Àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Oṣù August
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní August 2
Orin 39
10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Àwọn Ìfilọ̀ tí a yàn láti inú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Sọ̀rọ̀ nípa ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá oṣù April lórílẹ̀-èdè yìí àti níjọ yín. Fún gbogbo akéde níṣìírí pé kí wọ́n nípìn-ín nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá ní oṣù August.
17 min: “Gbé Orúkọ Rírẹwà Jèhófà Ga Gidigidi.” Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò rẹ̀ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn. Ṣàlàyé àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí a tọ́ka sí.—Wo ìwé Walaaye Titilae, ojú ìwé 184 àti 185.
18 min: “Lílọ sí Ilé Ìwé àti Àwọn Góńgó Rẹ Nípa Tẹ̀mí.” Bàbá kan bá ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin rẹ̀ jíròrò àpilẹ̀kọ yìí. Wọ́n tún ṣàtúnyẹ̀wò àkójọ ọ̀rọ̀ tó jẹ mọ́ ọn láti inú Jí!, December 22, 1995, ojú ìwé 7 sí 11.
Orin 148 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní August 9
Orin 138
8 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò.
12 min: Àwọn Aṣáájú Ọ̀nà Ń Ran Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́—Ìtẹ̀síwájú Wo La Ti Ní? Kí alábòójútó iṣẹ́ ìsìn sọ àsọyé kó sì fọ̀rọ̀ wá àwọn ará lẹ́nu wò. Ṣàtúnyẹ̀wò ìtọ́sọ́nà tí a pèsè nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti September 1998, ojú ìwé 8. Sọ bí a ṣe ṣe èyí nínú ìjọ kí o sì sọ ibi tí àwọn tí a ràn lọ́wọ́ tẹ̀ síwájú dé. Fọ̀rọ̀ wá aṣáájú ọ̀nà kan tàbí méjì àti díẹ̀ lára àwọn akéde tó ti jàǹfààní láti inú ìrànlọ́wọ́ wọn lẹ́nu wò. Fún àwọn tí a óò ràn lọ́wọ́ lẹ́yìn tiwọn ní ìṣírí láti lo àǹfààní ìpèsè yìí dáadáa.
25 min: “Ṣé Ọ̀nà Àtiṣe Aṣáájú Ọ̀nà Ti Ṣí Sílẹ̀ fún Ọ Báyìí?” Kí alàgbà kan jíròrò rẹ̀ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn. Lọ́nà tí ń fi ìgbọ́kànlé hàn, fi hàn pé ó ṣeé ṣe fún ọ̀pọ̀ akéde láti ṣe aṣáájú ọ̀nà. Fọ̀rọ̀ wá àwọn aṣáájú ọ̀nà lẹ́nu wò, àwọn tí wọ́n lè ṣàlàyé láti inú ìrírí àwọn fúnra wọn bí wọ́n ṣe borí àwọn ohun ìdènà tó wọ́pọ̀ tí wọ́n sì ṣàṣeyọrí. Ṣàlàyé “Àpẹẹrẹ Ìṣètò Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Aṣáájú Ọ̀nà Déédéé,” tẹnu mọ́ bí ìwéwèé tó dáa ṣe lè mú kí ọwọ́ ẹni tẹ iye wákàtí tí a ń béèrè. Ṣèfilọ̀ pé ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ láti gba ìwé ìwọṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà lè rí i gbà lẹ́yìn ìpàdé.
Orin 202 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní August 16
Orin 131
10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Ìròyìn ìnáwó. Ọ̀sẹ̀ méjì péré ló kù nínú oṣù August, nítorí náà, fún gbogbo akéde níṣìírí láti lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ kóṣù tó parí.
15 min: “Ǹjẹ́ A Mú Ọ Gbára Dì Láti Di Ẹni Tó Mọ̀ọ́kọ Mọ̀ọ́kà?” Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ, kí alábòójútó Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run bójú tó o.
20 min: Ǹjẹ́ O Máa Ń Nípìn-ín Nínú Sísọni Di Ọmọ Ẹ̀yìn? Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Lójú ìwòye ọ̀pọ̀ ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ táa ti fi sóde, ète wa gbọ́dọ̀ jẹ́ láti bẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kí a lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti jàǹfààní láti inú àwọn ìtẹ̀jáde tí wọ́n bá gbà. Jẹ́ kí àwọn akéde sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìṣòro tí ń dí wọn lọ́wọ́ tí kì í jẹ́ kí wọ́n lè darí ìkẹ́kọ̀ọ́ púpọ̀ sí i: (1) Ó máa ń ṣòro láti rí àwọn èèyàn tó fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́. (2) Àwọn èèyàn kan tó fi ìfẹ́ hàn sọ pé ọwọ́ àwọn ti di jù láti kẹ́kọ̀ọ́. (3) Lẹ́yìn tí a bá ti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ kan, ó máa ń ṣòro láti bá ẹni náà nílé kí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà lè máa lọ déédéé. Tún sọ̀rọ̀ nípa ìmọ̀lára tí àwọn akéde kan lè ní nípa iṣẹ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: (1) ‘N ò rò pé mo tóótun láti jẹ́ olùkọ́.’ (2) ‘N ò ní àkókò láti máa darí ìkẹ́kọ̀ọ́ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀.’ (3) ‘Mo máa ń lọ́ra láti ṣe àdéhùn pẹ̀lú ẹlòmíràn.’ (4) ‘Ó máa ń tẹ́ mi lọ́rùn láti kópa nínú àwọn apá mìíràn nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́.’ Dábàá tó dáa lórí bí a ṣe lè borí àwọn ohun ìdènà wọ̀nyí kí a lè nípìn-ín lẹ́nì kọ̀ọ̀kan nínú iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn. Jẹ́ kí àwọn akéde tó ti ṣàṣeyọrí ṣàlàyé ìdùnnú tí wọ́n ti rí nínú iṣẹ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.—Wo àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti December 1998, ìpínrọ̀ 3 sí 8, àti 15.
Orin 100 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní August 23
Orin 94
10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò.
15 min: Ran Àwọn Tó Ṣẹ̀ṣẹ̀ Ń Fìfẹ́ Hàn Lọ́wọ́ Láti Mọ Ìjẹ́mímọ́ Ìgbéyàwó. Alàgbà jíròrò pẹ̀lú àwùjọ láti inú ìwé Reasoning, ojú ìwé 248 sí 250. A máa ń bá àwọn tọkọtaya tí wọ́n máa ń tẹ́wọ́ gba ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà pàdé, ṣùgbọ́n tí wọn kì í tẹ̀ síwájú kíákíá nítorí pé wọ́n ń gbé papọ̀ láìṣègbéyàwó lábẹ́ òfin. Jíròrò bí a ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti lóye ìdí tí àwọn Kristẹni fi gbọ́dọ̀ ṣe ìgbéyàwó tó lọ́lá. (Wo Jí!, May 22, 1992, ojú ìwé 18 àti 19.) Dábàá nípa ohun tí a lè fọgbọ́n sọ láti ran irú àwọn tọkọtaya bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ láti mọ ìdí tí wọn kò fi lè jẹ́ apá kan ìjọ títí di ìgbà tí wọ́n bá tó ṣe ìgbéyàwó wọn lábẹ́ òfin.
20 min: “Nawọ́ Ìkésíni sí Gbogbo Àwọn Tí Òùngbẹ Ń Gbẹ.” Ṣàyẹ̀wò àpilẹ̀kọ yìí, sọ̀rọ̀ nípa bí a ṣe ṣètò àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tí a dábàá láti ru ìfẹ́ àwọn tó bá fetí sílẹ̀ sókè kó sì sún wọn gbégbèésẹ̀. Jẹ́ kí àgbàlagbà kan ṣàṣefihàn ìpínrọ̀ 2 àti 3 tàbí ìpínrọ̀ 4 àti 5 kí èwe kan sì ṣàṣefihàn ìpínrọ̀ 6.
Orin 208 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní August 30
Orin 99
10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Rán gbogbo akéde létí láti fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá toṣù August sílẹ̀. Kí gbogbo àwọn olùdarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ béèrè ìròyìn lọ́wọ́ gbogbo àwọn tó wà nínú àwùjọ wọn kí a lè kó gbogbo ìròyìn jọ ní September 6.
17 min: A Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Arákùnrin Wa. Àsọyé tí alàgbà kan sọ, kí ó ní ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ nínú, èyí tí a gbé karí Ilé-Ìṣọ́nà, December 1, 1995, ojú ìwé 15 sí 17, ìpínrọ̀ 7 sí 11. Tẹnu mọ́ àǹfààní tí tọ̀tún tòsì máa ń jẹ tí a bá mọ àwọn arákùnrin wa dáadáa, tí a bá ń ṣàjọpín ìṣírí, tí a bá sì ń ran ara wa lọ́wọ́ láti fara da àwọn àdánwò. Dábàá bí a ṣe lè ṣe èyí lọ́nà tó túbọ̀ pọ̀ sí i. Ké sí àwùjọ láti sọ àwọn ìrírí nípa bí ìṣírí onífẹ̀ẹ́ tí àwọn ẹlòmíràn fún wọn ṣe tù wọ́n lára, tó sì fún wọn lókun.
18 min: Sọ Ìdí Ìrètí Tí O Ní. Alàgbà kan fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu ọ̀dọ́langba kan tàbí méjì tí wọ́n jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ tí wọ́n ń lọ sí ilé ẹ̀kọ́ tí ìjọba ń bójú tó. Léraléra ni wọ́n ń kojú àwọn ọ̀ràn kan tí àwọn ojúgbà wọn nínú ayé ti máa ń fẹ́ láti mọ ìdí tí àwọn ọ̀dọ́langba wa ṣe yàn láti má ṣe dara pọ̀ mọ́ wọn nínú ìgbòkègbodò wọn. Bí wọ́n ti ń lo àǹfààní tó ṣí sílẹ̀ yẹn láti ṣàlàyé ìgbàgbọ́ wọn tí a gbé karí Bíbélì, àwọn ọ̀dọ́ wa ní láti dúró ṣinṣin láìyẹsẹ̀. Àwùjọ náà jíròrò bí àwọn ṣe lè fèsì tí a bá fi tábà tàbí oògùn lọ̀ wọ́n. Wọ́n ṣàtúnyẹ̀wò àlàyé tó wà nínú ìwé Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè, ojú ìwé 277 sí 281. Wọ́n ṣàlàyé bí gbígbèjà ìpinnu àwọn láti ṣe ohun tó tọ́ ṣe jẹ́ ààbò kan, tó sì jẹ́ ẹ̀rí rere nípa àwọn.
Orin 129 àti àdúrà ìparí.