ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 9/99 ojú ìwé 8
  • Ran Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́ Láti Ní Ìmọ̀ Pípéye

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ran Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́ Láti Ní Ìmọ̀ Pípéye
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1999
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1999
km 9/99 ojú ìwé 8

Ran Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́ Láti Ní Ìmọ̀ Pípéye

1 Gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣeé ṣe kí o mọ̀, ọ̀pọ̀ èèyàn tí ń gbé ní onírúurú ilẹ̀, títí kan orílẹ̀-èdè yìí, ló ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì ṣùgbọ́n tó jẹ́ pé ìwọ̀nba díẹ̀ lohun tí wọ́n mọ̀ nípa Bíbélì. Àǹfààní ló jẹ́ fún wa láti ran irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀ pípéye lóṣù September bí a ti ń fi ìwé Ìmọ̀ lọ̀ wọ́n nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́.

2 Rántí Kókó Wọ̀nyí: Kò dìgbà téèyàn lọ ṣe ìwádìí jíjinlẹ̀ nípa ọ̀pọ̀ ẹ̀sìn mìíràn tó wà lórílẹ̀-èdè yìí kó tó lè jẹ́rìí lọ́nà tó gbéṣẹ́. Gbígbé ọ̀rọ̀ òtítọ́ kalẹ̀ lọ́nà rírọrùn, pẹ̀lú ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ sábà máa ń mú ìyọrísí rere wá. Wíwulẹ̀ béèrè ìbéèrè kan tó jẹ mọ́ àwọn ìṣòro tó wà lágbègbè náà àti sísọ fónílé pé Bíbélì pèsè ojútùú lè yọrí sí ìjíròrò tó gbámúṣé. Ní ìbẹ̀rẹ̀, má ṣe jẹ́ kí ó dà bí ẹni pé ìsọfúnni tóo mú wá dára ju èyí tí onílé gbà gbọ́.

3 Lo Àwọn Irinṣẹ́ Yíyẹ: Ìsọfúnni tó wà nínú ìwé Ìmọ̀ àti ìwé pẹlẹbẹ Béèrè gba tàwọn tó jẹ́ mẹ́ńbà gbogbo ẹ̀sìn rò. A lè lo ìtẹ̀jáde wọ̀nyí láti fi ran àwọn ọ̀mọ̀wé gidi àti àwọn tí kò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀wé àti púrúǹtù pàápàá lọ́wọ́. Wọ́n kún fún àwòrán tó ṣeé lò lọ́nà gbígbéṣẹ́.

4 Bẹ̀rẹ̀ Níbi Tí Èdè Yín Ti Yéra: Kò lè nira láti rí àwọn ibi tí èdè ìwọ àti ti ọ̀pọ̀ onílé ti yéra. Wọ́n mọ̀ pé a ń gbé lákòókò tí ìwà ibi ń pọ̀ sí i àti pé gbogbo kìràkìtà ẹ̀dá láti mú ìṣòro kúrò láyé ti já sí pàbó. Níwọ̀n bí ọ̀pọ̀ jù lọ ti gbà pé ìgbésí ayé kún fáwọn ìṣòro tí kò lójútùú, wọ́n máa ń fẹ́ gbọ́ nípa ọ̀ràn ìdílé, ìwà ọ̀daràn àti ààbò, àti ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nígbà téèyàn bá kú. Ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ méjì rèé tóo lè lò.

5 Ẹni tó jẹ́ onídìílé lè nífẹ̀ẹ́ sí eléyìí:

◼ “Mo ń ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn èèyàn tí ń dààmú nípa bí ìdílé ṣe rí lónìí ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀. Kí lo rò pé ó máa so ìdílé pọ̀? [Jẹ́ kó fèsì.] Àwọn kan ní Bíbélì nílé ṣùgbọ́n wọn ò mọ ohun tó sọ nípa ìdílé rárá. Màá fẹ́ ká jọ ka ìsọfúnni yìí tó wà nínú Kólósè 3:18-21.” Tóo bá ka ẹsẹ Bíbélì yẹn tán, fi orí 15 nínú ìwé Ìmọ̀ han onílé, kí o sì sọ pé: “Ì bá wù mí láti lo àkókò díẹ̀ kí èmi pẹ̀lú rẹ lè jọ ka orí yìí.”

6 Eléyìí lè wọ ọ̀dọ́ lọ́kàn:

◼ “Ǹjẹ́ o gbà pé nítorí àìdúró sójú kan ọ̀pá ìdiwọ̀n ìwà híhù àti àìdánilójú tó rọ̀gbà yí ọjọ́ ọ̀la ká, ó pọndandan láti ní atọ́nà tó ṣeé gbára lé nínú ìgbésí ayé? [Jẹ́ kó fèsì.] Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì ni ìwé tó pẹ́ jù lọ, síbẹ̀ ó pèsè ìmọ̀ràn tó múná dóko tó bá òde ìwòyí mu, tó sì lè mú kí ìdílé láyọ̀.” Wá ṣí ìwé Ìmọ̀ sí orí 2, kí o sì ka ìpínrọ̀ 10 àti gbólóhùn àkọ́kọ́ ní ìpínrọ̀ 11, kí o sì ka 2 Tímótì 3:16, 17. Bí ó bá fìfẹ́ hàn, fi ìwé Ìmọ̀ lọ̀ ọ́, ṣàlàyé nípa ètò ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì táa ń ṣe fáwọn èèyàn lọ́fẹ̀ẹ́ nínú ilé wọn, kí o sì fi Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lọ̀ ọ́. Bí o bá ronú pé yóò sàn láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ nínú ìwé pẹlẹbẹ Béèrè, o lè ṣe bẹ́ẹ̀. Wàá rí àfikún ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ yíyẹ ní ojú ìwé 9 sí 15 nínú ìwé Reasoning.

7 Gbádùn Àbájáde Rere: Ọkùnrin ẹni ọdún méjìlélógún kan lọ bá arábìnrin kan tó ń jẹ́rìí ní ọjà, ó sì ní kó wá máa bá òun ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó sọ fún arábìnrin náà pé lọ́dún mẹ́jọ sẹ́yìn, òun fetí kọ́ ìjíròrò Bíbélì tó wáyé láàárín màmá òun àti arábìnrin náà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé inú rẹ̀ dùn sáwọn ìdáhùn tó múná dóko tí Bíbélì pèsè fáwọn ìṣòro aráyé, màmá rẹ̀ kò kọbi ara sí i, ọmọkùnrin náà sì nímọ̀lára pé òun kéré jù nígbà yẹn láti máa dá lépa òtítọ́. Nísinsìnyí tó ti tójúúbọ́, ó fẹ́ mọ̀ sí i. Ọ̀dọ́kùnrin náà kò fọ̀ràn falẹ̀ rárá. Ọjọ́ mẹ́tàlélógún péré ló fi kẹ́kọ̀ọ́ ìwé Ìmọ̀, ó sì sọ pé òun fẹ́ ṣèrìbọmi lẹ́yìn oṣù mẹ́rin péré tó bá arábìnrin yẹn pàdé lọ́jà!

8 Arákùnrin kan bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú ọkùnrin kan tó bá pàdé nínú rélùwéè. Ìgbéyàwó ọkùnrin náà ti fẹ́ forí ṣánpọ́n. Ó tún ń mu àmujù ọtí. Ọkùnrin náà gbà pé kí Ẹlẹ́rìí náà wá sílé òun, kí ó sì gba òun nímọ̀ràn látinú Bíbélì nípa ìgbésí ayé ìdílé. Àwọn ẹ̀kọ́ ìwà rere tó wà nínú Bíbélì wú u lórí, ó sì gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Òun àti ìdílé rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí jùmọ̀ lọ sáwọn ìpàdé. Nígbà tó yá, wọ́n tan òtítọ́ dé ọ̀dọ̀ ẹbí àti ọ̀rẹ́. Ní báyìí, mẹ́fà lára àwọn èèyàn yìí ló mà ti tẹ́wọ́ gba òtítọ́!

9 Ìfẹ́ Ọlọ́run ni pé “kí a gba gbogbo onírúurú ènìyàn là, kí wọ́n sì wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.” (1 Tím. 2:4) Lílò lára àwọn àbá tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí yóò fún wa láǹfààní láti ran àwọn kan lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀ pípéye tí ń sinni lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́