngbẹ́yín bí a bá fara dà á.
20 min: Lọ sí Ibi Tí Àwọn Èèyàn Wà! Àsọyé tí a gbé karí ìwé Yearbook ti ọdún 1997, ojú ìwé 42 sí 48. Nígbà tó jẹ́ pé a ní láti máa bá a nìṣó láti nípìn-ín déédéé nínú ìjẹ́rìí ilé dé ilé, ó tún yẹ kí a máa fi ìháragàgà wá àǹfààní láti jẹ́rìí láìjẹ́ bí àṣà—nígbàkigbà àti níbikíbi. Sọ àwọn ìrírí láti inú ìwé Yearbook yìí tó fi bí àwọn ẹlòmíràn ti ṣe é láṣeyọrí nígbà tí wọ́n wọkọ̀ èrò, nígbà tí wọ́n ń lọ lójú pópó tàbí tí wọ́n wà létí òkun, nígbà tí wọ́n lọ sídìí àwọn ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tó wà lórí ìdúró, nígbà tí wọ́n lọ sí ibi tí àwọn ọkọ̀ ẹrù gbé ń dúró, àti nípa kíkọ lẹ́tà. Bí àkókò bá ṣe wà tó, ké sí àwùjọ láti sọ àwọn ìrírí díẹ̀ tí wọ́n ti ní. Fún gbogbo àwùjọ níṣìírí láti lo gbogbo àǹfààní wọn láti máa jẹ́rìí níbikíbi tí àwọn èèyàn bá wà.
Orin 75 àti àdúrà ìparí.